previous next

Joh 15

Jesu Ni Igi Àjàrà

1 EMI ni àjara tõtọ, Baba mi si ni oluṣọgba. 2 Gbogbo ẹká ninu mi ti kò ba so eso, on a mu u kuro: gbogbo ẹka ti o ba si so eso, on a wẹ̀ ẹ mọ́, ki o le so eso si i. 3 Ẹnyin mọ́ nisisiyi nitori ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin. 4 Ẹ mã gbé inu mi, emi o si mã gbé inu nyin. Gẹgẹ bi ẹka kò ti le so eso fun ara rẹ̀, bikoṣepe o ba ngbé inu àjara, bẹ̃li ẹnyin, bikoṣepe ẹ ba ngbé inu mi. 5 Emi ni àjara, ẹnyin li ẹka. Ẹniti o ngbé inu mi, ati emi ninu rẹ̀, on ni yio so eso ọ̀pọlọpọ: nitori ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan. 6 Bi ẹnikan kò ba gbé inu mi, a gbe e sọnu gẹgẹ bi ẹka, a si gbẹ; nwọn a si kó wọn jọ, nwọn a si sọ wọn sinu iná, nwọn a si jóna. 7 Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọ̀rọ mi ba si ngbé inu nyin, ẹ ó bère ohunkohun ti ẹ ba fẹ, a o si ṣe e fun nyin. 8 Ninu eyi li a yìn Baba mi logo pe, ki ẹnyin ki o mã so eso pupọ; ẹnyin o si jẹ ọmọ-ẹhin mi. 9 Gẹgẹ bi Baba ti fẹ mi, bẹ̃li emi si fẹ nyin: ẹ duro ninu ifẹ mi. 10 Bi ẹnyin ba pa ofin mi mọ́, ẹ o duro ninu ifẹ mi; gẹgẹ bi emi ti pa ofin Baba mi mọ́, ti mo si duro ninu ifẹ rẹ̀. 11 Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki ayọ̀ mi ki o le wà ninu nyin, ati ki ayọ̀ nyin ki o le kún. 12 Eyi li ofin mi, pe ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin, gẹgẹ bi mo ti fẹràn nyin. 13 Ko si ẹnikan ti o ni ifẹ ti o tobi jù eyi lọ, pe ẹnikan fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn ọrẹ́ rẹ̀. 14 Ọrẹ́ mi li ẹnyin iṣẹ, bi ẹ ba ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun nyin. 15 Emi kò pè nyin li ọmọ-ọdọ mọ́; nitori ọmọ-ọdọ kò mọ̀ ohun ti oluwa rẹ̀ nṣe: ṣugbọn emi pè nyin li ọrẹ́; nitori ohun gbogbo ti mo ti gbọ́ lati ọdọ Baba mi wá, mo ti fi hàn fun nyin. 16 Ki iṣe ẹnyin li o yàn mi, ṣugbọn emi li o yàn nyin, mo si fi nyin sipo, ki ẹnyin ki o le lọ, ki ẹ si so eso, ati ki eso nyin le duro; ki ohunkohun ti ẹ ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, ki o le fi i fun nyin.

17 Nkan wọnyi ni mo palaṣẹ fun nyin pe, ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin.

Ọmọ-Aráyé Yóo Kórìíra Yín


18 Bi aiye ba korira nyin, ẹ mọ̀ pe, o ti korira mi ṣaju nyin. 19 Ibaṣepe ẹnyin iṣe ti aiye, aiye iba fẹ awọn tirẹ̀; ṣugbọn nitoriti ẹnyin kì iṣe ti aiye, ṣugbọn emi ti yàn nyin kuro ninu aiye, nitori eyi li aiye ṣe korira nyin. 20 Ẹ ranti ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin pe, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ. Bi nwọn ba ti ṣe inunibini si mi, nwọn ó ṣe inunibini si nyin pẹlu: bi nwọn ba ti pa ọ̀rọ mi mọ́, nwọn ó si pa ti nyin mọ́ pẹlu. 21 Ṣugbọn gbogbo nkan wọnyi ni nwọn o ṣe si nyin, nitori orukọ mi, nitoriti nwọn kò mọ̀ ẹniti o rán mi. 22 Ibaṣepe emi kò ti wá ki n si ti ba wọn sọrọ, nwọn kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn di alairiwi fun ẹ̀ṣẹ wọn. 23 Ẹniti o ba korira mi, o korira Baba mi pẹlu. 24 Ibaṣepe emi kò ti ṣe iṣẹ wọnni larin wọn, ti ẹlomiran kò ṣe ri, nwọn kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn ti ri, nwọn si korira ati emi ati Baba mi. 25 Ṣugbọn eyi ṣe ki ọ̀rọ ti a kọ ninu ofin wọn ki o le ṣẹ pe, Nwọn korira mi li ainidi. 26 Ṣugbọn nigbati Olutunu na ba de, ẹniti emi ó rán si nyin lati ọdọ Baba wá, ani Ẹmi otitọ nì, ti nti ọdọ Baba wá, on na ni yio jẹri mi: 27 Ẹnyin pẹlu yio si jẹri mi, nitoriti ẹnyin ti wà pẹlu mi lati ipilẹṣẹ wá.

John 15

Jesus Is the Vine-Followers Are Branches

1 "I am the true vine, and My Father is the vinedresser.2 Every branch in Me that does not bear fruit, He takes away; and every branch that bears fruit, He tprunes it so that it may bear more fruit.3 You are already clean because of the word which I have spoken to you.4 Abide in Me, and I in you. As the branch cannot bear fruit of itself unless it abides in the vine, so neither can you unless you abide in Me.5 I am the vine, you are the branches; he who abides in Me and I in him, he bears much fruit, for apart from Me you can do nothing.6 If anyone does not abide in Me, he is thrown away as a branch and dries up; and they gather them, and cast them into the fire and they are burned.7 If you abide in Me, and My words abide in you, ask whatever you wish, and it will be done for you.8 My Father is glorified by this, that you bear much fruit, and so prove to be My disciples.9 Just as the Father has loved Me, I have also loved you; abide in My love.10 If you keep My commandments, you will abide in My love; just as I have kept My Father's commandments and abide in His love.11 These things I have spoken to you so that My joy may be in you, and that your joy may be made full.

Disciples' Relation to Each Other

12 "This is My commandment, that you love one another, just as I have loved you.13 Greater love has no one than this, that one lay down his life for his friends.14 You are My friends if you do what I command you.15 No longer do I call you slaves, for the slave does not know what his master is doing; but I have called you friends, for all things that I have heard from My Father I have made known to you.16 You did not choose Me but I chose you, and appointed you that you would go and bear fruit, and that your fruit would remain, so that whatever you ask of the Father in My name He may give to you.17 This I command you, that you love one another.

Disciples' Relation to the World

18 "If the world hates you, you know that it has hated Me before it hated you.19 If you were of the world, the world would love its own; but because you are not of the world, but I chose you out of the world, because of this the world hates you.20 Remember the word that I said to you, 'A slave is not greater than his master.' If they persecuted Me, they will also persecute you; if they kept My word, they will keep yours also.21 But all these things they will do to you for My name's sake, because they do not know the One who sent Me.22 If I had not come and spoken to them, they would not have sin, but now they have no excuse for their sin.23 He who hates Me hates My Father also.24 If I had not done among them the works which no one else did, they would not have sin; but now they have both seen and hated Me and My Father as well.25 But they have done this to fulfill the word that is written in their Law, 'THEY HATED ME WITHOUT A CAUSE.'

26 "When the Helper comes, whom I will send to you from the Father, that is the Spirit of truth who proceeds from the Father, He will testify about Me,27 and you will testify also, because you have been with Me from the beginning.