Joh 2
Jesu Lọ sí Ibi Igbeyawo Kan ní Kana
1 NI ijọ kẹta a si nṣe igbeyawo kan ni Kana ti Galili; iya Jesu si mbẹ nibẹ̀: 2 A si pè Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu, si ibi igbeyawo. 3 Nigbati waini si tan, iya Jesu wi fun u pe, Nwọn kò ni waini. 4 Jesu wi fun u pe, Kini ṣe temi tirẹ, obinrin yi? wakati mi kò iti de. 5 Iya rẹ̀ wi fun awọn iranṣẹ pe, Ohunkohun ti o ba wi fun nyin, ẹ ṣe e. 6 Ikoko okuta omi mẹfa li a si gbé kalẹ nibẹ̀, gẹgẹ bi iṣe ìwẹnu awọn Ju, ọkọkan nwọn gbà to ìwọn ládugbó meji tabi mẹta. 7 Jesu wi fun wọn pe, Ẹ pọn omi kun ikoko wọnni. Nwọn si kún wọn titi de eti. 8 O si wi fun wọn pe, Ẹ bù u jade nisisiyi, ki ẹ si gbé e tọ̀ olori àse lọ. Nwọn si gbé e lọ. 9 Bi olori àse si ti tọ́ omi ti a sọ di waini wò, ti ko si mọ̀ ibi ti o ti wá (ṣugbọn awọn iranṣẹ ti o bù omi na wá mọ̀), olori àse pè ọkọ iyawo, 10 O si wi fun u pe, Olukuluku enia a mã kọ́ gbé waini rere kalẹ; nigbati awọn enia ba si mu yó tan, nigbana ni imu eyi ti kò dara tobẹ̃ wá: ṣugbọn iwọ ti pa waini daradara yi mọ́ titi o fi di isisiyi. 11 Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́.
12 Lẹhin eyi, o sọkalẹ lọ si Kapernamu, on ati iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: nwọn kò si gbé ibẹ̀ li ọjọ pupọ.Jesu Lòdì sí Lílò tí Wọn Ń Lo Tẹmpili Bí Ọjà
(Mat 21:12-13; Mak 11:15-17; Luk 19:45-46)
13 Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile, Jesu si goke lọ si Jerusalemu, 14 O si ri awọn ti ntà malu, ati agutan, ati àdaba ni tẹmpili, ati awọn onipaṣipàrọ owo joko: 15 O si fi okùn tẹrẹ ṣe paṣan, o si lé gbogbo wọn jade kuro ninu tẹmpili, ati agutan ati malu; o si dà owo awọn onipaṣipàrọ owo nù, o si bì tabili wọn ṣubu. 16 O si wi fun awọn ti ntà àdaba pe, Ẹ gbe nkan wọnyi kuro nihin; ẹ máṣe sọ ile Baba mi di ile ọjà tità. 17 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ranti pe, a ti kọ ọ pe, Itara ile rẹ jẹ mi run. 18 Nigbana li awọn Ju dahùn, nwọn si wi fun u pe Àmi wo ni iwọ fi hàn wa, ti iwọ fi nṣe nkan wọnyi? 19 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ wó tẹmpili yi palẹ̀, ni ijọ mẹta Emi o si gbé e ró. 20 Nigbana li awọn Ju wipe, Ọdún mẹrindiladọta li a fi kọ́ tẹmpili yi, iwọ o ha si gbé e ró ni ijọ mẹta? 21 Ṣugbọn on nsọ ti tẹmpili ara rẹ̀.
22 Nitorina nigbati o jinde kuro ninu okú, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ranti pe, o ti sọ eyi fun wọn; nwọn si gbà iwe-mimọ́ gbọ́, ati ọ̀rọ ti Jesu ti sọ.Jesu Mọ Inú Gbogbo Eniyan
23 Nigbati o si wà ni Jerusalemu, ni ajọ irekọja, lakoko ajọ na, ọ̀pọ enia gbà orukọ rẹ̀ gbọ nigbati nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀ ti o ṣe. 24 Ṣugbọn Jesu kò gbé ara le wọn, nitoriti o mọ̀ gbogbo enia. 25 On ko si wa ki ẹnikẹni ki o jẹri enia fun on: nitoriti on mọ̀ ohun ti mbẹ ninu enia.
John 2
Miracle at Cana
1 On the third day there was a wedding in Cana of Galilee, and the mother of Jesus was there;2 and both Jesus and His disciples were invited to the wedding.3 When the wine ran out, the mother of Jesus *said to Him, "They have no wine."4 And Jesus *said to her, "Woman, what does that have to do with us? My hour has not yet come."5 His mother *said to the servants, "Whatever He says to you, do it."6 Now there were six stone waterpots set there for the Jewish custom of purification, containing twenty or thirty gallons each.7 Jesus *said to them, "Fill the waterpots with water." So they filled them up to the brim.8 And He *said to them, "Draw some out now and take it to the theadwaiter." So they took it to him. 9 When the headwaiter tasted the water which had become wine, and did not know where it came from (but the servants who had drawn the water knew), the headwaiter *called the bridegroom,10 and *said to him, "Every man serves the good wine first, and when the people have drunk freely, then he serves the poorer wine; but you have kept the good wine until now."11 This beginning of His signs Jesus did in Cana of Galilee, and manifested His glory, and His disciples believed in Him.
12 After this He went down to Capernaum, He and His mother and His brothers and His disciples; and they stayed there a few days.
First Passover-Cleansing the Temple
13 The Passover of the Jews was near, and Jesus went up to Jerusalem.14 And He found in the temple those who were selling oxen and sheep and doves, and the money changers seated at their tables. 15 And He made a scourge of cords, and drove them all out of the temple, with the sheep and the oxen; and He poured out the coins of the money changers and overturned their tables;16 and to those who were selling the doves He said, "Take these things away; stop making My Father's house a place of business."17 His disciples remembered that it was written, "ZEAL FOR YOUR HOUSE WILL CONSUME ME."18 The Jews then said to Him, "What sign do You show us as your authority for doing these things?"19 Jesus answered them, "Destroy this temple, and in three days I will raise it up."20 The Jews then said, "It took forty-six years to build this temple, and will You raise it up in three days?"21 But He was speaking of the temple of His body.22 So when He was raised from the dead, His disciples remembered that He said this; and they believed the Scripture and the word which Jesus had spoken.
23 Now when He was in Jerusalem at the Passover, during the feast, many believed in His name, observing His signs which He was doing.24 But Jesus, on His part, was not entrusting Himself to them, for He knew all men,25 and because He did not need anyone to testify concerning man, for He Himself knew what was in man.