I. Kor 14
Ẹ̀bùn Èdè Àjèjì ati Ti Ìsọtẹ́lẹ̀
1 Ẹ mã lepa ifẹ, ki ẹ si mã fi itara ṣafẹri ẹ̀bun ti iṣe ti Ẹmí, ṣugbọn ki ẹ kuku le mã sọtẹlẹ. 2 Nitori ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀, kò bá enia sọ̀rọ bikoṣe Ọlọrun: nitori kò si ẹniti o gbọ; ṣugbọn nipa ti Ẹmí o nsọ ohun ijinlẹ: 3 Ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ mba awọn enia sọrọ fun imuduro, ati igbiyanju, ati itunu. 4 Ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀ nfi ẹsẹ ara rẹ̀ mulẹ; ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ nfi ẹsẹ ijọ mulẹ. 5 Ṣugbọn iba wu mi ki gbogbo nyin le mã sọ oniruru ède, ṣugbọn ki ẹ kuku mã sọtẹlẹ: nitori ẹniti nsọtẹlẹ pọ̀ju ẹniti nsọ oniruru ède lọ, ayaṣebi o ba nṣe itumọ̀, ki ijọ ki o le kọ́ ẹkọ́. 6 Njẹ nisisiyi, ará, bi mo ba wá si arin nyin, ti mo si nsọrọ li ede aimọ̀, ère kili emi o jẹ fun nyin, bikoṣepe mo ba mba nyin sọrọ, yala nipa iṣipaya, tabi nipa imọ̀, tabi nipa isọtẹlẹ, tabi nipa ẹkọ́? 7 Bẹni pẹlu awọn nkan ti kò li ẹmí ti ndún, ibã ṣe fère tabi dùru, bikoṣepe ìyatọ ba wà ninu ohùn wọn, a ó ti ṣe mọ̀ ohun ti fère tabi ti dùru nwi? 8 Nitoripe bi ohùn ipè kò ba daju, tani yio mura fun ogun? 9 Bẹ̃ si li ẹnyin, bikoṣepe ẹnyin ba nfi ahọ́n nyin sọrọ ti o ye ni, a o ti ṣe mọ̀ ohun ti a nwi? nitoripe ẹnyin o sọ̀rọ si ofurufu. 10 O le jẹ pe oniruru ohùn ni mbẹ li aiye, kò si si ọ̀kan ti kò ni itumọ. 11 Njẹ bi emi kò mọ̀ itumọ ohùn na, emi o jasi alaigbede si ẹniti nsọ̀rọ, ẹniti nsọ̀rọ yio si jasi alaigbede si mi. 12 Bẹ̃ si li ẹnyin, bi ẹnyin ti ni itara fun ẹ̀bun ẹmí, ẹ mã ṣe afẹri ati mã pọ si i fun idàgbàsoke ijọ. 13 Nitorina jẹ ki ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀ gbadura ki o le mã ṣe itumọ̀. 14 Nitori bi emi ba ngbadura li ède aimọ̀, ẹmí mi ngbadura, ṣugbọn oye mi jẹ alaileso. 15 Njẹ kini rè? Emi o fi ẹmí gbadura, emi o si fi oye gbadura pẹlu: emi o fi ẹmí kọrin, emi o si fi oye kọrin pẹlu. 16 Bi bẹ̃kọ, bi iwọ ba súre nipa, ẹmí, bawo ni ẹniti mbẹ ni ipò òpe yio ṣe ṣe Amin si idupẹ rẹ, nigbati kò mọ ohun ti iwọ wi? 17 Nitori iwọ dupẹ gidigidi nitõtọ, ṣugbọn a kò fi ẹsẹ ẹnikeji rẹ mulẹ. 18 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun ti emi nfọ oniruru ede jù gbogbo nyin lọ: 19 Ṣugbọn mo fẹ ki ng kuku fi oye mi sọ ọ̀rọ marun ni ijọ, ki ng le kọ́ awọn ẹlomiran pẹlu, jù ẹgbãrun ọ̀rọ li ède aimọ̀. 20 Ará, ẹ máṣe jẹ ọmọde ni oye: ṣugbọn ẹ jẹ ọmọde li arankan, ṣugbọn ni oye ki ẹ jẹ agba. 21 A ti kọ ọ ninu ofin pe, Nipa awọn alahọn miran ati elete miran li emi ó fi bá awọn enia yi sọrọ; sibẹ nwọn kì yio gbọ temi, li Oluwa wi. 22 Nitorina awọn ahọn jasi àmi kan, kì iṣe fun awọn ti o gbagbọ́, bikoṣe fun awọn alaigbagbọ́: ṣugbọn isọtẹlẹ kì iṣe fun awọn ti kò gbagbọ́, bikoṣe fun awọn ti o gbagbọ́. 23 Njẹ bi gbogbo ijọ ba pejọ si ibi kan, ti gbogbo nwọn si nfi ède fọ̀, bi awọn ti iṣe alailẹkọ́ ati alaigbagbọ́ ba wọle wá, nwọn kì yio ha wipe ẹnyin nṣe wère? 24 Ṣugbọn bi gbogbo nyin ba nsọtẹlẹ, ti ẹnikan ti kò gbagbọ́ tabi ti kò li ẹ̀kọ́ bá wọle wá, gbogbo nyin ni yio fi òye ẹ̀ṣẹ yé e, gbogbo nyin ni yio wadi rẹ̀:
25 Bẹ̃li a si fi aṣiri ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ̃li on o si dojubolẹ yio si sin Ọlọrun, yio si sọ pe, nitotọ Ọlọrun mbẹ larin nyin.Ẹ Ṣe Ohun Gbogbo Létòlétò
26 Njẹ ẽhatiṣe, ará? nigbati ẹnyin pejọ pọ̀, ti olukuluku nyin ni psalmu kan, ẹkọ́ kan, ède kan, ifihàn kan, itumọ̀ kan. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo lati gbe-ni-ro. 27 Bi ẹnikan ba fi ède fọ̀, ki o jẹ enia meji, tabi bi o pọ̀ tan, ki o jẹ mẹta, ati eyini li ọkọ̃kan; si jẹ ki ẹnikan gbufọ. 28 Ṣugbọn bi kò ba si ogbufọ, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ninu ijọ; si jẹ ki o mã bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọrọ. 29 Jẹ ki awọn woli meji bi mẹta sọrọ, ki awọn iyoku si ṣe idajọ. 30 Bi a bá si fi ohunkohun hàn ẹniti o joko nibẹ, jẹ ki ẹni iṣaju dakẹ. 31 Gbogbo nyin le mã sọtẹlẹ li ọkọ̃kan, ki gbogbo nyin le mã kọ ẹkọ ki a le tu gbogbo nyin ni inu. 32 Ẹmí awọn woli a si ma tẹriba fun awọn woli.
33 Nitori Ọlọrun kì iṣe Ọlọrun ohun rudurudu, ṣugbọn ti alafia, gẹgẹ bi o ti jẹ ninu gbogbo ijọ enia mimọ́.Ipò Obinrin ninu Ìsìn
34 Jẹ ki awọn obinrin nyin dakẹ ninu ijọ: nitori a kò fifun wọn lati sọrọ, ṣugbọn jẹ ki wọn wà labẹ itẹriba, gẹgẹ bi ofin pẹlu ti wi. 35 Bi nwọn ba si fẹ kọ́ ohunkohun, ki nwọn ki o bère lọwọ ọkọ wọn ni ile: nitori ohun itiju ni fun awọn obinrin lati mã sọrọ ninu ijọ.
36 Kini? lọdọ nyin li ọ̀rọ Ọlọrun ti jade ni? tabi ẹnyin nikan li o tọ̀ wá?Gbolohun Ìparí Nípa Ètò Ìsìn
37 Bi ẹnikẹni ba ro ara rẹ̀ pe on jẹ woli, tabi on jẹ ẹniti o li ẹmí, jẹ ki nkan wọnyi ti mo kọ si nyin ki o ye e daju pe ofin Oluwa ni nwọn. 38 Ṣugbọn bi ẹnikan ba jẹ òpe, ẹ jẹ ki o jẹ òpe. 39 Nitorina, ará, ẹ mã fi itara ṣafẹri lati sọtẹlẹ ki ẹ má si ṣe danilẹkun lati fi ède fọ̀. 40 Ẹ mã ṣe ohun gbogbo tẹyẹtẹyẹ ati lẹsẹlẹsẹ.
1 Corinthians 14
Prophecy a Superior Gift
1 Pursue love, yet desire earnestly spiritual gifts, but especially that you may prophesy.2 For one who speaks in a tongue does not speak to men but to God; for no one understands, but in his spirit he speaks mysteries.3 But one who prophesies speaks to men for edification and exhortation and consolation.4 One who speaks in a tongue edifies himself; but one who prophesies edifies the church.5 Now I wish that you all spoke in tongues, but even more that you would prophesy; and greater is one who prophesies than one who speaks in tongues, unless he interprets, so that the church may receive edifying.
6 But now, brethren, if I come to you speaking in tongues, what will I profit you unless I speak to you either by way of revelation or of knowledge or of prophecy or of teaching?7 Yet even lifeless things, either flute or harp, in producing a sound, if they do not produce a distinction in the tones, how will it be known what is played on the flute or on the harp?8 For if the bugle produces an indistinct sound, who will prepare himself for battle?9 So also you, unless you utter by the tongue speech that is clear, how will it be known what is spoken? For you will be speaking into the air.10 There are, perhaps, a great many kinds of languages in the world, and no kind is without meaning.11 If then I do not know the meaning of the language, I will be to the one who speaks a barbarian, and the one who speaks will be a barbarian to me.12 So also you, since you are zealous of spiritual gifts, seek to abound for the edification of the church.
13 Therefore let one who speaks in a tongue pray that he may interpret.14 For if I pray in a tongue, my spirit prays, but my mind is unfruitful.15 What is the outcome then? I will pray with the spirit and I will pray with the mind also; I will sing with the spirit and I will sing with the mind also.16 Otherwise if you bless in the spirit only, how will the one who fills the place of the ungifted say the "Amen" at your giving of thanks, since he does not know what you are saying?17 For you are giving thanks well enough, but the other person is not edified.18 I thank God, I speak in tongues more than you all;19 however, in the church I desire to speak five words with my mind so that I may instruct others also, rather than ten thousand words in a tongue.
Instruction for the Church
20 Brethren, do not be children in your thinking; yet in evil be infants, but in your thinking be mature.21 In the Law it is written, "BY MEN OF STRANGE TONGUES AND BY THE LIPS OF STRANGERS I WILL SPEAK TO THIS PEOPLE, AND EVEN SO THEY WILL NOT LISTEN TO ME," says the Lord.22 So then tongues are for a sign, not to those who believe but to unbelievers; but prophecy is for a sign, not to unbelievers but to those who believe.23 Therefore if the whole church assembles together and all speak in tongues, and ungifted men or unbelievers enter, will they not say that you are mad?24 But if all prophesy, and an unbeliever or an ungifted man enters, he is convicted by all, he is called to account by all;25 the secrets of his heart are disclosed; and so he will fall on his face and worship God, declaring that God is certainly among you.
26 What is the outcome then, brethren? When you assemble, each one has a psalm, has a teaching, has a revelation, has a tongue, has an interpretation. Let all things be done for edification.27 If anyone speaks in a tongue, it should be by two or at the most three, and each in turn, and one must interpret;28 but if there is no interpreter, he must keep silent in the church; and let him speak to himself and to God.29 Let two or three prophets speak, and let the others pass judgment.30 But if a revelation is made to another who is seated, the first one must keep silent.31 For you can all prophesy one by one, so that all may learn and all may be exhorted;32 and the spirits of prophets are subject to prophets;33 for God is not a God of confusion but of peace, as in all the churches of the saints.
34 The women are to keep silent in the churches; for they are not permitted to speak, but are to subject themselves, just as the Law also says.35 If they desire to learn anything, let them ask their own husbands at home; for it is improper for a woman to speak in church.36 Was it from you that the word of God first went forth? Or has it come to you only?
37 If anyone thinks he is a prophet or spiritual, let him recognize that the things which I write to you are the Lord's commandment.38 But if anyone does not recognize this, he tis not recognized.
39 Therefore, my brethren, desire earnestly to prophesy, and do not forbid to speak in tongues.40 But all things must be done properly and in an orderly manner.