previous next

Iṣe Apo 2

Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ti Ṣe Dé

1 NIGBATI ọjọ Pentekosti si de, gbogbo nwọn fi ọkàn kan wà nibikan. 2 Lojijì iró si ti ọrun wá, gẹgẹ bi iró ẹ̀fũfu lile, o si kún gbogbo ile nibiti nwọn gbé joko. 3 Ẹla ahọn bi ti iná si yọ si wọn, o pin ara rẹ̀ o si bà le olukuluku wọn. 4 Gbogbo nwọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si bẹ̀rẹ si ifi ède miran sọrọ, gẹgẹ bi Ẹmí ti fun wọn li ohùn. 5 Awọn Ju olufọkànsin lati orilẹ-ede gbogbo labẹ ọrun si ngbe Jerusalemu. 6 Nigbati nwọn si gbọ iró yi, ọ̀pọlọpọ enia pejọ, nwọn si damu, nitoriti olukuluku gbọ́ nwọn nsọ̀rọ li ède rẹ̀. 7 Hà si ṣe gbogbo wọn, ẹnu si yà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Wo o, ara Galili ki gbogbo awọn ti nsọ̀rọ wọnyi iṣe? 8 Ẽha si ti ṣe ti awa fi ngbọ́ olukuluku li ede wa ninu eyiti a bí wa? 9 Awọn ará Partia, ati Media, ati Elamu, ati awọn ti ngbé Mesopotamia, Judea, ati Kappadokia, Pontu, ati Asia, 10 Frigia, ati Pamfilia, Egipti, ati ẹkùn Libia niha Kirene, ati awọn atipo Romu, awọn Ju ati awọn alawọṣe Ju, 11 Awọn ara Krete ati Arabia, awa gbọ́ nwọn nsọ̀rọ iṣẹ iyanu nla Ọlọrun li ède wa. 12 Hà si ṣe gbogbo wọn, o si rú wọn lojú, nwọn wi fun ara wọn pe, Kili a le mọ̀ eyi si?

13 Ṣugbọn awọn ẹlomiran nṣẹ̀fẹ nwọn si wipe, Awọn ọkunrin wọnyi kún fun waini titun.

Iwaasu Peteru ní Ọjọ́ Pẹntikọsti


14 Ṣugbọn Peteru dide duro pẹlu awọn mọkanla iyokù, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o si wi fun wọn gbangba pe, Ẹnyin enia Judea, ati gbogbo ẹnyin ti ngbé Jerusalemu, ki eyiyi ki o yé nyin, ki ẹ si fetísi ọ̀rọ mi: 15 Nitori awọn wọnyi kò mutiyó, bi ẹnyin ti fi pè; wakati kẹta ọjọ sá li eyi. 16 Ṣugbọn eyi li ọ̀rọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joeli wá pe; 17 Ọlọrun wipe, Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmí mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyin-ọkunrin ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin nyin yio si ma ri iran, awọn arugbo nyin yio si ma lá alá: 18 Ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi ọkunrin, ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi obinrin li emi o tú ninu Ẹmí mi jade li ọjọ wọnni; nwọn o si ma sọtẹlẹ: 19 Emi o si fi iṣẹ iyanu hàn loke li ọrun, ati àmi nisalẹ lori ilẹ: ẹ̀jẹ, ati iná, ati ríru ẹ̃fin; 20 A o sọ õrùn di òkunkun, ati oṣupa di ẹ̀jẹ, ki ọjọ nla afiyesi Oluwa ki o to de: 21 Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba pè orukọ Oluwa, a o gbà a là. 22 Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ wọnyi: Jesu ti Nasareti, ọkunrin ti a fi hàn fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá, nipa iṣẹ agbara ati ti iyanu, ati ti àmi ti Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe lãrin nyin, bi ẹnyin tikaranyin ti mọ̀ pẹlu: 23 Ẹniti a ti fi le nyin lọwọ nipa ipinnu ìmọ ati imọtẹlẹ Ọlọrun; on li ẹnyin mu, ti ẹ ti ọwọ awọn enia buburu kàn mọ agbelebu, ti ẹ si pa. 24 Ẹniti Ọlọrun gbé dide, nigbati o ti tú irora ikú: nitoriti kò ṣe iṣe fun u lati dì i mu. 25 Nitori Dafidi ti wi nipa tirẹ̀ pe, Mo ri Oluwa nigba-gbogbo niwaju mi, nitoriti o mbẹ li ọwọ́ ọtún mi, ki a mà bà ṣí mi ni ipò: 26 Nitorina inu mi dùn, ahọn mi si yọ̀; pẹlupẹlu ara mi yio si simi ni ireti: 27 Nitoriti iwọ ki yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú, bẹ̃ni iwọ ki yio jẹ ki Ẹni-Mimọ́ rẹ ki o ri idibajẹ. 28 Iwọ mu mi mọ̀ ọ̀na iye; iwọ ó mu mi kún fun ayọ̀ ni iwaju rẹ. 29 Ará, ẹ jẹ ki emi ki o sọ fun nyin gbangba niti Dafidi baba nla pe, o kú, a si sin i, ibojì rẹ̀ si mbẹ lọdọ wa titi o fi di oni yi. 30 Nitoriti iṣe woli, ati bi o ti mọ̀ pe, Ọlọrun ti fi ibura ṣe ileri fun u pe, Ninu irú-ọmọ inu rẹ̀, on ó mu ọ̀kan ijoko lori itẹ́ rẹ̀; 31 O ri eyi tẹlẹ̀, o sọ ti ajinde Kristi pe, a kò fi ọkàn rẹ̀ silẹ ni ipò-okù, bẹ̃li ara rẹ̀ kò ri idibajẹ. 32 Jesu na yi li Ọlọrun ti ji dide, ẹlẹri eyiti gbogbo wa iṣe. 33 Nitorina bi a ti fi ọwọ́ ọtún Ọlọrun gbe e ga, ti o si ti gbà ileri Ẹmí Mimọ́ lati ọdọ Baba, o tú eyi silẹ, ti ẹnyin ri, ti ẹ si gbọ́. 34 Dafidi kò sá gòke lọ si ọrun: ṣugbọn on tikararẹ̀ wipe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi, 35 Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apotì itisẹ rẹ. 36 Njẹ ki gbogbo ile Israeli ki o mọ̀ dajudaju pe, Ọlọrun ti fi Jesu na, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, jẹ Oluwa ati Kristi. 37 Nigbati nwọn si gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ, nwọn si sọ fun Peteru ati awọn aposteli iyokù pe, Ará, kini ki awa ki o ṣe? 38 Peteru si wi fun wọn pe, Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku nyin li orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹ̀ṣẹ nyin, ẹnyin o si gbà ẹbun Ẹmi Mimọ́. 39 Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jìna rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè. 40 Ati ọ̀rọ pupọ miran li o fi njẹri ti o si nfi ngbà wọn niyanju wipe, Ẹ gbà ara nyin là lọwọ iran arekereke yi. 41 Nitorina awọn ti o si fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ rẹ̀ a baptisi wọn: li ọjọ na a si kà ìwọn ẹgbẹdogun ọkàn kún wọn.

42 Nwọn si duro ṣinṣin ninu ẹkọ́ awọn aposteli, ati ni idapọ, ni bibu akara ati ninu adura.
43 Ẹ̀rù si ba gbogbo ọkàn: iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi pipọ li a ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe. 44 Gbogbo awọn ti o si gbagbọ́ wà ni ibikan, nwọn ni ohun gbogbo ṣọkan; 45 Nwọn si ntà ohun ini ati ẹrù wọn, nwọn si npín wọn fun olukuluku, gẹgẹ bi ẹnikẹni ti ṣe alaini. 46 Nwọn si nfi ọkàn kan duro li ojojumọ́ ninu tẹmpili ati ni bibu akara ni ile, nwọn nfi inu didùn ati ọkàn kan jẹ onjẹ wọn. 47 Nwọn nyin Ọlọrun, nwọn si ni ojurere lọdọ enia gbogbo. Oluwa si nyàn kún wọn li ojojumọ awọn ti a ngbalà.

Acts 2

The Day of Pentecost

1 When the day of Pentecost had come, they were all together in one place.2 And suddenly there came from heaven a noise like a violent rushing wind, and it filled the whole house where they were sitting.3 And there appeared to them tongues as of fire distributing themselves, and they rested on each one of them.4 And they were all filled with the Holy Spirit and began to speak with other tongues, as the Spirit was giving them utterance.

5 Now there were Jews living in Jerusalem, devout men from every nation under heaven.6 And when this sound occurred, the crowd came together, and were bewildered because each one of them was hearing them speak in his own language.7 They were amazed and astonished, saying, "Why, are not all these who are speaking Galileans?8 And how is it that we each hear them in our own language to which we were born?9 Parthians and Medes and Elamites, and residents of Mesopotamia, Judea and Cappadocia, Pontus and Asia,10 Phrygia and Pamphylia, Egypt and the districts of Libya around Cyrene, and visitors from Rome, both Jews and tproselytes,11 Cretans and Arabs-we hear them in our own tongues speaking of the mighty deeds of God."12 And they all continued in amazement and great perplexity, saying to one another, "What does this mean?"13 But others were mocking and saying, "They are full of sweet wine."

Peter's Sermon

14 But Peter, taking his stand with the eleven, raised his voice and declared to them: "Men of Judea and all you who live in Jerusalem, let this be known to you and give heed to my words.15 For these men are not drunk, as you suppose, for it is only the tthird hour of the day;16 but this is what was spoken of through the prophet Joel:

17 'AND IT SHALL BE IN THE LAST DAYS,' God says,
'THAT I WILL POUR FORTH OF MY SPIRIT ON ALL MANKIND;
AND YOUR SONS AND YOUR DAUGHTERS SHALL PROPHESY,
AND YOUR YOUNG MEN SHALL SEE VISIONS,
AND YOUR OLD MEN SHALL DREAM DREAMS;

18 EVEN ON MY BONDSLAVES, BOTH MEN AND WOMEN,
I WILL IN THOSE DAYS POUR FORTH OF MY SPIRIT
And they shall prophesy.

19 'AND I WILL GRANT WONDERS IN THE SKY ABOVE
AND SIGNS ON THE EARTH BELOW,
BLOOD, AND FIRE, AND VAPOR OF SMOKE.

20 'THE SUN WILL BE TURNED INTO DARKNESS
AND THE MOON INTO BLOOD,
BEFORE THE GREAT AND GLORIOUS DAY OF THE LORD SHALL COME.

21 'AND IT SHALL BE THAT EVERYONE WHO CALLS ON THE NAME OF THE LORD WILL BE SAVED.'

22 "Men of Israel, listen to these words: Jesus the Nazarene, a man attested to you by God with miracles and wonders and signs which God performed through Him in your midst, just as you yourselves know-23 this Man, delivered over by the predetermined plan and foreknowledge of God, you nailed to a cross by the hands of godless men and put Him to death.24 But God raised Him up again, putting an end to the agony of death, since it was impossible for Him to be held in its power.25 For David says of Him,
'I SAW THE LORD ALWAYS IN MY PRESENCE;
FOR HE IS AT MY RIGHT HAND, SO THAT I WILL NOT BE SHAKEN.

26 'THEREFORE MY HEART WAS GLAD AND MY TONGUE EXULTED;
MOREOVER MY FLESH ALSO WILL LIVE IN HOPE;

27 BECAUSE YOU WILL NOT ABANDON MY SOUL TO HADES,
NOR ALLOW YOUR HOLY ONE TO UNDERGO DECAY.

28 'YOU HAVE MADE KNOWN TO ME THE WAYS OF LIFE;
YOU WILL MAKE ME FULL OF GLADNESS WITH YOUR PRESENCE.'

29 "Brethren, I may confidently say to you regarding the patriarch David that he both died and was buried, and his tomb is with us to this day.30 And so, because he was a prophet and knew that GOD HAD SWORN TO HIM WITH AN OATH TO SEAT one OF HIS DESCENDANTS ON HIS THRONE,31 he looked ahead and spoke of the resurrection of tthe Christ, that HE WAS NEITHER ABANDONED TO HADES, NOR DID His flesh SUFFER DECAY.32 This Jesus God raised up again, to which we are all witnesses.33 Therefore having been exalted to the right hand of God, and having received from the Father the promise of the Holy Spirit, He has poured forth this which you both see and hear.34 For it was not David who ascended into heaven, but he himself says:
'THE LORD SAID TO MY LORD,
"SIT AT MY RIGHT HAND,

35 UNTIL I MAKE YOUR ENEMIES A FOOTSTOOL FOR YOUR FEET."'36 Therefore let all the house of Israel know for certain that God has made Him both Lord and Christ-this Jesus whom you crucified."

The Ingathering

37 Now when they heard this, they were pierced to the heart, and said to Peter and the rest of the apostles, "Brethren, what shall we do?"38 Peter said to them, "Repent, and each of you be baptized in the name of Jesus Christ for the forgiveness of your sins; and you will receive the gift of the Holy Spirit.39 For the promise is for you and your children and for all who are far off, as many as the Lord our God will call to Himself."40 And with many other words he solemnly testified and kept on exhorting them, saying, "Be saved from this perverse generation!"41 So then, those who had received his word were baptized; and that day there were added about three thousand tsouls.42 They were continually devoting themselves to the apostles' teaching and to fellowship, to the breaking of bread and to prayer.

43 Everyone kept feeling a sense of awe; and many wonders and signs were taking place through the apostles.44 And all those who had believed twere together and had all things in common;45 and they began selling their property and possessions and were sharing them with all, as anyone might have need.46 Day by day continuing with one mind in the temple, and breaking bread from house to house, they were taking their meals together with gladness and sincerity of heart,47 praising God and having favor with all the people. And the Lord was adding to their number day by day those who were being saved.