Gal 6
Ẹ Máa Ran Ara Yín Lọ́wọ́
1 ARÁ, bi a tilẹ mu enia ninu iṣubu kan, ki ẹnyin ti iṣe ti Ẹmí ki o mu irú ẹni bẹ̃ bọ̀ sipò ni ẹmí iwa tutu; ki iwọ tikararẹ mã kiyesara, ki a má ba dan iwọ nã wò pẹlu. 2 Ẹ mã rù ẹrù ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bẹ̃ mu ofin Kristi ṣẹ. 3 Nitori bi enia kan ba nrò ara rẹ̀ si ẹnikan, nigbati kò jẹ nkan, o ntàn ara rẹ̀ jẹ. 4 Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ̀ wò, nigbana ni yio si ni ohun iṣogo nipa ti ara rẹ̀ nikan, kì yio si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ̀. 5 Nitori olukuluku ni yio rù ẹrù ti ara rẹ̀. 6 Ṣugbọn ki ẹniti a nkọ́ ninu ọ̀rọ na mã pese ohun rere gbogbo fun ẹniti nkọni. 7 Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká. 8 Nitori ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yio ká idibajẹ; ṣugbọn ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti Ẹmí, nipa ti Ẹmí ni yio ká ìye ainipẹkun. 9 Ẹ má si jẹ ki agãra da wa ni rere iṣe: nitori awa ó ká nigbati akokò ba de, bi a kò bá ṣe ãrẹ̀.
10 Njẹ bi a ti nri akoko, ẹ jẹ ki a mã ṣore fun gbogbo enia, ati pãpa fun awọn ti iṣe ara ile igbagbọ́.Gbolohun Ìparí
11 Ẹ wò bi mo ti fi ọwọ ara mi kọwe gàdàgbà-gàdàgbà si nyin. 12 Iye awọn ti nfẹ ṣe aṣehan li ara, nwọn nrọ̀ nyin lati kọla; kiki nitoripe ki a ma ba ṣe inunibini si wọn nitori agbelebu Kristi. 13 Nitori awọn ti a kọ nilà pãpã kò pa ofin mọ́, ṣugbọn nwọn nfẹ mu nyin kọla, ki nwọn ki o le mã ṣogo ninu ara nyin. 14 Ṣugbọn ki a máṣe ri pe emi nṣogo, bikoṣe ninu agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa, nipasẹ ẹniti a ti kàn aiye mọ agbelebu fun mi, ati emi fun aiye. 15 Nitoripe ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla, bikoṣe ẹda titun. 16 Iye awọn ti o si nrìn gẹgẹ bi ìwọn yi, alafia lori wọn ati ãnu, ati lori Israeli Ọlọrun. 17 Lati isisiyi lọ, ki ẹnikẹni máṣe yọ mi lẹnu mọ́: nitori emi nrù àpá Jesu Oluwa kiri li ara mi. 18 Ará, ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu ẹmí nyin. Amin.11-Feb-2009@11:05, Backup Description=11-Feb-2009@09:10, Ayo Durodola -
08-Apr-2009@14:15, Backup Description=08-Apr-2009@08:23, Ayo Durodola -
08-Apr-2009@14:52, Backup Description=08-Apr-2009@14:37, Ayo Durodola -
22-Dec-2009@14:07, Backup Description=22-Dec-2009@14:01, victor Damilare -
Galatians 6
Bear One Another's Burdens
1 Brethren, even if anyone is caught in any trespass, you who are spiritual, restore such a one in a spirit of gentleness; each one looking to yourself, so that you too will not be tempted.2 Bear one another's burdens, and thereby fulfill the law of Christ.3 For if anyone thinks he is something when he is nothing, he deceives himself.4 But each one must examine his own work, and then he will have reason for boasting in regard to himself alone, and not in regard to another.5 For each one will bear his own load.
6 The one who is taught the word is to share all good things with the one who teaches him. 7 Do not be deceived, God is not mocked; for whatever a man sows, this he will also reap.8 For the one who sows to his own flesh will from the flesh reap corruption, but the one who sows to the Spirit will from the Spirit reap eternal life.9 Let us not lose heart in doing good, for in due time we will reap if we do not grow weary.10 So then, while we have opportunity, let us do good to all people, and especially to those who are of the household of the faith.
11 See with what large letters I am writing to you with my own hand.12 Those who desire to make a good showing in the flesh try to compel you to be circumcised, simply so that they will not be persecuted for the cross of Christ.13 For those who tare circumcised do not even keep the Law themselves, but they desire to have you circumcised so that they may boast in your flesh.14 But may it never be that I would boast, except in the cross of our Lord Jesus Christ, through which the world has been crucified to me, and I to the world.15 For neither is circumcision anything, nor uncircumcision, but a new creation.16 And those who will walk by this rule, peace and mercy be upon them, and upon the Israel of God.
17 From now on let no one cause trouble for me, for I bear on my body the brand-marks of Jesus.
18 The grace of our Lord Jesus Christ be with your spirit, brethren. Amen.