previous next

Heb 5

1 NITORI olukuluku olori alufa ti a yàn ninu awọn enia, li a fi jẹ fun awọn enia niti ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le mã mu ẹ̀bun wá ati lati ṣe ẹbọ nitori ẹ̀ṣẹ: 2 Ẹniti o le bá awọn alaimoye ati awọn ti o ti yapa kẹdun, nitori a fi ailera yi on na ká pẹlu. 3 Nitori idi eyi li o si ṣe yẹ, bi o ti nṣe ẹbọ nitori ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, bẹ̃ pẹlu ni ki o ṣe fun ara rẹ̀. 4 Kò si si ẹniti o gbà ọlá yi fun ara rẹ̀, bikoṣe ẹniti a pè lati ọdọ Ọlọrun wá, gẹgẹ bi a ti pè Aaroni. 5 Bẹ̃ni Kristi pẹlu kò si ṣe ara rẹ̀ logo lati jẹ́ Olori Alufa; bikoṣe ẹniti o wi fun u pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ. 6 Bi o ti wi pẹlu nibomiran pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki. 7 Ẹni nigba ọjọ rẹ̀ ninu ara, ti o fi ẹkún rara ati omije gbadura, ti o si bẹ̀bẹ lọdọ ẹniti o le gbà a silẹ lọwọ ikú, a si gbohun rẹ̀ nitori ẹmi ọ̀wọ rẹ̀, 8 Bi o ti jẹ Ọmọ nì, sibẹ o kọ́ igbọran nipa ohun ti o jìya; 9 Bi a si ti sọ ọ di pipé, o wá di orisun igbala ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o ngbọ́ tirẹ̀:

10 Ti a yàn li Olori Alufa lati ọdọ Ọlọrun wá nipa ẹsẹ Melkisedeki.

Ìkìlọ̀ nípa Àwọn tí Ó Kúrò ninu Ẹ̀sìn Igbagbọ


11 Niti ẹniti awa ni ohun pupọ̀ lati sọ, ti o si ṣoro lati tumọ, nitoripe ẹ yigbì ni gbigbọ́. 12 Nitori nigbati akokò tó ti o yẹ ki ẹ jẹ olukọ, ẹ tun wà ni ẹniti ẹnikan yio mã kọ́ ni ibẹrẹ ipilẹ awọn ọ̀rọ Ọlọrun; ẹ si di irú awọn ti kò le ṣe aini wàra, ti nwọn kò si fẹ onjẹ lile. 13 Nitori olukuluku ẹniti nmu wàra jẹ́ alailoye ọ̀rọ ododo: nitori ọmọ-ọwọ ni. 14 Ṣugbọn onjẹ lile ni fun awọn ti o dagba, awọn ẹni nipa ìriri, ti nwọn nlò ọgbọ́n wọn lati fi iyatọ sarin rere ati buburu.

Hebrews 5

The Perfect High Priest

1 For every high priest taken from among men is appointed on behalf of men in things pertaining to God, in order to offer both gifts and sacrifices for sins;2 he can deal gently with the ignorant and misguided, since he himself also is beset with weakness;3 and because of it he is obligated to offer sacrifices for sins, as for the people, so also for himself.4 And no one takes the honor to himself, but receives it when he is called by God, even as Aaron was.

5 So also Christ did not glorify Himself so as to become a high priest, but He who said to Him,
"YOU ARE MY SON,
TODAY I HAVE BEGOTTEN YOU";
6 just as He says also in another passage,
"YOU ARE A PRIEST FOREVER
ACCORDING TO THE ORDER OF MELCHIZEDEK."
7 In the days of His flesh, He offered up both prayers and supplications with loud crying and tears to the One able to save Him from death, and He was heard because of His piety.8 Although He was a Son, He learned obedience from the things which He suffered.9 And having been made perfect, He became to all those who obey Him the source of eternal salvation,10 being designated by God as a high priest according to the order of Melchizedek.

11 Concerning thim we have much to say, and it is hard to explain, since you have become dull of hearing.12 For though by this time you ought to be teachers, you have need again for someone to teach you the elementary principles of the oracles of God, and you have come to need milk and not solid food.13 For everyone who partakes only of milk is not accustomed to the word of righteousness, for he is an infant.14 But solid food is for the mature, who because of practice have their senses trained to discern good and evil.