previous next

Efe 2

Láti Inú Ikú sí Inú Ìyè

1 ẸNYIN li a si ti sọ di àye, nigbati ẹnyin ti kú nitori irekọja ati ẹ̀ṣẹ nyin, 2 Ninu eyiti ẹnyin ti nrin rí gẹgẹ bi ipa ti aiye yi, gẹgẹ bi alaṣẹ agbara oju ọrun, ẹmí ti nṣiṣẹ nisisiyi ninu awọn ọmọ alaigbọran: 3 Ninu awọn ẹniti gbogbo wa pẹlu ti wà rí ninu ifẹkufẹ ara wa, a nmu ifẹ ara ati ti inu ṣẹ; ati nipa ẹda awa si ti jẹ ọmọ ibinu, gẹgẹ bi awọn iyoku pẹlu. 4 Ṣugbọn Ọlọrun, ẹniti iṣe ọlọrọ̀ li ãnu, nitori ifẹ nla rẹ̀ ti o fi fẹ wa, 5 Nigbati awa tilẹ ti kú nitori irekọja wa, o sọ wa di ãye pẹlu Kristi (ore-ọfẹ li a ti fi gba nyin là). 6 O si ti ji wa dide pẹlu rẹ̀, o si ti mu wa wa joko pẹlu rẹ̀ ninu awọn ọrun ninu Kristi Jesu: 7 Pe ni gbogbo ìgba ti mbọ ki o ba le fi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀ ti o pọ rekọja han ninu iṣeun rẹ̀ si wa ninu Kristi Jesu. 8 Nitori ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ́; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikaranyin: ẹ̀bun Ọlọrun ni: 9 Kì iṣe nipa iṣẹ, ki ẹnikẹni má bã ṣogo.

10 Nitori awa ni iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ ti a ti dá ninu Kristi Jesu fun iṣẹ rere, ti Ọlọrun ti pèse tẹlẹ, ki awa ki o le mã rìn ninu wọn.

Ọ̀kan ninu Kristi


11 Nitorina ẹ ranti pe, nigba atijọ ri, ẹnyin ti ẹ ti jẹ Keferi nipa ti ara, ti awọn ti a npè ni Akọla ti a fi ọwọ ṣe li ara npè li Alaikọla, 12 Pe li akokò na ẹnyin wà laini Kristi, ẹ jẹ ajeji si anfani awọn ọlọtọ Israeli, ati alejo si awọn majẹmu ileri nì, laini ireti, ati laini Ọlọrun li aiye: 13 Ṣugbọn nisisiyi ninu Kristi Jesu ẹnyin ti o ti jìna réré nigba atijọ rí li a mu sunmọ tosi, nipa ẹ̀jẹ Kristi. 14 Nitori on ni alafia wa, ẹniti o ti ṣe mejeji li ọ̀kan, ti o si ti wó ogiri ìkélé nì ti mbẹ lãrin; 15 O si ti fi opin si ọta nì ninu ara rẹ̀, ani si ofin aṣẹ wọnni ti mbẹ ninu ilana; ki o le fi awọn mejeji dá ẹni titun kan ninu ara rẹ̀, ki o si ṣe ilaja, 16 Ati ki o le mu awọn mejeji ba Ọlọrun làja ninu ara kan nipa agbelebu; o si ti pa iṣọta na kú nipa rẹ̀: 17 O si ti wá, o si ti wasu alafia fun ẹnyin ti o jìna réré, ati fun awọn ti o sunmọ tosi: 18 Nitori nipa rẹ̀ li awa mejeji ti ni ọ̀na nipa Ẹmí kan sọdọ Baba. 19 Njẹ nitorina ẹnyin kì iṣe alejò ati atipo mọ́, ṣugbọn àjumọ jẹ ọlọ̀tọ pẹlu awọn enia mimọ́, ati awọn ará ile Ọlọrun; 20 A si ngbé nyin ró lori ipilẹ awọn aposteli, ati awọn woli, Jesu Kristi tikararẹ̀ jẹ pàtaki okuta igun ile; 21 Ninu ẹniti gbogbo ile na, ti a nkọ ṣọkan pọ, ndagbà soke ni tẹmpili mimọ́ ninu Oluwa: 22 Ninu ẹniti a ngbé nyin ró pọ pẹlu fun ibujoko Ọlọrun ninu Ẹmí.

Ephesians 2

Made Alive in Christ

1 And you were dead in your trespasses and sins,2 in which you formerly walked according to the course of this world, according to the prince of the power of the air, of the spirit that is now working in the sons of disobedience.3 Among them we too all formerly lived in the lusts of our flesh, indulging the desires of the flesh and of the mind, and were by nature children of wrath, even as the rest.4 But God, being rich in mercy, because of His great love with which He loved us,5 even when we were dead in our transgressions, made us alive together twith Christ (by grace you have been saved),6 and raised us up with Him, and seated us with Him in the heavenly places in Christ Jesus,7 so that in the ages to come He might show the surpassing riches of His grace in kindness toward us in Christ Jesus.8 For by grace you have been saved through faith; and that not of yourselves, it is the gift of God;9 not as a result of works, so that no one may boast.10 For we are His workmanship, created in Christ Jesus for good works, which God prepared beforehand so that we would walk in them.

11 Therefore remember that formerly you, the Gentiles in the flesh, who are called "Uncircumcision" by the so-called "Circumcision," which is performed in the flesh by human hands-12  remember that you were at that time separate from Christ, excluded from the commonwealth of Israel, and strangers to the covenants of promise, having no hope and without God in the world.13 But now in Christ Jesus you who formerly were far off have been brought near by the blood of Christ.14 For He Himself is our peace, who made both groups into one and broke down the barrier of the dividing wall,15 by abolishing in His flesh the enmity, which is the Law of commandments contained in ordinances, so that in Himself He might make the two into one new man, thus establishing peace,16 and might reconcile them both in one body to God through the cross, by it having put to death the enmity.17 AND HE CAME AND PREACHED PEACE TO YOU WHO WERE FAR AWAY, AND PEACE TO THOSE WHO WERE NEAR;18 for through Him we both have our access in one Spirit to the Father.19 So then you are no longer strangers and aliens, but you are fellow citizens with the saints, and are of God's household,20 having been built on the foundation of the apostles and prophets, Christ Jesus Himself being the corner stone, 21 in whom the whole building, being fitted together, is growing into a holy temple in the Lord,22 in whom you also are being built together into a dwelling of God in the Spirit.