III. Joh 1
Ìkíni
1 ALÀGBA si Gaiu olufẹ, ẹniti mo fẹ ninu otitọ. 2 Olufẹ, emi ngbadura pe ninu ohun gbogbo ki o le mã dara fun ọ, ki o si mã wà ni ilera, ani bi o ti dara fun ọkàn rẹ. 3 Nitori mo yọ̀ gidigidi, nigbati awọn arakunrin de ti nwọn si jẹri si otitọ rẹ, ani bi iwọ ti nrìn ninu otitọ.
4 Emi kò ni ayọ̀ ti o pọjù eyi lọ, ki emi ki o mã gbọ́ pe, awọn ọmọ mi nrìn ninu otitọ.Àjọṣepọ̀
5 Olufẹ, iwọ nṣe iṣẹ igbagbọ li ohunkohun ti o bá nṣe fun awọn ti iṣe ará ati fun awọn alejò; 6 Ti nwọn jẹri ifẹ rẹ niwaju ijọ: bi ìwọ bá npese fun wọn li ọna ajo wọn bi o ti yẹ nipa ti Ọlọrun, iwọ o ṣe ohun ti o dara. 7 Nitoripe nitori orukọ rẹ̀ ni nwọn ṣe jade lọ, li aigbà ohunkohun lọwọ awọn Keferi.
8 Njẹ o yẹ ki awa ki o gbà irú awọn wọnni, ki awa ki o le jẹ́ alabaṣiṣẹpọ pẹlu otitọ.Diotirefe lòdì sí wa
9 Emi kọwe si ijọ: ṣugbọn Diotrefe, ẹniti o fẹ lati jẹ olori larin wọn, kò gbà wa.
10 Nitorina bi mo ba de, emi o mu iṣẹ rẹ̀ ti o ṣe wá si iranti, ti o nsọ ọrọ buburu ati isọkusọ si wa: eyini kò si tẹ́ ẹ lọrùn, bẹ̃ni on tikararẹ̀ kò gbà awọn ará, awọn ti o si nfẹ gbà wọn, o ndá wọn lẹkun, o si nlé wọn jade kuro ninu ijọ.Ọ̀rọ̀ Ìyànjú
11 Olufẹ, máṣe afarawe ohun ti iṣe ibi, bikoṣe ohun ti iṣe rere. Ẹniti o ba nṣe rere ti Ọlọrun ni: ẹniti o ba nṣe buburu kò ri Ọlọrun.
12 Demetriu li ẹri rere lọdọ gbogbo enia ati ti otitọ tikararẹ̀ pẹlu: nitõtọ, awa pẹlu si gbà ẹrí rẹ̀ jẹ; ẹnyin si mọ̀ pe otitọ ni ẹrí wa.Ó Dìgbà Díẹ̀
13 Emi ní ohun pupọ̀ lati kọwe si ọ, ṣugbọn emi kò fẹ fi tàdãwa on kalamu kọ wọn. 14 Ṣugbọn mo ni ireti lati ri ọ laipẹ, a o si sọrọ li ojukoju. 15 Alafia fun ọ. Awọn ọrẹ́ kí ọ. Kí awọn ọrẹ́ li ọkọ̃kan.11-Feb-2009@11:05, Backup Description=11-Feb-2009@09:10, Ayo Durodola -
08-Apr-2009@14:15, Backup Description=08-Apr-2009@08:23, Ayo Durodola -
08-Apr-2009@14:52, Backup Description=08-Apr-2009@14:37, Ayo Durodola -
22-Dec-2009@14:07, Backup Description=22-Dec-2009@14:01, victor Damilare -
3 John 1
You Walk in the Truth
1 The elder to the beloved Gaius, whom I love in truth.
2 Beloved, I pray that in all respects you may prosper and be in good health, just as your soul prospers.3 For I was very glad when brethren came and testified to your truth, that is, how you are walking in truth.4 I have no greater joy than this, to hear of my children walking in the truth.
5 Beloved, you are acting faithfully in whatever you accomplish for the brethren, and especially when they are strangers;6 and they have testified to your love before the church. You will do well to send them on their way in a manner worthy of God.7 For they went out for the sake of the Name, accepting nothing from the Gentiles.8 Therefore we ought to support such men, so that we may be fellow workers with the truth.
9 I wrote something to the church; but Diotrephes, who loves to be first among them, does not accept what we say.10 For this reason, if I come, I will call attention to his deeds which he does, unjustly accusing us with wicked words; and not satisfied with this, he himself does not receive the brethren, either, and he forbids those who desire to do so and puts them out of the church.
11 Beloved, do not imitate what is evil, but what is good. The one who does good is of God; the one who does evil has not seen God.12 Demetrius has received a good testimony from everyone, and from the truth itself; and we add our testimony, and you know that our testimony is true.
13 I had many things to write to you, but I am not willing to write them to you with pen and ink;14 but I hope to see you shortly, and we will speak face to face.
15 Peace be to you. The friends greet you. Greet the friends by name.