I. Kor 2
Paulu Ń Waasu Kristi Tí Wọ́n Kàn Mọ́ Agbelebu
1 ATI emi, ará, nigbati mo tọ̀ nyin wá, kì iṣe ọ̀rọ giga ati ọgbọ́n giga ni mo fi tọ̀ nyin wá, nigbati emi nsọ̀rọ ohun ijinlẹ Ọlọrun fun nyin. 2 Nitori mo ti pinnu rẹ̀ pe, emi kì yio mọ̀ ohunkohun larin nyin, bikoṣe Jesu Kristi, ẹniti a kàn mọ agbelebu. 3 Emi si wà pẹlu nyin ni ailera, ati ni ẹ̀ru, ati ni ọ̀pọlọpọ iwarìri. 4 Ati ọ̀rọ mi, ati iwasu mi kì iṣe nipa ọ̀rọ ọgbọ́n enia, ti a fi nyi ni lọkàn pada, bikoṣe nipa ifihan ti Ẹmí ati ti agbara:
5 Ki igbagbọ́ nyin ki o máṣe duro ninu ọgbọ́n enia, bikoṣe ninu agbara Ọlọrun.Àṣírí Tí Ẹ̀mí Ọlọrun Fi Hàn
6 Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n larin awọn ti o pé: ṣugbọn kì iṣe ọgbọ́n ti aiye yi, tabi ti awọn olori aiye yi, ti o di asan: 7 Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n Ọlọrun ni ijinlẹ, ani ọgbọ́n ti o farasin, eyiti Ọlọrun ti làna silẹ ṣaju ipilẹṣẹ aiye fun ogo wa: 8 Eyiti ẹnikẹni ninu awọn olori aiye yi kò mọ̀: nitori ibaṣepe nwọn ti mọ̀ ọ, nwọn kì ba ti kàn Oluwa ogo mọ agbelebu. 9 Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ, pe, Ohun ti oju kò ri, ati ti etí kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pèse silẹ fun awọn ti o fẹ ẹ. 10 Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣi wọn paya fun wa nipa Ẹmí rẹ̀: nitoripe Ẹmí ni nwadi ohun gbogbo, ani, ohun ijinlẹ ti Ọlọrun. 11 Nitori tani ninu enia ti o mọ̀ ohun enia kan, bikoṣe ẹmí enia ti o wà ninu rẹ̀? bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o mọ̀ ohun Ọlọrun, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun. 12 Ṣugbọn awa ti gbà, kì iṣe ẹmi ti aiye, bikoṣe Ẹmí ti iṣe ti Ọlọrun; ki awa ki o le mọ̀ ohun ti a fifun wa li ọfẹ lati ọdọ Ọlọrun wá. 13 Ohun na ti awa si nsọ, kì iṣe ninu ọ̀rọ ti ọgbọ́n enia nkọ́ni, ṣugbọn eyiti Ẹmí Mimọ́ fi nkọ́ni; eyiti a nfi ohun Ẹmí we ohun Ẹmí. 14 Ṣugbọn enia nipa ti ara kò gbà ohun ti Ẹmí Ọlọrun wọnni: nitoripe wère ni nwọn jasi fun u: on kò si le mọ̀ wọn, nitori nipa ti Ẹmí li a fi nwadi wọn. 15 Ṣugbọn ẹniti o wà nipa ti ẹmí nwadi ohun gbogbo, ṣugbọn kò si ẹnikẹni ti iwadi rẹ̀. 16 Nitoripe tali o mọ̀ inu Oluwa, ti yio fi mã kọ́ ọ? Ṣugbọn awa ni inu Kristi.
1 Corinthians 2
Paul's Reliance upon the Spirit
1 And when I came to you, brethren, I did not come with superiority of speech or of wisdom, proclaiming to you the ttestimony of God.2 For I determined to know nothing among you except Jesus Christ, and Him crucified.3 I was with you in weakness and in fear and in much trembling,4 and my message and my preaching were not in persuasive words of wisdom, but in demonstration of the Spirit and of power,5 so that your faith would not rest on the wisdom of men, but on the power of God.
6 Yet we do speak wisdom among those who are mature; a wisdom, however, not of this age nor of the rulers of this age, who are passing away;7 but we speak God's wisdom in a mystery, the hidden wisdom which God predestined before the ages to our glory;8 the wisdom which none of the rulers of this age has understood; for if they had understood it they would not have crucified the Lord of glory;9 but just as it is written,
"THINGS WHICH EYE HAS NOT SEEN AND EAR HAS NOT HEARD,
AND which HAVE NOT ENTERED THE HEART OF MAN,
ALL THAT GOD HAS PREPARED FOR THOSE WHO LOVE HIM."10 tFor to us God revealed them through the Spirit; for the Spirit searches all things, even the depths of God.11 For who among men knows the thoughts of a man except the spirit of the man which is in him? Even so the thoughts of God no one knows except the Spirit of God.12 Now we have received, not the spirit of the world, but the Spirit who is from God, so that we may know the things freely given to us by God,13 which things we also speak, not in words taught by human wisdom, but in those taught by the Spirit, combining spiritual thoughts with spiritual words.
14 But a natural man does not accept the things of the Spirit of God, for they are foolishness to him; and he cannot understand them, because they are spiritually appraised.15 But he who is spiritual appraises all things, yet he himself is appraised by no one.16 For WHO HAS KNOWN THE MIND OF THE LORD, THAT HE WILL INSTRUCT HIM? But we have the mind of Christ.