previous next

II. Tes 1

Ìkíni

1 PAULU, ati Silfanu, ati Timotiu, si ijọ Tessalonika, ninu Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kristi Oluwa:

2 Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba, ati Jesu Kristi Oluwa.

Ìdájọ́ Nígbà Tí Jesu Bá Dé


3 Iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, ani gẹgẹ bi o ti yẹ, nitoripe igbagbọ́ nyin ndàgba gidigidi, ati ifẹ olukuluku nyin gbogbo si ara nyin ndi pupọ; 4 Tobẹ̃ ti awa tikarawa nfi nyin ṣogo ninu ijọ Ọlọrun, nitori sũru ati igbagbọ́ nyin ninu gbogbo inunibini ati wahalà nyin ti ẹnyin nfarada, 5 Eyiti iṣe àmi idajọ ododo Ọlọrun ti o daju, ki a le kà nyin yẹ fun ijọba Ọlọrun, nitori eyiti ẹnyin pẹlu ṣe njìya: 6 Bi o ti jẹ pe ohun ododo ni fun Ọlọrun lati fi ipọnju gbẹsan lara awọn ti npọ́n nyin loju, 7 Ati fun ẹnyin, ti a npọ́n loju, isimi pẹlu wa, nigba ifarahàn Jesu Oluwa lati ọrun wá ninu ọwọ́ ina pẹlu awọn angẹli alagbara rẹ̀, 8 Ẹniti yio san ẹsan fun awọn ti kò mọ Ọlọrun, ti nwọn kò si gbà ihinrere Jesu Oluwa wa gbọ́: 9 Awọn ẹniti yio jiya iparun ainipẹkun lati iwaju Oluwa wá, ati lati inu ogo agbara rẹ̀, 10 Nigbati o ba de lati jẹ ẹni ãyìn logo ninu awọn enia mimọ́ rẹ̀, ati ẹni iyanu ninu gbogbo awọn ti o gbagbọ́ (nitori a ti gbà ẹrí ti a jẹ fun nyin gbọ) li ọjọ na. 11 Nitori eyiti awa pẹlu ngbadura fun nyin nigbagbogbo, pe ki Ọlọrun wa ki o le kà nyin yẹ fun ìpe nyin, ki o le mu gbogbo ifẹ ohun rere ati iṣẹ igbagbọ́ ṣẹ ni agbara: 12 Ki a le yìn orukọ Jesu Oluwa wa logo ninu nyin, ati ẹnyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun wa ati ti Jesu Kristi Oluwa.

2 Thessalonians 1

Thanksgiving for Faith and Perseverance

1 Paul and Silvanus and Timothy,
To the church of the Thessalonians in God our Father and the Lord Jesus Christ:
2 Grace to you and peace from God the Father and the Lord Jesus Christ.

3 We ought always to give thanks to God for you, brethren, as is only fitting, because your faith is greatly enlarged, and the love of each one of you toward one another grows ever greater;4 therefore, we ourselves speak proudly of you among the churches of God for your perseverance and faith in the midst of all your persecutions and afflictions which you endure.5  This is a plain indication of God's righteous judgment so that you will be considered worthy of the kingdom of God, for which indeed you are suffering.6 For after all it is only just for God to repay with affliction those who afflict you,7 and to give relief to you who are afflicted and to us as well when the Lord Jesus will be revealed from heaven with His mighty angels in flaming fire,8 dealing out retribution to those who do not know God and to those who do not obey the gospel of our Lord Jesus.9 These will pay the penalty of eternal destruction, away from the presence of the Lord and from the glory of His power,10 when He comes to be glorified in His saints on that day, and to be marveled at among all who have believed-for our testimony to you was believed.11 To this end also we pray for you always, that our God will count you worthy of your calling, and fulfill every desire for goodness and the work of faith with power,12 so that the name of our Lord Jesus will be glorified in you, and you in Him, according to the grace of our God and the Lord Jesus Christ.