previous next

I. Kor 10

Ìkìlọ̀ Nípa Ìbọ̀rìṣà

1 NITORI emi kò fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀, ara, bi gbogbo awọn baba wa ti wà labẹ awọsanma, ti gbogbo wọn si là okun já; 2 Ti a si baptisi gbogbo wọn si Mose ninu awọsanma ati ninu okun; 3 Ti gbogbo wọn si ti jẹ onjẹ ẹmí kanna; 4 Ti gbogbo wọn si mu ohun mimu ẹmí kanna: nitoripe nwọn nmu ninu Apata ẹmí ti ntọ̀ wọn lẹhin: Kristi si li Apata na. 5 Ṣugbọn ọ̀pọlọpọ wọn ni inu Ọlọrun kò dùn si: nitoripe a bì wọn ṣubu li aginjù. 6 Nkan wọnyi si jasi apẹrẹ fun awa, ki awa ki o má bã ṣe ifẹkufẹ ohun buburu, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti ṣe ifẹkufẹ. 7 Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si jẹ abọriṣa, bi awọn miran ninu wọn; bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia na joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire. 8 Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe ṣe àgbere gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti ṣe, ti ẹgbã-mọkanla-le-ẹgbẹrun enia si ṣubu ni ijọ kan. 9 Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe dán Oluwa wò, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti dán a wò, ti a si fi ejò run wọn. 10 Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe kùn, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti kùn, ti a si ti ọwọ́ oluparun run wọn. 11 Nkan wọnyi si ṣe si wọn bi apẹrẹ fun wa: a si kọwe wọn fun ikilọ̀ awa ẹniti igbẹhin aiye de bá. 12 Nitorina ẹniti o ba rò pe on duro, ki o kiyesara, ki o má ba ṣubu. 13 Kò si idanwò kan ti o ti ibá nyin, bikoṣe irú eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti kì yio jẹ ki a dan nyin wò jù bi ẹnyin ti le gbà; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò na, ki ẹnyin ki o ba le gbà a. 14 Nitorina, ẹnyin olufẹ mi, ẹ sá fun ibọriṣa. 15 Emi nsọ̀rọ bi ẹnipe fun ọlọgbọn; ẹ gbà eyiti mo wi rò. 16 Ago ibukún ti awa nsure si, ìdapọ ẹ̀jẹ Kristi kọ́ iṣe? Akara ti awa mbù, ìdapọ ara Kristi kọ́ iṣe? 17 Nitoripe awa ti iṣe ọ̀pọlọpọ jasi akara kan, ara kan: nitoripe gbogbo wa li o jumọ npin ninu akara kan nì. 18 Ẹ wo Israeli nipa ti ara: awọn ti njẹ ohun ẹbọ, nwọn ki ha iṣe alabapin pẹpẹ? 19 Njẹ kini mo nwi? pe, ohun ti a fi rubọ si oriṣa jẹ nkan, tabi pe oriṣa jẹ nkan? 20 Ṣugbọn ohun ti mo nwi nipe, ohun ti awọn Keferi fi nrubọ, nwọn fi nrubọ si awọn ẹ̃mi èṣu, kì si iṣe si Ọlọrun: emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ba awọn ẹmi èṣu ṣe ajọpin. 21 Ẹnyin kò le mu ago Oluwa ati ago awọn ẹmi èṣu: ẹnyin kò le ṣe ajọpin ni tabili Oluwa, ati ni tabili awọn ẹmi èṣu.

22 Awa ha nmu Oluwa jowú bi? awa ha li agbara jù u lọ?

Ẹ Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọrun


23 Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ere; ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn kì iṣe ohun gbogbo ni igbé-ni-ró. 24 Ki ẹnikẹni máṣe mã wá ti ara rẹ̀, ṣugbọn ki olukuluku mã wá ire ọmọnikeji rẹ̀. 25 Ohunkohun ti a ba ntà li ọjà ni ki ẹ mã jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn. 26 Nitoripe ti Oluwa ni ilẹ ati ẹkún rẹ̀. 27 Bi ọkan ninu awọn ti kò gbagbọ́ ba pè nyin sibi àse, bi ẹnyin ba si fẹ ilọ; ohunkohun ti a ba gbé kalẹ niwaju nyin ni ki ẹ jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn. 28 Ṣugbọn bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, A ti fi eyi ṣẹbọ, ẹ máṣe jẹ ẹ nitori ẹniti o fi hàn nyin, ati nitori ẹri-ọkàn (nitoripe ti Oluwa ni ilẹ, ati ẹkún rẹ̀): 29 Mo ni, ẹri-ọkàn kì iṣe ti ara rẹ, ṣugbọn ti ẹnikeji rẹ: nitori ẽṣe ti a fi fi ẹri-ọkàn ẹlomiran dá omnira mi lẹjọ? 30 Bi emi bá fi ọpẹ jẹ ẹ, ẽṣe ti a fi nsọ̀rọ mi ni buburu nitori ohun ti emi dupẹ fun? 31 Nitorina bi ẹnyin ba njẹ, tabi bi ẹnyin ba nmu, tabi ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun. 32 Ẹ máṣe jẹ́ ohun ikọsẹ, iba ṣe fun awọn Ju, tabi fun awọn Hellene, tabi fun ijọ Ọlọrun: 33 Ani bi emi ti nwù gbogbo enia li ohun gbogbo, laiwá ere ti ara mi, bikoṣe ti ọpọlọpọ, ki a le gbà wọn lã.

1 Corinthians 10

Avoid Israel's Mistakes

1 For I do not want you to be unaware, brethren, that our fathers were all under the cloud and all passed through the sea;2 and all were baptized into Moses in the cloud and in the sea;3 and all ate the same spiritual food;4 and all drank the same spiritual drink, for they were drinking from a spiritual rock which followed them; and the rock was Christ.5 Nevertheless, with most of them God was not well-pleased; for they were laid low in the wilderness.

6 Now these things happened as examples for us, so that we would not crave evil things as they also craved.7 Do not be idolaters, as some of them were; as it is written, "THE PEOPLE SAT DOWN TO EAT AND DRINK, AND STOOD UP TO PLAY."8 Nor let us act immorally, as some of them did, and twenty-three thousand fell in one day.9 Nor let us try the Lord, as some of them did, and were destroyed by the serpents.10 Nor grumble, as some of them did, and were destroyed by the destroyer.11 Now these things happened to them as an example, and they were written for our instruction, upon whom the ends of the ages have come.12 Therefore let him who thinks he stands take heed that he does not fall.13 No temptation has overtaken you but such as is common to man; and God is faithful, who will not allow you to be tempted beyond what you are able, but with the temptation will provide the way of escape also, so that you will be able to endure it.

14 Therefore, my beloved, flee from idolatry.15 I speak as to wise men; you judge what I say.16 Is not the cup of blessing which we bless a sharing in the blood of Christ? Is not the bread which we break a sharing in the body of Christ?17 Since there is one bread, we who are many are one body; for we all partake of the one bread.18 Look at the nation Israel; are not those who eat the sacrifices sharers in the altar?19 What do I mean then? That a thing sacrificed to idols is anything, or that an idol is anything?20  No, but I say that the things which the Gentiles sacrifice, they sacrifice to demons and not to God; and I do not want you to become sharers in demons.21 You cannot drink the cup of the Lord and the cup of demons; you cannot partake of the table of the Lord and the table of demons.22 Or do we provoke the Lord to jealousy? We are not stronger than He, are we?

23 All things are lawful, but not all things are profitable. All things are lawful, but not all things edify.24 Let no one seek his own good, but that of his neighbor.25 Eat anything that is sold in the meat market without asking questions for conscience' sake;26 FOR THE EARTH IS THE LORD'S, AND ALL IT CONTAINS.27 If one of the unbelievers invites you and you want to go, eat anything that is set before you without asking questions for conscience' sake.28 But if anyone says to you, "This is meat sacrificed to idols," do not eat it, for the sake of the one who informed you, and for conscience' sake;29 I mean not your own conscience, but the other man's; for why is my freedom judged by another's conscience?30 If I partake with thankfulness, why am I slandered concerning that for which I give thanks?

31 Whether, then, you eat or drink or whatever you do, do all to the glory of God.32 Give no offense either to Jews or to Greeks or to the church of God;33 just as I also please all men in all things, not seeking my own profit but the profit of the many, so that they may be saved.