previous next

Heb 13

Ìsìn Tí Ó Wu Ọlọrun

1 KI ifẹ ará ki o wà titi. 2 Ẹ máṣe gbagbé lati mã ṣe alejò; nitoripe nipa bẹ̃ li awọn ẹlomiran ṣe awọn angẹli li alejò laimọ̀. 3 Ẹ mã ranti awọn onde bi ẹniti a dè pẹlu wọn, ati awọn ti a npọn loju bi ẹnyin tikaranyin pẹlu ti mbẹ ninu ara. 4 Ki igbéyawo ki o li ọla larin gbogbo enia, ki akete si jẹ alailẽri: nitori awọn àgbere ati awọn panṣaga li Ọlọrun yio dá lẹjọ. 5 Ki ọkàn nyin ki o máṣe fa si ifẹ owo, ki ohun ti ẹ ni ki o to nyin; nitori on tikalarẹ ti wipe, Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọ ọ silẹ. 6 Nitorina ni awa ṣe nfi igboiya wipe, Oluwa li oluranlọwọ mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi? 7 Ẹ mã ranti awọn ti nwọn jẹ olori nyin, ti nwọn ti sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun nyin; ki ẹ mã ro opin ìwa-aiye wọn, ki ẹ si mã ṣe afarawe igbagbọ́ wọn. 8 Jesu Kristi ọkanna ni li aná, ati li oni, ati titi lai. 9 Ẹ máṣe jẹ ki a fi onirũru ati ẹkọ́ àjeji gbá nyin kiri. Nitori o dara ki a mu nyin li ọkàn le nipa ore-ọfẹ, kì iṣe nipa onjẹ, ninu eyiti awọn ti o ti nrìn ninu wọn kò li ère. 10 Awa ni pẹpẹ kan, ninu eyi ti awọn ti nsìn agọ́ kò li agbara lati mã jẹ. 11 Nitoripe ara awọn ẹran wọnni, ẹ̀jẹ eyiti olori alufa mu wá si ibi mimọ́ nitori ẹ̀ṣẹ, a sun wọn lẹhin ibudo. 12 Nitorina Jesu pẹlu, ki o le fi ẹ̀jẹ ara rẹ̀ sọ awọn enia di mimọ́, o jìya lẹhin bode. 13 Nitorina ẹ jẹ ki a jade tọ̀ ọ lọ lẹhin ibudo, ki a mã rù ẹ̀gan rẹ̀. 14 Nitoripe awa kò ni ilu ti o wà titi nihin, ṣugbọn awa nwá eyiti mbọ̀. 15 Njẹ nipasẹ rẹ̀, ẹ jẹ ki a mã ru ẹbọ iyìn si Ọlọrun nigbagbogbo, eyini ni eso ète wa, ti njẹwọ orukọ rẹ̀. 16 Ṣugbọn ati mã ṣõre on ati mã pinfunni ẹ máṣe gbagbé: nitori irú ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dùn si jọjọ. 17 Ẹ mã gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mã tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣíro, ki nwọn ki o le fi ayọ̀ ṣe eyi, li aisi ibinujẹ, nitori eyiyi yio jẹ ailere fun nyin. 18 Ẹ mã gbadura fun wa: nitori awa gbagbọ pe awa ni ẹri-ọkàn rere, a si nfẹ lati mã wà lododo ninu ohun gbogbo.

19 Ṣugbọn emi mbẹ̀ nyin gidigidi si i lati mã ṣe eyi, ki a ba le tète fi mi fun nyin pada.

Ìdágbére


20 Njẹ Ọlọrun alafia, ẹniti o tun mu oluṣọ-agutan nla ti awọn agutan, ti inu okú wá, nipa ẹ̀jẹ majẹmu aiyeraiye, ani Oluwa wa Jesu, 21 Ki o mu nyin pé ninu iṣẹ rere gbogbo lati ṣe ifẹ rẹ̀, ki o mã ṣiṣẹ ohun ti iṣe itẹwọgba niwaju rẹ̀ ninu wa nipasẹ Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin. 22 Emi si mbẹ nyin, ará, ẹ gbà ọ̀rọ iyanju mi; nitori iwe kukuru ni mo kọ si nyin. 23 Ẹ mọ̀ pé a dá Timotiu arakunrin wa silẹ; bi o ba tete de, emi pẹlu rẹ̀ yio ri nyin. 24 Ẹ kí gbogbo awọn ti nṣe olori nyin, ati gbogbo awọn enia mimọ́. Awọn ti o ti Itali wá kí nyin. 25 Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

11-Feb-2009@11:05, Backup Description=11-Feb-2009@09:10, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:15, Backup Description=08-Apr-2009@08:23, Ayo Durodola -

08-Apr-2009@14:52, Backup Description=08-Apr-2009@14:37, Ayo Durodola -

22-Dec-2009@14:07, Backup Description=22-Dec-2009@14:01, victor Damilare -

Hebrews 13

The Changeless Christ

1 Let love of the brethren continue.2 Do not neglect to show hospitality to strangers, for by this some have entertained angels without knowing it.3 Remember the prisoners, as though in prison with them, and those who are ill-treated, since you yourselves also are in the body.4 Marriage is to be held in honor among all, and the marriage bed is to be undefiled; for fornicators and adulterers God will judge.5  Make sure that your character is free from the love of money, being content with what you have; for He Himself has said, "I WILL NEVER DESERT YOU, NOR WILL I EVER FORSAKE YOU,"6 so that we confidently say,
"THE LORD IS MY HELPER, I WILL NOT BE AFRAID.
WHAT WILL MAN DO TO ME?"

7 Remember those who led you, who spoke the word of God to you; and considering the result of their conduct, imitate their faith.8 Jesus Christ is the same yesterday and today and forever.9 Do not be carried away by varied and strange teachings; for it is good for the heart to be strengthened by grace, not by foods, through which those who were so occupied were not benefited.10 We have an altar from which those who serve the tabernacle have no right to eat.11 For the bodies of those animals whose blood is brought into the holy place by the high priest as an offering for sin, are burned outside the camp.12 Therefore Jesus also, that He might sanctify the people through His own blood, suffered outside the gate.13 So, let us go out to Him outside the camp, bearing His reproach.14 For here we do not have a lasting city, but we are seeking the city which is to come.

God-pleasing Sacrifices

15 Through Him then, let us continually offer up a sacrifice of praise to God, that is, the fruit of lips that give thanks to His name.16 And do not neglect doing good and sharing, for with such sacrifices God is pleased.

17 Obey your leaders and submit to them, for they keep watch over your souls as those who will give an account. Let them do this with joy and not with grief, for this would be unprofitable for you.

18 Pray for us, for we are sure that we have a good conscience, desiring to conduct ourselves honorably in all things.19 And I urge you all the more to do this, so that I may be restored to you the sooner.

Benediction

20 Now the God of peace, who brought up from the dead the great Shepherd of the sheep through the blood of the eternal covenant, even Jesus our Lord,21 equip you in every good thing to do His will, working in us that which is pleasing in His sight, through Jesus Christ, to whom be the glory forever and ever. Amen.

22 But I urge you, brethren, bear with this word of exhortation, for I have written to you briefly.23 Take notice that our brother Timothy has been released, with whom, if he comes soon, I will see you.24 Greet all of your leaders and all the saints. Those from Italy greet you.

25 Grace be with you all.