previous next

II. Tim 3

Ìwà tí Àwọn Eniyan Yóo Máa Hù ní Ọjọ́ Ìkẹyìn

1 ṢUGBỌN eyi ni ki o mọ̀, pe ni ikẹhin ọjọ ìgbà ewu yio de. 2 Nitori awọn enia yio jẹ olufẹ ti ara wọn, olufẹ owo, afunnú, agberaga, asọ̀rọbuburu, aṣaigbọran si obi, alailọpẹ, alaimọ́, 3 Alainifẹ, alaile darijini, abanijẹ́, alaile-kó-ra-wọnnijanu, onroro, alainifẹ-ohun-rere, 4 Onikupani, alagidi, ọlọkàn giga, olufẹ fãji jù olufẹ Ọlọrun lọ; 5 Awọn ti nwọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn ti nwọn sẹ́ agbara rẹ̀: yẹra kuro lọdọ awọn wọnyi pẹlu. 6 Nitori ninu irú eyi li awọn ti nrakò wọ̀ inu ile, ti nwọn si ndì awọn obinrin alailọgbọn ti a dì ẹ̀ṣẹ rù ni igbekùn, ti a si nfi onirũru ifẹkufẹ fà kiri, 7 Nwọn nfi igbagbogbo kẹ́kọ, nwọn kò si le de oju ìmọ otitọ. 8 Njẹ gẹgẹ bi Janesi ati Jamberi ti kọ oju ija si Mose, bẹ̃li awọn wọnyi kọ oju ija si otitọ: awọn enia ti inu wọn dibajẹ, awọn ẹni ìtanù niti ọran igbagbọ́.

9 Ṣugbọn nwọn kì yio lọ siwaju jù bẹ̃lọ: nitori wère wọn yio farahan fun gbogbo enia gẹgẹ bi tiwọn ti yọri si.

A Tún Kìlọ̀ fún Timotiu


10 Ṣugbọn iwọ ti mọ̀ ẹkọ́ mi, igbesi aiye mi, ipinnu, igbagbọ́, ipamọra, ifẹ́ni, sũru, 11 Inunibini, iyà; awọn ohun ti o dé bá mi ni Antioku, ni Ikonioni ati ni Listra; awọn inunibini ti mo faradà: Oluwa si gbà mi kuro ninu gbogbo wọn. 12 Nitõtọ, gbogbo awọn ti o fẹ mã gbé igbé ìwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu, yio farada inunibini. 13 Ṣugbọn awọn enia buburu, ati awọn ẹlẹtàn yio mã gbilẹ siwaju si i, nwọn o mã tàn-ni-jẹ, a o si mã tàn wọn jẹ. 14 Ṣugbọn iwọ duro ninu nkan wọnni ti iwọ ti kọ́, ti a si ti jẹ ki oju rẹ dá ṣáṣa si, ki iwọ ki o si mọ̀ ọdọ ẹniti iwọ gbé kọ́ wọn; 15 Ati pe lati igba ọmọde ni iwọ ti mọ̀ iwe-mimọ́, ti o le sọ ọ di ọlọ́gbọn si igbala nipasẹ igbagbọ́ ninu Kristi Jesu. 16 Gbogbo iwe-mimọ́ ti o ni imísi Ọlọrun li o si ni ère fun ẹkọ́, fun ibani-wi, fun itọ́ni, fun ikọ́ni ti o wà ninu ododo: 17 Ki enia Ọlọrun ki o le pé, ti a ti mura silẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.

2 Timothy 3

"Difficult Times Will Come"

1 But realize this, that in the last days difficult times will come.2 For men will be lovers of self, lovers of money, boastful, arrogant, revilers, disobedient to parents, ungrateful, unholy,3 unloving, irreconcilable, malicious gossips, without self-control, brutal, haters of good,4 treacherous, reckless, conceited, lovers of pleasure rather than lovers of God,5 holding to a form of godliness, although they have denied its power; Avoid such men as these.6 For among them are those who enter into households and captivate weak women weighed down with sins, led on by various impulses,7 always learning and never able to come to the knowledge of the truth.8 Just as Jannes and Jambres opposed Moses, so these men also oppose the truth, men of depraved mind, rejected in regard to the faith.9 But they will not make further progress; for their folly will be obvious to all, just as Jannes's and Jambres's folly was also.

10 Now you followed my teaching, conduct, purpose, faith, patience, love, perseverance,11 persecutions, and sufferings, such as happened to me at Antioch, at Iconium and at Lystra; what persecutions I endured, and out of them all the Lord rescued me!12 Indeed, all who desire to live godly in Christ Jesus will be persecuted.13 But evil men and impostors will proceed from bad to worse, deceiving and being deceived.14 You, however, continue in the things you have learned and become convinced of, knowing from whom you have learned them, 15 and that from childhood you have known the sacred writings which are able to give you the wisdom that leads to salvation through faith which is in Christ Jesus.16 All Scripture is inspired by God and profitable for teaching, for reproof, for correction, for training in righteousness;17 so that the man of God may be adequate, equipped for every good work.