previous next

Heb 12

Ìtọ́ni ti Oluwa

1 NITORINA bi a ti fi awọsanmọ ti o kún to bayi fun awọn ẹlẹri yí wa ká, ẹ jẹ ki a pa ohun idiwọ gbogbo tì si apakan, ati ẹ̀ṣẹ ti o rọrun lati dì mọ wa, ki a si mã fi sũru sure ije ti a gbé ka iwaju wa, 2 Ki a mã wò Jesu olupilẹṣẹ ati alaṣepe igbagbọ́ wa; ẹni, nitori ayọ̀ ti a gbé ká iwaju rẹ̀, ti o farada agbelebu, laika itiju si, ti o si joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ Ọlọrun. 3 Sá ro ti ẹniti o farada irú isọrọ-odì yi lati ọdọ awọn ẹlẹṣẹ si ara rẹ̀, ki ẹ má ba rẹwẹsi ni ọkàn nyin, ki ãrẹ si mu nyin. 4 Ẹnyin kò ìtĩ kọ oju ija si ẹ̀ṣẹ titi de ẹ̀jẹ ni ijakadi nyin. 5 Ẹnyin si ti gbagbé ọ̀rọ iyanju ti mba nyin sọ bi ọmọ pe, Ọmọ mi, má ṣe alainani ibawi Oluwa, ki o má si ṣe rẹwẹsi nigbati a ba nti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wi: 6 Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ, on ni ibawi, a si mã nà olukuluku ọmọ ti o gbà. 7 Ẹ mã mu suru labẹ ibawi: Ọlọrun mba nyin lo bi ọmọ ni; nitoripe ọmọ wo ni mbẹ ti baba ki ibawi? 8 Ṣugbọn bi ẹnyin ba wà li aisi ibawi, ninu eyiti gbogbo enia ti jẹ alabapin, njẹ ọmọ àle ni nyin, ẹ kì isi iṣe ọmọ. 9 Pẹlupẹlu awa ni baba wa nipa ti ara ti o ntọ́ wa, awa si mbù ọlá fun wọn: awa kì yio kuku tẹriba fun Baba awọn ẹmí ki a si yè? 10 Nitori nwọn tọ́ wa fun ọjọ diẹ bi o ba ti dara loju wọn; ṣugbọn on fun ère wa, ki awa ki o le ṣe alabapin ìwa mimọ́ rẹ̀. 11 Gbogbo ibawi kò dabi ohun ayọ̀ nisisiyi, bikoṣe ibanujẹ; ṣugbọn nikẹhin a so eso alafia fun awọn ti a ti tọ́ nipa rẹ̀, ani eso ododo. 12 Nitorina ẹ na ọwọ́ ti o rọ, ati ẽkun ailera;

13 Ki ẹ si ṣe ipa-ọna ti o tọ fun ẹsẹ nyin, ki eyiti o rọ má bã kuro lori iké ṣugbọn ki a kuku wo o san.

Ìkìlọ̀ Kí Eniyan má Kọ Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun


14 Ẹ mã lepa alafia pẹlu enia gbogbo, ati ìwa mimọ́, li aisi eyini kò si ẹniti yio ri Oluwa: 15 Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe kùna ore-ọfẹ Ọlọrun; ki gbòngbo ikorò kan ki o má ba hù soke ki o si yọ nyin lẹnu, ọ̀pọlọpọ a si ti ipa rẹ̀ di aimọ́; 16 Ki o má bã si àgbere kan tabi alaiwa-bi-Ọlọrun bi Esau, ẹniti o ti itori òkele onjẹ kan tà ogún ibí rẹ̀. 17 Nitori ẹnyin mọ̀ pe lẹhinna ní ani nigbati o fẹ lati jogun ibukun na, a kọ̀ ọ (nitori kò ri aye ironupiwada) bi o tilẹ ti fi omije wá a gidigidi. 18 Nitori ẹnyin kò wá si òke, ti a le fi ọwọ kàn, ati si iná ti njó, ati si iṣúdùdu ati òkunkun, ati iji, 19 Ati iró ipè, ati ohùn ọ̀rọ, eyiti awọn ti o gbọ́ bẹ̀bẹ pe, ki a máṣe sọ ọ̀rọ si i fun wọn mọ́: 20 Nitoripe ara wọn kò le gbà ohun ti o palaṣẹ, Bi o tilẹ jẹ ẹranko li o farakan òke na, a o sọ ọ li okuta, tabi a o gún u li ọ̀kọ pa. 21 Iran na si lẹrù tobẹ̃, ti Mose wipe, ẹ̀ru bà mi gidigidi mo si warìri. 22 Ṣugbọn ẹnyin wá si òke Sioni, ati si ilu Ọlọrun alãye, si Jerusalemu ti ọ̀run, ati si ẹgbẹ awọn angẹli ainiye, 23 Si ajọ nla ati ìjọ akọbi ti a ti kọ orukọ wọn li ọ̀run, ati sọdọ Ọlọrun onidajọ gbogbo enia, ati sọdọ awọn ẹmí olõtọ enia ti a ṣe li aṣepé, 24 Ati sọdọ Jesu alarina majẹmu titun, ati si ibi ẹ̀jẹ ibuwọ́n nì, ti nsọ̀rọ ohun ti o dara jù ti Abeli lọ. 25 Kiyesi i, ki ẹ máṣe kọ̀ ẹniti nkilọ. Nitori bi awọn wọnni kò ba bọ́ nigbati nwọn kọ̀ ẹniti nkilọ li aiye, melomelo li awa kì yio bọ́ awa ti o pẹhinda si ẹniti nkilọ lati ọrun wá: 26 Ohùn ẹniti o mì aiye nigbana: ṣugbọn nisisiyi o ti ṣe ileri, wipe, Lẹ̃kan si i emi kì yio mì kìki aiye nikan, ṣugbọn ọrun pẹlu. 27 Ati ọ̀rọ yi, Lẹ̃kan si i, itumọ rẹ̀ ni mimu awọn ohun wọnni ti a nmì kuro, bi ohun ti a ti da, ki awọn ohun wọnni ti a kò le mì le wà sibẹ. 28 Nitorina bi awa ti ngbà ilẹ ọba ti a kò le mì, ẹ jẹ ki a ni ore-ọfẹ nipa eyiti awa le mã sin Ọlọrun ni itẹwọgbà pẹlu ọ̀wọ ati ibẹru rẹ̀. 29 Nitoripe Ọlọrun wa, iná ti ijonirun ni.

Hebrews 12

Jesus, the Example

1 Therefore, since we have so great a cloud of witnesses surrounding us, let us also lay aside every encumbrance and the sin which so easily entangles us, and let us run with endurance the race that is set before us,2 fixing our eyes on Jesus, the author and perfecter of faith, who for the joy set before Him endured the cross, despising the shame, and has sat down at the right hand of the throne of God.

3 For consider Him who has endured such hostility by sinners against Himself, so that you will not grow weary and lose heart.

A Father's Discipline

4 You have not yet resisted to the point of shedding blood in your striving against sin;5 and you have forgotten the exhortation which is addressed to you as sons,
"MY SON, DO NOT REGARD LIGHTLY THE DISCIPLINE OF THE LORD,
NOR FAINT WHEN YOU ARE REPROVED BY HIM;

6 FOR THOSE WHOM THE LORD LOVES HE DISCIPLINES,
AND HE SCOURGES EVERY SON WHOM HE RECEIVES."
7 It is for discipline that you endure; God deals with you as with sons; for what son is there whom his father does not discipline?8 But if you are without discipline, of which all have become partakers, then you are illegitimate children and not sons.9 Furthermore, we had earthly fathers to discipline us, and we respected them; shall we not much rather be subject to the Father of spirits, and live?10 For they disciplined us for a short time as seemed best to them, but He disciplines us for our good, so that we may share His holiness.11 All discipline for the moment seems not to be joyful, but sorrowful; yet to those who have been trained by it, afterwards it yields the peaceful fruit of righteousness.

12 Therefore, strengthen the hands that are weak and the knees that are feeble,13 and make straight paths for your feet, so that the limb which is lame may not be put out of joint, but rather be healed.

14 Pursue peace with all men, and the sanctification without which no one will see the Lord.15 See to it that no one comes short of the grace of God; that no root of bitterness springing up causes trouble, and by it many be defiled;16 that there be no immoral or godless person like Esau, who sold his own birthright for a single meal.17 For you know that even afterwards, when he desired to inherit the blessing, he was rejected, for he found no place for repentance, though he sought for it with tears.

Contrast of Sinai and Zion

18 For you have not come to a mountain that can be touched and to a blazing fire, and to darkness and gloom and whirlwind,19 and to the blast of a trumpet and the sound of words which sound was such that those who heard begged that no further word be spoken to them.20 For they could not bear the command, "IF EVEN A BEAST TOUCHES THE MOUNTAIN, IT WILL BE STONED."21 And so terrible was the sight, that Moses said, "I AM FULL OF FEAR and trembling."22 But you have come to Mount Zion and to the city of the living God, the heavenly Jerusalem, and to myriads of angels,23 to the general assembly and church of the firstborn who are enrolled in heaven, and to God, the Judge of all, and to the spirits of the righteous made perfect,24 and to Jesus, the mediator of a new covenant, and to the sprinkled blood, which speaks better than the blood of Abel.

The Unshaken Kingdom

25 See to it that you do not refuse Him who is speaking. For if those did not escape when they refused him who warned them on earth, much less will we escape who turn away from Him who warns from heaven.26 And His voice shook the earth then, but now He has promised, saying, "YET ONCE MORE I WILL SHAKE NOT ONLY THE EARTH, BUT ALSO THE HEAVEN."27 This expression, "Yet once more," denotes the removing of those things which can be shaken, as of created things, so that those things which cannot be shaken may remain.28 Therefore, since we receive a kingdom which cannot be shaken, let us show gratitude, by which we may offer to God an acceptable service with reverence and awe;29 for our God is a consuming fire.