previous next

Joh 11

Ikú Lasaru

1 ARA ọkunrin kan si ṣe alaidá, Lasaru, ara Betani, ti iṣe ilu Maria ati Marta arabinrin rẹ̀. 2 (Maria na li ẹniti o fi ororo ikunra kùn Oluwa, ti o si fi irun ori rẹ̀ nù ẹsẹ rẹ̀ nù, arakunrin rẹ̀ ni Lasaru iṣe, ara ẹniti kò dá.) 3 Nitorina awọn arabinrin rẹ̀ ranṣẹ si i, wipe, Oluwa, wo o, ara ẹniti iwọ fẹran kò da. 4 Nigbati Jesu si gbọ́, o wipe, Aisan yi kì iṣe si ikú, ṣugbọn fun ogo Ọlọrun, ki a le yìn Ọmọ Ọlọrun logo nipasẹ rẹ̀. 5 Jesu si fẹran Marta, ati arabinrin rẹ̀, ati Lasaru. 6 Nitorina nigbati o ti gbọ́ pe, ara rẹ̀ kò da, o gbé ijọ meji si i nibikanna ti o gbé wà. 7 Njẹ lẹhin eyi li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki a tún pada lọ si Judea. 8 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Rabbi, ni lọ̃lọ̃ yi li awọn Ju nwá ọ̀na ati sọ ọ li okuta; iwọ si ntún pada lọ sibẹ̀? 9 Jesu dahún pe, Wakati mejila ki mbẹ ninu ọsán kan? Bi ẹnikan ba rìn li ọsán, kì yio kọsẹ̀, nitoriti o ri imọlẹ aiye yi. 10 Ṣugbọn bi ẹnikan ba rìn li oru, yio kọsẹ̀, nitoriti kò si imọlẹ ninu rẹ̀. 11 Nkan wọnyi li o sọ: lẹhin eyini o si wi fun wọn pe, Lasaru ọrẹ́ wa sùn; ṣugbọn emi nlọ ki emi ki o le jí i dide ninu orun rẹ̀. 12 Nitorina awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Oluwa, bi o ba ṣe pe o sùn, yio sàn. 13 Ṣugbọn Jesu nsọ ti ikú rẹ̀: ṣugbọn nwọn rò pe, o nsọ ti orun sisun. 14 Nigbana ni Jesu wi fun wọn gbangba pe, Lasaru kú. 15 Emi si yọ̀ nitori nyin, ti emi kò si nibẹ̀, Ki ẹ le gbagbọ́; ṣugbọn ẹ jẹ ki a lọ sọdọ rẹ̀.

16 Nitorina Tomasi, ẹniti a npè ni Didimu, wi fun awọn ọmọ-ẹhin ẹgbẹ rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki awa na lọ, ki a le ba a kú pẹlu.

Jesu Ni Ajinde ati Ìyè


17 Nitorina nigbati Jesu de, o ri pe a ti tẹ́ ẹ sinu ibojì ni ijọ mẹrin na. 18 Njẹ Betani sunmọ Jerusalemu to furlongi mẹdogun: 19 Ọ̀pọ ninu awọn Ju si wá sọdọ Marta ati Maria, lati tù wọn ninu nitori ti arakunrin wọn. 20 Nitorina nigbati Marta gbọ́ pe Jesu mbọ̀ wá, o jade lọ ipade rẹ̀: ṣugbọn Maria joko ninu ile. 21 Nigbana ni Marta wi fun Jesu pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kì ba tí kú. 22 Ṣugbọn nisisiyi na, mo mọ̀ pe, ohunkohun ti iwọ ba bère lọwọ Ọlọrun, Ọlọrun yio fifun ọ. 23 Jesu wi fun u pe, Arakunrin rẹ yio jinde. 24 Marta wi fun u pe, mo mọ̀ pe yio jinde li ajinde nigbẹhin ọjọ. 25 Jesu wi fun u pe, Emi ni ajinde, ati ìye: ẹniti o ba gbà mi gbọ́, bi o tilẹ kú, yio yè: 26 Ẹnikẹni ti o mbẹ lãye, ti o si gbà mi gbọ́, kì yio kú lailai. Iwọ gbà eyi gbọ́?

27 O wi fun u pe, Bẹ̃ni, Oluwa: emi gbagbọ́ pe, iwọ ni Kristi na Ọmọ Ọlọrun, ẹniti mbọ̀ wá aiye.

Jesu Abánidárò


28 Nigbati o si ti wi eyi tan, o lọ, o si pè Maria arabinrin rẹ̀ sẹhin wipe, Olukọni de, o si npè ọ. 29 Nigbati o gbọ́, o dide lọgan, o si wá sọdọ rẹ̀. 30 Jesu kò sá ti iwọ̀ ilu, ṣugbọn o wà nibikanna ti Marta pade rẹ̀. 31 Nitorina awọn Ju ti o wà lọdọ rẹ̀ ninu ile, ti nwọn ntù u ninu, nigbati nwọn ri ti Maria dide kánkan, ti o si jade, nwọn tẹ̀le e, nwọn ṣebi o nlọ si ibojì lọ isọkun nibẹ̀. 32 Nigbati Maria si de ibiti Jesu gbé wà, ti o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o wi fun u pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kò ba má kú. 33 Njẹ nigbati Jesu ri i, ti o nsọkun, ati awọn Ju ti o ba a wá nsọkun pẹlu rẹ̀, o kerora li ọkàn rẹ̀, inu rẹ̀ si bajẹ, 34 O si wipe, Nibo li ẹnyin gbé tẹ́ ẹ si? Nwọn si wi fun u pe, Oluwa, wá wò o. 35 Jesu sọkun. 36 Nitorina awọn Ju wipe, sa wo o bi o ti fẹràn rẹ̀ to!

37 Awọn kan ninu wọn si wipe, Ọkunrin yi, ẹniti o là oju afọju, kò le ṣe ki ọkunrin yi má ku bi?

Lasaru Tún Di Alààyè


38 Nigbana ni Jesu tún kerora ninu ara rẹ̀, o wá si ibojì. O si jẹ ihò, a si gbé okuta le ẹnu rẹ̀. 39 Jesu wipe, Ẹ gbé okuta na kuro. Marta, arabinrin ẹniti o kú na wi fun u pe, Oluwa, o ti nrùn nisisiyi: nitoripe o di ijọ mẹrin ti o ti kú. 40 Jesu wi fun u pe, Emi kò ti wi fun ọ pe, bi iwọ ba gbagbọ́, iwọ o ri ogo Ọlọrun? 41 Nigbana ni nwọn gbé okuta na kuro nibiti a gbe tẹ́ okú na si. Jesu si gbé oju rẹ̀ soke, o si wipe, Baba, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti iwọ gbọ́ ti emi. 42 Emi si ti mọ̀ pe, iwọ a ma gbọ́ ti emi nigbagbogbo: ṣugbọn nitori ijọ enia ti o duro yi ni mo ṣe wi i, ki nwọn ki o le gbagbọ́ pe iwọ li o rán mi. 43 Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o kigbe li ohùn rara pe, Lasaru, jade wá.

44 Ẹniti o kú na si jade wá, ti a fi aṣọ okú dì tọwọ tẹsẹ a si fi gèle dì i loju. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tú u, ẹ si jẹ ki o mã lọ.

Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Jesu

(Mat 26:1-5; Mak 14:1-2; Luk 22:1-2)


45 Nitorina li ọ̀pọ awọn Ju ti o wá sọdọ Maria, ti nwọn ri ohun ti Jesu ṣe, nwọn gbà a gbọ. 46 Ṣugbọn awọn ẹlomiran ninu wọn tọ̀ awọn Farisi lọ, nwọn si sọ fun wọn ohun ti Jesu ṣe. 47 Nigbana li awọn olori alufa ati awọn Farisi pè igbimọ jọ, nwọn si wipe, Kili awa nṣe? nitori ọkunrin yi nṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ àmi. 48 Bi awa ba jọwọ rẹ̀ bẹ̃, gbogbo enia ni yio gbà a gbọ́: awọn ará Romu yio si wá gbà ilẹ ati orilẹ-ède wa pẹlu. 49 Ṣugbọn Kaiafa, ọkan ninu wọn, ẹniti iṣe olori alufa li ọdún na, o wi fun wọn pe, Ẹnyin kò mọ̀ ohunkohun rara. 50 Bẹ̃ni ẹ kò si ronu pe, o ṣànfani fun wa, ki enia kan kú fun awọn enia, ki gbogbo orilẹ-ède ki o má bà ṣegbé. 51 Ki iṣe fun ara rẹ̀ li o sọ eyi: ṣugbọn bi o ti jẹ olori alufa li ọdún na, o sọtẹlẹ pe, Jesu yio kú fun orilẹ-ède na: 52 Ki si iṣe kìki fun orilẹ-ède na nikan, ṣugbọn pẹlu ki o le kó awọn ọmọ Ọlọrun ti a ti funka kiri jọ li ọkanṣoṣo. 53 Nitorina lati ọjọ na lọ ni nwọn ti jọ gbìmọ pọ̀ lati pa a. 54 Nitorina Jesu kò rìn ni gbangba larin awọn Ju mọ́; ṣugbọn o ti ibẹ̀ lọ si igberiko kan ti o sunmọ aginjù, si ilu nla ti à npè ni Efraimu, nibẹ̀ li o si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 55 Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile: ọ̀pọlọpọ lati igberiko wá si gòke lọ si Jerusalemu ṣiwaju irekọja, lati yà ara wọn si mimọ́. 56 Nigbana ni nwọn nwá Jesu, nwọn si mba ara wọ́n sọ, bi nwọn ti duro ni tẹmpili, wipe, Ẹnyin ti rò o si? pe kì yio wá si ajọ? 57 Njẹ awọn olori alufa ati awọn Farisi ti paṣẹ pe bi ẹnikan ba mọ̀ ibi ti o gbé wà, ki o fi i hàn, ki nwọn ki o le mu u.

John 11

The Death and Resurrection of Lazarus

1 Now a certain man was sick, Lazarus of Bethany, the village of Mary and her sister Martha.2 It was the Mary who anointed the Lord with ointment, and wiped His feet with her hair, whose brother Lazarus was sick.3 So the sisters sent word to Him, saying, "Lord, behold, he whom You love is sick."4 But when Jesus heard this, He said, "This sickness is not to end in death, but for the glory of God, so that the Son of God may be glorified by it."5 Now Jesus loved Martha and her sister and Lazarus.6 So when He heard that he was sick, He then stayed two days longer in the place where He was.7 Then after this He *said to the disciples, "Let us go to Judea again."8 The disciples *said to Him, "Rabbi, the Jews were just now seeking to stone You, and are You going there again?"9 Jesus answered, "Are there not twelve hours in the day? If anyone walks in the day, he does not stumble, because he sees the light of this world.10 But if anyone walks in the night, he stumbles, because the light is not in him."11 This He said, and after that He *said to them, "Our friend Lazarus has fallen asleep; but I go, so that I may awaken him out of sleep."12 The disciples then said to Him, "Lord, if he has fallen asleep, he will recover."13 Now Jesus had spoken of his death, but they thought that He was speaking of literal sleep.14 So Jesus then said to them plainly, "Lazarus is dead,15 and I am glad for your sakes that I was not there, so that you may believe; but let us go to him."16 Therefore Thomas, who is called Didymus, said to his fellow disciples, "Let us also go, so that we may die with Him."

17 So when Jesus came, He found that he had already been in the tomb four days.18 Now Bethany was near Jerusalem, about two miles off;19 and many of the Jews had come to Martha and Mary, to console them concerning their brother.20 Martha therefore, when she heard that Jesus was coming, went to meet Him, but Mary stayed at the house.21 Martha then said to Jesus, "Lord, if You had been here, my brother would not have died.22 Even now I know that whatever You ask of God, God will give You."23 Jesus *said to her, "Your brother will rise again."24 Martha *said to Him, "I know that he will rise again in the resurrection on the last day."25 Jesus said to her, "I am the resurrection and the life; he who believes in Me will live even if he dies,26 and everyone who lives and believes in Me will never die. Do you believe this?"27 She *said to Him, "Yes, Lord; I have believed that You are the Christ, the Son of God, even He who comes into the world."

28 When she had said this, she went away and called Mary her sister, saying secretly, "The Teacher is here and is calling for you."29 And when she heard it, she *got up quickly and was coming to Him.

30 Now Jesus had not yet come into the village, but was still in the place where Martha met Him.31 Then the Jews who were with her in the house, and consoling her, when they saw that Mary got up quickly and went out, they followed her, supposing that she was going to the tomb to weep there.32 Therefore, when Mary came where Jesus was, she saw Him, and fell at His feet, saying to Him, "Lord, if You had been here, my brother would not have died."33 When Jesus therefore saw her weeping, and the Jews who came with her also weeping, He was deeply moved in spirit and was troubled,34 and said, "Where have you laid him?" They *said to Him, "Lord, come and see."35 Jesus wept.36 So the Jews were saying, "See how He loved him!"37 But some of them said, "Could not this man, who opened the eyes of the blind man, have kept this man also from dying?"

38 So Jesus, again being deeply moved within, *came to the tomb. Now it was a cave, and a stone was lying against it.39 Jesus *said, "Remove the stone." Martha, the sister of the deceased, *said to Him, "Lord, by this time there will be a stench, for he has been dead four days."40 Jesus *said to her, "Did I not say to you that if you believe, you will see the glory of God?"41 So they removed the stone. Then Jesus raised His eyes, and said, "Father, I thank You that You have heard Me.42 I knew that You always hear Me; but because of the people standing around I said it, so that they may believe that You sent Me."43 When He had said these things, He cried out with a loud voice, "Lazarus, come forth."44 The man who had died came forth, bound hand and foot with wrappings, and his face was wrapped around with a cloth. Jesus *said to them, "Unbind him, and let him go."

45 Therefore many of the Jews who came to Mary, and saw what He had done, believed in Him.46 But some of them went to the Pharisees and told them the things which Jesus had done.

Conspiracy to Kill Jesus

47 Therefore the chief priests and the Pharisees convened a council, and were saying, "What are we doing? For this man is performing many signs.48 If we let Him go on like this, all men will believe in Him, and the Romans will come and take away both our place and our nation."49 But one of them, Caiaphas, who was high priest that year, said to them, "You know nothing at all,50 nor do you take into account that it is expedient for you that one man die for the people, and that the whole nation not perish."51 Now he did not say this on his own initiative, but being high priest that year, he prophesied that Jesus was going to die for the nation,52 and not for the nation only, but in order that He might also gather together into one the children of God who are scattered abroad.53 So from that day on they planned together to kill Him.

54 Therefore Jesus no longer continued to walk publicly among the Jews, but went away from there to the country near the wilderness, into a city called Ephraim; and there He stayed with the disciples.

55 Now the Passover of the Jews was near, and many went up to Jerusalem out of the country before the Passover to purify themselves.56 So they were seeking for Jesus, and were saying to one another as they stood in the temple, "What do you think; that He will not come to the feast at all?"57 Now the chief priests and the Pharisees had given orders that if anyone knew where He was, he was to report it, so that they might seize Him.