previous next

II. Tim 2

Ọmọ-Ogun Rere Ti Kristi Jesu

1 NITORINA, iwọ ọmọ mi, jẹ alagbara ninu ore-ọfẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu. 2 Ati ohun wọnni ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi lati ọwọ ọ̀pọlọpọ ẹlẹri, awọn na ni ki iwọ fi le awọn olõtọ enia lọwọ, awọn ti yio le mã kọ́ awọn ẹlomiran pẹlu. 3 Ṣe alabapin pẹlu mi ninu ipọnju, bi ọmọ-ogun rere Jesu Kristi. 4 Kò si ẹniti njàgun ti ifi ohun aiye yi dí ara rẹ̀ lọwọ, ki o le mu inu ẹniti o yàn a li ọmọ-ogun dùn. 5 Bi ẹnikẹni ba si njà, a kì dé e li ade, bikoṣepe o ba jà li aiṣe erú. 6 Àgbẹ ti o nṣe lãlã li o ni lati kọ́ mu ninu eso wọnni. 7 Gbà ohun ti emi nsọ rò; nitori Oluwa yio fun ọ li òye ninu ohun gbogbo. 8 Ranti Jesu Kristi, ti o jinde kuro ninu okú, lati inu irú-ọmọ Dafidi, gẹgẹ bi ihinrere mi, 9 Ninu eyiti emi nri ipọnju titi dé inu ìde bi arufin; ṣugbọn a kò dè ọ̀rọ Ọlọrun. 10 Nitorina mo nfarada ohun gbogbo nitori ti awọn ayanfẹ, ki awọn na pẹlu le ni igbala ti mbẹ ninu Kristi Jesu pẹlu ogo ainipẹkun. 11 Otitọ li ọrọ na: Nitoripe bi awa ba bá a kú, awa ó si bá a yè: 12 Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba: bi awa ba sẹ́ ẹ, on na yio si sẹ́ wa. 13 Bi awa kò ba gbagbọ́, on duro li olõtọ: nitori on kò le sẹ́ ara rẹ̀. 14 Nkan wọnyi ni ki o mã rán wọn leti, mã kìlọ fun wọn niwaju Oluwa pe, ki nwọn ki o máṣe jijà ọ̀rọ ti kò lere, fun iparun awọn ti ngbọ. 15 Ṣãpọn lati fi ara rẹ hàn niwaju Ọlọrun li ẹniti o yege, aṣiṣẹ́ ti kò ni lati tiju, ti o npín ọ̀rọ otitọ bi o ti yẹ. 16 Ṣugbọn yà kuro ninu ọ̀rọ asan, nitoriti nwọn ó mã lọ siwaju ninu aiwa-bi-Ọlọrun, 17 Ọrọ wọn yio si mã jẹ bi egbò kikẹ̀; ninu awọn ẹniti Himeneu ati Filetu wà; 18 Awọn ẹniti o ti ṣìna niti otitọ, ti nwipe ajinde ti kọja na; ti nwọn si mbì igbagbọ́ awọn miran ṣubu. 19 Ṣugbọn ipilẹ Ọlọrun ti o daju duro ṣinṣin, o ni èdidi yi wipe, Oluwa mọ̀ awọn ti iṣe tirẹ̀. Ati pẹlu, ki olukuluku ẹniti npè orukọ Oluwa ki o kuro ninu aiṣododo. 20 Ṣugbọn ninu ile nla, kì iṣe kìki ohun elo wura ati ti fadaka nikan ni mbẹ nibẹ̀, ṣugbọn ti igi ati ti amọ̀ pẹlu; ati omiran si ọlá, ati omiran si ailọlá. 21 Bi ẹnikẹni ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́ kuro ninu wọnyi, on ó jẹ ohun èlo si ọlá, ti a yà si ọ̀tọ, ti o si yẹ fun ìlo bãle, ti a si ti pèse silẹ si iṣẹ rere gbogbo. 22 Mã sá fun ifẹkufẹ ewe: si mã lepa ododo, igbagbọ́, ifẹ, alafia, pẹlu awọn ti nkepè Oluwa lati inu ọkàn funfun wá. 23 Ṣugbọn ibẽre wère ati alaini ẹkọ́ ninu ni ki o kọ̀, bi o ti mọ̀ pe nwọn ama dá ìja silẹ. 24 Iranṣẹ Oluwa kò si gbọdọ jà; bikoṣe ki o jẹ ẹni pẹlẹ si enia gbogbo, ẹniti o le kọ́ni, onisũru, 25 Ẹniti yio mã kọ́ awọn aṣodi pẹlu iwa tutu; boya Ọlọrun le fun wọn ni ironupiwada si imọ otitọ; 26 Nwọn o si le sọji kuro ninu idẹkun Èṣu, awọn ti a ti dì ni igbekun lati ọwọ́ rẹ̀ wá si ifẹ rẹ̀.

2 Timothy 2

Be Strong

1 You therefore, my son, be strong in the grace that is in Christ Jesus.2 The things which you have heard from me in the presence of many witnesses, entrust these to faithful men who will be able to teach others also.3 Suffer hardship with me, as a good soldier of Christ Jesus.4 No soldier in active service entangles himself in the affairs of everyday life, so that he may please the one who enlisted him as a soldier.5 Also if anyone competes as an athlete, he does not win the prize unless he competes according to the rules.6 The hard-working farmer ought to be the first to receive his share of the crops.7 Consider what I say, for the Lord will give you understanding in everything.

8 Remember Jesus Christ, risen from the dead, descendant of David, according to my gospel,9 for which I suffer hardship even to imprisonment as a criminal; but the word of God is not imprisoned.10 For this reason I endure all things for the sake of those who are chosen, so that they also may obtain the salvation which is in Christ Jesus and with it eternal glory.11 It is a trustworthy statement:
For if we died with Him, we will also live with Him;

12 If we endure, we will also reign with Him;
If we deny Him, He also will deny us;

13 If we are faithless, He remains faithful, for He cannot deny Himself.

An Unashamed Workman

14 Remind them of these things, and solemnly charge them in the presence of God not to wrangle about words, which is useless and leads to the ruin of the hearers.15 Be diligent to present yourself approved to God as a workman who does not need to be ashamed, accurately handling the word of truth.16 But avoid worldly and empty chatter, for it will lead to further ungodliness,17 and their talk will spread like tgangrene. Among them are Hymenaeus and Philetus,18  men who have gone astray from the truth saying that the resurrection has already taken place, and they upset the faith of some.19 Nevertheless, the firm foundation of God stands, having this seal, "The Lord knows those who are His," and, "Everyone who names the name of the Lord is to abstain from wickedness."

20 Now in a large house there are not only gold and silver vessels, but also vessels of wood and of earthenware, and some to honor and some to dishonor.21 Therefore, if anyone cleanses himself from these things, he will be a vessel for honor, sanctified, useful to the Master, prepared for every good work.22 Now flee from youthful lusts and pursue righteousness, faith, love and peace, with those who call on the Lord from a pure heart.23 But refuse foolish and ignorant speculations, knowing that they produce quarrels.24 The Lord's bond-servant must not be quarrelsome, but be kind to all, able to teach, patient when wronged,25 with gentleness correcting those who are in opposition, if perhaps God may grant them repentance leading to the knowledge of the truth,26 and they may come to their senses and escape from the snare of the devil, having been held captive by him to do his will.