previous next

I. Tim 1

1 PAULU, Aposteli Kristi Jesu, gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Olugbala wa, ati Kristi Jesu ireti wa;

2 Si Timotiu, ọmọ mi tõtọ ninu igbagbọ́: Ore-ọfẹ, ãnu, alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa.

Ìkìlọ̀ nípa Ẹ̀kọ́ Èké


3 Bi mo ti gba ọ niyanju lati joko ni Efesu, nigbati mo nlọ si Makedonia, ki iwọ ki o le paṣẹ fun awọn kan, ki nwọn ki o máṣe kọ́ni li ẹkọ́ miran, 4 Ki nwọn má si ṣe fiyesi awọn itan lasan, ati ti ìran ti kò li opin, eyiti imã mú ijiyan wa dipo iṣẹ iriju Ọlọrun ti mbẹ ninu igbagbọ́; bẹni mo ṣe nisisiyi. 5 Ṣugbọn opin aṣẹ na ni ifẹ lati ọkàn mimọ́ ati ẹri-ọkan rere ati igbagbọ́ aiṣẹtan wa. 6 Lati inu eyiti awọn ẹlomiran ti yapa kuro ti nwọn si ya sapakan si ọrọ asan; 7 Nwọn nfẹ ṣe olukọ ofin; òye ohun ti nwọn nwi kò yé wọn, tabi ti ohun ti nwọn ntẹnumọ́. 8 Ṣugbọn awa mọ̀ pe ofin dara, bi enia ba lò o bi ã ti ilo ofin; 9 Bi a ti mọ̀ eyi pe, a kò ṣe ofin fun olododo, bikoṣe fun awọn alailofin ati awọn alaigbọran, fun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ati awọn ẹlẹṣẹ, fun awọn alaimọ́ ati awọn ẹlẹgan, fun awọn apa-baba ati awọn apa-iya, fun awọn apania, 10 Fun awọn àgbere, fun awọn ti nfi ọkunrin ba ara wọn jẹ́, fun awọn ají-enia tà, fun awọn eke, fun awọn abura eke, ati bi ohun miran ba si wà ti o lodi si ẹkọ́ ti o yè koro,

11 Gẹgẹ bi ihinrere ti ogo Ọlọrun olubukún, ti a fi si itọju mi.

Ọpẹ́ fún Àánú Ọlọrun


12 Mo dupẹ lọwọ Ẹniti o fun mi li agbara, ani Kristi Jesu Oluwa wa, nitoriti o kà mi si olõtọ ni yiyan mi si iṣẹ rẹ̀; 13 Bi mo tilẹ jẹ asọ ọ̀rọ-odì lẹkan rí, ati oninunibini, ati elewu enia: ṣugbọn mo ri ãnu gbà, nitoriti mo ṣe e li aimọ̀ ninu aigbagbọ. 14 Ore-ọfẹ Oluwa wa si pọ̀ rekọja pẹlu igbagbọ́ ati ifẹ, ti mbẹ ninu Kristi Jesu. 15 Otitọ li ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà, pe Kristi Jesu wá si aiye lati gbà ẹlẹṣẹ là; ninu awọn ẹniti emi jẹ pàtaki. 16 Ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe ri ãnu gbà, pe lara mi, bi olori, ni ki Jesu Kristi fi gbogbo ipamọra rẹ̀ hàn bi apẹrẹ fun awọn ti yio gbà a gbọ́ si ìye ainipẹkun nigba ikẹhin. 17 Njẹ fun Ọba aiyeraiye, aidibajẹ, airi, Ọlọrun kanṣoṣo, ni ọlá ati ogo wà fun lai ati lailai. Amin. 18 Aṣẹ yi ni mo pa fun ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹgẹ bi isọtẹlẹ wọnni ti o ti ṣaju lori rẹ, pe nipa wọn ki iwọ ki o le mã jà ogun rere; 19 Mã ni igbagbọ́ ati ẹri-ọkàn rere; eyiti awọn ẹlomiran tanu kuro lọdọ wọn ti nwọn si rì ọkọ̀ igbagbọ́ wọn: 20 Ninu awọn ẹniti Himeneu ati Aleksanderu wà; awọn ti mo ti fi le Satani lọwọ, ki a le kọ́ wọn ki nwọn ki o má sọrọ-odi mọ́.

1 Timothy 1

Misleadings in Doctrine and Living

1 Paul, an apostle of Christ Jesus according to the commandment of God our Savior, and of Christ Jesus, who is our hope,

2 To Timothy, my true child in the faith: Grace, mercy and peace from God the Father and Christ Jesus our Lord.

3 As I urged you upon my departure for Macedonia, remain on at Ephesus so that you may instruct certain men not to teach strange doctrines,4 nor to pay attention to myths and endless genealogies, which give rise to mere speculation rather than furthering the administration of God which is by faith.5 But the goal of our instruction is love from a pure heart and a good conscience and a sincere faith.6 For some men, straying from these things, have turned aside to fruitless discussion,7 wanting to be teachers of the Law, even though they do not understand either what they are saying or the matters about which they make confident assertions.

8 But we know that the Law is good, if one uses it lawfully,9 realizing the fact that law is not made for a righteous person, but for those who are lawless and rebellious, for the ungodly and sinners, for the unholy and profane, for those who kill their fathers or mothers, for murderers10 and immoral men and homosexuals and kidnappers and liars and perjurers, and whatever else is contrary to sound teaching,11 according to the glorious gospel of the blessed God, with which I have been entrusted.

12 I thank Christ Jesus our Lord, who has strengthened me, because He considered me faithful, putting me into service,13 even though I was formerly a blasphemer and a persecutor and a violent aggressor. Yet I was shown mercy because I acted ignorantly in unbelief;14 and the grace of our Lord was more than abundant, with the faith and love which are found in Christ Jesus.15 It is a trustworthy statement, deserving full acceptance, that Christ Jesus came into the world to save sinners, among whom I am foremost of all. 16 Yet for this reason I found mercy, so that in me as the foremost, Jesus Christ might demonstrate His perfect patience as an example for those who would believe in Him for eternal life.17 Now to the King eternal, immortal, invisible, the only God, be honor and glory forever and ever. Amen.

18 This command I entrust to you, Timothy, my son, in accordance with the prophecies previously made concerning you, that by them you fight the good fight,19 keeping faith and a good conscience, which some have rejected and suffered shipwreck in regard to their faith.20 Among these are Hymenaeus and Alexander, whom I have handed over to Satan, so that they will be taught not to blaspheme.