previous next

I. Tim 6

1 KI gbogbo awọn ti iṣe ẹrú labẹ ìrú mã ka awọn oluwa ti o ni wọn yẹ si ọla gbogbo, ki a má bã sọrọ-odi si orukọ Ọlọrun ati ẹkọ́ rẹ̀.

2 Awọn ti o si ni oluwa onigbagbọ́, ki nwọn máṣe gàn wọn nitori arakunrin ni nwọn; ṣugbọn ki nwọn tubọ mã sìn wọn, nitori awọn ti iṣe alabapin iṣẹ rere wọn jẹ onigbagbọ́ ati olufẹ. Nkan wọnyi ni ki o mã kọ́ni ki o si mã fi gba-ni-niyanju.

Ẹ̀kọ́ Burúkú ati Ọ̀rọ̀ Tòótọ́


3 Bi ẹnikẹni ba nkọ́ni li ẹkọ miran, ti kò si gba ọ̀rọ ti o ye kõro, ani ọ̀rọ Jesu Kristi Oluwa wa, ati ẹkọ́ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun. 4 O gberaga, kò mọ nkan kan, bikoṣe ifẹ iyan-jija ati ìja-ọ̀rọ ninu eyiti ilara, ìya, ọrọ buburu ati iro buburu ti iwá, 5 Ọ̀rọ̀ ayipo awọn enia ọlọkan ẽri ti kò si otitọ ninu wọn, ti nwọn ṣebi ọna si ere ni ìwa-bi-Ọlọrun: yẹra lọdọ irú awọn wọnni. 6 Ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun pẹlu itẹlọrùn ère nla ni. 7 Nitori a kò mu ohun kan wá si aiye, bẹni a kò si le mu ohunkohun jade lọ. 8 Bi a ba si li onjẹ ati aṣọ ìwọnyi yio tẹ́ wa lọrùn. 9 Ṣugbọn awọn ti nfẹ di ọlọrọ̀ a mã bọ́ sinu idanwò ati idẹkun, ati sinu wère ifẹkufẹ pipọ ti ipa-ni-lara, iru eyiti imã rì enia sinu iparun ati ègbé.

10 Nitori ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo: eyiti awọn miran nlepa ti a si mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ́, nwọn si fi ibinujẹ pupọ̀ gún ara wọn li ọ̀kọ̀.

Ìjà Rere ti Igbagbọ


11 Ṣugbọn iwọ enia Ọlọrun, sá fun nkan wọnyi; ki o si mã lepa ododo, ìwa-bi-Ọlọrun, igbagbọ́, ifẹ, sũru, ìwa tutù. 12 Mã jà ìja rere ti igbagbọ́, di ìye ainipẹkun mu ninu eyiti a gbé pè ọ si, ti iwọ si ṣe ijẹwo rere niwaju ẹlẹri pupọ̀. 13 Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ti nsọ ohun gbogbo di ãye, ati niwaju Jesu Kristi, ẹni, niwaju Pontiu Pilatu, ti o jẹri ijẹwọ rere, 14 Ki iwọ ki o pa ofin mọ́ li ailabawọn, li ailẹgan, titi di ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi: 15 Eyiti yio fihàn ni igba tirẹ̀, Ẹniti iṣe Olubukún ati Alagbara na kanṣoṣo, Ọba awọn ọba, ati Oluwa awọn oluwa; 16 Ẹnikanṣoṣo ti o ni aikú, ti ngbe inu imọlẹ ti a kò le sunmọ, ẹniti enia kan kò ri rí ti kò si le ri: ẹniti ọla ati agbara titi lai iṣe tirẹ. Amin. 17 Kìlọ fun awọn ti o lọrọ̀ li aiye isisiyi, ki nwọn máṣe gberaga, bẹni ki nwọn máṣe gbẹkẹle ọrọ̀ aidaniloju, bikoṣe le Ọlọrun alãye, ti nfi ohun gbogbo fun wa lọpọlọpọ lati lo; 18 Ki nwọn ki o mã ṣõre, ki nwọn ki o mã pọ̀ ni iṣẹ rere, ki nwọn mura lati pin funni, ki nwọn ki o ni ẹmi ibakẹdun; 19 Ki nwọn ki o mã tò iṣura ipilẹ rere jọ fun ara wọn dè igba ti mbọ̀, ki nwọn ki o le di ìye tõtọ mu. 20 Timotiu, ṣọ ohun ni ti a fi si itọju rẹ, yà kuro ninu ọ̀rọ asan ati ijiyan ohun ti a nfi eke pè ni imọ; 21 Eyiti awọn ẹlomiran jẹwọ rẹ̀ ti nwọn si ṣina igbagbọ́. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu rẹ. Amin.

11-Feb-2009@11:05, Backup Description=11-Feb-2009@09:10, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:15, Backup Description=08-Apr-2009@08:23, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:52, Backup Description=08-Apr-2009@14:37, Ayo Durodola -

22-Dec-2009@14:07, Backup Description=22-Dec-2009@14:01, victor Damilare -

1 Timothy 6

Instructions to Those Who Minister

1 All who are under the yoke as slaves are to regard their own masters as worthy of all honor so that the name of God and our doctrine will not be spoken against.2 Those who have believers as their masters must not be disrespectful to them because they are brethren, but must serve them all the more, because those who partake of the benefit are believers and beloved. Teach and preach these principles.

3 If anyone advocates a different doctrine and does not agree with sound words, those of our Lord Jesus Christ, and with the doctrine conforming to godliness,4 he is conceited and understands nothing; but he has a morbid interest in controversial questions and disputes about words, out of which arise envy, strife, abusive language, evil suspicions,5 and constant friction between men of depraved mind and deprived of the truth, who suppose that godliness is a means of gain.6 But godliness actually is a means of great gain when accompanied by contentment.7 For we have brought nothing into the world, so we cannot take anything out of it either.8 If we have food and covering, with these we shall be content.9 But those who want to get rich fall into temptation and a snare and many foolish and harmful desires which plunge men into ruin and destruction.10 For the love of money is a root of all sorts of evil, and some by longing for it have wandered away from the faith and pierced themselves with many griefs.

11 But flee from these things, you man of God, and pursue righteousness, godliness, faith, love, perseverance and gentleness.12 Fight the good fight of faith; take hold of the eternal life to which you were called, and you made the good confession in the presence of many witnesses.13 I charge you in the presence of God, who gives life to all things, and of Christ Jesus, who testified the good confession before Pontius Pilate,14 that you keep the commandment without stain or reproach until the appearing of our Lord Jesus Christ,15 which He will bring about at the proper time-He who is the blessed and only Sovereign, the King of kings and Lord of lords,16 who alone possesses immortality and dwells in unapproachable light, whom no man has seen or can see. To Him be honor and eternal dominion! Amen.

17 Instruct those who are rich in this present world not to be conceited or to fix their hope on the uncertainty of riches, but on God, who richly supplies us with all things to enjoy.18  Instruct them to do good, to be rich in good works, to be generous and ready to share,19 storing up for themselves the treasure of a good foundation for the future, so that they may take hold of that which is life indeed.

20 O Timothy, guard what has been entrusted to you, avoiding worldly and empty chatter and the opposing arguments of what is falsely called "knowledge"-

21 which some have professed and thus gone astray from the faith.
Grace be with you.