Heb 1
Ọlọrun Sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ Rẹ̀
1 ỌLỌRUN, ẹni, ni igba pupọ̀ ati li onirũru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọ̀rọ nigbãni. 2 Ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rẹ̀ ba wa sọ̀rọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu;
3 Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke;Ọmọ Ọlọrun ju àwọn Angẹli lọ
4 O si ti fi bẹ̃ di ẹniti o sàn ju awọn angẹli lọ, bi o ti jogun orukọ ti o ta tiwọn yọ. 5 Nitori ewo ninu awọn angẹli li o wi fun rí pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ? Ati pẹlu, Emi yio jẹ Baba fun u, on yio si jẹ Ọmọ fun mi? 6 Ati pẹlu, nigbati o mu akọbi ni wá si aiye, o wipe, Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun u. 7 Ati niti awọn angẹli, o wipe, Ẹniti o dá awọn angẹli rẹ̀ li ẹmí, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ li ọwọ́ iná. 8 Ṣugbọn niti Ọmọ li o wipe, Itẹ́ rẹ, Ọlọrun, lai ati lailai ni; ọpá alade ododo li ọpá alade ijọba rẹ. 9 Iwọ fẹ ododo, iwọ si korira ẹ̀ṣẹ; nitorina li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ, ṣe fi oróro ayọ̀ yan ọ jù awọn ẹgbẹ rẹ lọ. 10 Ati Iwọ, Oluwa, li atetekọṣe li o ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; awọn ọrun si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ: 11 Nwọn ó ṣegbe; ṣugbọn iwọ ó wà sibẹ, gbogbo wọn ni yio si gbó bi ẹwu; 12 Ati bi aṣọ ni iwọ o si ká wọn, a o si pàrọ wọn: ṣugbọn bakanna ni iwọ, ọdún rẹ kì yio si pin. 13 Ṣugbọn ewo ninu awọn angẹli li o sọ nipa rẹ̀ ri pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ? 14 Ẹmí ti njiṣẹ ki gbogbo wọn iṣe, ti a nran lọ lati mã jọsin nitori awọn ti yio jogun igbala?
Hebrews 1
God's Final Word in His Son
1 God, after He spoke long ago to the fathers in the prophets in many portions and in many ways,2 in these last days has spoken to us in His Son, whom He appointed heir of all things, through whom also He made the world.3 And He is the radiance of His glory and the exact representation of His nature, and upholds all things by the word of His power. When He had made purification of sins, He sat down at the right hand of the Majesty on high,4 having become as much better than the angels, as He has inherited a more excellent name than they.
5 For to which of the angels did He ever say,
"YOU ARE MY SON,
TODAY I HAVE BEGOTTEN YOU"?
And again,
"I WILL BE A FATHER TO HIM
AND HE SHALL BE A SON TO ME"?6 And when He again brings the firstborn into the world, He says,
"AND LET ALL THE ANGELS OF GOD WORSHIP HIM."7 And of the angels He says,
"WHO MAKES HIS ANGELS WINDS,
AND HIS MINISTERS A FLAME OF FIRE."8 But of the Son He says,
"YOUR THRONE, O GOD, IS FOREVER AND EVER,
AND THE RIGHTEOUS SCEPTER IS THE SCEPTER OF tHIS KINGDOM.
9 "YOU HAVE LOVED RIGHTEOUSNESS AND HATED LAWLESSNESS;
THEREFORE GOD, YOUR GOD, HAS ANOINTED YOU
WITH THE OIL OF GLADNESS ABOVE YOUR COMPANIONS."10 And,
"YOU, LORD, IN THE BEGINNING LAID THE FOUNDATION OF THE EARTH,
AND THE HEAVENS ARE THE WORKS OF YOUR HANDS;
11 THEY WILL PERISH, BUT YOU REMAIN;
AND THEY ALL WILL BECOME OLD LIKE A GARMENT,
12 AND LIKE A MANTLE YOU WILL ROLL THEM UP;
LIKE A GARMENT THEY WILL ALSO BE CHANGED.
BUT YOU ARE THE SAME,
AND YOUR YEARS WILL NOT COME TO AN END."13 But to which of the angels has He ever said,
"SIT AT MY RIGHT HAND,
UNTIL I MAKE YOUR ENEMIES
A FOOTSTOOL FOR YOUR FEET"?14 Are they not all ministering spirits, sent out to render service for the sake of those who will inherit salvation?