Iṣe Apo 9
Saulu di Onigbagbọ
(A. Apo 22:6-16; 26:12-18)
1 ṢUGBỌN Saulu, o nmí ẹmi ikilọ ati pipa sibẹ si awọn ọmọ-ẹhin Oluwa, o tọ̀ olori alufa lọ; 2 O bẽre iwe lọwọ rẹ̀ si Damasku si awọn sinagogu pe, bi on ba ri ẹnikẹni ti mbẹ li Ọna yi, iba ṣe ọkunrin, tabi obinrin, ki on le mu wọn ni didè wá si Jerusalemu. 3 O si ṣe, bi o ti nlọ, o si sunmọ Damasku: lojijì lati ọrun wá, imọlẹ si mọlẹ yi i ka: 4 O si ṣubu lulẹ, o gbọ́ ohùn ti o nfọ̀ si i pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi? 5 O si wipe, Iwọ tani, Oluwa? Oluwa si wipe, Emi Jesu ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si: ohun irora ni fun ọ lati tapá si ẹgún. 6 O si nwarìri, ẹnu si yà a, o ni, Oluwa, kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe? Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ilu na, a o sọ fun ọ li ohun ti iwọ o ṣe. 7 Awọn ọkunrin ti nwọn si mba a re àjo duro, kẹ́kẹ pa mọ́ wọn li ẹnu, nwọn gbọ́ ohùn na, ṣugbọn nwọn kò ri ẹnikan. 8 Saulu si dide ni ilẹ; nigbati oju rẹ̀ si là kò ri ohunkan: ṣugbọn nwọn fà a li ọwọ́, nwọn si mu u wá si Damasku. 9 O si gbé ijọ mẹta li airiran, kò si jẹ, bẹ̃ni kò si mu. 10 Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Damasku, ti a npè ni Anania; Oluwa si wi fun u li ojuran pe, Anania. O si wipe, Wò o, emi niyi, Oluwa. 11 Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ita ti a npè ni Ọgãnran, ki o si bère ẹniti a npè ni Saulu, ara Tarsu, ni ile Juda: sá wo o, o ngbadura. 12 On si ti ri ọkunrin kan li ojuran ti a npè ni Anania o wọle, o si fi ọwọ́ le e, ki o le riran. 13 Anania si dahùn wipe, Oluwa, mo ti gburó ọkunrin yi lọdọ ọ̀pọ enia, gbogbo buburu ti o ṣe si awọn enia mimọ́ rẹ ni Jerusalemu. 14 O si gbà aṣẹ lati ọdọ awọn olori alufa wá si ihinyi, lati dè gbogbo awọn ti npè orukọ rẹ. 15 Ṣugbọn Oluwa wi fun u pe, Mã lọ: nitori ohun elo àyo li on jẹ fun mi, lati gbe orukọ mi lọ si iwaju awọn Keferi, ati awọn ọba, ati awọn ọmọ Israeli: 16 Nitori emi o fi gbogbo ìya ti kò le ṣaijẹ nitori orukọ mi han a. 17 Anania si lọ, o si wọ̀ ile na; nigbati o si fi ọwọ́ rẹ̀ le e, o ni, Saulu Arakunrin, Oluwa li o rán mi, Jesu ti o fi ara hàn ọ li ọ̀na ti iwọ ba wá, ki iwọ ki o le riran, ki o si kún fun Ẹmí Mimọ́. 18 Lojukanna nkan si bọ kuro li oju rẹ̀ bi ipẹpẹ́: o si riran; o si dide, a si baptisi rẹ̀. 19 Nigbati o si jẹun, ara rẹ̀ mokun: Saulu si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin ni Damasku ni ijọ melokan. 20 Lojukanna o si nwasu Kristi ninu awọn sinagogu pe, Ọmọ Ọlọrun li on iṣe. 21 Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o ngbọ́, nwọn si wipe, Ẹniti o ti fõro awọn ti npè orukọ yi ni Jerusalemu kọ li eyi, ti o si ti itori na wá si ihinyi, lati mu wọn ni didè lọ sọdọ awọn olori alufa?
22 Ṣugbọn Saulu npọ̀ si i li agbara o si ndãmu awọn Ju ti o ngbe Damasku, o nfi hàn pe, eyi ni Kristi na.Saulu Bọ́ lọ́wọ́ Àwọn Juu
23 Lẹhin igbati ọjọ pipọ kọja, awọn Ju ngbìmọ lati pa a: 24 Ṣugbọn ìditẹ̀ wọn di mimọ̀ fun Saulu. Nwọn si nṣọ ẹnu-bode pẹlu li ọsán ati li oru lati pa a.
25 Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mu u li oru, nwọn si sọ̀ ọ kalẹ lara odi ninu agbọ̀n.Saulu Pada Dé Jerusalẹmu
26 Nigbati Saulu si de Jerusalemu, o pete ati da ara rẹ̀ pọ̀ mọ awọn ọmọ-ẹhin: gbogbo nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, nitori nwọn kò gbagbọ́ pe ọmọ-ẹhin kan ni. 27 Ṣugbọn Barnaba mu u, o si sìn i lọ sọdọ awọn aposteli, o si sọ fun awọn bi o ti ri Oluwa li ọ̀na, ati pe o ti ba a sọ̀rọ, ati bi o ti fi igboiya wasu ni Damasku li orukọ Jesu. 28 O si wà pẹlu wọn, o nwọle o si njade ni Jerusalemu. 29 O si nfi igboiya sọ̀rọ li orukọ Jesu Oluwa, o nsọrọ lòdi si awọn ara Hellene, o si njà wọn niyàn: ṣugbọn nwọn npete ati pa a. 30 Nigbati awọn arakunrin si mọ̀, nwọn mu u sọkalẹ lọ si Kesarea, nwọn si rán a lọ si Tarsu.
31 Nigbana ni ijọ wà li alafia yi gbogbo Judea ká ati ni Galili ati ni Samaria, nwọn nfẹsẹmulẹ; nwọn nrìn ni ìbẹru Oluwa, ati ni itunu Ẹmí Mimọ́, nwọn npọ̀ si i.Peteru Mú Enea Láradá
32 O si ṣe, bi Peteru ti nkọja nlà ẹkùn gbogbo lọ, o sọkalẹ tọ̀ awọn enia mimọ́ ti ngbe Lidda pẹlu. 33 Nibẹ̀ li o ri ọkunrin kan ti a npè ni Enea ti o ti dubulẹ lori akete li ọdún mẹjọ, o ni àrun ẹ̀gba. 34 Peteru si wi fun u pe, Enea, Jesu Kristi mu ọ larada: dide, ki o si tún akete rẹ ṣe. O si dide lojukanna.
35 Gbogbo awọn ti ngbe Lidda ati Saroni si ri i, nwọn si yipada si Oluwa.Peteru Jí Dorka Dìde
36 Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Joppa ti a npè ni Tabita, ni itumọ̀ rẹ̀ ti a npè ni Dorka: obinrin yi pọ̀ ni iṣẹ ore, ati itọrẹ-ãnu ti o ṣe. 37 O si ṣe ni ijọ wọnni, ti o ṣaisàn, o si kú: nigbati nwọn wẹ̀ ẹ tan, nwọn tẹ́ ẹ si yara kan loke. 38 Bi Lidda si ti sunmọ Joppa, nigbati awọn ọmọ-ẹhin gbọ́ pe Peteru wà nibẹ̀, awọn rán ọkunrin meji si i lọ ibẹ̀ ẹ pe, Máṣe jafara ati de ọdọ wa. 39 Peteru si dide, o si bá wọn lọ. Nigbati o de, nwọn mu u lọ si yara oke na: gbogbo awọn opó si duro tì i, nwọn nsọkun, nwọn si nfi ẹ̀wu ati aṣọ ti Dorka dá hàn a, nigbati o wà pẹlu wọn. 40 Ṣugbọn Peteru ti gbogbo wọn sode, o si kunlẹ, o si gbadura; o si yipada si okú, o ni, Tabita, dide. O si là oju rẹ̀: nigbati o si ri Peteru, o dide joko. 41 O si nà ọwọ́ rẹ̀ si i, o fà a dide; nigbati o si pè awọn enia mimọ́ ati awọn opó, o fi i le wọn lọwọ lãye. 42 O si di mimọ̀ yi gbogbo Joppa ká; ọpọlọpọ si gba Oluwa gbọ́. 43 O si ṣe, o gbé ọjọ pipọ ni Joppa lọdọ ọkunrin kan Simoni alawọ.
Acts 9
The Conversion of Saul
1 Now Saul, still breathing threats and murder against the disciples of the Lord, went to the high priest,2 and asked for letters from him to the synagogues at Damascus, so that if he found any belonging to the Way, both men and women, he might bring them bound to Jerusalem.3 As he was traveling, it happened that he was approaching Damascus, and suddenly a light from heaven flashed around him;4 and he fell to the ground and heard a voice saying to him, "Saul, Saul, why are you persecuting Me?"5 And he said, "Who are You, Lord?" And He said, "I am Jesus whom you are persecuting,6 but get up and enter the city, and it will be told you what you must do."7 The men who traveled with him stood speechless, hearing the voice but seeing no one.8 Saul got up from the ground, and though his eyes were open, he could see nothing; and leading him by the hand, they brought him into Damascus.9 And he was three days without sight, and neither ate nor drank.
10 Now there was a disciple at Damascus named Ananias; and the Lord said to him in a vision, "Ananias." And he said, "Here I am, Lord."11 And the Lord said to him, "Get up and go to the street called Straight, and inquire at the house of Judas for a man from Tarsus named Saul, for he is praying,12 and he has seen tin a vision a man named Ananias come in and lay his hands on him, so that he might regain his sight."13 But Ananias answered, "Lord, I have heard from many about this man, how much harm he did to Your saints at Jerusalem;14 and here he has authority from the chief priests to bind all who call on Your name."15 But the Lord said to him, "Go, for he is a chosen tinstrument of Mine, to bear My name before the Gentiles and kings and the sons of Israel;16 for I will show him how much he must suffer for My name's sake."17 So Ananias departed and entered the house, and after laying his hands on him said, "Brother Saul, the Lord Jesus, who appeared to you on the road by which you were coming, has sent me so that you may regain your sight and be filled with the Holy Spirit."18 And immediately there fell from his eyes something like scales, and he regained his sight, and he got up and was baptized;
19 and he took food and was strengthened.
Now for several days he was with the disciples who were at Damascus,
Saul Begins to Preach Christ
20 and immediately he began to proclaim Jesus in the synagogues, saying, "He is the Son of God."21 All those hearing him continued to be amazed, and were saying, "Is this not he who in Jerusalem destroyed those who called on this name, and who had come here for the purpose of bringing them bound before the chief priests?"22 But Saul kept increasing in strength and confounding the Jews who lived at Damascus by proving that this Jesus is the Christ.
23 When many days had elapsed, the Jews plotted together to do away with him,24 but their plot became known to Saul. They were also watching the gates day and night so that they might put him to death;25 but his disciples took him by night and let him down through an opening in the wall, lowering him in a large basket.
26 When he came to Jerusalem, he was trying to associate with the disciples; but they were all afraid of him, not believing that he was a disciple.27 But Barnabas took hold of him and brought him to the apostles and described to them how he had seen the Lord on the road, and that He had talked to him, and how at Damascus he had spoken out boldly in the name of Jesus.28 And he was with them, moving about freely in Jerusalem, speaking out boldly in the name of the Lord.29 And he was talking and arguing with the Hellenistic Jews; but they were attempting to put him to death.30 But when the brethren learned of it, they brought him down to Caesarea and sent him away to Tarsus.
31 So the church throughout all Judea and Galilee and Samaria enjoyed peace, being built up; and going on in the fear of the Lord and in the comfort of the Holy Spirit, it continued to increase.
Peter's Ministry
32 Now as Peter was traveling through all those regions, he came down also to the saints who lived at Lydda.33 There he found a man named Aeneas, who had been bedridden eight years, for he was paralyzed.34 Peter said to him, "Aeneas, Jesus Christ heals you; get up and make your bed." Immediately he got up.35 And all who lived at Lydda and Sharon saw him, and they turned to the Lord.
36 Now in Joppa there was a disciple named Tabitha (which translated in Greek is called Dorcas); this woman was abounding with deeds of kindness and charity which she continually did.37 And it happened at that time that she fell sick and died; and when they had washed her body, they laid it in an upper room.38 Since Lydda was near Joppa, the disciples, having heard that Peter was there, sent two men to him, imploring him, "Do not delay in coming to us."39 So Peter arose and went with them. When he arrived, they brought him into the upper room; and all the widows stood beside him, weeping and showing all the ttunics and garments that Dorcas used to make while she was with them.40 But Peter sent them all out and knelt down and prayed, and turning to the body, he said, "Tabitha, arise." And she opened her eyes, and when she saw Peter, she sat up.41 And he gave her his hand and raised her up; and calling the saints and widows, he presented her alive.42 It became known all over Joppa, and many believed in the Lord.43 And Peter stayed many days in Joppa with a tanner named Simon.