previous next

I. Kor 15

Ajinde Kristi

1 NJẸ, ará, emi nsọ ihinrere na di mimọ̀ fun nyin ti mo ti wãsu fun nyin, eyiti ẹnyin pẹlu ti gbà, ninu eyi ti ẹnyin si duro; 2 Nipaṣe eyiti a fi ngbà nyin là pẹlu, bi ẹnyin ba di ọ̀rọ ti mo ti wãsu fun nyin mú ṣinṣin, bikoṣepe ẹnyin ba gbagbọ́ lasan. 3 Nitoripe ṣiwaju ohun gbogbo mo fi eyiti emi pẹlu ti gbà le nyin lọwọ, bi Kristi ti kú nitori ẹ̀ṣẹ wa gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi; 4 Ati pe a sinkú rẹ̀, ati pe o jinde ni ijọ kẹta gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi: 5 Ati pe o farahan Kefa, lẹhin eyini awọn mejila: 6 Lẹhin eyini o farahan awọn ará ti o jù ẹ̃dẹgbẹta lọ lẹkanna; apakan ti o pọ̀ju ninu wọn wà titi fi di isisiyi, ṣugbọn awọn diẹ ti sùn. 7 Lẹhin eyini o farahan Jakọbu; lẹhinna fun gbogbo awọn Aposteli. 8 Ati nikẹhin gbogbo wọn o farahàn mi pẹlu, bi ẹni ti a bí ṣiwaju akokò rẹ̀. 9 Nitori emi li ẹniti o kere jùlọ ninu awọn Aposteli, emi ẹniti kò yẹ ti a ba pè li Aposteli, nitoriti mo ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun. 10 Ṣugbọn nipa õre-ọfẹ Ọlọrun, mo ri bi mo ti ri: õre-ọfẹ rẹ̀ ti a fifun mi kò si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ jù gbogbo wọn lọ: ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe õre-ọfẹ Ọlọrun ti o wà pẹlu mi.

11 Nitorina ibã ṣe emi tabi awọn ni, bẹ̃li awa wãsu, bẹ̃li ẹnyin si gbagbọ́.

Ajinde Òkú


12 Njẹ bi a ba nwasu Kristi pe o ti jinde kuro ninu okú, ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si? 13 Ṣugbọn bi ajinde okú kò si, njẹ Kristi kò jinde: 14 Bi Kristi kò ba si jinde, njẹ asan ni iwãsu wa, asan si ni igbagbọ́ nyin pẹlu. 15 Pẹlupẹlu a mu wa li ẹlẹri eke fun Ọlọrun; nitoriti awa jẹri Ọlọrun pe o jí Kristi dide: ẹniti on kò jí dide, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde? 16 Nitoripe bi a kò bá ji awọn oku dide, njẹ a kò jí Kristi dide: 17 Bi a kò ba si jí Kristi dide, asan ni igbagbọ́ nyin; ẹnyin wà ninu ẹ̀ṣẹ nyin sibẹ. 18 Njẹ awọn pẹlu ti o sùn ninu Kristi ṣegbé. 19 Bi o ba ṣe pe ni kìki aiye yi nikan li awa ni ireti ninu Kristi, awa jasi òtoṣi jùlọ ninu gbogbo enia. 20 Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn. 21 Nitori igbati o ti ṣepe nipa enia ni ikú ti wá, nipa enia li ajinde ninu okú si ti wá pẹlu. 22 Nitori bi gbogbo enia ti kú ninu Adamu, bẹ̃ni a ó si sọ gbogbo enia di alãye ninu Kristi. 23 Ṣugbọn olukuluku enia ni ipa tirẹ̀: Kristi akọbi; lẹhin eyini awọn ti iṣe ti Kristi ni bibọ rẹ̀. 24 Nigbana ni opin yio de, nigbati o ba ti fi ijọba fun Ọlọrun ani Baba; nigbati o ba ti mu gbogbo aṣẹ ati gbogbo ọla ati agbara kuro. 25 Nitori on kò le ṣaima jọba titi yio fi fi gbogbo awọn ọta sabẹ ẹsẹ rẹ̀. 26 Ikú ni ọtá ikẹhin ti a ó parun. 27 Nitori o ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Ṣugbọn nigbati o wipe ohun gbogbo li a fi sabẹ rẹ̀, o daju pe, on nikanṣoṣo li o kù, ti o fi ohun gbogbo si i labẹ. 28 Nigbati a ba si fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ tan, nigbana li a ó fi Ọmọ tikararẹ̀ pẹlu sabẹ ẹniti o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀, ki Ọlọrun ki o le jasi ohun gbogbo li ohun gbogbo. 29 Njẹ kili awọn ti a baptisi nitori okú yio ha ṣe, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde rara? nitori kili a ha ṣe mbaptisi wọn nitori okú? 30 Nitori kili awa si ṣe mbẹ ninu ewu ni wakati gbogbo? 31 Mo sọ nipa ayọ̀ ti mo ni lori nyin ninu Kristi Jesu Oluwa wa pe, emi nkú lojojumọ́. 32 Ki a wi bi enia, bi mo ba ẹranko jà ni Efesu, anfãni kili o jẹ́ fun mi? bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde, ẹ jẹ ki a mã jẹ, ẹ jẹ ki a mã mu; ọla li awa o sá kú. 33 Ki a má tàn nyin jẹ: ẹgbẹ́ buburu bà ìwa rere jẹ.

34 Ẹ jí iji ododo, ki ẹ má si dẹṣẹ̀; nitori awọn ẹlomiran kò ni ìmọ Ọlọrun: mo sọ eyi ki oju ki o le ti nyin.

Ara Lẹ́yìn Ajinde


35 Ṣugbọn ẹnikan yio wipe, Bawo li a o ha ji awọn okú dide? iru ara wo ni nwọn o pada si? 36 Iwọ alaimoye, ohun ti iwọ fọnrugbin ki iyè bikoṣepe o ba kú: 37 Ati eyiti iwọ fọnrugbin, ara ti mbọ̀ ki iwọ fọnrugbin, ṣugbọn irugbin lasan ni, ibã ṣe alikama, tabi irú miran. 38 Ṣugbọn Ọlọrun fun u li ara bi o ti wù u, ati fun olukuluku irú ara tirẹ̀. 39 Gbogbo ẹran-ara kì iṣe ẹran-ara kanna: ṣugbọn ọ̀tọ li ẹran-ara ti enia, ọ̀tọ li ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ ni ti ẹja, ọ̀tọ si ni ti ẹiyẹ. 40 Ara ti oke ọrun mbẹ, ara ti aiye pẹlu si mbẹ: ṣugbọn ogo ti oke ọrun ọ̀tọ, ati ogo ti aiye ọ̀tọ. 41 Ọtọ li ogo ti õrùn, ọ̀tọ li ogo ti oṣupa, ọ̀tọ si li ogo ti irawọ; irawọ sá yàtọ si irawọ li ogo. 42 Gẹgẹ bẹ̃ si li ajinde okú. A gbìn i ni idibajẹ; a si jí i dide li aidibajẹ: 43 A gbìn i li ainiyìn; a si jí i dide li ogo: a gbìn i li ailera, a si jí i dide li agbara: 44 A gbìn i li ara iyara; a si jí i dide li ara ẹmí. Bi ara iyara ba mbẹ, ara ẹmí si mbẹ. 45 Bẹ̃li a si kọ ọ pe, Adamu ọkunrin iṣaju, alãye ọkàn li a da a; Adamu ikẹhin ẹmí isọnidãye. 46 Ṣugbọn eyi ti iṣe ẹlẹmí kọ́ tète ṣaju, bikoṣe eyi ti iṣe ara iyara; lẹhinna eyi ti iṣe ẹlẹmí. 47 Ọkunrin iṣaju ti inu erupẹ̀ wá, ẹni erupẹ̀: ọkunrin ekeji Oluwa lati ọrun wá ni. 48 Bi ẹni erupẹ̀ ti ri, irú bẹ̃ si ni awọn ti iṣe ti erupẹ̀: bi ẹni ti ọrun ti ri, irú bẹ si ni awọn ti iṣe ti ọrun. 49 Bi awa si ti rù aworan ẹni erupẹ̀, bẹ̃li awa ó si ru aworan ẹni ti ọrun. 50 Ará, njẹ eyi ni mo wipe, ara on ẹ̀jẹ kò le jogún ijọba Ọlọrun; bẹ̃ni idibajẹ kò le jogún aidibajẹ. 51 Kiyesi i, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun nyin; gbogbo wa kì yio sùn, ṣugbọn gbogbo wa li a o palarada, 52 Lọgan, ni iṣẹ́ju, nigba ipè ikẹhin: nitori ipè yio dún, a o si jí awọn okú dide li aidibajẹ, a ó si pawalara dà. 53 Nitoripe ara idibajẹ yi kò le ṣaigbé aidibajẹ wọ̀, ati ara kikú yi kò le ṣaigbé ara aiku wọ̀. 54 Ṣugbọn nigbati ara idibajẹ yi ba ti gbe aidibajẹ wọ̀, ti ara kikú yi ba si ti gbe aikú wọ̀ bẹ̃ tan, nigbana ni ọ̀rọ ti a kọ yio ṣẹ pe, A gbé ikú mì ni iṣẹgun. 55 Ikú, oró rẹ dà? Isà okú, iṣẹgun rẹ dà? 56 Oró ikú li ẹ̀ṣẹ; ati agbara ẹ̀ṣẹ li ofin. 57 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun ẹniti o fi iṣẹgun fun wa nipa Oluwa wa Jesu Kristi. 58 Nitorina ẹnyin ará mi olufẹ ẹ mã duro ṣinṣin, laiyẹsẹ, ki ẹ mã pọ̀ si i ni iṣẹ Oluwa nigbagbogbo, niwọn bi ẹnyin ti mọ̀ pe iṣẹ nyin kì iṣe asan ninu Oluwa.

1 Corinthians 15

The Fact of Christ's Resurrection

1 Now I make known to you, brethren, the gospel which I preached to you, which also you received, in which also you stand,2 by which also you are saved, if you hold fast the word which I preached to you, unless you believed in vain.

3 For I delivered to you as of first importance what I also received, that Christ died for our sins according to the Scriptures,4 and that He was buried, and that He was raised on the third day according to the Scriptures,5 and that He appeared to Cephas, then to the twelve.6 After that He appeared to more than five hundred brethren at one time, most of whom remain until now, but some have fallen asleep;7 then He appeared to James, then to all the apostles;8 and last of all, as to one untimely born, He appeared to me also.9 For I am the least of the apostles, and not fit to be called an apostle, because I persecuted the church of God.10 But by the grace of God I am what I am, and His grace toward me did not prove vain; but I labored even more than all of them, yet not I, but the grace of God with me.11 Whether then it was I or they, so we preach and so you believed.

12 Now if Christ is preached, that He has been raised from the dead, how do some among you say that there is no resurrection of the dead?13 But if there is no resurrection of the dead, not even Christ has been raised;14 and if Christ has not been raised, then our preaching is vain, your faith also is vain.15 Moreover we are even found to be false witnesses of God, because we testified against God that He raised tChrist, whom He did not raise, if in fact the dead are not raised.16 For if the dead are not raised, not even Christ has been raised;17 and if Christ has not been raised, your faith is worthless; you are still in your sins.18 Then those also who have fallen asleep in Christ have perished.19 If we have hoped in Christ in this life only, we are of all men most to be pitied.

The Order of Resurrection

20 But now Christ has been raised from the dead, the first fruits of those who are asleep.21 For since by a man came death, by a man also came the resurrection of the dead.22 For as in Adam all die, so also in Christ all will be made alive.23 But each in his own order: Christ the first fruits, after that those who are Christ's at His coming,24 then comes the end, when He hands over the kingdom to the God and Father, when He has abolished all rule and all authority and power.25 For He must reign until He has put all His enemies under His feet.26 The last enemy that will be abolished is death.27 For HE HAS PUT ALL THINGS IN SUBJECTION UNDER HIS FEET. But when He says, "All things are put in subjection," it is evident that He is excepted who put all things in subjection to Him.28 When all things are subjected to Him, then the Son Himself also will be subjected to the One who subjected all things to Him, so that God may be all in all.

29 Otherwise, what will those do who are baptized for the dead? If the dead are not raised at all, why then are they baptized for them?30 Why are we also in danger every hour?31 I affirm, brethren, by the boasting in you which I have in Christ Jesus our Lord, I die daily.32 If from human motives I fought with wild beasts at Ephesus, what does it profit me? If the dead are not raised, LET US EAT AND DRINK, FOR TOMORROW WE DIE.33 Do not be deceived: "Bad company corrupts good morals."34 Become sober-minded as you ought, and stop sinning; for some have no knowledge of God. I speak this to your shame.

35 But someone will say, "How are the dead raised? And with what kind of body do they come?"36 You fool! That which you sow does not come to life unless it dies;37 and that which you sow, you do not sow the body which is to be, but a bare grain, perhaps of wheat or of something else.38 But God gives it a body just as He wished, and to each of the seeds a body of its own.39 All flesh is not the same flesh, but there is one flesh of men, and another flesh of beasts, and another flesh of birds, and another of fish.40 There are also heavenly bodies and earthly bodies, but the glory of the heavenly is one, and the glory of the earthly is another.41 There is one glory of the sun, and another glory of the moon, and another glory of the stars; for star differs from star in glory.

42 So also is the resurrection of the dead. It is sown a perishable body, it is raised an imperishable body; 43 it is sown in dishonor, it is raised in glory; it is sown in weakness, it is raised in power;44 it is sown a natural body, it is raised a spiritual body. If there is a natural body, there is also a spiritual body. 45 So also it is written, "The first MAN, Adam, BECAME A LIVING SOUL." The last Adam became a life-giving spirit.46 However, the spiritual is not first, but the natural; then the spiritual.47 The first man is from the earth, earthy; the second man is from heaven.48 As is the earthy, so also are those who are earthy; and as is the heavenly, so also are those who are heavenly.49 Just as we have borne the image of the earthy, twe will also bear the image of the heavenly.

The Mystery of Resurrection

50 Now I say this, brethren, that flesh and blood cannot inherit the kingdom of God; nor does the perishable inherit the imperishable.51 Behold, I tell you a mystery; we will not all sleep, but we will all be changed,52 in a moment, in the twinkling of an eye, at the last trumpet; for the trumpet will sound, and the dead will be raised imperishable, and we will be changed.53 For this perishable must put on the imperishable, and this mortal must put on immortality.54 But when this perishable will have put on the imperishable, and this mortal will have put on immortality, then will come about the saying that is written, "DEATH IS SWALLOWED UP in victory.55 O DEATH, WHERE IS YOUR VICTORY? O DEATH, WHERE IS YOUR STING?"56 The sting of death is sin, and the power of sin is the law;57 but thanks be to God, who gives us the victory through our Lord Jesus Christ.

58 Therefore, my beloved brethren, be steadfast, immovable, always abounding in the work of the Lord, knowing that your toil is not in vain in the Lord.