previous next

Joh 1

Ọlọrun di Eniyan

1 LI àtetekọṣe li Ọ̀rọ wà, Ọ̀rọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọ̀rọ na. 2 On na li o wà li àtetekọṣe pẹlu Ọlọrun. 3 Nipasẹ̀ rẹ̀ li a ti da ohun gbogbo; lẹhin rẹ̀ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da. 4 Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye. 5 Imọlẹ na si nmọlẹ ninu òkunkun; òkunkun na kò si bori rẹ̀. 6 Ọkunrin kan wà ti a rán lati ọdọ Ọlọrun wá, orukọ ẹniti njẹ Johanu. 7 On na li a si rán fun ẹri, ki o le ṣe ẹlẹri fun imọlẹ na, ki gbogbo enia ki o le gbagbọ́ nipasẹ rẹ̀. 8 On kì iṣe imọlẹ̀ na, ṣugbọn a rán a wá lati ṣe ẹlẹri fun Imọlẹ na. 9 Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye. 10 On si wà li aiye, nipasẹ rẹ̀ li a si ti da aiye, aiye kò si mọ̀ ọ. 11 O tọ̀ awọn tirẹ̀ wá, awọn ará tirẹ̀ kò si gbà a. 12 Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ̀ gbọ́: 13 Awọn ẹniti a bí, kì iṣe nipa ti ẹ̀jẹ, tabi nipa ti ifẹ ara, bẹ̃ni kì iṣe nipa ifẹ ti enia, bikoṣe nipa ifẹ ti Ọlọrun. 14 Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ. 15 Johanu si jẹri rẹ̀ o si kigbe, wipe, Eyi ni ẹniti mo sọrọ rẹ̀ pe, Ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, o pọ̀ju mi lọ: nitori o wà ṣiwaju mi. 16 Nitori ninu ẹkún rẹ̀ ni gbogbo wa si ti gbà, ati ore-ọfẹ kún ore-ọfẹ. 17 Nitoripe nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá.

18 Ko si ẹniti o ri Ọlọrun rí; Ọmọ bíbi kanṣoṣo, ti mbẹ li õkan àiya Baba, on na li o fi i hàn.

Ẹ̀rí Johanu Onítẹ̀bọmi nípa Jesu

(Mat 3:1-12; Mak 1:1-8; Luk 3:1-18)


19 Eyi si li ẹrí Johanu, nigbati awọn Ju rán awọn alufã ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalemu wá lati bi i lẽre pe, Tani iwọ ṣe? 20 O si jẹwọ, kò si sẹ́; o si jẹwọ pe, Emi kì iṣe Kristi na. 21 Nwọn si bi i pe, Tani iwọ ha iṣe? Elijah ni ọ bi? O si wipe Bẹ̃kọ. Iwọ ni woli na bi? O si dahùn wipe, Bẹ̃kọ. 22 Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? ki awa ki o le fi èsi fun awọn ti o rán wa. Kili o wi ni ti ara rẹ? 23 O wipe, Emi li ohùn ẹni ti nkigbe ni ijù, Ẹ ṣe ki ọ̀na Oluwa tọ́, gẹgẹ bi woli Isaiah ti wi. 24 Awọn ti a rán si jẹ ninu awọn Farisi. 25 Nwọn si bi i lẽre, nwọn si wi fun u pe, Njẹ ẽṣe ti iwọ fi mbaptisi, bi iwọ kì ibá ṣe Kristi na, tabi Elijah, tabi woli na? 26 Johanu da wọn lohùn, wipe, Emi nfi omi baptisi: ẹnikan duro larin nyin, ẹniti ẹnyin kò mọ̀; 27 On na li ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, ti o pọju mi lọ, ẹniti emi kò yẹ lati tú okùn bàta rẹ̀.

28 Nkan wọnyi li a ṣe ni Betani loke odò Jordani, nibiti Johanu gbé mbaptisi.

Ọ̀dọ́ Aguntan Ọlọrun Farahàn


29 Ni ijọ keji Johanu ri Jesu mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀; o wipe, Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó ẹ̀ṣẹ aiye lọ! 30 Eyi li ẹniti mo ti wipe, ọkunrin kan mbọ̀ wá lẹhin mi, ẹniti o pọ̀ju mi lọ: nitoriti o ti wà ṣiwaju mi. 31 Emi kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ki a le fi i hàn fun Israeli, nitorina li emi ṣe wá ti mo nfi omi baptisi. 32 Johanu si jẹri, o wipe, mo ri Ẹmi sọkalẹ lati ọrun wá bi àdaba, o si bà le e. 33 Emi kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹniti o rán mi wá, lati fi omi baptisi, on na li o wi fun mi pe, Lori ẹniti iwọ ba ri, ti Ẹmí sọkalẹ si, ti o si bà le e, on na li ẹniti nfi Ẹmí Mimọ́ baptisi.

34 Emi si ti ri, emi si ti njẹri pe, Eyi li Ọmọ Ọlọrun.

Àwọn Ọmọ-Ẹ̀hìn Kinni tí Jesu Ní


35 Ni ijọ keji ẹwẹ Johanu duro, ati meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: 36 O si wò Jesu bi o ti nrìn, o si wipe, Wò Ọdọ-agutan Ọlọrun! 37 Awọn ọmọ-ẹhin meji na si gbọ́ nigbati o wi, nwọn si tọ̀ Jesu lẹhin. 38 Nigbana ni Jesu yipada, o ri nwọn ntọ̀ on lẹhin, o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nwá? Nwọn wi fun u pe, Rabbi, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Olukọni,) nibo ni iwọ ngbé? 39 O wi fun wọn pe, Ẹ wá wò o. Nwọn si wá, nwọn si ri ibi ti o ngbé, nwọn si ba a joko ni ijọ na: nitoriti o jẹ ìwọn wakati kẹwa ọjọ. 40 Ọkan ninu awọn meji ti o gbọ́ ọ̀rọ Johanu, ti o si tọ̀ Jesu lẹhin, ni Anderu, arakunrin Simoni Peteru. 41 On tètekọ ri Simoni arakunrin on tikararẹ̀, o si wi fun u pe, Awa ti ri Messia, itumọ̀ eyi ti ijẹ Kristi.

42 O si mu u wá sọdọ Jesu. Jesu si wò o, o wipe, Iwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa li a o si ma pè ọ, itumọ̀ eyi ti ijẹ Peteru.

Jesu Pe Filipi ati Natanaeli


43 Ni ọjọ keji Jesu nfẹ jade lọ si Galili, o si ri Filippi, o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. 44 Ara Betsaida ni Filippi iṣe, ilu Anderu ati Peteru. 45 Filippi ri Natanaeli, o si wi fun u pe, Awa ti ri ẹniti Mose ninu ofin ati awọn woli ti kọwe rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josefu. 46 Natanaeli si wi fun u pe, Ohun rere kan ha le ti Nasareti jade? Filippi wi fun u pe, Wá wò o. 47 Jesu ri Natanaeli mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀, o si wi nipa rẹ̀ pe, Wo o, ọmọ Israelì nitõtọ, ninu ẹniti ẹ̀tan kò si! 48 Natanaeli wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti mọ̀ mi? Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ki Filippi to pè ọ, nigbati iwọ wà labẹ igi ọ̀pọ́tọ, mo ti ri ọ. 49 Natanaeli dahùn, o si wi fun u pe, Rabbi, iwọ li Ọmọ Ọlọrun; iwọ li Ọba Israeli. 50 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Nitori mo wi fun ọ pe, mo ri ọ labẹ igi ọpọtọ ni iwọ ṣe gbagbọ? iwọ ó ri ohun ti o pọ̀ju wọnyi lọ. 51 O si wi fun u pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin o ri ọrun ṣí silẹ, awọn angẹli Ọlọrun yio si ma gòke, nwọn o si ma sọkalẹ sori Ọmọ-enia.

John 1

The Deity of Jesus Christ

1 In the beginning was the Word, and the Word was with God, and the Word was God.2 He was in the beginning with God.3 All things came into being through Him, and apart from Him nothing came into being that has come into being.4 In Him was life, and the life was the Light of men.5 The Light shines in the darkness, and the darkness did not tcomprehend it.

The Witness John

6 There tcame a man sent from God, whose name was John.7 He came as a witness, to testify about the Light, so that all might believe through him.8 He was not the Light, but he came to testify about the Light.

9 There was the true Light twhich, coming into the world, enlightens every man.10 He was in the world, and the world was made through Him, and the world did not know Him.11 He came to His town, and those who were His own did not receive Him.12 But as many as received Him, to them He gave the right to become children of God, even to those who believe in His name,13 who were born, not of blood nor of the will of the flesh nor of the will of man, but of God.

The Word Made Flesh

14 And the Word became flesh, and dwelt among us, and we saw His glory, glory as of the only begotten from the Father, full of grace and truth.15 John *testified about Him and cried out, saying, "This was He of whom I said, 'He who comes after me has a higher rank than I, for He existed before me.'"16 For of His fullness we have all received, and grace upon grace.17 For the Law was given through Moses; grace and truth were realized through Jesus Christ.18 No one has seen God at any time; the only begotten God who is in the bosom of the Father, He has explained Him.

The Testimony of John

19 This is the testimony of John, when the Jews sent to him priests and Levites from Jerusalem to ask him, "Who are you?"20 And he confessed and did not deny, but confessed, "I am not the Christ."21 They asked him, "What then? Are you Elijah?" And he *said, "I am not." "Are you the Prophet?" And he answered, "No."22 Then they said to him, "Who are you, so that we may give an answer to those who sent us? What do you say about yourself?"23 He said, "I am A VOICE OF ONE CRYING IN THE WILDERNESS, 'MAKE STRAIGHT THE WAY OF THE LORD,' as Isaiah the prophet said."

24 Now they had been sent from the Pharisees.25 They asked him, and said to him, "Why then are you baptizing, if you are not the Christ, nor Elijah, nor the Prophet?"26 John answered them saying, "I baptize tin water, but among you stands One whom you do not know.27  It is He who comes after me, the thong of whose sandal I am not worthy to untie."28 These things took place in Bethany beyond the Jordan, where John was baptizing.

29 The next day he *saw Jesus coming to him and *said, "Behold, the Lamb of God who takes away the sin of the world!30 This is He on behalf of whom I said, 'After me comes a Man who has a higher rank than I, for He existed before me.'31 I did not recognize Him, but so that He might be manifested to Israel, I came baptizing tin water."32 John testified saying, "I have seen the Spirit descending as a dove out of heaven, and He remained upon Him.33 I did not recognize Him, but He who sent me to baptize tin water said to me, 'He upon whom you see the Spirit descending and remaining upon Him, this is the One who baptizes in the Holy Spirit.'34 I myself have seen, and have testified that this is the Son of God."

Jesus' Public Ministry, First Converts

35 Again the next day John was standing with two of his disciples,36 and he looked at Jesus as He walked, and *said, "Behold, the Lamb of God!"37 The two disciples heard him speak, and they followed Jesus.38 And Jesus turned and saw them following, and *said to them, "What do you seek?" They said to Him, "Rabbi (which translated means Teacher), where are You staying?"39 He *said to them, "Come, and you will see." So they came and saw where He was staying; and they stayed with Him that day, for it was about the ttenth hour.40 One of the two who heard John speak and followed Him, was Andrew, Simon Peter's brother.41 He *found first his own brother Simon and *said to him, "We have found the Messiah" (which translated means Christ).42 He brought him to Jesus. Jesus looked at him and said, "You are Simon the son of John; you shall be called Cephas" (which is translated Peter).

43 The next day He purposed to go into Galilee, and He *found Philip. And Jesus *said to him, "Follow Me."44 Now Philip was from Bethsaida, of the city of Andrew and Peter.45 Philip *found Nathanael and *said to him, "We have found Him of whom Moses in the Law and also the Prophets wrote-Jesus of Nazareth, the son of Joseph."46 Nathanael said to him, "Can any good thing come out of Nazareth?" Philip *said to him, "Come and see."47 Jesus saw Nathanael coming to Him, and *said of him, "Behold, an Israelite indeed, in whom there is no deceit!"48 Nathanael *said to Him, "How do You know me?" Jesus answered and said to him, "Before Philip called you, when you were under the fig tree, I saw you."49 Nathanael answered Him, "Rabbi, You are the Son of God; You are the King of Israel."50 Jesus answered and said to him, "Because I said to you that I saw you under the fig tree, do you believe? You will see greater things than these."51 And He *said to him, "Truly, truly, I say to you, you will see the heavens opened and the angels of God ascending and descending on the Son of Man."