I. Kor 6
Onigbagbọ Ń Pe Ara Wọn Lẹ́jọ́ Níwájú Àwọn Alaigbagbọ
1 ẸNIKẸNI ninu nyin, ti o ni ọ̀ran kan si ẹnikeji rẹ̀, ha gbọdọ lọ pè e li ẹjọ niwaju awọn alaiṣõtọ, ki o má si jẹ niwaju awọn enia mimọ́? 2 Ẹnyin kò ha mọ̀ pe awọn enia mimọ́ ni yio ṣe idajọ aiye? Njẹ bi o ba ṣepe a ó tipasẹ nyin ṣe idajọ aiye, ẹnyin ha ṣe alaiyẹ lati ṣe idajọ awọn ọ̀ran ti o kere julọ? 3 E kò mọ̀ pe awa ni yio ṣe idajọ awọn angẹli? melomelo li ohun ti iṣe ti aiye yi? 4 Njẹ bi ẹnyin ni yio ba ṣe idajọ ohun ti iṣe ti aiye yi, ẹnyin ha nyan awọn ti a kò kà si rara ninu ijọ ṣe onidajọ? 5 Mo sọ eyi fun itiju nyin. O ha le jẹ bẹ̃ pe kò si ọlọgbọn kan ninu nyin ti yio le ṣe idajọ larin awọn arakunrin rẹ̀? 6 Ṣugbọn arakunrin npè arakunrin li ẹjọ, ati eyini niwaju awọn alaigbagbọ́. 7 Njẹ nisisiyi, abuku ni fun nyin patapata pe ẹnyin mba ara nyin ṣe ẹjọ. Ẽṣe ti ẹnyin kò kuku gbà ìya? ẽṣe ti ẹnyin kò kuku jẹ ki a rẹ́ nyin jẹ? 8 Ṣugbọn ẹnyin njẹni ni ìya, ẹ sì nrẹ́ ni jẹ, ati eyini awọn arakunrin nyin. 9 Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn alaiṣõtọ kì yio jogún ijọba Ọlọrun? Ki a má tàn nyin jẹ: kì iṣe awọn àgbere, tabi awọn abọriṣa, tabi awọn panṣaga, tabi awọn alailera, tabi awọn ti nfi ọkunrin bà ara wọn jẹ́, 10 Tabi awọn olè, tabi awọn olojukòkoro, tabi awọn ọmuti, tabi awọn ẹlẹgàn, tabi awọn alọnilọwọgbà ni yio jogún ijọba Ọlọrun.
11 Bẹ̃ li awọn ẹlomiran ninu nyin si ti jẹ rí: ṣugbọn a ti wẹ̀ nyin nù, ṣugbọn a ti sọ nyin di mimọ́, ṣugbọn a ti da nyin lare li orukọ Jesu Kristi Oluwa, ati nipa Ẹmí Ọlọrun wa.Ẹ Fi Ara Yín Yin Ọlọrun
12 Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ère: ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn emi kì yio jẹ ki a fi mi sabẹ agbara ohunkohun. 13 Onjẹ fun inu, ati inu fun onjẹ: ṣugbọn Ọlọrun yio fi opin si ati inu ati onjẹ. Ṣugbọn ara kì iṣe ti àgbere, bikoṣe fun Oluwa; ati Oluwa fun ara. 14 Ṣugbọn Ọlọrun ti jí Oluwa dide, yio si jí awa dide pẹlu nipa agbara rẹ̀. 15 Ẹnyin kò mọ̀ pe ẹ̀ya-ara Kristi li ara nyin iṣe? njẹ emi o ha mu ẹ̀ya-ara Kristi, ki emi ki o si fi ṣe ẹ̀ya-ara àgbere bi? ki a má ri. 16 Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ẹniti o ba dàpọ mọ́ àgbere di ara kan? nitoriti o wipe, Awọn mejeji ni yio di ara kan. 17 Ṣugbọn ẹniti o dàpọ mọ́ Oluwa di ẹmí kan. 18 Ẹ mã sá fun àgbere. Gbogbo ẹ̀ṣẹ ti enia ndá o wà lode ara; ṣugbọn ẹniti o nṣe àgbere nṣẹ̀ si ara on tikararẹ̀. 19 Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ara nyin ni tẹmpili Ẹmí Mimọ́, ti mbẹ ninu nyin, ti ẹnyin ti gbà lọwọ Ọlọrun? ẹnyin kì si iṣe ti ara nyin, 20 Nitori a ti rà nyin ni iye kan: nitorina ẹ yìn Ọlọrun logo ninu ara nyin, ati ninu ẹmí nyin, ti iṣe ti Ọlọrun.
1 Corinthians 6
Lawsuits Discouraged
1 Does any one of you, when he has a case against his neighbor, dare to go to law before the unrighteous and not before the saints?2 Or do you not know that the saints will judge the world? If the world is judged by you, are you not competent to constitute the smallest law courts?3 Do you not know that we will judge angels? How much more matters of this life?4 So if you have law courts dealing with matters of this life, do you appoint them as judges who are of no account in the church?5 I say this to your shame. Is it so, that there is not among you one wise man who will be able to decide between his brethren,6 but brother goes to law with brother, and that before unbelievers?
7 Actually, then, it is already a defeat for you, that you have lawsuits with one another. Why not rather be wronged? Why not rather be defrauded?8 On the contrary, you yourselves wrong and defraud. You do this even to your brethren.
9 Or do you not know that the unrighteous will not inherit the kingdom of God? Do not be deceived; neither fornicators, nor idolaters, nor adulterers, nor teffeminate, nor homosexuals,10 nor thieves, nor the covetous, nor drunkards, nor revilers, nor swindlers, will inherit the kingdom of God.11 Such were some of you; but you were washed, but you were sanctified, but you were justified in the name of the Lord Jesus Christ and in the Spirit of our God.
The Body Is the Lord's
12 All things are lawful for me, but not all things are profitable. All things are lawful for me, but I will not be mastered by anything.13 Food is for the stomach and the stomach is for food, but God will do away with both of them. Yet the body is not for immorality, but for the Lord, and the Lord is for the body.14 Now God has not only raised the Lord, but will also raise us up through His power.15 Do you not know that your bodies are members of Christ? Shall I then take away the members of Christ and make them members of a prostitute? May it never be!16 Or do you not know that the one who joins himself to a prostitute is one body with her? For He says, "THE TWO SHALL BECOME ONE FLESH."17 But the one who joins himself to the Lord is one spirit with Him. 18 Flee immorality. Every other sin that a man commits is outside the body, but the immoral man sins against his own body.19 Or do you not know that your body is a temple of the Holy Spirit who is in you, whom you have from God, and that you are not your own?20 For you have been bought with a price: therefore glorify God in your body.