previous next

I. Tes 5

Ẹ Múra Sílẹ̀ De Ìpadàbọ̀ Oluwa

1 ṢUGBỌN niti akokò ati ìgba wọnni, ará, ẹnyin kò tun fẹ ki a kọ ohunkohun si nyin, 2 Nitoripe ẹnyin tikaranyin mọ̀ dajudaju pe, ọjọ Oluwa mbọ̀wá gẹgẹ bi olè li oru. 3 Nigbati nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojijì yio de sori wọn gẹgẹ bi irọbi lori obinrin ti o lóyun; nwọn kì yio si le sálà. 4 Ṣugbọn ẹnyin, ará, kò si ninu òkunkun, ti ọjọ na yio fi de bá nyin bi olè. 5 Nitori gbogbo nyin ni ọmọ imọlẹ, ati ọmọ ọsán: awa kì iṣe ti oru, tabi ti òkunkun. 6 Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a sùn, bi awọn iyoku ti nṣe; ṣugbọn ẹ jẹ ki a mã ṣọna ki a si mã wa ni airekọja. 7 Nitori awọn ti nsùn, ama sùn li oru; ati awọn ti nmutipara, ama mutipara li oru. 8 Ṣugbọn ẹ jẹ ki awa, bi a ti jẹ ti ọsán, mã wà li airekọja, ki a mã gbé igbaiya igbagbọ́ ati ifẹ wọ̀; ati ireti igbala fun aṣibori. 9 Nitori Ọlọrun yàn wa ki iṣe si ibinu, ṣugbọn si ati ni igbala nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa, 10 Ẹniti o kú fun wa, pe bi a ba jí, tabi bi a ba sùn, ki a le jùmọ wà lãye pẹlu rẹ̀.

11 Nitorina ẹ mã gbà ara nyin niyanju, ki ẹ si mã fi ẹsẹ ara nyin mulẹ, ani gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe.

Gbolohun Ìparí


12 Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, lati mã mọ awọn ti nṣe lãla larin nyin, ti nwọn si nṣe olori nyin ninu Oluwa, ti nwọn si nkìlọ fun nyin; 13 Ki ẹ si mã bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn. Ẹ si mã wà li alafia lãrin ara nyin. 14 Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, ki ẹ mã kìlọ fun awọn ti iṣe alaigbọran, ẹ mã tù awọn alailọkàn ninu, ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ẹ mã mu sũru fun gbogbo enia. 15 Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mã lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, lãrin ara nyin, ati larin gbogbo enia. 16 Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo. 17 Ẹ mã gbadura li aisimi. 18 Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin. 19 Ẹ máṣe pa iná Ẹmí. 20 Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ. 21 Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin. 22 Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi. 23 Ki Ọlọrun alafia tikararẹ̀ ki o sọ nyin di mimọ́ patapata; ki a si pa ẹmí ati ọkàn ati ara nyin mọ́ patapata li ailabukù ni ìgba wíwa Oluwa wa Jesu Kristi. 24 Olododo li ẹniti o pè nyin, ti yio si ṣe e. 25 Ará, ẹ mã gbadura fun wa. 26 Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí gbogbo awọn ará. 27 Mo fi Oluwa mu nyin bura pe, ki a ka iwe yi fun gbogbo awọn ará. 28 Ki ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi ki o wà pẹlu nyin. Amin.

11-Feb-2009@11:05, Backup Description=11-Feb-2009@09:10, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:15, Backup Description=08-Apr-2009@08:23, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:52, Backup Description=08-Apr-2009@14:37, Ayo Durodola -

22-Dec-2009@14:07, Backup Description=22-Dec-2009@14:01, victor Damilare -

1 Thessalonians 5

The Day of the Lord

1 Now as to the times and the epochs, brethren, you have no need of anything to be written to you.2 For you yourselves know full well that the day of the Lord will come just like a thief in the night.3 While they are saying, "Peace and safety!" then destruction will come upon them suddenly like labor pains upon a woman with child, and they will not escape.4 But you, brethren, are not in darkness, that the day would overtake you like a thief;5 for you are all sons of light and sons of day. We are not of night nor of darkness;6 so then let us not sleep as others do, but let us be alert and tsober.7 For those who sleep do their sleeping at night, and those who get drunk get drunk at night.8 But since we are of the day, let us be tsober, having put on the breastplate of faith and love, and as a helmet, the hope of salvation.9 For God has not destined us for wrath, but for obtaining salvation through our Lord Jesus Christ,10 who died for us, so that whether we are awake or asleep, we will live together with Him.11 Therefore encourage one another and build up one another, just as you also are doing.

Christian Conduct

12 But we request of you, brethren, that you appreciate those who diligently labor among you, and have charge over you in the Lord and give you instruction,13 and that you esteem them very highly in love because of their work. Live in peace with one another.14 We urge you, brethren, admonish the unruly, encourage the fainthearted, help the weak, be patient with everyone.15 See that no one repays another with evil for evil, but always seek after that which is good for one another and for all people.16 Rejoice always;17 pray without ceasing;18 in everything give thanks; for this is God's will for you in Christ Jesus.19 Do not quench the Spirit;20 do not despise prophetic tutterances.21 But examine everything carefully; hold fast to that which is good;22 abstain from every tform of evil.

23 Now may the God of peace Himself sanctify you entirely; and may your spirit and soul and body be preserved complete, without blame at the coming of our Lord Jesus Christ.24 Faithful is He who calls you, and He also will bring it to pass.

25 Brethren, pray for ust.

26 Greet all the brethren with a holy kiss.27 I adjure you by the Lord to have this letter read to all the brethren.

28 The grace of our Lord Jesus Christ be with you.