Iṣe Apo 5
Anania ati Safira
1 ṢUGBỌN ọkunrin kan ti a npè ni Anania, pẹlu Safira aya rẹ̀, tà ilẹ iní kan. 2 O si yàn apakan pamọ́ ninu owo na, aya rẹ̀ ba a mọ̀ ọ pọ̀, o si mu apakan rẹ̀ wá, o si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli. 3 Ṣugbọn Peteru wipe, Anania, Ẽṣe ti Satani fi kún ọ li ọkàn lati ṣeke si Ẹmí Mimọ́, ti iwọ si fi yàn apakan pamọ́ ninu owo ilẹ na? 4 Nigbati o wà nibẹ, tirẹ ki iṣe? nigbati a si ta a tan, kò ha wà ni ikawọ ara rẹ? Ẽha ti ṣe ti iwọ fi rò kini yi li ọkàn rẹ? enia ki iwọ ṣeke si bikoṣe si Ọlọrun. 5 Nigbati Anania si gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o ṣubu lulẹ, o si kú: ẹ̀ru nla si ba gbogbo awọn ti o gbọ́. 6 Awọn ọdọmọkunrin si dide, nwọn dì i, nwọn si gbé e jade, nwọn si sin i. 7 O si to bi ìwọn wakati mẹta, aya rẹ̀ laimọ̀ ohun ti o ti ṣe, o wọle. 8 Peteru si da a lohùn pe, Wi fun mi, bi iye bayi li ẹnyin tà ilẹ na? O si wipe, Lõtọ iye bẹ̃ ni. 9 Peteru si wi fun u pe, Ẽṣe ti ẹnyin fohùn ṣọkan lati dán Ẹmí Oluwa wò? wò o, ẹsẹ awọn ti o sinkú ọkọ rẹ mbẹ li ẹnu ọ̀na, nwọn o si gbé ọ jade. 10 O si ṣubu lulẹ li ẹsẹ rẹ̀ lojukanna, o si kú: awọn ọdọmọkunrin si wọle, nwọn bá a o kú, nwọn si gbé e jade, nwọn sin i lẹba ọkọ rẹ̀.
11 Ẹru nla si ba gbogbo ijọ, ati gbogbo awọn ti o gbọ́ nkan wọnyi.Àwọn Aposteli Ṣe Iṣẹ́ Àmì Pupọ
12 A si ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu pipọ lãrin awọn enia: gbogbo wọn si fi ọkàn kan wà ni iloro Solomoni. 13 Ninu awọn iyokù ẹnikan kò daṣà ati dapọ mọ wọn: ṣugbọn enia nkókiki wọn. 14 A si nyàn awọn ti o gbà Oluwa gbọ kun wọn si i, ati ọkunrin ati obinrin; 15 Tobẹ̃ ti nwọn ngbé awọn abirùn jade si igboro, ti nwọn ntẹ́ wọn si ori akete ati ohun ibĩrọgbọku, pe bi Peteru ba nkọja ki ojiji rẹ̀ tilẹ le ṣijibò omiran ninu wọn.
16 Ọ̀pọ enia si ko ara wọn jọ lati awọn ilu ti o yi Jerusalemu ka, nwọn nmu awọn abirùn wá, ati awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ́: a si ṣe dida ara olukuluku wọn.A Ṣe Inúnibíni sí Àwọn Aposteli
17 Ṣugbọn olori alufa dide, ti on ti gbogbo awọn ti nwọn wà lọdọ rẹ̀ (ti iṣe ẹya ti awọn Sadusi), nwọn si kún fun owu. 18 Nwọn si nawọ́ mu awọn aposteli, nwọn si fi wọn sinu tubu. 19 Ṣugbọn angẹli Oluwa ṣí ilẹkun tubu li oru; nigbati o si mu wọn jade, o wipe, 20 Ẹ lọ, ẹ duro, ki ẹ si mã sọ gbogbo ọ̀rọ iye yi fun awọn enia ni tẹmpili. 21 Nigbati nwọn si gbọ́ yi, nwọn wọ̀ tẹmpili lọ ni kutukutu, nwọn si nkọ́ni. Ṣugbọn olori alufa de, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, nwọn si pè apejọ igbimọ, ati gbogbo awọn agbàgba awọn ọmọ Israeli, nwọn si ranṣẹ si ile tubu lati mu wọn wá. 22 Ṣugbọn nigbati awọn onṣẹ de ibẹ̀, nwọn kò si ri wọn ninu tubu, nwọn pada wá, nwọn si sọ pe, 23 Awa bá ile tubu o sé pinpin, ati awọn oluṣọ duro lode niwaju ilẹkun: ṣugbọn nigbati awa ṣílẹkun, awa kò bá ẹnikan ninu tubu. 24 Nigbati olori ẹṣọ́ tẹmpili ati awọn olori alufa si gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn dãmu nitori wọn pe, nibo li eyi ó yọri si. 25 Nigbana li ẹnikan de, o wi fun wọn pe, Wo o, awọn ọkunrin ti ẹnyin fi sinu tubu wà ni tẹmpili, nwọn duro nwọn si nkọ́ awọn enia. 26 Nigbana li olori ẹṣọ́ lọ pẹlu awọn onṣẹ, o si mu wọn wá kì iṣe pẹlu ipa: nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn enia, ki a má ba sọ wọn li okuta. 27 Nigbati nwọn si mu wọn de, nwọn mu wọn duro niwaju ajọ igbimọ; olori alufa si bi wọn lẽre, 28 Wipe, Awa kò ti kìlọ fun nyin gidigidi pe, ki ẹ maṣe fi orukọ yi kọ́ni mọ́? si wo o, ẹnyin ti fi ẹkọ́ nyin kún Jerusalemu, ẹ si npete ati mu ẹ̀jẹ ọkunrin yi wá si ori wa. 29 Ṣugbọn Peteru ati awọn aposteli dahùn, nwọn si wipe, Awa kò gbọdọ má gbọ́ ti Ọlọrun jù ti enia lọ. 30 Ọlọrun awọn baba wa ji Jesu dide, ẹniti ẹnyin pa, tí ẹnyin si gbe kọ́ sori igi. 31 On li Ọlọrun fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ gbéga lati jẹ Ọmọ alade ati Olugbala, lati fi ironupiwada fun Israeli, ati idariji ẹ̀ṣẹ. 32 Awa si li ẹlẹri nkan wọnyi; ati Ẹmí Mimọ́ pẹlu, ti Ọlọrun fifun awọn ti o gbọ́ tirẹ̀. 33 Ṣugbọn nigbati nwọn gbọ́ eyi, àiya wọn gbà ọgbẹ́ de inu, nwọn gbèro ati pa wọn. 34 Ṣugbọn ọkan ninu ajọ igbimọ, ti a npè ni Gamalieli, Farisi ati amofin, ti o ni iyìn gidigidi lọdọ gbogbo enia, o dide duro, o ni ki a mu awọn aposteli bì sẹhin diẹ; 35 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ọkunrin Israeli, ẹ kiyesi ara nyin li ohun ti ẹnyin npete ati ṣe si awọn ọkunrin wọnyi. 36 Nitori ṣaju ọjọ wọnyi ni Teuda dide, o nwipe ẹni nla kan li on; ẹniti ìwọn irinwo ọkunrin gbatì: ẹniti a pa; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a tú wọn ká, a si sọ wọn di asan. 37 Lẹhin ọkunrin yi ni Juda ti Galili dide lakoko kikà enia, o si fà enia pipọ lẹhin rẹ̀: on pẹlu ṣegbé; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a fọn wọn ká. 38 Njẹ emi wi fun nyin nisisiyi, Ẹ gafara fun awọn ọkunrin wọnyi, ki ẹ si jọwọ wọn jẹ: nitori bi ìmọ tabi iṣẹ yi ba jẹ ti enia, a o bì i ṣubu: 39 Ṣugbọn bi ti Ọlọrun ba ni, ẹnyin kì yio le bì i ṣubu; ki o ma ba jẹ pe, a ri nyin ẹ mba Ọlọrun jà. 40 Nwọn si tẹ̀ si tirẹ̀: nigbati nwọn si pè awọn aposteli wọle, nwọn lù wọn, nwọn si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ̀rọ li orukọ Jesu mọ́, nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ. 41 Nitorina nwọn si lọ kuro niwaju ajọ igbimọ: nwọn nyọ̀ nitori ti a kà wọn yẹ si ìya ijẹ nitori orukọ rẹ̀. 42 Ati li ojojumọ́ ni tẹmpili ati ni ile, nwọn kò dẹkun ikọ́ni, ati lati wasu Jesu Kristi.
Acts 5
Fate of Ananias and Sapphira
1 But a man named Ananias, with his wife Sapphira, sold a piece of property,2 and kept back some of the price for himself, with his wife's full knowledge, and bringing a portion of it, he laid it at the apostles' feet.3 But Peter said, "Ananias, why has Satan filled your heart to lie to the Holy Spirit and to keep back some of the price of the land?4 While it remained unsold, did it not remain your own? And after it was sold, was it not under your control? Why is it that you have conceived this deed in your heart? You have not lied to men but to God."5 And as he heard these words, Ananias fell down and breathed his last; and great fear came over all who heard of it.6 The young men got up and covered him up, and after carrying him out, they buried him.
7 Now there elapsed an interval of about three hours, and his wife came in, not knowing what had happened.8 And Peter responded to her, "Tell me whether you sold the land for such and such a price?" And she said, "Yes, that was the price."9 Then Peter said to her, "Why is it that you have agreed together to put the Spirit of the Lord to the test? Behold, the feet of those who have buried your husband are at the door, and they will carry you out as well. "10 And immediately she fell at his feet and breathed her last, and the young men came in and found her dead, and they carried her out and buried her beside her husband.11 And great fear came over the whole church, and over all who heard of these things.
12 At the hands of the apostles many signs and wonders were taking place among the people; and they were all with one accord in Solomon's portico.13 But none of the rest dared to associate with them; however, the people held them in high esteem.14 And all the more believers in the Lord, multitudes of men and women, were constantly added to their number, 15 to such an extent that they even carried the sick out into the streets and laid them on cots and pallets, so that when Peter came by at least his shadow might fall on any one of them.16 Also the people from the cities in the vicinity of Jerusalem were coming together, bringing people who were sick tor afflicted with unclean spirits, and they were all being healed.
Imprisonment and Release
17 But the high priest rose up, along with all his associates (that is the sect of the Sadducees), and they were filled with jealousy.18 They laid hands on the apostles and put them in a public jail.19 But during the night an angel of the Lord opened the gates of the prison, and taking them out he said,20 "Go, stand and speak to the people in the temple the whole message of this Life."
21 Upon hearing this, they entered into the temple about daybreak and began to teach.
Now when the high priest and his associates came, they called the Council together, even all the Senate of the sons of Israel, and sent orders to the prison house for them to be brought.22 But the officers who came did not find them in the prison; and they returned and reported back,23 saying, "We found the prison house locked quite securely and the guards standing at the doors; but when we had opened up, we found no one inside."24 Now when the captain of the temple guard and the chief priests heard these words, they were greatly perplexed about them as to what would come of this.25 But someone came and reported to them, "The men whom you put in prison are standing in the temple and teaching the people!"26 Then the captain went along with the officers and proceeded to bring them back without violence (for they were afraid of the people, that they might be stoned).
27 When they had brought them, they stood them before the Council. The high priest questioned them,28 saying, "We gave you strict orders not to continue teaching in this name, and yet, you have filled Jerusalem with your teaching and intend to bring this man's blood upon us."29 But Peter and the apostles answered, "We must obey God rather than men.30 The God of our fathers raised up Jesus, whom you had put to death by hanging Him on a cross.31 He is the one whom God exalted to His right hand as a Prince and a Savior, to grant repentance to Israel, and forgiveness of sins.32 And we are witnesses tof these things; and so is the Holy Spirit, whom God has given to those who obey Him."
Gamaliel's Counsel
33 But when they heard this, they were cut to the quick and intended to kill them.34 But a Pharisee named Gamaliel, a teacher of the Law, respected by all the people, stood up in the Council and gave orders to put the men outside for a short time.35 And he said to them, "Men of Israel, take care what you propose to do with these men.36 For some time ago Theudas rose up, claiming to be somebody, and a group of about four hundred men joined up with him. But he was killed, and all who followed him were dispersed and came to nothing.37 After this man, Judas of Galilee rose up in the days of the census and drew away some people after him; he too perished, and all those who followed him were scattered.38 So in the present case, I say to you, stay away from these men and let them alone, for if this plan or action is of men, it will be overthrown;39 but if it is of God, you will not be able to overthrow them; or else you may even be found fighting against God."
40 They took his advice; and after calling the apostles in, they flogged them and ordered them not to speak in the name of Jesus, and then released them.41 So they went on their way from the presence of the Council, rejoicing that they had been considered worthy to suffer shame for His name.42 And every day, in the temple and from house to house, they kept right on teaching and preaching Jesus as the Christ.