Gal 3
Òfin tabi Igbagbọ
1 ẸNYIN alaironu ara Galatia, tani ha tàn nyin jẹ, ki ẹnyin ki o máṣe gbà otitọ gbọ́, li oju ẹniti a fi Jesu Kristi hàn gbangba lãrin nyin li ẹniti a kàn mọ agbelebu. 2 Kìki eyi ni mo fẹ mọ̀ lọwọ nyin pe, Nipa iṣẹ ofin li ẹnyin gbà Ẹmí bi, tabi nipa igbọran igbagbọ́? 3 Bayi li ẹnyin ṣe alaironu to? ẹnyin ti o ti bẹ̀rẹ nipa ti Ẹmí a ha ṣe nyin pé nisisiyi nipa ti ara? 4 Ẹnyin ha ti jìya ọ̀pọlọpọ nkan wọnni lasan? bi o tilẹ ṣepe lasan ni. 5 Nitorina ẹniti o fun nyin li Ẹmí na, ti o si ṣe iṣẹ-agbara larin nyin, nipa iṣẹ ofin li o fi nṣe e bi, tabi nipa igbọran igbagbọ́? 6 Gẹgẹ bi Abrahamu ti gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si fun u li ododo. 7 Nitorina ki ẹnyin ki o mọ̀ pe awọn ti iṣe ti igbagbọ́, awọn na ni iṣe ọmọ Abrahamu. 8 Bi iwe-mimọ́ si ti ri i tẹlẹ pe, Ọlọrun yio dá awọn Keferi lare nipa igbagbọ́, o ti wasu ihinrere ṣaju fun Abrahamu, o nwipe, Ninu rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède. 9 Gẹgẹ bẹ̃li awọn ti iṣe ti igbagbọ́ jẹ ẹni alabukún-fun pẹlu Abrahamu olododo. 10 Nitoripe iye awọn ti mbẹ ni ipa iṣẹ ofin mbẹ labẹ ègún: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu ni olukuluku ẹniti kò duro ninu ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin lati mã ṣe wọn. 11 Nitori o daniloju pe, a kò da ẹnikẹni lare niwaju Ọlọrun nipa iṣẹ ofin: nitoripe, Olododo yio yè nipa igbagbọ́. 12 Ofin kì si iṣe ti igbagbọ́: ṣugbọn Ẹniti nṣe wọn yio yè nipasẹ wọn. 13 Kristi ti rà wa pada kuro lọwọ egun ofin, ẹniti a fi ṣe egun fun wa: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu li olukuluku ẹniti a fi kọ́ sori igi:
14 Ki ibukún Abrahamu ki o le wá sori awọn Keferi nipa Kristi Jesu; ki awa ki o le gbà ileri Ẹmí nipa igbagbọ́.Òfin ati Ìlérí
15 Ará, emi nsọ̀rọ bi enia; bi o tilẹ jẹ pe majẹmu enia ni, ṣugbọn bi a ba ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò si ẹniti o le sọ ọ di asan, tabi ti o le fi kún u mọ́. 16 Njẹ fun Abrahamu ati fun irú-ọmọ rẹ̀ li a ti ṣe awọn ileri na. On kò wipe, Fun awọn irú ọmọ, bi ẹnipe ọ̀pọlọpọ; ṣugbọn bi ẹnipe ọ̀kan, ati fun irú-ọmọ rẹ, eyiti iṣe Kristi. 17 Eyi ni mo nwipe, majẹmu ti Ọlọrun ti fi idi rẹ̀ mulẹ niṣãju, ofin ti o de lẹhin ọgbọ̀n-le-nirinwo ọdún kò le sọ ọ di asan, ti a ba fi mu ileri na di alailagbara. 18 Nitori bi ijogun na ba ṣe ti ofin, kì iṣe ti ileri mọ́: ṣugbọn Ọlọrun ti fi i fun Abrahamu nipa ileri. 19 Njẹ ki ha li ofin? a fi kun u nitori irekọja titi irú-ọmọ ti a ti ṣe ileri fun yio fi de; a si ti ipasẹ awọn angẹli ṣe ìlana rẹ̀ lati ọwọ́ alarina kan wá.
20 Njẹ alarina kì iṣe alarina ti ẹnikan, ṣugbọn ọ̀kan li Ọlọrun.Ọmọ ati Ẹrú
21 Nitorina ofin ha lodi si awọn ileri Ọlọrun bi? Ki a má ri: nitori ibaṣepe a ti fi ofin kan funni, ti o lagbara lati sọni di ãye, nitotọ ododo iba ti ti ipasẹ ofin wá. 22 Ṣugbọn iwe-mimọ́ ti sé gbogbo nkan mọ́ sabẹ ẹ̀ṣẹ, ki a le fi ileri nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi fun awọn ti o gbagbọ́. 23 Ṣugbọn ki igbagbọ́ to de, a ti pa wa mọ́ labẹ ofin, a si sé wa mọ́ de igbagbọ́ ti a mbọwa fihàn. 24 Nitorina ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ́. 25 Ṣugbọn lẹhin igbati igbagbọ́ ti de, awa kò si labẹ olukọni mọ́. 26 Nitoripe ọmọ Ọlọrun ni gbogbo nyin, nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu. 27 Nitoripe iye ẹnyin ti a ti baptisi sinu Kristi, ti gbe Kristi wọ̀. 28 Kò le si Ju tabi Hellene, ẹrú tabi omnira, ọkunrin tabi obinrin: nitoripe ọ̀kan ni gbogbo nyin jẹ ninu Kristi Jesu. 29 Bi ẹnyin ba si jẹ ti Kristi, njẹ ẹnyin ni irú-ọmọ Abrahamu, ati arole gẹgẹ bi ileri.
Galatians 3
Faith Brings Righteousness
1 You foolish Galatians, who has bewitched you, before whose eyes Jesus Christ was publicly portrayed as crucified?2 This is the only thing I want to find out from you: did you receive the Spirit by the works of the Law, or by hearing with faith?3 Are you so foolish? Having begun by the Spirit, are you now being perfected by the flesh?4 Did you suffer so many things in vain-if indeed it was in vain?5 So then, does He who provides you with the Spirit and works miracles among you, do it by the works of the Law, or by hearing with faith?
6 Even so Abraham BELIEVED GOD, AND IT WAS RECKONED TO HIM AS RIGHTEOUSNESS.7 Therefore, be sure that it is those who are of faith who are sons of Abraham.8 The Scripture, foreseeing that God would justify the Gentiles by faith, preached the gospel beforehand to Abraham, saying, "ALL THE NATIONS WILL BE BLESSED IN YOU."9 So then those who are of faith are blessed with Abraham, the believer.
10 For as many as are of the works of the Law are under a curse; for it is written, "CURSED IS EVERYONE WHO DOES NOT ABIDE BY ALL THINGS WRITTEN IN THE BOOK OF THE LAW, TO PERFORM THEM."11 Now that no one is justified by the Law before God is evident; for, "THE RIGHTEOUS MAN SHALL LIVE BY FAITH."12 However, the Law is not of faith; on the contrary, "HE WHO PRACTICES THEM SHALL LIVE BY THEM."13 Christ redeemed us from the curse of the Law, having become a curse for us-for it is written, "CURSED IS EVERYONE WHO HANGS ON A TREE"-14 in order that in Christ Jesus the blessing of Abraham might come to the Gentiles, so that we would receive the promise of the Spirit through faith.
Intent of the Law
15 Brethren, I speak in terms of human relations: even though it is only a man's covenant, yet when it has been ratified, no one sets it aside or adds conditions to it.16 Now the promises were spoken to Abraham and to his seed. He does not say, "And to seeds," as referring to many, but rather to one, "And to your seed," that is, Christ.17 What I am saying is this: the Law, which came four hundred and thirty years later, does not invalidate a covenant previously ratified by God, so as to nullify the promise.18 For if the inheritance is based on law, it is no longer based on a promise; but God has granted it to Abraham by means of a promise.
19 Why the Law then? It was added because of transgressions, having been ordained through angels by the agency of a mediator, until the seed would come to whom the promise had been made.20 Now a mediator is not for one party only; whereas God is only one.21 Is the Law then contrary to the promises of God? May it never be! For if a law had been given which was able to impart life, then righteousness would indeed have been based on law.22 But the Scripture has shut up everyone under sin, so that the promise by faith in Jesus Christ might be given to those who believe.
23 But before faith came, we were kept in custody under the law, being shut up to the faith which was later to be revealed.24 Therefore the Law has become our tutor to lead us to Christ, so that we may be justified by faith.25 But now that faith has come, we are no longer under a tutor.26 For you are all sons of God through faith in Christ Jesus.27 For all of you who were baptized into Christ have clothed yourselves with Christ.28 There is neither Jew nor Greek, there is neither slave nor free man, there is neither male nor female; for you are all one in Christ Jesus.29 And if you belong to Christ, then you are Abraham's descendants, heirs according to promise.