previous next

Efe 4

Ìṣọ̀kan Ara Kristi

1 NITORINA emi ondè ninu Oluwa, mbẹ̀ nyin pe, ki ẹnyin ki o mã rìn bi o ti yẹ fun ìpe na ti a fi pè nyin, 2 Pẹlu irẹlẹ gbogbo ati inu tutù, pẹlu ipamọra, ẹ mã fi ifẹ farada a fun ẹnikeji nyin; 3 Ki ẹ si mã lakaka lati pa iṣọkan Ẹmí mọ́ ni ìdipọ alafia. 4 Ara kan ni mbẹ, ati Ẹmí kan, ani bi a ti pè nyin sinu ireti kan ti ipè nyin; 5 Oluwa kan, igbagbọ́ kan, baptismu kan, 6 Ọlọrun kan ati Baba gbogbo, ẹniti o wà lori gbogbo ati nipa gbogbo ati ninu nyin gbogbo. 7 Ṣugbọn olukuluku wa li a fi ore-ọfẹ fun gẹgẹ bi oṣuwọn ẹ̀bun Kristi. 8 Nitorina o wipe, Nigbati o gòke lọ si ibi giga, o di igbekun ni igbekun, o si fi ẹ̀bun fun enia. 9 (Njẹ niti pe o goke lọ, kili o jẹ, bikoṣepe o kọ́ sọkalẹ pẹlu lọ si iha isalẹ ilẹ? 10 Ẹniti o ti sọkalẹ, on kanna li o si ti goke rekọja gbogbo awọn ọrun, ki o le kún ohun gbogbo.) 11 O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran bi oluṣọ-agutan ati olukọni; 12 Fun aṣepé awọn enia mimọ́ fun iṣẹ-iranṣẹ, fun imudagba ara Kristi: 13 Titi gbogbo wa yio fi de iṣọkan igbagbọ́ ati ìmọ Ọmọ Ọlọrun, titi a o fi di ọkunrin, titi a o fi de iwọn gigun ẹ̀kún Kristi: 14 Ki awa ki o máṣe jẹ ewe mọ́, ti a nfi gbogbo afẹfẹ ẹ̀kọ́ tì siwa tì sẹhin, ti a si fi ngbá kiri, nipa itanjẹ enia, nipa arekereke fun ọgbọnkọgbọn ati múni ṣina; 15 Ṣugbọn ki a mã sọ otitọ ni ifẹ, ki a le mã dàgbasoke ninu rẹ̀ li ohun gbogbo, ẹniti iṣe ori, ani Kristi:

16 Lati ọdọ ẹniti ara na ti a nso ṣọkan pọ, ti o si nfi ara mọra, nipa gbogbo orike ipese, (gẹgẹ bi iṣẹ olukuluku ẹya-ara ni ìwọn tirẹ̀) o nmu ara na bi si i fun idagbasoke on tikararẹ ninu ifẹ.

Ìgbé-Ayé ti Àtijọ́ ati ti Ìsinsìnyìí


17 Njẹ eyi ni mo nwi, ti mo si njẹri ninu Oluwa pe, lati isisiyi lọ ki ẹnyin ki o máṣe rìn mọ́, ani gẹgẹ bi awọn Keferi ti nrin ninu ironu asan wọn, 18 Òye awọn ẹniti o ṣòkunkun, awọn ti o si ti di àjeji si ìwa-bi-Ọlọrun nitori aimọ̀ ti mbẹ ninu wọn, nitori lile ọkàn wọn: 19 Awọn ẹniti ọkàn wọn le rekọja, ti nwọn si ti fi ara wọn fun wọ̀bia, lati mã fi iwọra ṣiṣẹ ìwa-ẽri gbogbo. 20 Ṣugbọn a kò fi Kristi kọ́ nyin bẹ̃; 21 Bi o ba ṣe pe nitotọ li ẹ ti gbohùn rẹ̀, ti a si ti kọ́ nyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi otitọ ti mbẹ ninu Jesu: 22 Pe, niti iwa nyin atijọ, ki ẹnyin ki o bọ ogbologbo ọkunrin nì silẹ, eyiti o dibajẹ gẹgẹ bi ifẹkufẹ ẹ̀tan; 23 Ki ẹ si di titun ni ẹmi inu nyin;

24 Ki ẹ si gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a da nipa ti Ọlọrun li ododo ati li iwa mimọ́ otitọ́.

Ìlànà fún Ìgbé-Ayé Titun


25 Nitorina ẹ fi eke ṣiṣe silẹ, ki olukuluku nyin ki o mã ba ọmọnikeji rẹ̀ sọ otitọ, nitori ẹ̀ya-ara ọmọnikeji wa li awa iṣe. 26 Ẹ binu; ẹ má si ṣe ṣẹ̀: ẹ máṣe jẹ ki õrùn wọ̀ bá ibinu nyin: 27 Bẹni ki ẹ má ṣe fi àye fun Èṣu. 28 Ki ẹniti njale máṣe jale mọ́: ṣugbọn ki o kuku mã ṣe lãlã, ki o mã fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki on ki o le ni lati pín fun ẹniti o ṣe alaini. 29 Ẹ máṣe jẹ ki ọ̀rọ idibajẹ kan ti ẹnu nyin jade, ṣugbọn iru eyiti o dara fun ẹ̀kọ́, ki o le mã fi ore-ọfẹ fun awọn ti ngbọ́. 30 Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande. 31 Gbogbo ìwa kikorò, ati ibinu, ati irunu, ati ariwo, ati ọ̀rọ buburu ni ki a mu kuro lọdọ nyin, pẹlu gbogbo arankàn: 32 Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.

Ephesians 4

Unity of the Spirit

1 Therefore I, the prisoner of the Lord, implore you to walk in a manner worthy of the calling with which you have been called,2 with all humility and gentleness, with patience, showing tolerance for one another in love,3 being diligent to preserve the unity of the Spirit in the bond of peace.4  There is one body and one Spirit, just as also you were called in one hope of your calling;5 one Lord, one faith, one baptism,6 one God and Father of all who is over all and through all and in all.

7 But to each one of us grace was given according to the measure of Christ's gift.8 Therefore it says,
"WHEN HE ASCENDED ON HIGH,
HE LED CAPTIVE A HOST OF CAPTIVES,
AND HE GAVE GIFTS TO MEN."
9 (Now this expression, "He ascended," what does it mean except that He also had descended into the lower parts of the earth?10 He who descended is Himself also He who ascended far above all the heavens, so that He might fill all things.)11 And He gave some as apostles, and some as prophets, and some as evangelists, and some as pastors and teachers,12 for the equipping of the saints for the work of service, to the building up of the body of Christ;13 until we all attain to the unity of the faith, and of the knowledge of the Son of God, to a mature man, to the measure of the stature which belongs to the fullness of Christ.14 As a result, we are no longer to be children, tossed here and there by waves and carried about by every wind of doctrine, by the trickery of men, by craftiness in deceitful scheming;15 but speaking the truth in love, we are to grow up in all aspects into Him who is the head, even Christ,16 from whom the whole body, being fitted and held together by what every joint supplies, according to the proper working of each individual part, causes the growth of the body for the building up of itself in love.

The Christian's Walk

17 So this I say, and affirm together with the Lord, that you walk no longer just as the Gentiles also walk, in the futility of their mind,18 being darkened in their understanding, excluded from the life of God because of the ignorance that is in them, because of the hardness of their heart;19 and they, having become callous, have given themselves over to sensuality for the practice of every kind of impurity with greediness.20 But you did not learn Christ in this way,21 if indeed you have heard Him and have been taught in Him, just as truth is in Jesus,22 that, in reference to your former manner of life, you lay aside the old self, which is being corrupted in accordance with the lusts of deceit,23 and that you be renewed in the spirit of your mind,24 and put on the new self, which in the likeness of God has been created in righteousness and holiness of the truth.

25 Therefore, laying aside falsehood, SPEAK TRUTH EACH ONE of you WITH HIS NEIGHBOR, for we are members of one another.26 BE ANGRY, AND yet DO NOT SIN; do not let the sun go down on your anger,27 and do not give the devil an opportunity.28 He who steals must steal no longer; but rather he must labor, performing with his own hands what is good, so that he will have something to share with one who has need.29 Let no unwholesome word proceed from your mouth, but only such a word as is good for edification according to the need of the moment, so that it will give grace to those who hear.30 Do not grieve the Holy Spirit of God, by whom you were sealed for the day of redemption.31 Let all bitterness and wrath and anger and clamor and slander be put away from you, along with all malice.32 Be kind to one another, tender-hearted, forgiving each other, just as God in Christ also has forgiven tyou.