Joh 13
Jesu Wẹ Ẹsẹ̀ Àwọn Ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀
1 NJE ki ajọ irekọja ki o to de, nigbati Jesu mọ̀ pe wakati rẹ̀ de tan, ti on ó ti aiye yi kuro lọ sọdọ Baba, fifẹ ti o fẹ awọn tirẹ̀ ti o wà li aiye, o fẹ wọn titi de opin. 2 Bi nwọn si ti njẹ onjẹ alẹ, ti Èṣu ti fi i si ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni lati fi i hàn; 3 Ti Jesu si ti mọ̀ pe Baba ti fi ohun gbogbo le on lọwọ, ati pe lọdọ Ọlọrun li on ti wá, on si nlọ sọdọ Ọlọrun; 4 O dide ni idi onjẹ alẹ, o si fi agbáda rẹ̀ lelẹ̀ li apakan; nigbati o si mu gèle, o di ara rẹ̀ li àmure. 5 Lẹhinna o bù omi sinu awokòto kan, o si bẹ̀rẹ si ima wẹ̀ ẹsẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si nfi gèle ti o fi di àmure nù wọn. 6 Nigbana li o de ọdọ Simoni Peteru. On si wi fun u pe, Oluwa, iwọ nwẹ̀ mi li ẹsẹ? 7 Jesu dahùn o si wi fun u pe, Ohun ti emi nṣe iwọ kò mọ̀ nisisiyi; ṣugbọn yio ye ọ nikẹhin. 8 Peteru wi fun u pe, Iwọ kì yio wẹ̀ mi li ẹsẹ lai. Jesu da a lohùn pe, Bi emi kò bá wẹ̀ ọ, iwọ kò ni ìpin lọdọ mi. 9 Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, kì iṣe ẹsẹ mi nikan, ṣugbọn ati ọwọ́ ati ori mi pẹlu. 10 Jesu wi fun u pe, Ẹniti a ti wẹ̀ kò tun fẹ ju ki a ṣan ẹsẹ rẹ̀, ṣugbọn o mọ́ nibi gbogbo: ẹnyin si mọ́, ṣugbọn kì iṣe gbogbo nyin. 11 Nitoriti o mọ̀ ẹniti yio fi on hàn; nitorina li o ṣe wipe, Kì iṣe gbogbo nyin li o mọ́. 12 Nitorina lẹhin ti o wẹ̀ ẹsẹ wọn tan, ti o si ti mu agbáda rẹ̀, ti o tún joko, o wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ohun ti mo ṣe si nyin? 13 Ẹnyin npè mi li Olukọni ati Oluwa: ẹnyin wi rere; bẹ̃ni mo jẹ. 14 Njẹ bi emi ti iṣe Oluwa ati Olukọni nyin ba wẹ̀ ẹsẹ nyin, o tọ́ ki ẹnyin pẹlu si mã wẹ̀ ẹsẹ ara nyin. 15 Nitori mo ti fi apẹ̃rẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã ṣe gẹgẹ bi mo ti ṣe si nyin. 16 Lòtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ; bẹ̃ni ẹniti a rán kò tobi jù ẹniti o rán a lọ. 17 Bi ẹnyin ba mọ̀ nkan wọnyi, alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn. 18 Kì iṣe ti gbogbo nyin ni mo nsọ: emi mọ̀ awọn ti mo yàn: ṣugbọn ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, Ẹniti mba mi jẹun pọ̀ si gbé gigĩsẹ rẹ̀ si mi. 19 Lati isisiyi lọ mo sọ fun nyin ki o to de, pe nigbati o ba de, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe emi ni.
20 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà ẹnikẹni ti mo rán, o gbà mi; ẹniti o ba si gbà mi o gbà ẹniti o rán mi.Jesu Sọ Ẹni Tí Yóo fi Òun Hàn fún Àwọn Ọ̀tá
(Mat 26:20-25; Mak 14:17-21; Luk 22:21-23)
21 Nigbati Jesu ti wi nkan wọnyi tan, ọkàn rẹ̀ daru ninu rẹ̀, o si jẹri, o si wipe, Lõtọ lõtọ ni mo wi fun nyin pe, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn. 22 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nwò ara wọn loju, nwọn nṣiye-meji ti ẹniti o wi. 23 Njẹ ẹnikan rọ̀gún si àiya Jesu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹniti Jesu fẹràn. 24 Nitorina ni Simoni Peteru ṣapẹrẹ si i, o si wi fun u pe, Wi fun wa ti ẹniti o nsọ. 25 Ẹniti o nrọ̀gún li àiya Jesu wi fun u pe, Oluwa, tani iṣe? 26 Nitorina Jesu dahùn pe, On na ni, ẹniti mo ba fi òkele fun nigbati mo ba fi run. Nigbati o si fi i run tan, o fifun Judasi Iskariotu ọmọ Simoni. 27 Lẹhin òkele na ni Satani wọ̀ inu rẹ̀ lọ. Nitorina Jesu wi fun u pe, Ohun ti iwọ nṣe nì, yara ṣe e kánkan. 28 Kò si si ẹnikan nibi tabili ti o mọ̀ idi ohun ti o ṣe sọ eyi fun u. 29 Nitori awọn miran ninu wọn rò pe, nitori Judasi li o ni àpo, ni Jesu fi wi fun u pe, Rà nkan wọnni ti a kò le ṣe alaini fun ajọ na; tabi ki o le fi nkan fun awọn talakà. 30 Nigbati o si ti gbà òkele na tan, o jade lojukanna: oru si ni. 31 Nitorina nigbati o jade lọ tan, Jesu wipe, Nisisiyi li a yìn Ọmọ-enia logo, a si yìn Ọlọrun logo ninu rẹ̀. 32 Bi a ba yìn Ọlọrun logo ninu rẹ̀, Ọlọrun yio si yìn i logo ninu on tikararẹ̀, yio si yìn i logo nisisiyi. 33 Ẹnyin ọmọde, nigba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin. Ẹnyin ó wá mi: ati gẹgẹ bi mo ti wi fun awọn Ju pe, Nibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì o le wá; bẹ̃ni mo si wi fun nyin nisisiyi. 34 Ofin titun kan ni mo fifun nyin, Ki ẹnyin ki o fẹ ọmọnikeji nyin; gẹgẹ bi emi ti fẹran nyin, ki ẹnyin ki o si le fẹran ọmọnikeji nyin.
35 Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin.Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóo Sẹ́ Òun
(Mat 26:31-35; Mak 14:27-31; Luk 22:31-34)
36 Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, nibo ni iwọ nlọ? Jesu da a lohùn pe, Nibiti emi nlọ, iwọ ki ó le tọ̀ mi nisisiyi; ṣugbọn iwọ yio tọ̀ mi nikẹhin. 37 Peteru wi fun u pe, Oluwa, ẽṣe ti emi ko fi le tọ̀ ọ nisisiyi? emi o fi ẹmí mi lelẹ nitori rẹ. 38 Jesu da a lohùn wipe, Iwọ o ha fi ẹmí rẹ lelẹ nitori mi? Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Akukọ kì yio kọ, ki iwọ ki o to sẹ́ mi nigba mẹta.
John 13
The Lord's Supper
1 Now before the Feast of the Passover, Jesus knowing that His hour had come that He would depart out of this world to the Father, having loved His own who were in the world, He loved them to the end.2 During supper, the devil having already put into the heart of Judas Iscariot, the son of Simon, to betray Him,3 Jesus, knowing that the Father had given all things into His hands, and that He had come forth from God and was going back to God,4 *got up from supper, and *laid aside His garments; and taking a towel, He girded Himself.
Jesus Washes the Disciples' Feet
5 Then He *poured water into the basin, and began to wash the disciples' feet and to wipe them with the towel with which He was girded.6 So He *came to Simon Peter. He *said to Him, "Lord, do You wash my feet?"7 Jesus answered and said to him, "What I do you do not realize now, but you will understand hereafter."8 Peter *said to Him, "Never shall You wash my feet!" Jesus answered him, "If I do not wash you, you have no part with Me."9 Simon Peter *said to Him, "Lord, then wash not only my feet, but also my hands and my head."10 Jesus *said to him, "He who has bathed needs only to wash his feet, but is completely clean; and you are clean, but not all of you."11 For He knew the one who was betraying Him; for this reason He said, "Not all of you are clean."
12 So when He had washed their feet, and taken His garments and reclined at the table again, He said to them, "Do you know what I have done to you?13 You call Me Teacher and Lord; and you are right, for so I am.14 If I then, the Lord and the Teacher, washed your feet, you also ought to wash one another's feet.15 For I gave you an example that you also should do as I did to you.16 Truly, truly, I say to you, a slave is not greater than his master, nor is one who is sent greater than the one who sent him.17 If you know these things, you are blessed if you do them.18 I do not speak of all of you. I know the ones I have chosen; but it is that the Scripture may be fulfilled, 'HE WHO EATS MY BREAD HAS LIFTED UP HIS HEEL AGAINST ME.'19 From now on I am telling you before it comes to pass, so that when it does occur, you may believe that I am He.20 Truly, truly, I say to you, he who receives whomever I send receives Me; and he who receives Me receives Him who sent Me."
Jesus Predicts His Betrayal
21 When Jesus had said this, He became troubled in spirit, and testified and said, "Truly, truly, I say to you, that one of you will betray Me."22 The disciples began looking at one another, at a loss to know of which one He was speaking.23 There was reclining on Jesus' bosom one of His disciples, whom Jesus loved.24 So Simon Peter *gestured to him, and *said to him, "Tell us who it is of whom He is speaking."25 He, leaning back thus on Jesus' bosom, *said to Him, "Lord, who is it?"26 Jesus then *answered, "That is the one for whom I shall dip the morsel and give it to him." So when He had dipped the morsel, He *took and *gave it to Judas, the son of Simon Iscariot.27 After the morsel, Satan then entered into him. Therefore Jesus *said to him, "What you do, do quickly."28 Now no one of those reclining at the table knew for what purpose He had said this to him.29 For some were supposing, because Judas had the money box, that Jesus was saying to him, "Buy the things we have need of for the feast"; or else, that he should give something to the poor.30 So after receiving the morsel he went out immediately; and it was night.
31 Therefore when he had gone out, Jesus *said, "Now is the Son of Man glorified, and God is glorified in Him;32 if God is glorified in Him, God will also glorify Him in Himself, and will glorify Him immediately.33 Little children, I am with you a little while longer. You will seek Me; and as I said to the Jews, now I also say to you, 'Where I am going, you cannot come.'34 A new commandment I give to you, that you love one another, even as I have loved you, that you also love one another.35 By this all men will know that you are My disciples, if you have love for one another."
36 Simon Peter *said to Him, "Lord, where are You going?" Jesus answered, "Where I go, you cannot follow Me now; but you will follow later."37 Peter *said to Him, "Lord, why can I not follow You right now? I will lay down my life for You."38 Jesus *answered, "Will you lay down your life for Me? Truly, truly, I say to you, a rooster will not crow until you deny Me three times.