previous next

I. Joh 5

Igbagbọ ni Ìṣẹ́gun lórí Ayé

1 OLUKULUKU ẹniti o ba gbagbọ́ pe Jesu ni Kristi, a bí i nipa ti Ọlọrun: ati gbogbo ẹniti o fẹran ẹniti o bí ni, o fẹran ẹniti a bí nipasẹ rẹ̀ pẹlu. 2 Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa fẹran awọn ọmọ Ọlọrun, nigbati awa fẹran Ọlọrun, ti a si npa ofin rẹ̀ mọ́. 3 Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò si nira. 4 Nitori olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun o ṣẹgun aiye: eyi si ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aiye, ani igbagbọ́ wa.

5 Tani ẹniti o ṣẹgun aiye, bikoṣe ẹniti o gbagbọ́ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu iṣe?

Ẹ̀rí nípa Ọmọ


6 Eyi li ẹniti o wá, pẹlu omi ati ẹjẹ̀, ani Jesu Kristi, kì iṣe pẹlu omi nikan, bikoṣe pẹlu omi ati ẹ̀jẹ. Ẹmí li o si njẹri, nitoripe otitọ li Ẹmí. 7 Nitoripe awọn mẹta li o njẹri li ọrun, Baba, Ọrọ̀, ati Ẹmi Mimọ; awọn mẹtẹ̃ta yi si jẹ ọ̀kan 8 Nitoripe awọn mẹta li o njẹri, Ẹmí, ati omi, ati ẹ̀jẹ: awọn mẹtẹ̃ta sì fi ohun ṣọkan. 9 Bi awa ba ngbà ẹ̀rí enia, ẹ̀rí Ọlọrun tobi ju: nitọri ẹri Ọlọrun li eyi pe O ti jẹri niti Ọmọ rẹ̀. 10 Ẹniti o ba gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́, o ni ẹrí ninu ara rẹ̀: ẹniti kò ba gbà Ọlọrun gbọ́, o ti mu u li eke; nitori kò gbà ẹrí na gbọ́ ti Ọlọrun jẹ niti Ọmọ rẹ̀. 11 Ẹ̀rí na si li eyi pe Ọlọrun fun wa ni ìye ainipẹkun, ìye yi si mbẹ ninu Ọmọ rẹ̀.

12 Ẹniti o ba ni Ọmọ, o ni ìye; ẹniti kò ba si ni Ọmọ Ọlọrun, kò ni ìye.

Ìyè Ainipẹkun


13 Nkan wọnyi ni mo kọwe rẹ̀ si nyin ani si ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe ẹnyin ni iye ainipẹkun, ani fun ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́. 14 Eyi si ni igboiya ti awa ni niwaju rẹ̀, pe bi awa ba bère ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, o ngbọ ti wa: 15 Bi awa ba si mọ̀ pe o ngbọ́ ti wa, ohunkohun ti awa ba bère, awa mọ̀ pe awa rí ibere ti awa ti bère lọdọ rẹ̀ gbà. 16 Bi ẹnikẹni ba ri arakunrin rẹ̀ ti ndá ẹ̀ṣẹ ti kì iṣe si ikú, on o bère, On o si fun ni ìye fun awọn ti ndá ẹ̀ṣẹ ti ki iṣe si ikú. Ẹṣẹ kan mbẹ si ikú: emi kò wipe ki on ki o gbadura fun eyi. 17 Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ: ẹṣẹ̀ kan sì mbẹ ti ki iṣe si ikú. 18 Awa mọ̀ pe ẹnikẹni ti a bí nipa ti Ọlọrun kì idẹṣẹ: ṣugbọn ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun a mã pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni buburu nì ki si ifọwọ́kàn a. 19 Awa mọ̀ pe ti Ọlọrun ni wa, ati gbogbo aiye li o wa ni agbara ẹni buburu nì. 20 Awa si mọ̀ pe Ọmọ Ọlọrun de, o si ti fi òye fun wa, ki awa ki o le mọ̀ ẹniti iṣe otitọ, awa si mbẹ ninu ẹniti iṣe otitọ, ani ninu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Eyi li Ọlọrun otitọ, ati ìye ainipẹkun. 21 Ẹnyin ọmọ mi, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu oriṣa. Amin.

11-Feb-2009@11:05, Backup Description=11-Feb-2009@09:10, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:15, Backup Description=08-Apr-2009@08:23, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:52, Backup Description=08-Apr-2009@14:37, Ayo Durodola -

22-Dec-2009@14:07, Backup Description=22-Dec-2009@14:01, victor Damilare -

1 John 5

Overcoming the World

1 Whoever believes that Jesus is the tChrist is born of God, and whoever loves the Father loves the child born of Him.2 By this we know that we love the children of God, when we love God and observe His commandments.3 For this is the love of God, that we keep His commandments; and His commandments are not burdensome.4 For whatever is born of God overcomes the world; and this is the victory that has overcome the world-our faith.

5 Who is the one who overcomes the world, but he who believes that Jesus is the Son of God?6 This is the One who came by water and blood, Jesus Christ; not with the water only, but with the water and with the blood. It is the Spirit who testifies, because the Spirit is the truth.7 For there are three that testify:8 tthe Spirit and the water and the blood; and the three are in agreement.9 If we receive the testimony of men, the testimony of God is greater; for the testimony of God is this, that He has testified concerning His Son.10 The one who believes in the Son of God has the testimony in himself; the one who does not believe God has made Him a liar, because he has not believed in the testimony that God has given concerning His Son.11 And the testimony is this, that God has given us eternal life, and this life is in His Son.12 He who has the Son has the life; he who does not have the Son of God does not have the life.

This Is Written That You May Know

13 These things I have written to you who believe in the name of the Son of God, so that you may know that you have eternal life.14 This is the confidence which we have before Him, that, if we ask anything according to His will, He hears us.15 And if we know that He hears us in whatever we ask, we know that we have the requests which we have asked from Him.

16 If anyone sees his brother committing a sin not leading to death, he shall ask and God will for him give life to those who commit sin not leading to death. There is a sin leading to death; I do not say that he should make request for this.17 All unrighteousness is sin, and there is a sin not leading to death.

18 We know that no one who is born of God sins; but He who was born of God keeps him, and the evil one does not touch him.19 We know that we are of God, and that the whole world lies in the power of the evil one.20 And we know that the Son of God has come, and has given us understanding so that we may know Him who is true; and we are in Him who is true, in His Son Jesus Christ. This is the true God and eternal life.

21 Little children, guard yourselves from idols.