Iṣe Apo 18
Iṣẹ́ Paulu ní Kọrinti
1 LẸHIN nkan wọnyi, Paulu jade kuro ni Ateni, o si lọ si Korinti; 2 O si ri Ju kan ti a npè ni Akuila, ti a bí ni Pontu, ti o ti Itali de nilọ̃lọ̃, pẹlu Priskilla aya rẹ̀; nitoriti Klaudiu paṣẹ pe, ki gbogbo awọn Ju ki o jade kuro ni Romu: o si tọ̀ wọn wá. 3 Ati itori ti iṣe oniṣẹ ọnà kanna, o ba wọn joko, o si nṣiṣẹ: nitori agọ́ pipa ni iṣẹ ọnà wọn. 4 O si nfọ̀rọ̀ we ọrọ fun wọn ninu sinagogu li ọjọjọ isimi, o si nyi awọn Ju ati awọn Hellene li ọkàn pada. 5 Nigbati Sila on Timotiu si ti Makedonia wá, ọrọ na ká Paulu lara, o nfi hàn, o sọ fun awọn Ju pe, Jesu ni Kristi na. 6 Nigbati nwọn si wà li òdi, ti nwọn si nsọrọ-odi, o gbọ̀n aṣọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ̀jẹ nyin mbẹ lori ara nyin; ọrùn emi mọ́: lati isisiyi lọ emi o tọ̀ awọn Keferi lọ. 7 O si lọ kuro nibẹ̀, o wọ̀ ile ọkunrin kan ti a npè ni Titu Justu, ẹniti o nsìn Ọlọrun ti ile rẹ̀ fi ara mọ́ sinagogu tímọ́tímọ́. 8 Ati Krispu, olori sinagogu, o gbà Oluwa gbọ́ pẹlu gbogbo ile rẹ̀; ati ọ̀pọ ninu awọn ara Korinti, nigbati nwọn gbọ́, nwọn gbagbọ́, a si baptisi wọn. 9 Oluwa si sọ fun Paulu li oru li ojuran pe, Má bẹ̀ru, sá mã sọ, má si ṣe pa ẹnu rẹ mọ́: 10 Nitoriti emi wà pẹlu rẹ, kò si si ẹniti yio dide si ọ lati pa ọ lara: nitori mo li enia pipọ ni ilu yi.
11 O si joko nibẹ̀ li ọdún kan on oṣù mẹfa, o nkọ́ni li ọ̀rọ Ọlọrun lãrin wọn.Ọlọrun Láàrin Wọn.
12 Nigbati Gallioni si jẹ bãlẹ Akaia, awọn Ju fi ọkàn kan dide si Paulu, nwọn si mu u wá siwaju itẹ idajọ. 13 Nwọn wipe, ọkunrin yi nyi awọn enia li ọkàn pada, lati mã sin Ọlọrun lodi si ofin. 14 Nigbati Paulu nfẹ ati dahùn, Gallioni wi fun awọn Ju pe, Ibaṣepe ọ̀ran buburu tabi ti jagidijagan kan ni, bi ọ̀rọ ti ri, ẹnyin Ju, emi iba gbè nyin: 15 Ṣugbọn bi o ba ṣe ọ̀ran nipa ọ̀rọ ati orukọ, ati ti ofin nyin ni, ki ẹnyin ki o bojuto o fun ara nyin, nitoriti emi kò fẹ ṣe onidajọ nkan bawọnni. 16 O si lé wọn kuro ni ibi itẹ idajọ.
17 Gbogbo awọn Hellene si mu Sostene, olori sinagogu, nwọn si lù u niwaju itẹ idajọ. Gallioni kò si ṣú si nkan wọnyi.Paulu Pada Lọ sí Antioku
18 Paulu si duro si i nibẹ̀ li ọjọ pipọ, nigbati o si dágbere fun awọn arakunrin, o ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, ati Priskilla ati Akuila pẹlu rẹ̀; o ti fá ori rẹ̀ ni Kenkrea: nitoriti o ti jẹjẹ. 19 O si sọkalẹ wá si Efesu, o si fi wọn silẹ nibẹ̀: ṣugbọn on tikararẹ̀ wọ̀ inu sinagogu lọ, o si ba awọn Ju fi ọrọ we ọrọ. 20 Nigbati nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o ba awọn joko diẹ si i, o kọ̀; 21 Ṣugbọn o dágbere fun wọn, o si wipe, Emi kò gbọdọ ṣaima ṣe ajọ ọdún ti mbọ̀ yi ni Jerusalemu bi o ti wù ki o ri: ṣugbọn emi ó tún pada tọ̀ nyin wá, bi Ọlọrun ba fẹ. O si ṣikọ̀ ni Efesu. 22 Nigbati o si ti gúnlẹ ni Kesarea, ti o goke, ti o si ki ijọ, o sọkalẹ lọ si Antioku.
23 Nigbati o si gbé ọjọ diẹ nibẹ̀, o lọ, o si kọja ni ilẹ Galatia on Frigia lẹsẹsẹ, o nmu gbogbo awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le.Apolo Dé Efesu
24 Ju kan si wà ti a npè ni Apollo, ti a bí ni Aleksandria, ọkunrin ọlọrọ li ẹnu, ti o pọ̀ ni iwe-mimọ́, o wá si Efesu. 25 Ọkunrin yi li a ti kọ́ ni ọ̀na ti Oluwa; o si ṣe ẹniti o gboná li ọkàn, o nfi ãyan nsọ̀rọ, o si nkọ́ni ni nkan ti Oluwa; kìki baptismu ti Johanu li o mọ̀. 26 O si bẹ̀rẹ si fi igboiya sọrọ ni sinagogu: nigbati Akuila on Priskilla ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, nwọn mu u si ọdọ nwọn si tubọ sọ idi ọ̀na Ọlọrun fun u dajudaju. 27 Nigbati o si nfẹ kọja lọ si Akaia, awọn arakunrin gba a ni iyanju, nwọn si kọwe si awọn ọmọ-ẹhin ki nwọn ki o gba a: nigbati o si de, o ràn awọn ti o gbagbọ́ nipa ore-ọfẹ lọwọ pupọ. 28 Nitoriti o sọ asọye fun awọn Ju ni gbangba, o nfi i hàn ninu iwe-mimọ́ pe, Jesu ni Kristi.
Acts 18
Paul at Corinth
1 After these things he left Athens and went to Corinth.2 And he found a Jew named Aquila, a native of Pontus, having recently come from Italy with his wife Priscilla, because Claudius had commanded all the Jews to leave Rome. He came to them,3 and because he was of the same trade, he stayed with them and they were working, for by trade they were tent-makers.4 And he was reasoning in the synagogue every Sabbath and trying to persuade Jews and Greeks.
5 But when Silas and Timothy came down from Macedonia, Paul began devoting himself completely to the word, solemnly testifying to the Jews that Jesus was the Christ.6 But when they resisted and blasphemed, he shook out his garments and said to them, "Your blood be on your own heads! I am clean. From now on I will go to the Gentiles."7 Then he left there and went to the house of a man named Titius Justus, a worshiper of God, whose house was next to the synagogue.8 Crispus, the leader of the synagogue, believed in the Lord with all his household, and many of the Corinthians when they heard were believing and being baptized.9 And the Lord said to Paul in the night by a vision, "Do not be afraid any longer, but go on speaking and do not be silent;10 for I am with you, and no man will attack you in order to harm you, for I have many people in this city."11 And he settled there a year and six months, teaching the word of God among them.
12 But while Gallio was proconsul of Achaia, the Jews with one accord rose up against Paul and brought him before the judgment seat,13 saying, "This man persuades men to worship God contrary to the law."14 But when Paul was about to open his mouth, Gallio said to the Jews, "If it were a matter of wrong or of vicious crime, O Jews, it would be reasonable for me to put up with you;15 but if there are questions about words and names and your own law, look after it yourselves; I am unwilling to be a judge of these matters."16 And he drove them away from the judgment seat.17 And they all took hold of Sosthenes, the leader of the synagogue, and began beating him in front of the judgment seat. But Gallio was not concerned about any of these things.
18 Paul, having remained many days longer, took leave of the brethren and put out to sea for Syria, and with him were Priscilla and Aquila. In Cenchrea he had his hair cut, for he was keeping a vow.19 They came to Ephesus, and he left them there. Now he himself entered the synagogue and reasoned with the Jews.20 When they asked him to stay for a longer time, he did not consent,21 but taking leave of them and saying, "I will return to you again if God wills," he set sail from Ephesus.
22 When he had landed at Caesarea, he went up and greeted the church, and went down to Antioch.
Third Missionary Journey
23 And having spent some time there, he left and passed successively through the Galatian region and Phrygia, strengthening all the disciples.
24 Now a Jew named Apollos, an Alexandrian by birth, an eloquent man, came to Ephesus; and he was mighty in the Scriptures.25 This man had been instructed in the way of the Lord; and being fervent in spirit, he was speaking and teaching accurately the things concerning Jesus, being acquainted only with the baptism of John;26 and he began to speak out boldly in the synagogue. But when Priscilla and Aquila heard him, they took him aside and explained to him the way of God more accurately.27 And when he wanted to go across to Achaia, the brethren encouraged him and wrote to the disciples to welcome him; and when he had arrived, he greatly helped those who had believed through grace,28 for he powerfully refuted the Jews in public, demonstrating by the Scriptures that Jesus was the Christ.