Gal 5
Òmìnira Onigbagbọ
1 NITORINA ẹ duro ṣinṣin ninu omnira na eyi ti Kristi fi sọ wa di omnira, ki ẹ má si ṣe tún fi ọrùn bọ àjaga ẹrú mọ́. 2 Kiyesi i, emi Paulu li o wi fun nyin pe, bi a ba kọ nyin nila, Kristi ki yio li ère fun nyin li ohunkohun. 3 Mo si tún sọ fun olukuluku enia ti a kọ ni ila pe, o di ajigbese lati pa gbogbo ofin mọ́. 4 A ti yà nyin kuro lọdọ Kristi, ẹnyin ti nfẹ ki a da nyin lare nipa ofin; ẹ ti ṣubu kuro ninu ore-ọfẹ. 5 Nitori nipa Ẹmí awa nfi igbagbọ duro de ireti ododo. 6 Nitori ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla; ṣugbọn igbagbọ́ ti nṣiṣẹ nipa ifẹ. 7 Ẹnyin ti nsáre daradara; tani ha dí nyin lọwọ ki ẹnyin ki o máṣe gba otitọ? 8 Iyipada yi kò ti ọdọ ẹniti o pè nyin wá. 9 Iwukara kiun ni imu gbogbo iyẹfun wu. 10 Mo ni igbẹkẹle si nyin ninu Oluwa pe, ẹnyin kì yio ni ero ohun miran; ṣugbọn ẹniti nyọ nyin lẹnu yio rù idajọ tirẹ̀, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ. 11 Ṣugbọn, ara, bi emi ba nwasu ikọla sibẹ, ehatiṣe ti a nṣe inunibini si mi sibẹ? njẹ ikọsẹ agbelebu ti kuro. 12 Emi iba fẹ ki awọn ti nyọ nyin lẹnu tilẹ ké ara wọn kuro. 13 Nitori a ti pè nyin si omnira, ará; kiki pe ki ẹ máṣe lò omnira nyin fun àye sipa ti ara, ṣugbọn ẹ mã fi ifẹ sìn ọmọnikeji nyin. 14 Nitoripe a kó gbogbo ofin já ninu ọ̀rọ kan, ani ninu eyi pe; Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.
15 Ṣugbọn bi ẹnyin ba mbù ara nyin ṣán, ti ẹ si njẹ ara nyin run, ẹ kiyesara ki ẹ máṣe pa ara nyin run.Èso Ti Ẹ̀mí ati Àwọn Iṣẹ́ Ti Ara
16 Njẹ mo ni, Ẹ ma rìn nipa ti Ẹmí, ẹnyin kì yio si mu ifẹkufẹ ti ara ṣẹ. 17 Nitoriti ara nṣe ifẹkufẹ lodi si Ẹmí, ati Ẹmí lodi si ara: awọn wọnyi si lodi si ara wọn; ki ẹ má ba le ṣe ohun ti ẹnyin nfẹ. 18 Ṣugbọn bi a ba nti ọwọ Ẹmí ṣamọna nyin, ẹnyin kò si labẹ ofin. 19 Njẹ awọn iṣẹ ti ara farahàn, ti iṣe wọnyi; panṣaga, àgbere, ìwa-ẽri, wọ̀bia, 20 Ibọriṣa, oṣó, irira, ìja, ilara, ibinu, asọ, ìṣọtẹ, adamọ̀, 21 Arankàn, ipania, imutipara, iréde-oru, ati iru wọnni: awọn ohun ti mo nwi fun nyin tẹlẹ, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin tẹlẹ rí pe, awọn ti nṣe nkan bawọnni kì yio jogún ijọba Ọlọrun. 22 Ṣugbọn eso ti Ẹmí ni ifẹ, ayọ̀, alafia, ipamọra, ìwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ́, 23 Ìwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu: ofin kan kò lodi si iru wọnni. 24 Awọn ti iṣe ti Kristi Jesu ti kàn ara mọ agbelebu ti on ti ifẹ ati ifẹkufẹ rẹ̀. 25 Bi awa ba wà lãye sipa ti Ẹmí, ẹ jẹ ki a si mã rìn nipa ti Ẹmí. 26 Ẹ máṣe jẹ ki a mã ṣogo-asan, ki a má mu ọmọnikeji wa binu, ki a má ṣe ilara ọmọnikeji wa.
Galatians 5
Walk by the Spirit
1 It was for freedom that Christ set us free; therefore keep standing firm and do not be subject again to a yoke of slavery.
2 Behold I, Paul, say to you that if you receive circumcision, Christ will be of no benefit to you.3 And I testify again to every man who receives circumcision, that he is under obligation to keep the whole Law.4 You have been severed from Christ, you who are seeking to be justified by law; you have fallen from grace.5 For we through the Spirit, by faith, are waiting for the hope of righteousness.6 For in Christ Jesus neither circumcision nor uncircumcision means anything, but faith working through love.
7 You were running well; who hindered you from obeying the truth?8 This persuasion did not come from Him who calls you.9 A little leaven leavens the whole lump of dough. 10 I have confidence in you in the Lord that you will adopt no other view; but the one who is disturbing you will bear his judgment, whoever he is.11 But I, brethren, if I still preach circumcision, why am I still persecuted? Then the stumbling block of the cross has been abolished.12 I wish that those who are troubling you would even mutilate themselves.
13 For you were called to freedom, brethren; only do not turn your freedom into an opportunity for the flesh, but through love serve one another.14 For the whole Law is fulfilled in one word, in the statement, "YOU SHALL LOVE YOUR NEIGHBOR AS YOURSELF."15 But if you bite and devour one another, take care that you are not consumed by one another.
16 But I say, walk by the Spirit, and you will not carry out the desire of the flesh.17 For the flesh sets its desire against the Spirit, and the Spirit against the flesh; for these are in opposition to one another, so that you may not do the things that you please.18 But if you are led by the Spirit, you are not under the Law.19 Now the deeds of the flesh are evident, which are: immorality, impurity, sensuality,20 idolatry, sorcery, enmities, strife, jealousy, outbursts of anger, disputes, dissensions, factions,21 envying, drunkenness, carousing, and things like these, of which I forewarn you, just as I have forewarned you, that those who practice such things will not inherit the kingdom of God.22 But the fruit of the Spirit is love, joy, peace, patience, kindness, goodness, faithfulness,23 gentleness, self-control; against such things there is no law.24 Now those who belong to Christ Jesus have crucified the flesh with its passions and desires.
25 If we live by the Spirit, let us also walk by the Spirit.26 Let us not become boastful, challenging one another, envying one another.