Joh 3
Jesu ati Nikodemu
1 ỌKUNRIN kan si wà ninu awọn Farisi, ti a npè ni Nikodemu, ijoye kan ninu awọn Ju: 2 On na li o tọ̀ Jesu wá li oru, o si wi fun u pe, Rabbi, awa mọ̀ pe olukọni lati ọdọ Ọlọrun wá ni iwọ iṣe: nitoripe kò si ẹniti o le ṣe iṣẹ àmi wọnyi ti iwọ nṣe, bikoṣepe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. 3 Jesu dahùn o si wi fun u pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a tún enia bí, on kò le ri ijọba Ọlọrun. 4 Nikodemu wi fun u pe, A o ti ṣe le tún enia bí, nigbati o di agbalagba tan? o ha le wọ̀ inu iya rẹ̀ lọ nigba keji, ki a si bí i? 5 Jesu dahùn wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a fi omi ati Ẹmi bi enia, on kò le wọ̀ ijọba Ọlọrun. 6 Eyiti a bí nipa ti ara, ara ni; eyiti a si bí nipa ti Ẹmí, ẹmí ni. 7 Ki ẹnu ki o máṣe yà ọ, nitori mo wi fun ọ pe, A kò le ṣe alaitún nyin bí. 8 Afẹfẹ nfẹ si ibi ti o gbé wù u, iwọ si ngbọ́ iró rẹ̀, ṣugbọn iwọ kò mọ̀ ibi ti o ti wá, ati ibi ti o gbé nlọ: gẹgẹ bẹ̃ni olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ẹmí. 9 Nikodemu dahùn, o si wi fun u pe, Nkan wọnyi yio ti ṣe le ri bẹ̃? 10 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ṣe olukọni ni Israeli ni iwọ iṣe, o kò si mọ̀ nkan wọnyi? 11 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Awa nsọ eyiti awa mọ̀, a si njẹri eyiti awa ti ri; ẹnyin kò si gbà ẹri wa. 12 Bi mo ba sọ̀ ohun ti aiye yi fun nyin, ti ẹnyin kò si gbagbọ́, ẹnyin o ti ṣe gbagbọ́ bi mo ba sọ ohun ti ọrun fun nyin? 13 Ko si si ẹniti o gòke re ọrun, bikoṣe ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ani Ọmọ-enia ti mbẹ li ọrun. 14 Bi Mose si ti gbé ejò soke li aginjù, gẹgẹ bẹ̃li a kò le ṣe alaigbé Ọmọ-enia soke pẹlu: 15 Ki ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ, ki o má ba ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun. 16 Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun. 17 Nitori Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ si aiye lati da araiye lẹjọ; ṣugbọn ki a le ti ipasẹ rẹ̀ gbà araiye là. 18 Ẹniti o ba gbà a gbọ́, a ko ni da a lẹjọ; ṣugbọn a ti da ẹniti kò gbà a gbọ́ lẹjọ na, nitoriti kò gbà orukọ Ọmọ bíbi kanṣoṣo ti Ọlọrun gbọ́. 19 Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹ òkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru. 20 Nitori olukuluku ẹniti o ba hùwa buburu ni ikorira imọlẹ, ki isi wá si imọlẹ, ki a máṣe ba iṣẹ rẹ̀ wí.
21 Ṣugbọn ẹniti o ba nṣe otitọ ni iwá si imọlẹ, ki iṣẹ rẹ̀ ki o le fi ara hàn pe, a ṣe wọn nipa ti Ọlọrun.Johanu Tún Sọ̀rọ̀ nípa Jesu
22 Lẹhin nkan wọnyi Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá si ilẹ Judea; o si duro pẹlu wọn nibẹ o si baptisi. 23 Johanu pẹlu si mbaptisi ni Ainoni, li àgbegbe Salimu, nitoriti omi pipọ wà nibẹ̀: nwọn si nwá, a si baptisi wọn. 24 Nitoriti a kò ti isọ Johanu sinu tubu. 25 Nigbana ni iyàn kan wà larin awọn ọmọ-ẹhin Johanu, pẹlu Ju kan niti ìwẹnu. 26 Nwọn si tọ̀ Johanu wá, nwọn si wi fun u pe, Rabbi, ẹniti o ti wà pẹlu rẹ loke odò Jordani, ti iwọ ti jẹrí rẹ̀, wo o, on mbaptisi, gbogbo enia si ntọ̀ ọ̀ wá. 27 Johanu dahùn o si wipe, Enia ko le ri nkankan gbà, bikoṣepe a ba ti fifun u lati ọrun wá. 28 Ẹnyin tikaranyin jẹri mi, pe mo wipe, Emi kì iṣe Kristi na, ṣugbọn pe a rán mi ṣiwaju rẹ̀. 29 Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun.
30 On kò le ṣaima pọsi i, ṣugbọn emi kò le ṣaima rẹ̀hin.Ipò Ẹni Tí Ó Wá láti Ọ̀run
31 Ẹniti o ti oke wá ju gbogbo enia lọ: ẹniti o ti aiye wá ti aiye ni, a si ma sọ̀ ohun ti aiye: ẹniti o ti ọrun wá ju gbogbo enia lọ. 32 Ohun ti o ti ri ti o si ti gbọ́ eyina si li on njẹri rẹ̀; ko si si ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀. 33 Ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀ fi edidi di i pe, otitọ li Ọlọrun. 34 Nitori ẹniti Ọlọrun ti rán nsọ ọ̀rọ Ọlọrun: nitoriti Ọlọrun kò fi Ẹmí fun u nipa oṣuwọn. 35 Baba fẹ Ọmọ, o si ti fi ohun gbogbo le e lọwọ. 36 Ẹniti o ba gbà Ọmọ gbọ́, o ni iye ainipẹkun: ẹniti kò ba si gbà Ọmọ gbọ, kì yio ri ìye; ṣugbọn ibinu Ọlọrun mbẹ lori rẹ̀.
John 3
The New Birth
1 Now there was a man of the Pharisees, named Nicodemus, a ruler of the Jews;2 this man came to Jesus by night and said to Him, "Rabbi, we know that You have come from God as a teacher; for no one can do these signs that You do unless God is with him."3 Jesus answered and said to him, "Truly, truly, I say to you, unless one is born again he cannot see the kingdom of God."
4 Nicodemus *said to Him, "How can a man be born when he is old? He cannot enter a second time into his mother's womb and be born, can he?"5 Jesus answered, "Truly, truly, I say to you, unless one is born of water and the Spirit he cannot enter into the kingdom of God.6 That which is born of the flesh is flesh, and that which is born of the Spirit is spirit.7 Do not be amazed that I said to you, 'You must be born again.'8 The wind blows where it wishes and you hear the sound of it, but do not know where it comes from and where it is going; so is everyone who is born of the Spirit."
9 Nicodemus said to Him, "How can these things be?"10 Jesus answered and said to him, "Are you the teacher of Israel and do not understand these things?11 Truly, truly, I say to you, we speak of what we know and testify of what we have seen, and you do not accept our testimony.12 If I told you earthly things and you do not believe, how will you believe if I tell you heavenly things?13 No one has ascended into heaven, but He who descended from heaven: the Son of Man.14 As Moses lifted up the serpent in the wilderness, even so must the Son of Man be lifted up;15 so that whoever tbelieves will in Him have eternal life.
16 "For God so loved the world, that He gave His only begotten Son, that whoever believes in Him shall not perish, but have eternal life.17 For God did not send the Son into the world to judge the world, but that the world might be saved through Him.18 He who believes in Him is not judged; he who does not believe has been judged already, because he has not believed in the name of the only begotten Son of God.19 This is the judgment, that the Light has come into the world, and men loved the darkness rather than the Light, for their deeds were evil.20 For everyone who does evil hates the Light, and does not come to the Light for fear that his deeds will be exposed.21 But he who practices the truth comes to the Light, so that his deeds may be manifested as having been wrought in God."
John's Last Testimony
22 After these things Jesus and His disciples came into the land of Judea, and there He was spending time with them and baptizing.23 John also was baptizing in Aenon near Salim, because there was much water there; and people were coming and were being baptized-24 for John had not yet been thrown into prison.
25 Therefore there arose a discussion on the part of John's disciples with a Jew about purification.26 And they came to John and said to him, "Rabbi, He who was with you beyond the Jordan, to whom you have testified, behold, He is baptizing and all are coming to Him."27 John answered and said, "A man can receive nothing unless it has been given him from heaven.28 You yourselves are my witnesses that I said, 'I am not the Christ,' but, 'I have been sent ahead of Him.'29 He who has the bride is the bridegroom; but the friend of the bridegroom, who stands and hears him, rejoices greatly because of the bridegroom's voice. So this joy of mine has been made full.30 He must increase, but I must decrease.
31 "He who comes from above is above all, he who is of the earth is from the earth and speaks of the earth. He who comes from heaven is above all.32 What He has seen and heard, of that He testifies; and no one receives His testimony.33 He who has received His testimony has set his seal to this, that God is true.34 For He whom God has sent speaks the words of God; for He gives the Spirit without measure.35 The Father loves the Son and has given all things into His hand.36 He who believes in the Son has eternal life; but he who does not obey the Son will not see life, but the wrath of God abides on him."