previous next

I. Tes 4

Ìgbé-Ayé Tí Ó Wu Ọlọrun

1 NJẸ li akotan, ará, awa mbẹ̀ nyin, awa si ngbà nyin niyanju ninu Jesu Oluwa, pe bi ẹnyin ti gbà lọwọ wa bi ẹnyin iba ti mã rìn, ti ẹnyin iba si mã wù Ọlọrun, ani gẹgẹ bi ẹnyin ti nrìn, ki ẹnyin le mã pọ̀ siwaju si i. 2 Nitori ẹnyin mọ̀ irú aṣẹ ti a ti pa fun nyin lati ọdọ Jesu Oluwa. 3 Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ́ nyin, pe ki ẹnyin ki o takéte si àgbere: 4 Ki olukuluku nyin le mọ̀ bi on iba ti mã ko ohun èlo rẹ̀ ni ijanu ni ìwa-mimọ́ ati ni ọlá; 5 Kì iṣe ni ṣiṣe ifẹkufẹ, gẹgẹ bi awọn Keferi ti kò mọ̀ Ọlọrun: 6 Ki ẹnikẹni máṣe rekọja, ki o má si ṣe ṣẹ arakunrin rẹ̀ ninu nkan na: nitori Oluwa ni olugbẹsan ninu gbogbo nkan wọnyi, gẹgẹ bi awa ti kilọ fun nyin tẹlẹ, ti a si jẹri pẹlu. 7 Nitori Ọlọrun kò pè wa fun ìwa ẽri, ṣugbọn ni ìwamimọ́. 8 Nitorina ẹnikẹni ti o bá kọ̀, ko kọ̀ enia, bikoṣe Ọlọrun, ẹniti o fun nyin ni Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ pẹlu. 9 Ṣugbọn niti ifẹ awọn ará, ẹ kò tun fẹ ki ẹnikẹni kọwe si nyin: nitori a ti kọ́ ẹnyin tikaranyin lati ọdọ Ọlọrun wá lati mã fẹ ara nyin. 10 Nitõtọ ẹnyin si nṣe e si gbogbo awọn ará ti o wà ni gbogbo Makedonia: ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, pe ki ẹnyin ki o mã pọ̀ siwaju si i; 11 Ati pe ki ẹnyin ki o mã dù u gidigidi lati gbé jẹ, lati mã gbọ ti ara nyin, ki ẹ mã fi ọwọ́ nyin ṣiṣẹ, gẹgẹ bi awa ti paṣẹ fun nyin;

12 Ki ẹnyin ki o le mã rìn ìrin ẹ̀tọ́ si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ le má ṣe alaini ohunkohun.

Àkókò Tí Oluwa Yóo Dé


13 Ṣugbọn awa kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ òpe, ará, niti awọn ti o sùn, pe ki ẹ má binujẹ gẹgẹ bi awọn iyoku ti kò ni ireti. 14 Nitori bi awa ba gbagbọ́ pe Jesu ti kú, o si ti jinde, gẹgẹ bẹ̃ni Ọlọrun yio mu awọn ti o sùn pẹlu ninu Jesu wá pẹlu ara rẹ̀. 15 Nitori eyiyi li awa nwi fun nyin nipa ọ̀rọ Oluwa, pe awa ti o wà lãye, ti a si kù lẹhin de atiwá Oluwa, bi o ti wu ki o ri kì yio ṣaju awọn ti o sùn. 16 Nitori Oluwa tikararẹ̀ yio sọkalẹ lati ọrun wá ti on ti ariwo, pẹlu ohùn olori awọn angẹli, ati pẹlu ipè Ọlọrun; awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ́ jinde: 17 Nigbana li a ó si gbà awa ti o wà lãye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bẹ̃li awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa. 18 Nitorina, ẹ mã fi ọ̀rọ wọnyi tu ara nyin ninu.

1 Thessalonians 4

Sanctification and Love

1 Finally then, brethren, we request and exhort you in the Lord Jesus, that as you received from us instruction as to how you ought to walk and please God (just as you actually do twalk), that you excel still more.2 For you know what commandments we gave you tby the authority of the Lord Jesus.3 For this is the will of God, your sanctification; that is, that you abstain from sexual immorality;4 that each of you know how to possess his own tvessel in sanctification and honor,5 not in lustful passion, like the Gentiles who do not know God;6  and that no man transgress and defraud his brother in the matter because the Lord is the avenger in all these things, just as we also told you before and solemnly warned you. 7 For God has not called us for the purpose of impurity, but in sanctification.8 So, he who rejects this is not rejecting man but the God who gives His Holy Spirit to you.

9 Now as to the love of the brethren, you have no need for anyone to write to you, for you yourselves are taught by God to love one another;10 for indeed you do practice it toward all the brethren who are in all Macedonia. But we urge you, brethren, to excel still more,11 and to make it your ambition to lead a quiet life and attend to your own business and work with your hands, just as we commanded you,12 so that you will behave properly toward outsiders and not be in any need.

Those Who Died in Christ

13 But we do not want you to be uninformed, brethren, about those who are asleep, so that you will not grieve as do the rest who have no hope.14 For if we believe that Jesus died and rose again, even so God will bring with Him those who have fallen asleep in Jesus.15 For this we say to you by the word of the Lord, that we who are alive and remain until the coming of the Lord, will not precede those who have fallen asleep.16 For the Lord Himself will descend from heaven with a shout, with the voice of the archangel and with the trumpet of God, and the dead in Christ will rise first.17 Then we who are alive and remain will be caught up together with them in the clouds to meet the Lord in the air, and so we shall always be with the Lord.18 Therefore comfort one another with these words.