previous next

Kol 4

1 ẸNYIN oluwa, ẹ ma fi eyiti o tọ́ ti o si dọgba fun awọn ọmọ-ọdọ nyin; ki ẹ si mọ̀ pe ẹnyin pẹlu ni Oluwa kan li ọrun.

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú


2 Ẹ mã duro ṣinṣin ninu adura igbà, ki ẹ si mã ṣọra ninu rẹ̀ pẹlu idupẹ; 3 Ju gbogbo rẹ̀, ẹ mã gbadura fun wa pẹlu, ki Ọlọrun le ṣí ilẹkun fun wa fun ọrọ na, lati mã sọ ohun ijinlẹ Kristi, nitori eyiti mo ṣe wà ninu ìde pẹlu: 4 Ki emi ki o le fihan, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ. 5 Ẹ mã rìn nipa ọgbọ́n si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ si mã ṣe ìrapada ìgba.

6 Ẹ jẹ ki ọ̀rọ nyin ki o dàpọ mọ́ ore-ọfẹ nigbagbogbo, eyiti a fi iyọ̀ dùn, ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi ẹnyin ó ti mã dá olukuluku enia lohùn.

Gbolohun Ìparí


7 Gbogbo bi nkan ti ri fun mi ni Tikiku yio jẹ́ ki ẹ mọ̀, arakunrin olufẹ ati olõtọ iranṣẹ, ati ẹlẹgbẹ ninu Oluwa: 8 Ẹniti mo ti rán si nyin nitori eyi kanna, ki ẹnyin le mọ̀ bi a ti wà, ki on ki o le tù ọkàn nyin ninu; 9 Pẹlu Onesimu, arakunrin olõtọ ati olufẹ, ẹniti iṣe ọ̀kan ninu nyin. Awọn ni yio sọ ohun gbogbo ti a nṣe nihinyi fun nyin. 10 Aristarku, ẹlẹgbẹ mi ninu tubu ki nyin, ati Marku, ọmọ arabinrin Barnaba (nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbà aṣẹ: bi o ba si wá sọdọ nyin, ẹ gbà a), 11 Ati Jesu, ẹniti a npè ni Justu, ẹniti iṣe ti awọn onila. Awọn wọnyi nikan ni olubaṣiṣẹ mi fun ijọba Ọlọrun, awọn ẹniti o ti jasi itunu fun mi. 12 Epafra, ẹniti iṣe ọkan ninu nyin, iranṣẹ Kristi, kí nyin, on nfi iwaya-ija gbadura nigbagbogbo fun nyin, ki ẹnyin ki o le duro ni pipé ati ni kíkun ninu gbogbo ifẹ Ọlọrun. 13 Nitori mo jẹri rẹ̀ pe, o ni itara pupọ fun nyin, ati fun awọn ti o wà ni Laodikea, ati awọn ti o wà ni Hierapoli. 14 Luku, oniṣegun olufẹ, ati Dema ki nyin. 15 Ẹ kí awọn ará ti o wà ni Laodikea, ati Nimfa, ati ijọ ti o wà ni ile rẹ̀. 16 Nigbati a ba si kà iwe yi larin nyin tan, ki ẹ mu ki a kà a pẹlu ninu ìjọ Laodikea; ki ẹnyin pẹlu si kà eyi ti o ti Laodikea wá. 17 Ki ẹ si wi fun Arkippu pe, Kiyesi iṣẹ-iranṣẹ ti iwọ ti gbà ninu Oluwa, ki o si ṣe e ni kikún. 18 Ikíni nipa ọwọ́ emi Paulu. Ẹ mã ranti ìde mi. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu nyin. Amin.

11-Feb-2009@11:05, Backup Description=11-Feb-2009@09:10, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:15, Backup Description=08-Apr-2009@08:23, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:52, Backup Description=08-Apr-2009@14:37, Ayo Durodola -

22-Dec-2009@14:07, Backup Description=22-Dec-2009@14:01, victor Damilare -

Colossians 4

Fellow Workers

1 Masters, grant to your slaves justice and fairness, knowing that you too have a Master in heaven.

2 Devote yourselves to prayer, keeping alert in it with an attitude of thanksgiving;3 praying at the same time for us as well, that God will open up to us a door for the word, so that we may speak forth the mystery of Christ, for which I have also been imprisoned;4 that I may make it clear in the way I ought to speak.

5 Conduct yourselves with wisdom toward outsiders, making the most of the opportunity.6 Let your speech always be with grace, as though seasoned with salt, so that you will know how you should respond to each person.

7 As to all my affairs, Tychicus, our beloved brother and faithful servant and fellow bond-servant in the Lord, will bring you information.8  For I have sent him to you for this very purpose, that you may know about our circumstances and that he may encourage your hearts;9 and with him Onesimus, our faithful and beloved brother, who is one of your number. They will inform you about the whole situation here.

10 Aristarchus, my fellow prisoner, sends you his greetings; and also Barnabas's cousin Mark (about whom you received instructions; if he comes to you, welcome him);11 and also Jesus who is called Justus; these are the only fellow workers for the kingdom of God who are from the circumcision, and they have proved to be an encouragement to me.12 Epaphras, who is one of your number, a bondslave of Jesus Christ, sends you his greetings, always laboring earnestly for you in his prayers, that you may stand perfect and fully assured in all the will of God.13 For I testify for him that he has a deep concern for you and for those who are in Laodicea and Hierapolis.14 Luke, the beloved physician, sends you his greetings, and also Demas.15 Greet the brethren who are in Laodicea and also tNympha and the church that is in her house.16 When this letter is read among you, have it also read in the church of the Laodiceans; and you, for your part read my letter that is coming from Laodicea.17 Say to Archippus, "Take heed to the ministry which you have received in the Lord, that you may fulfill it."

18 I, Paul, write this greeting with my own hand. Remember my imprisonment. Grace be with you.