previous next

I. Pet 3

Ọ̀rọ̀ fún Àwọn Ọkọ ati Aya

1 BẸ̃ gẹgẹ, ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin; pe, bi ẹnikẹni bá tilẹ nṣe aigbọran si ọ̀rọ na, ki a lè jere wọn li aisọrọ nipa ìwa awọn aya wọn, 2 Nigbati nwọn ba nwò ìwa rere ti on ti ẹ̀ru nyin: 3 Ọṣọ́ ẹniti ki o má jẹ ọṣọ́ ode, ti irun didì, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ̀; 4 Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọ̀ṣọ́ aidibajẹ ti ẹmí irẹlẹ ati ẹmí tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun. 5 Nitori bayi li awọn obinrin mimọ́ igbãni pẹlu, ti nwọn gbẹkẹle Ọlọrun, fi ṣe ara wọn li ọ̀ṣọ́, nwọn a mã tẹriba fun awọn ọkọ tiwọn. 6 Gẹgẹ bi Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, ti o npè e li oluwa: ọmọbinrin ẹniti ẹnyin iṣe, bi ẹnyin ba nṣe rere, ti ohunkohun kò si dẹruba nyìn.

7 Bẹ̃ gẹgẹ ẹnyin ọkọ, ẹ mã fi oye bá awọn aya nyin gbé, ẹ mã fi ọla fun aya, bi ohun èlo ti kò lagbara, ati pẹlu bi ajumọ-jogun ore-ọfẹ ìye; ki adura nyin ki o má bã ni ìdena.

Ìjìyà Nítorí Òdodo


8 Lakotan, ki gbogbo nyin ṣe oninu kan, ẹ mã ba ará nyin kẹdun, ẹ ni ifẹ ará, ẹ mã ṣe ìyọnú, ẹ ni ẹmí irẹlẹ. 9 Ẹ máṣe fi buburu san buburu, tabi fi ẽbú san ẽbú; ṣugbọn kàka bẹ̃, ẹ mã súre; nitori eyi li a pè nyin si, ki ẹnyin ki o le jogún ibukún. 10 Nitori, Ẹniti yio ba fẹ ìye, ti yio si ri ọjọ rere, ki o pa ahọn rẹ̀ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ̀ kuro ni sisọ ọrọ ẹ̀tan: 11 Ki o yà kuro ninu ibi, ki o si mã ṣe rere; ki o mã wá alafia, ki o si mã lepa rẹ̀. 12 Nitori oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, etí rẹ̀ si ṣí si ẹbẹ wọn: ṣugbọn oju Oluwa nwo awọn ti nṣe buburu. 13 Tani yio si ṣe nyin ni ibi, bi ẹnyin ba jẹ onítara si ohun rere? 14 Ṣugbọn bi ẹnyin ba jìya nitori ododo, alafia ni: ẹ máṣe bẹru wọn, ki ẹ má si ṣe kọminu; 15 Ṣugbọn ẹ bọ̀wọ fun Kristi bi Oluwa lọkan nyin: ki ẹ si mura tan nigbagbogbo lati dá olukuluku lohùn ti mbere ireti ti o mbẹ ninu nyin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tutù ati ìbẹru. 16 Ki ẹ mã ni ẹri-ọkàn rere, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin ni ibi, ki oju ki o le ti awọn ti nkẹgan iwa rere nyin ninu Kristi. 17 Nitori o san, bi o bá jẹ ifẹ Ọlọrun, ki ẹ jìya fun rere iṣe jù fun buburu iṣe lọ. 18 Nitoriti Kristi pẹlu jìya lẹ̃kan nitori ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ãye ninu ẹmí: 19 Ninu eyiti o lọ pẹlu, ti o si wãsu fun awọn ẹmí ninu tubu: 20 Awọn ti o ṣe alaigbọran nigbakan, nigbati sũru Ọlọrun duro pẹ ni sã kan ni ọjọ Noa, nigbati nwọn fi nkàn ọkọ̀ ninu eyiti à gba ọkàn diẹ là nipa omi, eyini ni ẹni mẹjọ; 21 Apẹrẹ eyiti ngbà nyin là nisisiyi pẹlu, ani baptismu, kì iṣe ìwẹ ẽri ti ara nù, bikoṣe idahùn ọkàn rere sipa Ọlọrun, nipa ajinde Jesu Kristi: 22 Ẹniti o ti lọ si ọrun, ti o si mbẹ li ọwọ́ ọtún Ọlọrun; awọn angẹli, ati awọn ọlọlá, ati awọn alagbara si ntẹriba fun.

1 Peter 3

Godly Living

1 In the same way, you wives, be submissive to your own husbands so that even if any of them are disobedient to the word, they may be won without a word by the behavior of their wives,2 as they observe your chaste and respectful behavior.3 Your adornment must not be merely external-braiding the hair, and wearing gold jewelry, or putting on dresses;4 but let it be the hidden person of the heart, with the imperishable quality of a gentle and quiet spirit, which is precious in the sight of God.5 For in this way in former times the holy women also, who hoped in God, used to adorn themselves, being submissive to their own husbands;6 just as Sarah obeyed Abraham, calling him lord, and you have become her children if you do what is right without being frightened by any fear.

7 You husbands in the same way, live with your wives in an understanding way, as with someone weaker, since she is a woman; and show her honor as a fellow heir of the grace of life, so that your prayers will not be hindered.

8 To sum up, all of you be harmonious, sympathetic, brotherly, kindhearted, and humble in spirit;9 not returning evil for evil or insult for insult, but giving a blessing instead; for you were called for the very purpose that you might inherit a blessing.10 For,
"THE ONE WHO DESIRES LIFE, TO LOVE AND SEE GOOD DAYS,
MUST KEEP HIS TONGUE FROM EVIL AND HIS LIPS FROM SPEAKING DECEIT.

11 "HE MUST TURN AWAY FROM EVIL AND DO GOOD;
HE MUST SEEK PEACE AND PURSUE IT.

12 "FOR THE EYES OF THE LORD ARE TOWARD THE RIGHTEOUS,
AND HIS EARS ATTEND TO THEIR PRAYER,
BUT THE FACE OF THE LORD IS AGAINST THOSE WHO DO EVIL."

13 Who is there to harm you if you prove zealous for what is good?14 But even if you should suffer for the sake of righteousness, you are blessed. AND DO NOT FEAR THEIR INTIMIDATION, AND DO NOT BE TROUBLED,15 but tsanctify Christ as Lord in your hearts, always being ready to make a defense to everyone who asks you to give an account for the hope that is in you, yet with gentleness and reverence;16 and keep a good conscience so that in the thing in which you are slandered, those who revile your good behavior in Christ will be put to shame.17 For it is better, if God should will it so, that you suffer for doing what is right rather than for doing what is wrong.18 For Christ also died for sins once for all, the just for the unjust, so that He might bring us to God, having been put to death in the flesh, but made alive in the spirit;19 in which also He went and made proclamation to the spirits now in prison,20 who once were disobedient, when the patience of God kept waiting in the days of Noah, during the construction of the ark, in which a few, that is, eight persons, were brought safely through the water.21 Corresponding to that, baptism now saves you-not the removal of dirt from the flesh, but an appeal to God for a good conscience-through the resurrection of Jesus Christ,22 who is at the right hand of God, having gone into heaven, after angels and authorities and powers had been subjected to Him.