previous next

I. Kor 12

Àwọn Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́

1 NJẸ niti ẹbun ẹmí, ará, emi kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ ope. 2 Ẹnyin mọ̀ pe nigbati ẹnyin jẹ Keferi, a fà nyin lọ sọdọ awọn odi oriṣa, lọnakọna ti a fa nyin. 3 Nitorina mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe, kò si ẹniti nsọ̀rọ nipa Ẹmí Ọlọrun ki o wipe ẹni ifibu ni Jesu: ati pe, kò si ẹniti o le wipe, Oluwa ni Jesu, bikoṣe nipa Ẹmí Mimọ́. 4 Njẹ onirũru ẹ̀bun li o wà, ṣugbọn Ẹmí kanna ni. 5 Onirũru iṣẹ-iranṣẹ li ó si wà, Oluwa kanna si ni. 6 Onirũru iṣẹ li o si wà, ṣugbọn Ọlọrun kanna ni ẹniti nṣiṣẹ gbogbo wọn ninu gbogbo wọn. 7 Ṣugbọn a nfi ifihàn Ẹmí fun olukuluku enia lati fi jère. 8 Nitoriti a fi ọ̀rọ ọgbọ́n fun ẹnikan nipa Ẹmí; ati fun ẹlomiran ọ̀rọ-ìmọ nipa Ẹmí kanna; 9 Ati fun ẹlomiran igbagbọ́ nipa Ẹmí kanna; ati fun ẹlomiran ẹ̀bun imularada nipa Ẹmí kanna; 10 Ati fun ẹlomiran iṣẹ iyanu iṣe; ati fun ẹlomiran isọtẹlẹ; ati fun ẹlomiran ìmọ ẹmí yatọ; ati fun ẹlomiran onirũru ède; ati fun ẹlomiran itumọ̀ ède:

11 Ṣugbọn gbogbo wọnyi li ẹnikan nì, ani Ẹmí kanna nṣe, o npín fun olukuluku gẹgẹ bi o ti wù u.

Gbogbo Ìjọ Jẹ́ Ẹ̀yà Ara Kan


12 Nitori gẹgẹ bi ara ti jẹ ọ̀kan, ti o si li ẹ̀ya pupọ, ṣugbọn ti gbogbo ẹ̀ya ara ti iṣe pupọ jẹ́ ara kan: bẹ̃ si ni Kristi pẹlu. 13 Nitoripe ninu Ẹmí kan li a ti baptisi gbogbo wa sinu ara kan, iba ṣe Ju, tabi Hellene, iba ṣe ẹrú, tabi omnira; a si ti mú gbogbo wa mu ninu Ẹmí kan. 14 Nitoripe ara kì iṣe ẹ̀ya kan, bikoṣe pupọ. 15 Bi ẹsẹ ba wipe, Nitori emi kì iṣe ọwọ́, emi kì iṣe ti ara; eyi kò wipe ki iṣe ti ara. 16 Bi etí ba si wipe, Nitori emi ki iṣe oju, emi kì iṣe ti ara: eyi kò wipe ki iṣe ti ara. 17 Bi gbogbo ara ba jẹ oju, nibo ni igbọràn iba gbé wà? Bi gbogbo rẹ̀ ba si jẹ igbọràn, nibo ni igbõrùn iba gbé wà? 18 Ṣugbọn nisisiyi Ọlọrun ti fi awọn ẹ̀ya sinu ara, olukuluku wọn gẹgẹ bi o ti wù u. 19 Bi gbogbo wọn ba si jẹ ẹ̀ya kan, nibo li ara iba gbé wà? 20 Ṣugbọn nisisiyi, nwọn jẹ ẹya pupọ, ṣugbọn ara kan. 21 Oju kò si le wi fun ọwọ́ pe, emi kò ni ifi ọ ṣe: tabi ki ori wi ẹ̀wẹ fun ẹsẹ pe, emi kò ni ifi nyin ṣe. 22 Ṣugbọn awọn ẹ̀ya ara wọnni ti o dabi ẹnipe nwọn ṣe ailera jù, awọn li a kò le ṣe alaini jù: 23 Ati awọn ẹ̀ya ara wọnni ti awa rò pe nwọn ṣe ailọlá jù, lori wọnyi li awa si nfi ọlá si jù; bẹni ibi aiyẹ wa si ni ẹyẹ lọpọlọpọ jù. 24 Nitoripe awọn ibi ti o li ẹyẹ li ara wa kò fẹ ohun kan: ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe ara lọkan, o si fi ọ̀pọlọpọ ọlá fun ibi ti o ṣe alaini: 25 Ki ìyapa ki o máṣe si ninu ara; ṣugbọn ki awọn ẹ̀ya ara ki o le mã ṣe aniyan kanna fun ara wọn. 26 Bi ẹ̀ya kan ba si njìya, gbogbo ẹ̀ya a si jùmọ ba a jìya; tabi bi a ba mbọla fun ẹ̀ya kan, gbogbo ẹ̀ya a jùmọ ba a yọ̀. 27 Njẹ ara Kristi li ẹnyin iṣe, olukuluku nyin si jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀. 28 Ọlọrun si gbé awọn miran kalẹ ninu ijọ, ekini awọn aposteli, ekeji awọn woli, ẹkẹta awọn olukọni, lẹhinna iṣẹ iyanu, lẹhinna ẹ̀bun imularada, iranlọwọ, ẹbùn akoso, onirũru ède. 29 Gbogbo wọn ni iṣe aposteli bi? gbogbo wọn ni iṣe woli bi? gbogbo wọn ni iṣe olukọni bi? gbogbo wọn ni iṣe iṣẹ iyanu bi? 30 Gbogbo wọn li o li ẹ̀bun imularada bi? gbogbo wọn ni nfi onirũru ède fọ̀ bi? gbogbo wọn ni nṣe itumọ̀ bi? 31 Ṣugbọn ẹ mã fi itara ṣafẹri ẹ̀bun ti o tobi jù: sibẹ emi o fi ọ̀na kan ti o tayọ rekọja hàn nyin.

1 Corinthians 12

The Use of Spiritual Gifts

1 Now concerning spiritual gifts, brethren, I do not want you to be unaware.2 You know that when you were pagans, you were led astray to the mute idols, however you were led.3 Therefore I make known to you that no one speaking by the Spirit of God says, "Jesus is accursed"; and no one can say, "Jesus is Lord," except by the Holy Spirit.

4 Now there are varieties of gifts, but the same Spirit.5 And there are varieties of ministries, and the same Lord.6 There are varieties of effects, but the same God who works all things in all persons. 7 But to each one is given the manifestation of the Spirit for the common good.8 For to one is given the word of wisdom through the Spirit, and to another the word of knowledge according to the same Spirit;9 to another faith by the same Spirit, and to another gifts of healing by the one Spirit,10 and to another the effecting of miracles, and to another prophecy, and to another the distinguishing of spirits, to another various kinds of tongues, and to another the interpretation of tongues.11 But one and the same Spirit works all these things, distributing to each one individually just as He wills.

12 For even as the body is one and yet has many members, and all the members of the body, though they are many, are one body, so also is Christ.13 For by one Spirit we were all baptized into one body, whether Jews or Greeks, whether slaves or free, and we were all made to drink of one Spirit.

14 For the body is not one member, but many.15 If the foot says, "Because I am not a hand, I am not a part of the body," it is not for this reason any the less a part of the body.16 And if the ear says, "Because I am not an eye, I am not a part of the body," it is not for this reason any the less a part of the body.17 If the whole body were an eye, where would the hearing be? If the whole were hearing, where would the sense of smell be?18 But now God has placed the members, each one of them, in the body, just as He desired.19 If they were all one member, where would the body be?20 But now there are many members, but one body.21 And the eye cannot say to the hand, "I have no need of you"; or again the head to the feet, "I have no need of you."22 On the contrary, it is much truer that the members of the body which seem to be weaker are necessary;23 and those members of the body which we deem less honorable, on these we bestow more abundant honor, and our less presentable members become much more presentable,24 whereas our more presentable members have no need of it. But God has so composed the body, giving more abundant honor to that member which lacked,25 so that there may be no division in the body, but that the members may have the same care for one another.26 And if one member suffers, all the members suffer with it; if one member is honored, all the members rejoice with it.

27 Now you are Christ's body, and individually members of it.28 And God has appointed in the church, first apostles, second prophets, third teachers, then miracles, then gifts of healings, helps, administrations, various kinds of tongues.29 All are not apostles, are they? All are not prophets, are they? All are not teachers, are they? All are not workers of miracles, are they?30 All do not have gifts of healings, do they? All do not speak with tongues, do they? All do not interpret, do they?

31 But earnestly desire the greater gifts.
And I show you a still more excellent way.