previous next

I. Kor 5

Paulu Ṣe Ìdájọ́ Lórí Ìwà Ìbàjẹ́

1 A nròhin rẹ̀ kalẹ pe, àgbere wà larin nyin, ati irú àgbere ti a kò tilẹ gburo rẹ̀ larin awọn Keferi, pe ẹnikan ninu nyin fẹ aya baba rẹ̀. 2 Ẹnyin si nfẹ̀ soke, ẹnyin kò kuku kãnu ki a le mu ẹniti o hu iwa yi kuro larin nyin. 3 Nitori lõtọ, bi emi kò ti si lọdọ nyin nipa ti ara, ṣugbọn ti mo wà pẹlu nyin nipa ti ẹmí, mo ti ṣe idajọ ẹniti o hu iwà yi tan, bi ẹnipe mo wà lọdọ nyin. 4 Li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa. Nigbati ẹnyin ba pejọ, ati ẹmí mi, pẹlu agbara Jesu Kristi Oluwa wa, 5 Ki ẹ fi irú enia bẹ̃ le Satani lọwọ fun iparun ara, ki a le gbà ẹmí là li ọjọ Jesu Oluwa. 6 Iṣeféfe nyin kò dara. Ẹnyin kò mọ̀ pe iwukara diẹ ni imu gbogbo iyẹfun di wiwu? 7 Nitorina ẹ mu iwukara atijọ kuro ninu nyin, ki ẹnyin ki o le jẹ́ iyẹfun titun, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ́ aiwukara. Nitori a ti fi irekọja wa, ani Kristi, rubọ fun wa. 8 Nitorina ẹ jẹ ki a ṣe ajọ na, kì iṣe pẹlu iwukara atijọ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu iwukara arankàn ati ìwa buburu; bikoṣe pẹlu aiwukara ododo ati otitọ. 9 Emi ti kọwe si nyin ninu iwe mi pe, ki ẹ máṣe ba awọn àgbere kẹgbẹ pọ̀: 10 Ṣugbọn kì iṣe pẹlu awọn àgbere aiye yi patapata, tabi pẹlu awọn olojukòkoro, tabi awọn alọnilọwọgbà, tabi awọn abọriṣa; nitori nigbana ẹ kò le ṣaima ti aiye kuro. 11 Ṣugbọn nisisiyi mo kọwe si nyin pe, bi ẹnikẹni ti a npè ni arakunrin ba jẹ àgbere, tabi olojukòkoro, tabi abọriṣa, tabi ẹlẹgàn, tabi ọmutipara, tabi alọnilọwọgbà; ki ẹ máṣe ba a kẹgbẹ; irú ẹni bẹ̃ ki ẹ má tilẹ ba a jẹun. 12 Nitori ewo ni temi lati mã ṣe idajọ awọn ti mbẹ lode? ki ha ṣe awọn ti o wà ninu li ẹnyin ṣe idajọ wọn? 13 Ṣugbọn awọn ti o wà lode li Ọlọrun nṣe idajọ wọn. Ẹ yọ enia buburu na kuro larin ara nyin.

1 Corinthians 5

Immorality Rebuked

1 It is actually reported that there is immorality among you, and immorality of such a kind as does not exist even among the Gentiles, that someone has his father's wife.2 You have become arrogant and have not mourned instead, so that the one who had done this deed would be removed from your midst.

3 For I, on my part, though absent in body but present in spirit, have already judged him who has so committed this, as though I were present.4 In the name of our Lord Jesus, when you are assembled, and I with you in spirit, with the power of our Lord Jesus,5  I have decided to deliver such a one to Satan for the destruction of his flesh, so that his spirit may be saved in the day of the Lord tJesus.

6 Your boasting is not good. Do you not know that a little leaven leavens the whole lump of dough? 7 Clean out the old leaven so that you may be a new lump, just as you are in fact unleavened. For Christ our Passover also has been sacrificed.8 Therefore let us celebrate the feast, not with old leaven, nor with the leaven of malice and wickedness, but with the unleavened bread of sincerity and truth.

9 I wrote you in my letter not to associate with immoral people;10 I did not at all mean with the immoral people of this world, or with the covetous and swindlers, or with idolaters, for then you would have to go out of the world.11 But actually, I wrote to you not to associate with any so-called brother if he is an immoral person, or covetous, or an idolater, or a reviler, or a drunkard, or a swindler-not even to eat with such a one.12 For what have I to do with judging outsiders? Do you not judge those who are within the church? 13 But those who are outside, God judges. REMOVE THE WICKED MAN FROM AMONG YOURSELVES.