previous next

I. Kor 8

Oúnjẹ Tí A Fi Rúbọ fún Oriṣa

1 ṢUGBỌN niti awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe gbogbo wa li o ni ìmọ. Ìmọ a mã fẹ̀, ṣugbọn ifẹ ni gbe-ni-ro. 2 Bi ẹnikan ba si rò pe on mọ̀ ohun kan, kò ti imọ̀ bi o ti yẹ ti iba mọ̀. 3 Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba fẹ Ọlọrun, oluwarẹ̀ li o di mimọ̀ fun u. 4 Nitorina niti jijẹ awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe ohun asan li oriṣa li aiye, ati pe kò si Ọlọrun miran bikoṣe ọkanṣoṣo. 5 Nitoripe bi awọn ti a npè li ọlọrun tilẹ wà, iba ṣe li ọrun tabi li aiye (gẹgẹ bi ọ̀pọ ọlọrun ti wà ati ọ̀pọ oluwa,) 6 Ṣugbọn fun awa Ọlọrun kan ni mbẹ, Baba, lọwọ ẹniti ohun gbogbo ti wá, ati ti ẹniti gbogbo wa iṣe; ati Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ati awa nipasẹ rẹ̀. 7 Ṣugbọn ìmọ yi kò si ninu gbogbo enia: ṣugbọn awọn ẹlomiran ti o ti mbọriṣa pẹ titi fi di isisiyi jẹ ẹ bi ohun ti a fi rubọ si oriṣa; ati ẹri-ọkàn wọn ti o ṣe ailera si di alaimọ́. 8 Ṣugbọn onjẹ ki yio mu wa sunmọ Ọlọrun: nitoripe kì iṣe bi awa ba jẹ li awa san ju; tabi bi awa kò si jẹ li awa buru ju. 9 Ṣugbọn ẹ mã kiyesara ki omnira nyin yi ki o máṣe di ohun ikọsẹ fun awọn ti o ṣe ailera. 10 Nitoripe bi ẹnikan ba ri ti iwọ ti o ni ìmọ ba joko tì onjẹ ni ile oriṣa, bi on ba ṣe alailera, ọkan rẹ̀ kì yio ha duro lati mã jẹ nkan wọnni ti a fi rubọ si oriṣa? 11 Ati nipa ìmọ rẹ li alailera arakunrin, nitori ẹniti Kristi ṣe kú, yio fi ṣegbé? 12 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣẹ̀ si awọn arakunrin bẹ̃, ti ẹ si npa ọkàn wọn ti iṣe ailera lara, ẹnyin nṣẹ̀ si Kristi. 13 Nitorina, bi onjẹ ba mu arakunrin mi kọsẹ̀, emi kì yio si jẹ ẹran mọ́ titi lai, ki emi má bà mu arakunrin mi kọsẹ̀.

1 Corinthians 8

Take Care with Your Liberty

1 Now concerning things sacrificed to idols, we know that we all have knowledge. Knowledge makes arrogant, but love edifies.2 If anyone supposes that he knows anything, he has not yet known as he ought to know;3 but if anyone loves God, he is known by Him.

4 Therefore concerning the eating of things sacrificed to idols, we know that tthere is no such thing as an idol in the world, and that there is no God but one.5 For even if there are so-called gods whether in heaven or on earth, as indeed there are many gods and many lords,6 yet for us there is but one God, the Father, from whom are all things and we exist for Him; and one Lord, Jesus Christ, by whom are all things, and we exist through Him.

7 However not all men have this knowledge; but some, being accustomed to the idol until now, eat food as if it were sacrificed to an idol; and their conscience being weak is defiled.8 But food will not commend us to God; we are neither the worse if we do not eat, nor the better if we do eat.9 But take care that this liberty of yours does not somehow become a stumbling block to the weak.10 For if someone sees you, who have knowledge, dining in an idol's temple, will not his conscience, if he is weak, be strengthened to eat things sacrificed to idols?11 For through your knowledge he who is weak is ruined, the brother for whose sake Christ died.12 And so, by sinning against the brethren and wounding their conscience when it is weak, you sin against Christ.13 Therefore, if food causes my brother to stumble, I will never eat meat again, so that I will not cause my brother to stumble.