previous next

I. Kor 1

Ìkíni

1 PAULU, ẹniti a pè lati jẹ Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Sostene arakunrin, 2 Si ijọ enia Ọlọrun ti o wà ni Korinti, awọn ti a sọ di mimọ́ ninu Kristi Jesu, awọn ẹniti a npè li enia mimọ́, pẹlu gbogbo awọn ti npè orukọ Jesu Kristi Oluwa wa nibigbogbo, ẹniti iṣe tiwọn ati tiwa:

3 Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa wa Jesu Kristi.

Ìdúpẹ́


4 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo nitori nyin, nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun nyin ninu Jesu Kristi; 5 Nitoripe nipasẹ rẹ̀ li a ti sọ nyin di ọlọrọ̀ li ohun gbogbo, ninu ọ̀rọ-isọ gbogbo, ati ninu ìmọ gbogbo; 6 Ani gẹgẹ bi a ti fi idi ẹrí Kristi kalẹ ninu nyin: 7 Tobẹ ti ẹnyin kò fi rẹ̀hin ninu ẹ̀bunkẹbun; ti ẹ si nreti ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi: 8 Ẹniti yio si fi idi nyin kalẹ titi de opin, ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn li ọjọ Oluwa wa Jesu Kristi.

9 Olododo li Ọlọrun, nipasẹ ẹniti a pè nyin sinu ìdapọ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.

Ìyapa ninu Ìjọ


10 Mo si bẹ̀ nyin, ará, li orukọ Oluwa wa Jesu Kristi, ki gbogbo nyin mã sọ̀rọ ohun kanna, ati ki ìyapa ki o máṣe si ninu nyin; ṣugbọn ki a le ṣe nyin pé ni inu kanna, ati ni ìmọ kanna. 11 Nitori a ti fihàn mi nipa tinyin, ará mi, lati ọdọ awọn ara ile Kloe, pe ìja mbẹ larin nyin. 12 Njẹ eyi ni mo wipe, olukuluku nyin nwipe, Emi ni ti Paulu; ati emi ni ti Apollo; ati emi ni ti Kefa; ati emi ni ti Kristi. 13 A ha pin Kristi bi? iṣe Paulu li a kàn mọ agbelebu fun nyin bi? tabi li orukọ Paulu li a baptisi nyin si? 14 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe emi kò baptisi ẹnikẹni ninu nyin, bikoṣe Krispu ati Gaiu; 15 Ki ẹnikẹni ki o máṣe wipe mo ti mbaptisi li orukọ emi tikarami. 16 Mo si baptisi awọn ara ile Stefana pẹlu: lẹhin eyi emi kò mọ̀ bi mo ba baptisi ẹlomiran pẹlu.

17 Nitori Kristi kò rán mi lọ ibaptisi, bikoṣe lati wãsu ihinrere: kì iṣe nipa ọgbọ́n ọ̀rọ, ki a máṣe sọ agbelebu Kristi di alailagbara.

Kristi Ni Agbára ati Ọgbọ́n Ọlọrun


18 Nitoripe wère li ọ̀rọ agbelebu si awọn ti o nṣegbé; ṣugbọn si awa ti a ngbalà, agbara Ọlọrun ni. 19 Nitoriti a kọ ọ pe, Emi ó pa ọgbọ́n awọn ọlọ́gbọn run, emi ó si sọ òye awọn olóye di asan. 20 Ọlọ́gbọn na ha da? akọwe na ha da? ojiyan aiye yi na ha da? Ọlọrun kò ha ti sọ ọgbọ́n aiye yi di wère? 21 Nitoripe ninu ọgbọ́n Ọlọrun niwọnbi aiye kò ti mọ̀ nitori ọgbọ́n, o wù Ọlọrun nipa wère iwasu lati gbà awọn ti o gbagbọ́ là. 22 Nitoripe awọn Ju mbère àmi, awọn Hellene si nṣafẹri ọgbọ́n: 23 Ṣugbọn awa nwasu Kristi ti a kàn mọ agbelebu, ikọsẹ̀ fun awọn Ju, ati wère fun awọn Hellene, 24 Ṣugbọn fun awọn ti a pè, ati Ju ati Hellene, Kristi li agbara Ọlọrun, ati ọgbọ́n Ọlọrun. 25 Nitoripe wère Ọlọrun gbọ́n jù enia lọ; ati ailera Ọlọrun li agbara jù enia lọ. 26 Ẹ sa wo ìpè nyin, ará, bi o ti ṣepe kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọ́gbọn enia nipa ti ara, kì iṣe ọ̀pọ awọn alagbara, kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọlá li a pè: 27 Ṣugbọn Ọlọrun ti yàn awọn ohun wère aiye lati fi dãmu awọn ọlọgbọ́n; Ọlọrun si ti yàn awọn ohun ailera aiye lati fi dãmu awọn ohun ti o li agbara; 28 Ati awọn ohun aiye ti kò niyìn, ati awọn ohun ti a nkẹgàn, li Ọlọrun si ti yàn, ani, awọn ohun ti kò si, lati sọ awọn ohun ti o wà di asan: 29 Ki o máṣe si ẹlẹran-ara ti yio ṣogo niwaju rẹ̀. 30 Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa: 31 Pe, gẹgẹ bi a ti kọ ọ, Ẹniti o ba nṣogo, ki o mã ṣogo ninu Oluwa.

1 Corinthians 1

Appeal to Unity

1 Paul, called as an apostle of Jesus Christ by the will of God, and Sosthenes our brother,

2 To the church of God which is at Corinth, to those who have been sanctified in Christ Jesus, saints by calling, with all who in every place call on the name of our Lord Jesus Christ, their Lord and ours:

3 Grace to you and peace from God our Father and the Lord Jesus Christ.

4 I thank tmy God always concerning you for the grace of God which was given you in Christ Jesus,5 that in everything you were enriched in Him, in all speech and all knowledge,6 even as the testimony concerning Christ was confirmed in you,7 so that you are not lacking in any gift, awaiting eagerly the revelation of our Lord Jesus Christ,8 who will also confirm you to the end, blameless in the day of our Lord Jesus Christ.9 God is faithful, through whom you were called into fellowship with His Son, Jesus Christ our Lord.

10 Now I exhort you, brethren, by the name of our Lord Jesus Christ, that you all agree and that there be no divisions among you, but that you be made complete in the same mind and in the same judgment.11 For I have been informed concerning you, my brethren, by Chloe's people, that there are quarrels among you.12 Now I mean this, that each one of you is saying, "I am of Paul," and "I of Apollos," and "I of Cephas," and "I of Christ."13 Has Christ been divided? Paul was not crucified for you, was he? Or were you baptized in the name of Paul?14 tI thank God that I baptized none of you except Crispus and Gaius,15 so that no one would say you were baptized in my name.16 Now I did baptize also the household of Stephanas; beyond that, I do not know whether I baptized any other.17 For Christ did not send me to baptize, but to preach the gospel, not in cleverness of speech, so that the cross of Christ would not be made void.

The Wisdom of God

18 For the word of the cross is foolishness to those who are perishing, but to us who are being saved it is the power of God.19 For it is written,
"I WILL DESTROY THE WISDOM OF THE WISE,
AND THE CLEVERNESS OF THE CLEVER I WILL SET ASIDE."
20 Where is the wise man? Where is the scribe? Where is the debater of this age? Has not God made foolish the wisdom of the world?21 For since in the wisdom of God the world through its wisdom did not come to know God, God was well-pleased through the foolishness of the message preached to save those who believe.22 For indeed Jews ask for signs and Greeks search for wisdom;23 but we preach tChrist crucified, to Jews a stumbling block and to Gentiles foolishness,24 but to those who are the called, both Jews and Greeks, Christ the power of God and the wisdom of God.25 Because the foolishness of God is wiser than men, and the weakness of God is stronger than men.

26 For consider your calling, brethren, that there were not many wise according to the flesh, not many mighty, not many noble;27 but God has chosen the foolish things of the world to shame the wise, and God has chosen the weak things of the world to shame the things which are strong,28 and the base things of the world and the despised God has chosen, the things that are not, so that He may nullify the things that are,29 so that no man may boast before God.30 But by His doing you are in Christ Jesus, who became to us wisdom from God, and righteousness and sanctification, and redemption,31 so that, just as it is written, "LET HIM WHO BOASTS, BOAST IN THE LORD."