I. Pet 5
Bíbọ́ Agbo Aguntan Ọlọrun
1 AWỌN alàgba ti mbẹ lãrin nyin ni mo bẹ̀, emi ẹniti iṣe alàgba bi ẹnyin, ati ẹlẹri ìya Kristi, ati alabapin ninu ogo ti a o fihàn: 2 Ẹ mã tọju agbo Ọlọrun ti mbẹ lãrin nyin, ẹ mã bojuto o, kì iṣe afipáṣe, bikoṣe tifẹtifẹ; bẹni ki iṣe ọrọ ère ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkàn ti o mura tan. 3 Bẹ̃ni ki iṣe bi ẹniti nlo agbara lori ijọ, ṣugbọn ki ẹ ṣe ara nyin li apẹrẹ fun agbo. 4 Nigbati olori Oluṣọ-agutan ba si fi ara hàn, ẹnyin ó gbà ade ogo ti kì iṣá. 5 Bẹ̃ pẹlu, ẹnyin ipẹ̃rẹ, ẹ tẹriba fun awọn àgba. Ani, gbogbo nyin, ẹ mã tẹriba fun ara nyin, ki ẹ si fi irẹlẹ wọ̀ ara nyin li aṣọ: nitori Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn O nfi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ. 6 Nitorina ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ labẹ ọwọ́ agbara Ọlọrun, ki on ki o le gbé nyin ga li akokò. 7 Ẹ mã kó gbogbo aniyan nyin le e; nitoriti on nṣe itọju nyin. 8 Ẹ mã wà li airekọja, ẹ mã ṣọra; nitori Èṣu, ọtá nyin, bi kiniun ti nke ramuramu, o nrìn kãkiri, o nwá ẹniti yio pajẹ kiri: 9 Ẹniti ki ẹnyin ki o kọ oju ija si pẹlu iduroṣinṣin ninu igbagbọ́, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe ìya kanna ni awọn ara nyin ti mbẹ ninu aiye njẹ. 10 Ọlọrun ore-ọfẹ gbogbo, ti o ti pè nyin sinu ogo rẹ̀ ti kò nipẹkun ninu Kristi Jesu, nigbati ẹnyin ba ti jìya diẹ, On tikarãrẹ, yio si ṣe nyin li aṣepé, yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, yio fun nyin li agbara, yio fi idi nyin kalẹ.
11 Tirẹ̀ li ogo ati agbara titi lailai. Amin.Ìdágbére
12 Nipa Silfanu, arakunrin wa olõtọ gẹgẹbi mo ti ka a si, ni mo kọwe kukuru si nyin, ti mo ngbà nyin niyanju, ti mo si njẹri pe, eyi ni otitọ ore-ọfẹ Ọlọrun: ẹ duro ṣinṣin ninu rẹ̀. 13 Ijọ ti mbẹ ni Babiloni, ti a yàn pẹlu nyin, kí nyin; bẹ̃ si ni Marku ọmọ mi pẹlu. 14 Ẹ fi ifẹnukonu ifẹ kí ara nyin. Amin.11-Feb-2009@11:05, Backup Description=11-Feb-2009@09:10, Ayo Durodola -
08-Apr-2009@14:15, Backup Description=08-Apr-2009@08:23, Ayo Durodola -
08-Apr-2009@14:52, Backup Description=08-Apr-2009@14:37, Ayo Durodola -
22-Dec-2009@14:07, Backup Description=22-Dec-2009@14:01, victor Damilare -
1 Peter 5
Serve God Willingly
1 Therefore, I exhort the elders among you, as your fellow elder and witness of the sufferings of Christ, and a partaker also of the glory that is to be revealed,2 shepherd the flock of God among you, exercising oversight not under compulsion, but voluntarily, according to the will of God; and not for sordid gain, but with eagerness;3 nor yet as lording it over those allotted to your charge, but proving to be examples to the flock.4 And when the Chief Shepherd appears, you will receive the unfading crown of glory.5 You younger men, likewise, be subject to your elders; and all of you, clothe yourselves with humility toward one another, for GOD IS OPPOSED TO THE PROUD, BUT GIVES GRACE TO THE HUMBLE.
6 Therefore humble yourselves under the mighty hand of God, that He may exalt you at the proper time,7 casting all your anxiety on Him, because He cares for you.8 Be of sober spirit, be on the alert. Your adversary, the devil, prowls around like a roaring lion, seeking someone to devour.9 But resist him, firm in your faith, knowing that the same experiences of suffering are being accomplished by your brethren who are in the world.10 After you have suffered for a little while, the God of all grace, who called you to His eternal glory in Christ, will Himself perfect, confirm, strengthen and establish you.11 To Him be dominion forever and ever. Amen.
12 Through Silvanus, our faithful brother (for so I regard him ), I have written to you briefly, exhorting and testifying that this is the true grace of God. Stand firm in it!13 She who is in Babylon, chosen together with you, sends you greetings, and so does my son, Mark.
14 Greet one another with a kiss of love.
Peace be to you all who are in Christ.