II. Kor 13
Ìkìlọ̀ Ìgbẹ̀yìn
1 EYI li o di igba kẹta ti emi ntọ̀ nyin wá. Li ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta li a o fi idi ọ̀rọ gbogbo mulẹ. 2 Mo ti sọ fun nyin ṣaju, mo si nsọ fun nyin tẹlẹ, bi ẹnipe mo wà pẹlu nyin nigba keji, ati bi emi kò ti si lọdọ nyin nisisiyi, mo kọwe si awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ati si gbogbo awọn ẹlomiran, pe bi mo ba tún pada wá, emi kì yio da wọn si: 3 Niwọnbi ẹnyin ti nwá àmi Kristi ti nsọ̀rọ ninu mi, ẹniti ki iṣe ailera si nyin, ṣugbọn ti o jẹ agbara ninu nyin. 4 Nitoripe a kàn a mọ agbelebu nipa ailera, ṣugbọn on wà lãye nipa agbara Ọlọrun. Nitori awa pẹlu jasi alailera ninu rẹ̀, ṣugbọn awa ó wà lãye pẹlu rẹ̀ nipa agbara Ọlọrun si nyin. 5 Ẹ mã wadi ara nyin, bi ẹnyin bá wà ninu igbagbọ́; ẹ mã dan ara nyin wò. Tabi ẹnyin tikaranyin kò mọ̀ ara nyin pe Jesu Kristi wà ninu nyin? afi bi ẹnyin ba jẹ awọn ti a tanù. 6 Ṣugbọn mo ni igbẹkẹle pe ẹnyin ó mọ̀ pe, awa kì iṣe awọn ti a tanù. 7 Njẹ awa ngbadura si Ọlọrun, ki ẹnyin ki o máṣe ibikibi kan; kì iṣe nitori ki awa ki o le fi ara hàn bi awọn ti a mọ̀ daju, ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mã ṣe eyi ti o dara, bi awa tilẹ dabi awọn ti a tanù. 8 Nitori awa kò le ṣe ohun kan lodi si otitọ, bikoṣe fun otitọ. 9 Nitori awa nyọ̀, nigbati awa jẹ alailera, ti ẹnyin si jẹ alagbara: eyi li awa si ngbadura fun pẹlu, ani pipe nyin.
10 Nitori idi eyi, nigbati emi kò si, mo kọwe nkan wọnyi pe, nigbati mo ba de, ki emi ki o má bã lò ikannú, gẹgẹ bi aṣẹ ti Oluwa ti fifun mi fun idagbasoke, kì si iṣe fun iparun.Gbolohun Ìdágbére
11 Li akotan, ará, odigboṣe. Ẹ jẹ pipé, ẹ tújuka, ẹ jẹ oninu kan, ẹ mã wà li alafia; Ọlọrun ifẹ ati ti alafia yio wà pẹlu nyin. 12 Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin. 13 Gbogbo awọn enia mimọ́ kí nyin. 14 Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa, ati ifẹ Ọlọrun, ati ìdapọ ti Ẹmí Mimọ́, ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.11-Feb-2009@11:05, Backup Description=11-Feb-2009@09:10, Ayo Durodola -
08-Apr-2009@14:15, Backup Description=08-Apr-2009@08:23, Ayo Durodola -
08-Apr-2009@14:52, Backup Description=08-Apr-2009@14:37, Ayo Durodola -
22-Dec-2009@14:07, Backup Description=22-Dec-2009@14:01, victor Damilare -
2 Corinthians 13
Examine Yourselves
1 This is the third time I am coming to you. EVERY FACT IS TO BE CONFIRMED BY THE TESTIMONY OF TWO OR THREE WITNESSES.2 I have previously said when present the second time, and though now absent I say in advance to those who have sinned in the past and to all the rest as well, that if I come again I will not spare anyone, 3 since you are seeking for proof of the Christ who speaks in me, and who is not weak toward you, but mighty in you.4 For indeed He was crucified because of weakness, yet He lives because of the power of God. For we also are weak tin Him, yet we will live with Him because of the power of God directed toward you.
5 Test yourselves to see if you are in the faith; examine yourselves! Or do you not recognize this about yourselves, that Jesus Christ is in you-unless indeed you fail the test?6 But I trust that you will realize that we ourselves do not fail the test.7 Now we pray to God that you do no wrong; not that we ourselves may appear approved, but that you may do what is right, even though we may appear unapproved.8 For we can do nothing against the truth, but only for the truth.9 For we rejoice when we ourselves are weak but you are strong; this we also pray for, that you be made complete.10 For this reason I am writing these things while absent, so that when present I need not use severity, in accordance with the authority which the Lord gave me for building up and not for tearing down.
11 Finally, brethren, rejoice, be made complete, be comforted, be like-minded, live in peace; and the God of love and peace will be with you.12 Greet one another with a holy kiss.13 All the saints greet you.
14 The grace of the Lord Jesus Christ, and the love of God, and the fellowship of the Holy Spirit, be with you all.