previous next

Iṣe Apo 19

Paulu Dé Efesu

1 O si ṣe, nigbati Apollo ti wà ni Korinti, ti Paulu kọja lọ niha ẹkùn oke, o wá si Efesu: o si ri awọn ọmọ-ẹhin kan; 2 O wi fun wọn pe, Ẹnyin ha gbà Ẹmí Mimọ́ na nigbati ẹnyin gbagbọ́? Nwọn si wi fun u pe, Awa kò gbọ́ rara bi Ẹmí Mimọ́ kan wà. 3 O si wipe, Njẹ baptismu wo li a ha baptisi nyin si? Nwọn si wipe, Si baptismu ti Johanu. 4 Paulu si wipe, Nitõtọ, ni Johanu fi baptismu ti ironupiwada baptisi, o nwi fun awọn enia pe, ki nwọn ki o gbà ẹniti mbọ̀ lẹhin on gbọ, eyini ni Kristi Jesu. 5 Nigbati nwọn si gbọ́, a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa. 6 Nigbati Paulu si gbe ọwọ́ le wọn, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn; nwọn si nfọ̀ ède miran, nwọn si nsọ asọtẹlẹ. 7 Iye awọn ọkunrin na gbogbo to mejila. 8 Nigbati o si wọ̀ inu sinagogu lọ, o fi igboiya sọ̀rọ li oṣù mẹta, o nfi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀, o si nyi wọn lọkan pada si nkan ti iṣe ti ijọba Ọlọrun. 9 Ṣugbọn nigbati ọkàn awọn miran ninu wọn di lile, ti nwọn kò si gbagbọ́, ti nwọn nsọ̀rọ ibi si Ọna na niwaju ijọ enia, o lọ kuro lọdọ wọn, o si yà awọn ọmọ-ẹhin sọtọ̀, o si nsọ asọye li ojojumọ́ ni ile-iwe Tirannu.

10 Eyi nlọ bẹ̃ fun iwọn ọdún meji; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti ngbe Asia gbọ́ ọ̀rọ Jesu Oluwa, ati awọn Ju ati awọn Hellene.

Àwọn Ọmọ Skefa


11 Ọlọrun si ti ọwọ́ Paulu ṣe iṣẹ aṣẹ akanṣe, 12 Tobẹ̃ ti a fi nmu gèle ati ibantẹ́ ara rẹ̀ tọ̀ awọn olokunrun lọ, arùn si fi wọn silẹ, ati awọn ẹmi buburu si jade kuro lara wọn. 13 Ṣugbọn awọn Ju kan alarinkiri, alẹmi-èṣu-jade, dawọle e li adabọwọ ara wọn, lati pè orukọ Jesu Oluwa si awọn ti o li ẹmi buburu, wipe, Awa fi orukọ Jesu ti Paulu nwasu fi nyin bu. 14 Awọn meje kan si wà, ọmọ ẹnikan ti a npè ni Skefa, Ju, ati olori kan ninu awọn alufa, ti nwọn ṣe bẹ̃. 15 Ẹmi buburu na si dahùn, o ni, Jesu emi mọ̀, Paulu emi si mọ̀; ṣugbọn tali ẹnyin? 16 Nigbati ọkunrin ti ẹmi buburu wà lara rẹ̀ si fò mọ́ wọn, o ba wọn dimú, o bori wọn, bẹ̃ni nwọn sá jade kuro ni ile na ni ìhoho ati ni ifarapa. 17 Ihìn yi si di mimọ̀ fun gbogbo awọn Ju ati awọn ara Hellene pẹlu ti o ṣe atipo ni Efesu; ẹ̀ru si ba gbogbo wọn, a si gbé orukọ Jesu Oluwa ga. 18 Ọ̀pọ awọn ti nwọn gbagbọ́ si wá, nwọn jẹwọ, nwọn si fi iṣẹ wọn hàn. 19 Kì isi ṣe diẹ ninu awọn ti nṣe àlúpàyídà li o kó iwe wọn jọ, nwọn dáná sun wọn loju gbogbo enia: nwọn si ṣírò iye wọn, nwọn si ri i, o jẹ ẹgbã-mẹdọgbọ̀n iwọn fadaka.

20 Bẹ̃li ọ̀rọ Oluwa si gbilẹ si i gidigidi, o si gbilẹ.

Ìrúkèrúdò Bẹ́ Sílẹ̀ ní Efesu


21 Njẹ bi nkan wọnyi ti pari tan, Paulu pinnu rẹ̀ li ọkàn pe, nigbati on ba kọja ni Makedonia ati Akaia, on ó lọ si Jerusalemu, o wipe, Lẹhin igba ti mo ba de ibẹ̀, emi kò le ṣaima ri Romu pẹlu. 22 Nigbati o si ti rán meji ninu awọn ti nṣe iranṣẹ fun u lọ si Makedonia, Timotiu ati Erastu, on tikararẹ̀ duro ni Asia ni igba diẹ na. 23 Li akokò na èmìmì diẹ ki o wà nitori Ọna na. 24 Nitori ọkunrin kan ti a npè ni Demetriu, alagbẹdẹ fadaka, ti ima fi fadaka ṣe ile-oriṣa fun Diana, o mu ère ti kò mọ̀ ni iwọn fun awọn oniṣọnà wá; 25 Nigbati o pè wọn jọ, ati irú awọn ọlọnà bẹ̃, o ni, Alàgba, ẹnyin mọ̀ pe nipa iṣẹ-ọna yi li awa fi li ọrọ̀ wa. 26 Ẹnyin si ri, ẹ si gbọ́ pe, kì iṣe ni Efesu nikanṣoṣo ni, ṣugbọn o fẹrẹ ṣe gbogbo Asia, ni Paulu yi nyi ọ̀pọ enia li ọkàn pada, ti o si ndari wọn wipe, Ohun ti a fi ọwọ́ ṣe, kì iṣe ọlọrun. 27 Ki si iṣe pe kìki iṣẹ-ọnà wa yi li o wà li ewu ati di asan; ṣugbọn ile Diana oriṣa nla yio si di gigàn pẹlu, ati gbogbo ọla nla rẹ̀ yio si run, ẹniti gbogbo Asia ati gbogbo aiye mbọ. 28 Nigbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn kún fun ibinu, nwọn kigbe, wipe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu. 29 Gbogbo ilu na si kún fun irukerudò: nwọn fi ọkàn kan rọ́ sinu ile ibĩṣire, nwọn si mu Gaiu ati Aristarku ara Makedonia, awọn ẹgbẹ ajọrin Paulu. 30 Nigbati Paulu si nfẹ wọ̀ ãrin awọn enia lọ, awọn ọmọ-ẹhin kò jẹ fun u. 31 Awọn olori kan ara Asia, ti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ranṣẹ si i, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe fi ara rẹ̀ wewu ninu ile ibiṣire. 32 Njẹ awọn kan nwi ohun kan, awọn miran nwi omiran: nitori ajọ di rudurudu; ati ọ̀pọ enia ni kò mọ̀ itori ohun ti nwọn tilẹ fi wọjọ pọ̀ si. 33 Nwọn si fà Aleksanderu kuro li awujọ, awọn Ju tì i ṣaju. Aleksanderu si juwọ́ si wọn, on iba si wi ti ẹnu rẹ̀ fun awọn enia. 34 Ṣugbọn nigbati nwọn mọ̀ pe Ju ni, gbogbo wọn li ohùn kan, niwọn wakati meji ọjọ, kigbe pe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu. 35 Nigbati akọwe ilu si mu ki ijọ enia dakẹ, o ni, Ẹnyin ará Efesu, tali ẹniti o wà ti kò mọ̀ pe, ilu ara Efesu ni iṣe olusin Diana oriṣa nla, ati ti ere ti o ti ọdọ Jupiteri bọ́ silẹ? 36 Njẹ bi a ko ti le sọrọ odi si nkan wọnni, o yẹ ki ẹ dakẹ, ki ẹnyin ki o máṣe fi iwara ṣe ohunkohun. 37 Nitoriti ẹnyin mu awọn ọkunrin wọnyi wá, nwọn kò kó ile oriṣa, bẹ̃ni nwọn kò sọrọ-odi si oriṣa wa. 38 Njẹ nitorina bi Demetriu, ati awọn oniṣọnà ti o wà pẹlu rẹ̀, ba li ọ̀rọ kan si ẹnikẹni, ile-ẹjọ ṣí silẹ, awọn onidajọ si mbẹ: jẹ ki nwọn ki o lọ ifi ara wọn sùn. 39 Ṣugbọn bi ẹ ba nwadi ohun kan nipa ọ̀ran miran, a ó pari rẹ̀ ni ajọ ti o tọ́. 40 Nitori awa sá wà li ewu ati pè bi lẽrè nitori ariwo oni yi, kò sa nidi, ati nitori eyi awa kì yio le dahun fun iwọjọ yi. 41 Nigbati o si ti sọ bẹ̃ tan, o tú ijọ na ká.

Acts 19

Paul at Ephesus

1 It happened that while Apollos was at Corinth, Paul passed through the upper country and came to Ephesus, and found some disciples.2 He said to them, "Did you receive the Holy Spirit when you believed?" And they said to him, "No, we have not even heard whether there is a Holy Spirit."3 And he said, "Into what then were you baptized?" And they said, "Into John's baptism."4 Paul said, "John baptized with the baptism of repentance, telling the people to believe in Him who was coming after him, that is, in Jesus."5 When they heard this, they were baptized in the name of the Lord Jesus.6 And when Paul had laid his hands upon them, the Holy Spirit came on them, and they began speaking with tongues and prophesying.7 There were in all about twelve men.

8 And he entered the synagogue and continued speaking out boldly for three months, reasoning and persuading them about the kingdom of God.9 But when some were becoming hardened and disobedient, speaking evil of the Way before the people, he withdrew from them and took away the disciples, reasoning daily in the school of Tyrannus.10 This took place for two years, so that all who lived in Asia heard the word of the Lord, both Jews and Greeks.

Miracles at Ephesus

11 God was performing extraordinary miracles by the hands of Paul,12 so that handkerchiefs or aprons were even carried from his body to the sick, and the diseases left them and the evil spirits went out.13 But also some of the Jewish exorcists, who went from place to place, attempted to name over those who had the evil spirits the name of the Lord Jesus, saying, "I adjure you by Jesus whom Paul preaches."14 Seven sons of one Sceva, a Jewish chief priest, were doing this.15 And the evil spirit answered and said to them, "I recognize Jesus, and I know about Paul, but who are you?"16 And the man, in whom was the evil spirit, leaped on them and subdued all of them and overpowered them, so that they fled out of that house naked and wounded.17 This became known to all, both Jews and Greeks, who lived in Ephesus; and fear fell upon them all and the name of the Lord Jesus was being magnified.18 Many also of those who had believed kept coming, confessing and disclosing their practices.19 And many of those who practiced magic brought their books together and began burning them in the sight of everyone; and they counted up the price of them and found it fifty thousand pieces of silver.20 So the word of the Lord was growing mightily and prevailing.

21 Now after these things were finished, Paul purposed in the Spirit to go to Jerusalem after he had passed through Macedonia and Achaia, saying, "After I have been there, I must also see Rome."22 And having sent into Macedonia two of those who ministered to him, Timothy and Erastus, he himself stayed in Asia for a while.

23 About that time there occurred no small disturbance concerning the Way.24 For a man named Demetrius, a silversmith, who made silver shrines of Artemis, was bringing no little business to the craftsmen;25 these he gathered together with the workmen of similar trades, and said, "Men, you know that our prosperity depends upon this business.26 You see and hear that not only in Ephesus, but in almost all of Asia, this Paul has persuaded and turned away a considerable number of people, saying that gods made with hands are no gods at all. 27 Not only is there danger that this trade of ours fall into disrepute, but also that the temple of the great goddess Artemis be regarded as worthless and that she whom all of Asia and the world worship will even be dethroned from her magnificence."

28 When they heard this and were filled with rage, they began crying out, saying, "Great is Artemis of the Ephesians!"29 The city was filled with the confusion, and they rushed with one accord into the theater, dragging along Gaius and Aristarchus, Paul's traveling companions from Macedonia.30 And when Paul wanted to go into the assembly, the disciples would not let him.31 Also some of the tAsiarchs who were friends of his sent to him and repeatedly urged him not to venture into the theater.32 So then, some were shouting one thing and some another, for the assembly was in confusion and the majority did not know for what reason they had come together.33 Some of the crowd concluded it was Alexander, since the Jews had put him forward; and having motioned with his hand, Alexander was intending to make a defense to the assembly.34 But when they recognized that he was a Jew, a single outcry arose from them all as they shouted for about two hours, "Great is Artemis of the Ephesians!"35 After quieting the crowd, the town clerk *said, "Men of Ephesus, what man is there after all who does not know that the city of the Ephesians is guardian of the temple of the great Artemis and of the image which fell down from heaven?36 So, since these are undeniable facts, you ought to keep calm and to do nothing rash.37 For you have brought these men here who are neither robbers of temples nor blasphemers of our goddess.38 So then, if Demetrius and the craftsmen who are with him have a complaint against any man, the courts are in session and proconsuls are available; let them bring charges against one another.39 But if you want anything beyond this, it shall be settled in the lawful assembly.40 For indeed we are in danger of being accused of a riot in connection with today's events, since there is no real cause for it, and in this connection we will be unable to account for this disorderly gathering."41 After saying this he dismissed the assembly.