Joh 16
1 NKAN wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki a má ba mu nyin kọsẹ̀. 2 Nwọn o yọ nyin kuro ninu sinagogu: ani, akokò mbọ̀, ti ẹnikẹni ti o ba pa nyin, yio rò pe on nṣe ìsin fun Ọlọrun. 3 Nkan wọnyi ni nwọn o si ṣe, nitoriti nwọn kò mọ̀ Baba, nwọn kò si mọ̀ mi.
4 Ṣugbọn nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, pe nigbati wakati wọn ba de, ki ẹ le ranti wọn pe mo ti wi fun nyin. Ṣugbọn emi ko sọ nkan wọnyi fun nyin lati ipilẹṣẹ wá, nitoriti mo wà pẹlu nyin.Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́
5 Ṣugbọn nisisiyi emi nlọ sọdọ ẹniti o rán mi; kò si si ẹnikan ninu nyin ti o bi mi lẽre pe, Nibo ni iwọ nlọ? 6 Ṣugbọn nitori mo sọ nkan wọnyi fun nyin, ibinujẹ kún ọkàn nyin. 7 Ṣugbọn otitọ li emi nsọ fun nyin; Anfani ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu kì yio tọ̀ nyin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o rán a si nyin. 8 Nigbati on ba si de, yio fi òye yé araiye niti ẹ̀ṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ: 9 Niti ẹ̀ṣẹ, nitoriti nwọn kò gbà mi gbọ́; 10 Niti ododo, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba, ẹnyin kò si ri mi mọ́; 11 Niti idajọ, nitoriti a ti ṣe idajọ alade aiye yi. 12 Mo ni ohun pipọ lati sọ fun nyin pẹlu, ṣugbọn ẹ kò le gbà wọn nisisiyi. 13 Ṣugbọn nigbati on, ani Ẹmí otitọ ni ba de, yio tọ́ nyin si ọ̀na otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ̀ ti ara rẹ̀; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ́, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ̀ fun nyin. 14 On o ma yìn mi logo: nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin.
15 Ohun gbogbo ti Baba ni temi ni: nitori eyi ni mo ṣe wipe, on ó gbà ninu temi, yio si sọ ọ fun nyin.Ìbànújẹ́ Yóo Di Ayọ̀
16 Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹ ó si ri mi, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba. 17 Nitorina omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mba ara wọn sọ pe, Kili eyi ti o nwi fun wa yi, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi: ati, Nitoriti emi nlọ sọdọ Baba? 18 Nitorina nwọn wipe, Kili eyi ti o wi yi, Nigba diẹ? awa kò mọ̀ ohun ti o wi. 19 Jesu sá ti mọ̀ pe, nwọn nfẹ lati bi on lẽre, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mbi ara nyin lẽre niti eyi ti mo wipe, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi? 20 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin pe, Ẹnyin o ma sọkun ẹ o si ma pohùnrere ẹkún, ṣugbọn awọn araiye yio ma yọ̀: inu nyin yio si bajẹ, ṣugbọn ibinujẹ nyin li yio si di ayọ̀. 21 Nigbati obinrin bá nrọbi, a ni ibinujẹ, nitoriti wakati rẹ̀ de: ṣugbọn nigbati o ba ti bí ọmọ na tan, on kì si iranti irora na mọ́, fun ayọ̀ nitori a bí enia si aiye. 22 Nitorina ẹnyin ni ibinujẹ nisisiyi: ṣugbọn emi o tún ri nyin, ọkàn nyin yio si yọ̀, kò si si ẹniti yio gbà ayọ̀ nyin lọwọ nyin. 23 Ati ni ijọ na ẹnyin kì o bi mi lẽre ohunkohun. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, on o fifun nyin.
24 Titi di isisiyi ẹ kò ti ibère ohunkohun li orukọ mi: ẹ bère, ẹ o si ri gbà, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.Jesu Ti Ṣẹgun Ayé
25 Nkan wọnyi ni mo ti fi owe sọ fun nyin: ṣugbọn akokò de, nigbati emi kì yio fi owe ba nyin sọrọ mọ́, ṣugbọn emi o sọ ti Baba fun nyin gbangba. 26 Li ọjọ na ẹnyin o bère li orukọ mi: emi kò si wi fun nyin pe, emi o bère lọwọ Baba fun nyin: 27 Nitoriti Baba tikararẹ̀ fẹran nyin, nitoriti ẹnyin ti fẹràn mi, ẹ si ti gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun li emi ti jade wá. 28 Mo ti ọdọ Baba jade wá, mo si wá si aiye: ẹ̀wẹ, mo fi aiye silẹ, mo si nlọ sọdọ Baba. 29 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Wo o, nigbayi ni iwọ nsọ̀rọ̀ gbangba, iwọ kò si sọ ohunkohun li owe. 30 Nigbayi li awa mọ̀ pe, iwọ mọ̀ ohun gbogbo, iwọ kò ni ki a bi ọ lẽre: nipa eyi li awa gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun ni iwọ ti jade wá. 31 Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin gbagbọ́ wayi? 32 Kiyesi i, wakati mbọ̀, ani o de tan nisisiyi, ti a o fọ́n nyin ká kiri, olukuluku si ile rẹ̀; ẹ ó si fi emi nikan silẹ: ṣugbọn kì yio si ṣe emi nikan, nitoriti Baba mbẹ pẹlu mi. 33 Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin tẹlẹ̀, ki ẹnyin ki o le ni alafia ninu mi. Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye.
John 16
Jesus' Warning
1 "These things I have spoken to you so that you may be kept from stumbling.2 They will make you outcasts from the synagogue, but an hour is coming for everyone who kills you to think that he is offering service to God.3 These things they will do because they have not known the Father or Me.4 But these things I have spoken to you, so that when their hour comes, you may remember that I told you of them. These things I did not say to you at the beginning, because I was with you.
The Holy Spirit Promised
5 "But now I am going to Him who sent Me; and none of you asks Me, 'Where are You going?'6 But because I have said these things to you, sorrow has filled your heart.7 But I tell you the truth, it is to your advantage that I go away; for if I do not go away, the Helper will not come to you; but if I go, I will send Him to you.8 And He, when He comes, will convict the world concerning sin and righteousness and judgment;9 concerning sin, because they do not believe in Me;10 and concerning righteousness, because I go to the Father and you no longer see Me;11 and concerning judgment, because the ruler of this world has been judged.
12 "I have many more things to say to you, but you cannot bear them now.13 But when He, the Spirit of truth, comes, He will guide you into all the truth; for He will not speak on His own initiative, but whatever He hears, He will speak; and He will disclose to you what is to come.14 He will glorify Me, for He will take of Mine and will disclose it to you.15 All things that the Father has are Mine; therefore I said that He takes of Mine and will disclose it to you.
Jesus' Death and Resurrection Foretold
16 "A little while, and you will no longer see Me; and again a little while, and you will see Me."17 Some of His disciples then said to one another, "What is this thing He is telling us, 'A little while, and you will not see Me; and again a little while, and you will see Me'; and, 'because I go to the Father'?"18 So they were saying, "What is this that He says, 'A little while'? We do not know what He is talking about."19 Jesus knew that they wished to question Him, and He said to them, "Are you deliberating together about this, that I said, 'A little while, and you will not see Me, and again a little while, and you will see Me'?20 Truly, truly, I say to you, that you will weep and lament, but the world will rejoice; you will grieve, but your grief will be turned into joy.21 Whenever a woman is in labor she has pain, because her hour has come; but when she gives birth to the child, she no longer remembers the anguish because of the joy that a child has been born into the world.22 Therefore you too have grief now; but I will see you again, and your heart will rejoice, and no one will take your joy away from you.
Prayer Promises
23 In that day you will not question Me about anything. Truly, truly, I say to you, if you ask the Father for anything in My name, He will give it to you.24 Until now you have asked for nothing in My name; ask and you will receive, so that your joy may be made full.
25 "These things I have spoken to you in figurative language; an hour is coming when I will no longer speak to you in figurative language, but will tell you plainly of the Father.26 In that day you will ask in My name, and I do not say to you that I will request of the Father on your behalf;27 for the Father Himself loves you, because you have loved Me and have believed that I came forth from the Father.28 I came forth from the Father and have come into the world; I am leaving the world again and going to the Father."
29 His disciples *said, "Lo, now You are speaking plainly and are not using a figure of speech.30 Now we know that You know all things, and have no need for anyone to question You; by this we believe that You came from God."31 Jesus answered them, "Do you now believe?32 Behold, an hour is coming, and has already come, for you to be scattered, each to his own home, and to leave Me alone; and yet I am not alone, because the Father is with Me.33 These things I have spoken to you, so that in Me you may have peace. In the world you have tribulation, but take courage; I have overcome the world."