previous next

Joh 10

Jesu Fi Aguntan Ṣe Àkàwé

1 LÕTỌ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti kò ba gbà ẹnu-ọ̀na wọ̀ inu agbo agutan, ṣugbọn ti o ba gbà ibomiran gùn oke, on na li olè ati ọlọṣà. 2 Ṣugbọn ẹniti o ba ba ti ẹnu-ọ̀na wọle, on ni iṣe oluṣọ awọn agutan. 3 On ni oludèna ṣilẹkun fun; awọn agutan si gbọ ohùn rẹ̀: o si pè awọn agutan tirẹ̀ li orukọ, o si ṣe amọ̀na wọn jade. 4 Nigbati o si mu awọn agutan tirẹ̀ jade, o ṣiwaju wọn, awọn agutan si ntọ̀ ọ lẹhin: nitoriti nwọn mọ̀ ohùn rẹ̀. 5 Nwọn kò jẹ tọ̀ alejò lẹhin, ṣugbọn nwọn a ma sá lọdọ rẹ̀: nitoriti nwọn kò mọ̀ ohùn alejò.

6 Owe yi ni Jesu pa fun wọn: ṣugbọn òye ohun ti nkan wọnni jẹ ti o nsọ fun wọn kò yé wọn.

Jesu Ni Olùṣọ́-Aguntan Rere


7 Nitorina Jesu tún wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Emi ni ilẹkun awọn agutan. 8 Olè ati ọlọṣà ni gbogbo awọn ti o ti wá ṣiwaju mi: ṣugbọn awọn agutan kò gbọ́ ti wọn. 9 Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là, yio wọle, yio si jade, yio si ri koriko. 10 Olè kì iwá bikoṣe lati jale, ati lati pa, ati lati parun: emi wá ki nwọn le ni ìye, ani ki nwọn le ni i lọpọlọpọ. 11 Emi ni oluṣọ-agutan rere: oluṣọ-agutan rere fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn agutan. 12 Ṣugbọn alagbaṣe, ti kì iṣe oluṣọ-agutan, ẹniti awọn agutan kì iṣe tirẹ̀, o ri ikõkò mbọ̀, o si fi awọn agutan silẹ, o si sá lọ: ikõkò si mu awọn agutan, o si fọn wọn ká kiri. 13 Alagbaṣe sá lọ nitoriti iṣe alagbaṣe, kò si náni awọn agutan. 14 Emi ni oluṣọ-agutan rere, mo si mọ̀ awọn temi, awọn temi si mọ̀ mi. 15 Gẹgẹ bi Baba ti mọ̀ mi, ti emi si mọ̀ Baba; mo si fi ẹmí mi lelẹ nitori awọn agutan. 16 Emi si ní awọn agutan miran, ti kì iṣe ti agbo yi: awọn li emi kò le ṣe alaimu wá pẹlu, nwọn ó si gbọ ohùn mi; nwọn o si jẹ agbo kan, oluṣọ-agutan kan. 17 Nitorina ni Baba mi ṣe fẹran mi, nitoriti mo fi ẹmí mi lelẹ, ki emi ki o le tún gbà a. 18 Ẹnikan kò gbà a lọwọ mi, ṣugbọn mo fi i lelẹ fun ara mi. Mo li agbara lati fi i lelẹ, mo si li agbara lati tún gbà a. Aṣẹ yi ni mo ti gbà lati ọdọ Baba mi wá. 19 Nitorina iyapa tun wà larin awọn Ju nitori ọ̀rọ wọnyi. 20 Ọpọ ninu wọn si wipe, O li ẹmi èṣu, ori rẹ̀ si bajẹ; ẽṣe ti ẹnyin ngbọ̀rọ rẹ̀?

21 Awọn miran wipe, Wọnyi kì iṣe ọ̀rọ ẹniti o li ẹmi èsu. Ẹmi èsu le là oju awọn afọju bi?

Àwọn Juu Kọ Jesu


22 O si jẹ ajọ ọdun iyasimimọ́ ni Jerusalemu, igba otutù ni. 23 Jesu si nrìn ni tẹmpili, nì ìloro Solomoni. 24 Nitorina awọn Ju wá duro yi i ká, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ó ti mu wa ṣe iyemeji pẹ to? Bi iwọ ni iṣe Kristi na, wi fun wa gbangba. 25 Jesu da wọn lohùn wipe, Emi ti wi fun nyin, ẹnyin kò si gbagbọ́; iṣẹ ti emi nṣe li orukọ Baba mi, awọn ni njẹri mi. 26 Ṣugbọn ẹnyin kò gbagbọ́, nitori ẹnyin kò si ninu awọn agutan mi, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin. 27 Awọn agutan mi ngbọ ohùn mi, emi si mọ̀ wọn, nwọn a si ma tọ̀ mi lẹhin: 28 Emi si fun wọn ni ìye ainipẹkun; nwọn kì o si ṣegbé lailai, kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ mi. 29 Baba mi, ẹniti o fi wọn fun mi, pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ Baba mi. 30 Ọ̀kan li emi ati Baba mi jasi. 31 Awọn Ju si tún he okuta, lati sọ lù u. 32 Jesu da wọn lohùn pe, Ọpọlọpọ iṣẹ rere ni mo fi hàn nyin lati ọdọ Baba mi wá; nitori ewo ninu iṣẹ wọnni li ẹnyin ṣe sọ mi li okuta? 33 Awọn Ju si da a lohùn, wipe, Awa kò sọ ọ li okuta nitori iṣẹ rere, ṣugbọn nitori ọrọ-odi: ati nitori iwọ ti iṣe enia nfi ara rẹ ṣe Ọlọrun. 34 Jesu da wọn lohùn pe, A kò ha ti kọ ọ ninu ofin nyin pe, Mo ti wipe, ọlọrun li ẹnyin iṣe? 35 Bi o ba pè wọn li ọlọrun, awọn ẹniti a fi ọ̀rọ Ọlọrun fun, a kò si le ba iwe-mimọ́ jẹ, 36 Ẹnyin ha nwi niti ẹniti Baba yà si mimọ́, ti o si rán si aiye pe, Iwọ nsọrọ-odi, nitoriti mo wipe Ọmọ Ọlọrun ni mi? 37 Bi emi kò ba ṣe iṣẹ Baba mi, ẹ máṣe gbà mi gbọ́. 38 Ṣugbọn bi emi ba ṣe wọn, bi ẹnyin kò tilẹ gbà mi gbọ́, ẹ gbà iṣẹ na gbọ́: ki ẹnyin ki o le mọ̀, ki o si le ye nyin pe, Baba wà ninu mi, emi si wà ninu rẹ̀. 39 Nwọn si tun nwá ọ̀na lati mu u: o si bọ́ lọwọ wọn. 40 O si tún kọja lọ si apakeji Jordani si ibiti Johanu ti kọ́ mbaptisi; nibẹ̀ li o si joko. 41 Awọn enia pipọ si wá sọdọ rẹ̀, nwọn si wipe, Johanu ko ṣe iṣẹ àmi kan: ṣugbọn otitọ li ohun gbogbo ti Johanu sọ nipa ti ọkunrin yi. 42 Awọn enia pipọ nibẹ̀ si gbà a gbọ́.

John 10

Parable of the Good Shepherd

1 "Truly, truly, I say to you, he who does not enter by the door into the fold of the sheep, but climbs up some other way, he is a thief and a robber.2 But he who enters by the door is a shepherd of the sheep.3 To him the doorkeeper opens, and the sheep hear his voice, and he calls his own sheep by name and leads them out.4 When he puts forth all his own, he goes ahead of them, and the sheep follow him because they know his voice.5 A stranger they simply will not follow, but will flee from him, because they do not know the voice of strangers."6 This figure of speech Jesus spoke to them, but they did not understand what those things were which He had been saying to them.

7 So Jesus said to them again, "Truly, truly, I say to you, I am the door of the sheep.8 All who came before Me are thieves and robbers, but the sheep did not hear them.9 I am the door; if anyone enters through Me, he will be saved, and will go in and out and find pasture.10 The thief comes only to steal and kill and destroy; I came that they may have life, and have it abundantly.

11 "I am the good shepherd; the good shepherd lays down His life for the sheep.12 He who is a hired hand, and not a shepherd, who is not the owner of the sheep, sees the wolf coming, and leaves the sheep and flees, and the wolf snatches them and scatters them.13 He flees because he is a hired hand and is not concerned about the sheep.14 I am the good shepherd, and I know My own and My own know Me,15 even as the Father knows Me and I know the Father; and I lay down My life for the sheep.16 I have other sheep, which are not of this fold; I must bring them also, and they will hear My voice; and they will become one flock with one shepherd.17 For this reason the Father loves Me, because I lay down My life so that I may take it again.18 No one has taken it away from Me, but I lay it down on My own initiative. I have authority to lay it down, and I have authority to take it up again. This commandment I received from My Father."

19 A division occurred again among the Jews because of these words.20 Many of them were saying, "He has a demon and is insane. Why do you listen to Him?"21 Others were saying, "These are not the sayings of one demon-possessed. A demon cannot open the eyes of the blind, can he?"

Jesus Asserts His Deity

22 At that time the Feast of the Dedication took place at Jerusalem;23 it was winter, and Jesus was walking in the temple in the portico of Solomon.24 The Jews then gathered around Him, and were saying to Him, "How long will You keep us in suspense? If You are the Christ, tell us plainly."25 Jesus answered them, "I told you, and you do not believe; the works that I do in My Father's name, these testify of Me.26 But you do not believe because you are not of My sheep.27 My sheep hear My voice, and I know them, and they follow Me;28 and I give eternal life to them, and they will never perish; and no one will snatch them out of My hand.29 tMy Father, who has given them to Me, is greater than all; and no one is able to snatch them out of the Father's hand.30 I and the Father are one."

31 The Jews picked up stones again to stone Him.32 Jesus answered them, "I showed you many good works from the Father; for which of them are you stoning Me?"33 The Jews answered Him, "For a good work we do not stone You, but for blasphemy; and because You, being a man, make Yourself out to be God."34 Jesus answered them, "Has it not been written in your Law, 'I SAID, YOU ARE GODS'?35 If he called them gods, to whom the word of God came (and the Scripture cannot be broken),36 do you say of Him, whom the Father sanctified and sent into the world, 'You are blaspheming,' because I said, 'I am the Son of God'?37 If I do not do the works of My Father, do not believe Me;38 but if I do them, though you do not believe Me, believe the works, so that you may know and understand that the Father is in Me, and I in the Father."39 Therefore they were seeking again to seize Him, and He eluded their grasp.

40 And He went away again beyond the Jordan to the place where John was first baptizing, and He was staying there.41 Many came to Him and were saying, "While John performed no sign, yet everything John said about this man was true."42 Many believed in Him there.