previous next

Efe 3

Iṣẹ́ Paulu láàrin Àwọn Tí Kì í Ṣe Juu

1 NITORI eyina, emi Paulu, ondè Jesu Kristi nitori ẹnyin Keferi, 2 Bi ẹnyin ba ti gbọ ti iṣẹ iriju ore-ọfẹ Ọlọrun, ti a fifun mi fun nyin: 3 Bi o ti ṣepe nipa ifihan li o ti fi ohun ijinlẹ nì hàn fun mi, (gẹgẹ bi mo ti kọ ṣaju li ọrọ diẹ, 4 Nigbati ẹnyin ba kà a, nipa eyi ti ẹnyin ó fi le mọ oye mi ninu ijinlẹ Kristi,) 5 Eyiti a kò ti fihàn awọn ọmọ enia rí ni irandiran miran, bi a ti fi wọn hàn nisisiyi fun awọn aposteli rẹ̀ mimọ́ ati awọn woli nipa Ẹmí; 6 Pe, awọn Keferi jẹ àjumọjogun ati ẹya-ara kanna, ati alabapin ileri ninu Kristi Jesu nipa ihinrere: 7 Iranṣẹ eyiti a fi mi ṣe gẹgẹ bi ẹ̀bun ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀. 8 Fun emi ti o kere ju ẹniti o kere julọ ninu gbogbo awọn enia mimọ́, li a fi ore-ọfẹ yi fun, lati wasu awamáridi ọrọ̀ Kristi fun awọn Keferi; 9 Ati lati mu ki gbogbo enia ri kini iṣẹ-iriju ohun ijinlẹ na jasi, eyiti a ti fi pamọ́ lati aiyebaiye ninu Ọlọrun, ẹniti o dá ohun gbogbo nipa Jesu Kristi: 10 Ki a ba le fi ọ̀pọlọpọ onirũru ọgbọ́n Ọlọrun hàn nisisiyi fun awọn ijoye ati awọn alagbara ninu awọn ọrun, nipasẹ ijọ, 11 Gẹgẹ bi ipinnu ataiyebaiye ti o ti pinnu ninu Kristi Jesu Oluwa wa: 12 Ninu ẹniti awa ni igboiya, ati ọ̀na pẹlu igbẹkẹle nipa igbagbọ́ wa ninu rẹ̀.

13 Nitorina mo bẹ̀ nyin ki ãrẹ̀ ki o máṣe mu nyin ni gbogbo wahalà mi nitori nyin, ti iṣe ogo nyin.

Ìfẹ́ Tí Kristi Ní


14 Nitori idi eyi ni mo ṣe nfi ẽkun mi kunlẹ fun Baba Oluwa wa Jesu Kristi, 15 Orukọ ẹniti a fi npè gbogbo idile ti mbẹ li ọrun ati li aiye, 16 Ki on ki o le fifun nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ ogo rẹ̀, ki a le fi agbara rẹ̀ mú nyin li okun nipa Ẹmí rẹ̀ niti ẹni inu; 17 Ki Kristi ki o le mã gbé inu ọkàn nyin nipa igbagbọ; pe bi ẹ ti nfi gbongbo mulẹ, ti ẹ si nfi ẹsẹ mulẹ ninu ifẹ, 18 Ki ẹnyin ki o le li agbara lati mọ̀ pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́, kini ìbú, ati gigùn, ati jijìn, ati giga na jẹ, 19 Ati lati mọ ifẹ Kristi ti o ta ìmọ yọ, ki a le fi gbogbo ẹ̀kún Ọlọrun kun nyin. 20 Njẹ ẹniti o le ṣe lọpọlọpọ jù gbogbo eyiti a mbère tabi ti a nrò lọ, gẹgẹ bi agbara ti nṣiṣẹ ninu wa, 21 On ni ki a mã fi ogo fun ninu ijọ ati ninu Kristi Jesu titi irandiran gbogbo, aiye ainipẹkun. Amin.

Ephesians 3

Paul's Stewardship

1 For this reason I, Paul, the prisoner of Christ Jesus for the sake of you Gentiles-2 if indeed you have heard of the stewardship of God's grace which was given to me for you;3 that by revelation there was made known to me the mystery, as I wrote before in brief.4 By referring to this, when you read you can understand my insight into the mystery of Christ,5 which in other generations was not made known to the sons of men, as it has now been revealed to His holy apostles and prophets in the Spirit;6  to be specific, that the Gentiles are fellow heirs and fellow members of the body, and fellow partakers of the promise in Christ Jesus through the gospel,7 of which I was made a minister, according to the gift of God's grace which was given to me according to the working of His power.8 To me, the very least of all saints, this grace was given, to preach to the Gentiles the unfathomable riches of Christ,9 and to bring to light what is the administration of the mystery which for ages has been hidden in God who created all things;10 so that the manifold wisdom of God might now be made known through the church to the rulers and the authorities in the heavenly places. 11  This was in accordance with the eternal purpose which He carried out in Christ Jesus our Lord,12 in whom we have boldness and confident access through faith in Him.13 Therefore I ask you not to lose heart at my tribulations on your behalf, for they are your glory.

14 For this reason I bow my knees before the Father,15 from whom every family in heaven and on earth derives its name,16 that He would grant you, according to the riches of His glory, to be strengthened with power through His Spirit in the inner man,17 so that Christ may dwell in your hearts through faith; and that you, being rooted and grounded in love,18 may be able to comprehend with all the saints what is the breadth and length and height and depth,19 and to know the love of Christ which surpasses knowledge, that you may be filled up to all the fullness of God.

20 Now to Him who is able to do far more abundantly beyond all that we ask or think, according to the power that works within us,21 to Him be the glory in the church and in Christ Jesus to all generations forever and ever. Amen.