I. Pet 2
Òkúta Ààyè ati Orílẹ̀-Èdè Mímọ́
1 NITORINA ẹ fi arankàn gbogbo lelẹ li apakan, ati ẹ̀tan gbogbo, ati agabagebe, ati ilara, ati sisọ ọ̀rọ buburu gbogbo. 2 Bi ọmọ-ọwọ titun, ki ẹ mã fẹ wàra ti Ẹmí na eyiti kò li ẹ̀tan, ki ẹnyin ki o le mã ti ipasẹ rẹ̀ dàgba si igbala, 3 Bi ẹnyin ba ti tọ́ ọ wò pe, olõre li Oluwa: 4 Ẹniti ẹnyin ntọ̀ bọ̀, bi si okuta ãye, ti a ti ọwọ́ enia kọ̀ silẹ nitõtọ, ṣugbọn lọdọ Ọlọrun, àṣayan, iyebiye, 5 Ẹnyin pẹlu, bi okuta ãye, li a kọ ni ile ẹmí, alufa mimọ́, lati mã ru ẹbọ ẹmí, ti iṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun nipa Jesu Kristi. 6 Nitori o mbẹ ninu iwe-mimọ́ pe, Kiyesi i, Mo fi pàtaki okuta igunle, àṣayan, iyebiye, lelẹ ni Sioni: ẹniti o ba si gbà a gbọ́ oju kì yio ti i. 7 Nitorina fun ẹnyin ti o gbagbọ́, ọla ni: ṣugbọn fun awọn ti kò gbagbọ́, okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li o di pàtaki igunle, 8 Ati pẹlu, okuta idigbolu, on apata ikọsẹ̀. Nitori nwọn kọsẹ nipa ṣiṣe aigbọran si ọrọ na ninu eyiti a gbé yàn wọn si pẹlu. 9 Ṣugbọn ẹnyin ni iran ti a yàn, olu-alufa, orilẹ-ède mimọ́, enia ọ̀tọ; ki ẹnyin ki o le fi ọla nla ẹniti o pè nyin jade kuro ninu òkunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ̀ hàn:
10 Ẹnyin ti kì iṣe enia nigbakan rí, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin di enia Ọlọrun, ẹnyin ti kò ti ri ãnu gbà ri, ṣugbọn nisisiyi ẹ ti ri ãnu gbà.Ẹ Jẹ́ Iranṣẹ Ọlọrun
11 Olufẹ, mo bẹ̀ nyin, bi alejò ati bi èro, lati fà sẹhin kuro ninu ifẹkufẹ ara, ti mba ọkàn jagun; 12 Ki ìwa nyin larin awọn Keferi kí o dara; pe, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere nyin, ti nwọn o mã kiyesi, ki nwọn ki o le mã yìn Ọlọrun logo li ọjọ ìbẹwo. 13 Ẹ mã tẹriba fun gbogbo ìlana enia nitori ti Oluwa: ibãṣe fun ọba, bi fun olori; 14 Tabi fun awọn bãlẹ, bi fun awọn ti a rán lati ọdọ rẹ̀ fun igbẹsan lara awọn ti nṣe buburu, ati fun iyìn awọn ti nṣe rere. 15 Bẹ̃ sá ni ifẹ Ọlọrun, pe ni rere iṣe, ki ẹ le dá òpe awọn wère enia lẹkun: 16 Bi omnira, laisi lo omnira nyin fun ohun bibo arakàn nyin mọlẹ, ṣugbọn bi ẹrú Ọlọrun.
17 Ẹ bọ̀wọ fun gbogbo enia. Ẹ fẹ awọn ará. Ẹ bẹru Ọlọrun. Ẹ bọ̀wọ fun ọba.Àpẹẹrẹ Ìjìyà Jesu
18 Ẹnyin ọmọ-ọ̀dọ, ẹ mã tẹriba fun awọn oluwa nyin pẹlu ìbẹru gbogbo; ki iṣe fun awọn ẹni rere ati oniwa tutu nikan, ṣugbọn fun awọn onrorò pẹlu. 19 Nitoripe eyi ni ìtẹwọgba, bi enia ba fi ori tì ibanujẹ, ti o si njìya laitọ́, nitori ọkàn rere si Ọlọrun. 20 Nitori ogo kili o jẹ, nigbati ẹ ba ṣẹ̀ ti a si lù nyin, bi ẹ ba fi sũru gbà a? ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣe rere; ti ẹ si njiya, bi ẹnyin ba fi sũru gbà a, eyi ni itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun. 21 Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ̀ ipasẹ rẹ̀: 22 Ẹniti kò dẹṣẹ̀, bẹni a kò si ri arekereke lì ẹnu rẹ̀: 23 Ẹni, nigbati a kẹgan rẹ̀, ti kò si pada kẹgan; nigbati o jìya, ti kò si kilọ; ṣugbọn o fi ọ̀ran rẹ̀ le ẹniti nṣe idajọ ododo lọwọ: 24 Ẹniti on tikararẹ̀ fi ara rẹ̀ rù ẹ̀ṣẹ wa lori igi, pe ki awa ki o le di okú si ẹ̀ṣẹ ki a si di ãye si ododo: nipa ìnà ẹniti a mu nyin larada. 25 Nitori ẹnyin ti nṣako lọ bi agutan, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin pada si ọdọ Oluṣọ-agutan ati Biṣopu ọkàn nyin.
1 Peter 2
As Newborn Babes
1 Therefore, putting aside all malice and all deceit and hypocrisy and envy and all slander,2 like newborn babies, long for the pure milk of the word, so that by it you may grow in respect to salvation,3 if you have tasted the kindness of the Lord.
As Living Stones
4 And coming to Him as to a living stone which has been rejected by men, but is choice and precious in the sight of God,5 you also, as living stones, are being built up as a spiritual house for a holy priesthood, to offer up spiritual sacrifices acceptable to God through Jesus Christ.6 For this is contained in Scripture:
"BEHOLD, I LAY IN ZION A CHOICE STONE, A PRECIOUS CORNER stone,
AND HE WHO BELIEVES IN HIM WILL NOT BE DISAPPOINTED."7 This precious value, then, is for you who believe; but for those who disbelieve,
"THE STONE WHICH THE BUILDERS REJECTED,
THIS BECAME THE VERY CORNER stone, "
8 and,
"A STONE OF STUMBLING AND A ROCK OF OFFENSE";
for they stumble because they are disobedient to the word, and to this doom they were also appointed.
9 But you are A CHOSEN RACE, A royal PRIESTHOOD, A HOLY NATION, A PEOPLE FOR God's OWN POSSESSION, so that you may proclaim the excellencies of Him who has called you out of darkness into His marvelous light;10 for you once were NOT A PEOPLE, but now you are THE PEOPLE OF GOD; you had NOT RECEIVED MERCY, but now you have RECEIVED MERCY.
11 Beloved, I urge you as aliens and strangers to abstain from fleshly lusts which wage war against the soul.12 Keep your behavior excellent among the Gentiles, so that in the thing in which they slander you as evildoers, they may because of your good deeds, as they observe them, glorify God in the day of tvisitation.
Honor Authority
13 Submit yourselves for the Lord's sake to every human institution, whether to a king as the one in authority,14 or to governors as sent by him for the punishment of evildoers and the praise of those who do right.15 For such is the will of God that by doing right you may silence the ignorance of foolish men.16 Act as free men, and do not use your freedom as a covering for evil, but use it as bondslaves of God.17 Honor all people, love the brotherhood, fear God, honor the king.
18 Servants, be submissive to your masters with all respect, not only to those who are good and gentle, but also to those who are unreasonable.19 For this finds favor, if for the sake of conscience toward God a person bears up under sorrows when suffering unjustly.20 For what credit is there if, when you sin and are harshly treated, you endure it with patience? But if when you do what is right and suffer for it you patiently endure it, this finds favor with God.
Christ Is Our Example
21 For you have been called for this purpose, since Christ also suffered for you, leaving you an example for you to follow in His steps,22 WHO COMMITTED NO SIN, NOR WAS ANY DECEIT FOUND IN HIS MOUTH;23 and while being reviled, He did not revile in return; while suffering, He uttered no threats, but kept entrusting Himself to Him who judges righteously;24 and He Himself bore our sins in His body on the cross, so that we might die to sin and live to righteousness; for by His wounds you were healed.25 For you were continually straying like sheep, but now you have returned to the Shepherd and Guardian of your souls.