previous next

Efe 1

Ìkínni

1 PAULU, Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, si awọn enia mimọ́ ti o wà ni Efesu, ati si awọn onigbagbọ ninu Kristi Jesu:

2 Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kristi Oluwa.

Ibukun ti Ẹ̀mí Nípa Kristi


3 Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, ẹniti o ti fi gbogbo ibukún ẹmí ninu awọn ọrun bukún wa ninu Kristi: 4 Ani gẹgẹ bi o ti yàn wa ninu rẹ̀ ṣaju ipilẹṣẹ aiye, ki awa ki o le jẹ mimọ́ ati alailabùku niwaju rẹ̀ ninu ifẹ: 5 Ẹniti o ti yàn wa tẹlẹ si isọdọmọ nipa Jesu Kristi fun ara rẹ̀, gẹgẹ bi ìdunnú ifẹ rẹ̀: 6 Fun iyin ogo ore-ọfẹ rẹ̀, eyiti o dà lù wa ninu Ayanfẹ nì: 7 Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rẹ̀, idariji ẹ̀ṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀; 8 Eyiti o sọ di pupọ fun wa ninu gbogbo ọgbọ́n ati oye, 9 Ẹniti o ti sọ ohun ijinlẹ ifẹ rẹ̀ di mimọ̀ fun wa, gẹgẹ bi idunnú rẹ̀, eyiti o ti pinnu ninu rẹ̀, 10 Fun iṣẹ iriju ti kikun akoko na, ki o le ko ohun gbogbo jọ ninu Kristi, iba ṣe eyiti mbẹ ninu awọn ọrun, tabi eyiti mbẹ li aiye, ani ninu rẹ̀: 11 Ninu ẹniti a fi wa ṣe ini rẹ̀ pẹlu, awa ti a ti yan tẹlẹ, gẹgẹ bi ipinnu ẹniti nṣiṣẹ ohun gbogbo gẹgẹ bi ìmọ ifẹ rẹ̀: 12 Ki awa ki o le jẹ fun iyin ogo rẹ̀, awa ti a ti ni ireti ṣaju ninu Kristi; 13 Ninu ẹniti, ẹnyin pẹlu, nigbati ẹnyin ti gbọ ọrọ otitọ nì, ihinrere igbala nyin, ninu ẹniti nigbati ẹnyin ti gbagbọ pẹlu, a fi Ẹmi Mimọ́ ileri nì ṣe edidi nyin,

14 Eyiti iṣe ẹri ini wa, fun irapada ohun ini Ọlọrun si iyìn ogo rẹ̀.

Adura Paulu


15 Nitori eyi, emi pẹlu, nigbati mo ti gburó igbagbọ ti mbẹ larin nyin ninu Jesu Oluwa, ati ifẹ nyin si gbogbo awọn enia mimọ́, 16 Emi kò si simi lati mã dupẹ nitori nyin, ati lati mã darukọ nyin ninu adura mi; 17 Pe ki Ọlọrun Jesu Kristi Oluwa wa, Baba ogo, le fun nyin li Ẹmi nipa ti ọgbọ́n ati ti ifihan ninu ìmọ rẹ̀: 18 Ki oju ọkàn nyin le mọlẹ; ki ẹnyin ki o le mọ ohun ti ireti ìpe rẹ̀ jẹ, ati ohun ti ọrọ̀ ogo ini rẹ̀ ninu awọn enia mimọ́ jẹ, 19 Ati agbara rẹ̀ ti o tobi julọ si awa ti o gbagbọ́, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀, 20 Eyiti o ti ṣiṣẹ ninu Kristi, nigbati o ti jí dide kuro ninu okú, ti o si fi i joko li ọwọ́ ọtún ninu awọn ọrun, 21 Ga ju gbogbo ijọba ati ọla, ati agbara, ati oyè, ati gbogbo orukọ ti a ndá, ki iṣe li aiye yi nikan, ṣugbọn li eyiti mbọ̀ pẹlu. 22 O si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀, o si ti fi i ṣe ori lori ohun gbogbo fun ijọ, 23 Eyiti iṣe ara rẹ̀, ẹkún ẹniti o kún ohun gbogbo ninu ohun gbogbo.

Ephesians 1

The Blessings of Redemption

1 Paul, an apostle of Christ Jesus by the will of God,
To the saints who are tat Ephesus and who are faithful in Christ Jesus:
2 Grace to you and peace from God our Father and the Lord Jesus Christ.

3 Blessed be the God and Father of our Lord Jesus Christ, who has blessed us with every spiritual blessing in the heavenly places in Christ,4 just as He chose us in Him before the foundation of the world, that we would be holy and blameless before tHim. In love5 He predestined us to adoption as sons through Jesus Christ to Himself, according to the kind intention of His will,6 to the praise of the glory of His grace, which He freely bestowed on us in the Beloved.7 In Him we have redemption through His blood, the forgiveness of our trespasses, according to the riches of His grace8 which He lavished on us. In all wisdom and insight9 He made known to us the mystery of His will, according to His kind intention which He purposed in Him10 with a view to an administration suitable to the fullness of the times, that is, the summing up of all things in Christ, things in the heavens and things on the earth. In Him11 also we have obtained an inheritance, having been predestined according to His purpose who works all things after the counsel of His will,12 to the end that we who were the first to hope in tChrist would be to the praise of His glory.13 In Him, you also, after listening to the message of truth, the gospel of your salvation-having also believed, you were sealed in Him with the Holy Spirit of promise,14 who is given as a pledge of our inheritance, with a view to the redemption of God's own possession, to the praise of His glory.

15 For this reason I too, having heard of the faith in the Lord Jesus which exists among you and tyour love for all the saints,16 do not cease giving thanks for you, while making mention of you in my prayers;17 that the God of our Lord Jesus Christ, the Father of glory, may give to you a spirit of wisdom and of revelation in the knowledge of Him.18  I pray that the eyes of your heart may be enlightened, so that you will know what is the hope of His calling, what are the riches of the glory of His inheritance in the saints,19 and what is the surpassing greatness of His power toward us who believe. These are in accordance with the working of the strength of His might20 which He brought about in Christ, when He raised Him from the dead and seated Him at His right hand in the heavenly places, 21 far above all rule and authority and power and dominion, and every name that is named, not only in this age but also in the one to come.22 And He put all things in subjection under His feet, and gave Him as head over all things to the church,23 which is His body, the fullness of Him who fills all in all.