Joh 4
Jesu Bá Obinrin Ará Samaria Sọ̀rọ̀
1 NITORINA nigbati Oluwa ti mọ̀ bi awọn Farisi ti gbọ́ pe, Jesu nṣe o si mbaptisi awọn ọmọ-ẹhin pupọ jù Johanu lọ, 2 (Ṣugbọn Jesu tikararẹ̀ kò baptisi bikoṣe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,) 3 O fi Judea silẹ, o si tún lọ si Galili. 4 On kò si le ṣaima kọja lãrin Samaria. 5 Nigbana li o de ilu Samaria kan, ti a npè ni Sikari, ti o sunmọ eti ilẹ biri nì, ti Jakọbu ti fifun Josefu, ọmọ rẹ̀. 6 Kanga Jakọbu si wà nibẹ̀. Nitorina bi o ti rẹ̀ Jesu tan nitori ìrin rẹ̀, bẹ̀li o joko leti kanga: o si jẹ ìwọn wakati kẹfa ọjọ. 7 Obinrin kan, ara Samaria, si wá lati pọn omi: Jesu wi fun u pe, Fun mi mu. 8 (Nitori awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti lọ si ilu lọ irà onjẹ.) 9 Nigbana li obinrin ara Samaria na wi fun u pe, Ẽti ri ti iwọ ti iṣe Ju, fi mbère ohun mimu lọwọ mi, emi ẹniti iṣe obinrin ara Samaria? nitoriti awọn Ju ki iba awọn ara Samaria da nkan pọ̀. 10 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ibaṣepe iwọ mọ̀ ẹ̀bun Ọlọrun, ati ẹniti o wi fun ọ pe, Fun mi mu, iwọ iba si ti bère lọwọ rẹ̀, on iba ti fi omi ìye fun ọ. 11 Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, iwọ kò ni nkan ti iwọ o fi fà omi, bẹ̃ni kanga na jìn: nibo ni iwọ gbé ti ri omi ìye na? 12 Iwọ pọ̀ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹniti o fun wa ni kanga na, ti on tikararẹ̀ mu ninu rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ẹran rẹ̀? 13 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi yi, orùngbẹ yio si tún gbẹ ẹ: 14 Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun. 15 Obinrin na si wi fun u pe, Ọgbẹni, fun mi li omi yi, ki orùngbẹ ki o màṣe gbẹ mi, ki emi ki o má si wá fà omi nihin. 16 Jesu wi fun u pe, Lọ ipè ọkọ rẹ, ki o si wá si ihinyi. 17 Obinrin na dahùn, o si wi fun u pe, Emi kò li ọkọ. Jesu wi fun u pe, Iwọ wi rere pe, emi kò li ọkọ: 18 Nitoriti iwọ ti li ọkọ marun ri; ẹniti iwọ si ni nisisiyi kì iṣe ọkọ rẹ; iwọ sọ otitọ li eyini. 19 Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, mo woye pe, woli ni iwọ iṣe. 20 Awọn baba wa sìn lori òke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sìn. 21 Jesu wi fun u pe, Gbà mi gbọ́, obinrin yi, wakati na mbọ̀, nigbati kì yio ṣe lori òke yi, tabi Jerusalemu, li ẹnyin o ma sìn Baba. 22 Ẹnyin nsìn ohun ti ẹnyin kò mọ̀: awa nsìn ohun ti awa mọ̀: nitori igbala ti ọdọ awọn Ju wá. 23 Ṣugbọn wakati mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sìn Baba li ẹmí ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sìn on. 24 Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ. 25 Obinrin na wi fun u pe, mo mọ̀ pe Messia mbọ̀ wá, ti a npè ni Kristi: nigbati on ba de, yio sọ ohun gbogbo fun wa. 26 Jesu wi fun u pe, Emi ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi li on. 27 Lori eyi li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ de, ẹnu si yà wọn, pe o mba obinrin sọ̀rọ: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o wipe, Kini iwọ nwá? tabi, Ẽṣe ti iwọ fi mba a sọ̀rọ? 28 Nigbana li obinrin na fi ladugbo rẹ̀ silẹ, o si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n lọ si ilu, o si wi fun awọn enia pe, 29 Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na? 30 Nigbana ni nwọn ti ilu jade, nwọn si tọ̀ ọ wá. 31 Lãrin eyi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nrọ̀ ọ, wipe, Rabbi, jẹun. 32 Ṣugbọn o wi fun wọn pe, emi li onjẹ lati jẹ, ti ẹnyin kò mọ̀. 33 Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mbi ara wọn lère wipe, Ẹnikan mú onjẹ fun u wá lati jẹ bi? 34 Jesu wi fun wọn pe, Onjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹniti o rán mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀. 35 Ẹnyin kò ha nwipe, O kù oṣù mẹrin, ikorè yio si de? wo o, mo wi fun nyin, Ẹ gbé oju nyin soke, ki ẹ si wó oko; nitoriti nwọn ti funfun fun ikore na. 36 Ẹniti nkorè ngba owo ọ̀ya, o si nkó eso jọ si ìye ainipẹkun: ki ẹniti o nfunrugbin ati ẹniti nkore le jọ mã yọ̀ pọ̀. 37 Nitori ninu eyi ni ọ̀rọ na fi jẹ otitọ: Ẹnikan li o fọnrugbin, ẹlomiran li o si nkòre jọ. 38 Mo rán nyin lọ ikore ohun ti ẹ kò ṣiṣẹ le lori: awọn ẹlomiran ti ṣiṣẹ, ẹnyin si wọ̀ inu iṣẹ wọn lọ. 39 Ọpọ awọn ara Samaria lati ilu na wá si gbà a gbọ́, nitori ọ̀rọ obinrin na, o jẹri pe, O sọ gbogbo ohun ti mo ti ṣe fun mi. 40 Nitorina, nigbati awọn ara Samaria wá sọdọ rẹ̀, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o ba wọn joko: o si gbé ibẹ̀ ni ijọ meji. 41 Awọn ọ̀pọlọpọ si i si gbagbọ́ nitori ọ̀rọ rẹ̀;
42 Nwọn si wi fun obinrin na pe, Ki iṣe nitori ọrọ rẹ mọ li awa ṣe gbagbọ: nitoriti awa tikarawa ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, awa si mọ̀ pe, nitõtọ eyi ni Kristi na, Olugbala araiye.Jesu Wo Ọmọ Ìjòyè kan Sàn
43 Lẹhin ijọ meji o si ti ibẹ̀ kuro, o lọ si Galili. 44 Nitori Jesu tikararẹ̀ ti jẹri wipe, Woli ki ini ọlá ni ilẹ on tikararẹ̀. 45 Nitorina nigbati o de Galili, awọn ara Galili gbà a, nitoriti nwọn ti ri ohun gbogbo ti o ṣe ni Jerusalemu nigba ajọ; nitori awọn tikarawọn lọ si ajọ pẹlu. 46 Bẹ̃ni Jesu tún wà si Kana ti Galili, nibiti o gbé sọ omi di waini. ọkunrin ọlọla kan si wà, ẹniti ara ọmọ rẹ̀ kò da ni Kapernaumu. 47 Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Judea wá si Galili, o tọ̀ ọ wá, o si mbẹ̀ ẹ, ki o le sọkalẹ wá ki o mu ọmọ on larada: nitoriti o wà li oju ikú. 48 Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Bikoṣepe ẹnyin ba ri àmi ati iṣẹ iyanu, ẹnyin kì yio gbagbọ́ lai. 49 Ọkunrin ọlọla na wi fun u pe, Oluwa, sọkalẹ wá, ki ọmọ mi ki o to ku. 50 Jesu wi fun u pe, Mã ba ọ̀na rẹ lọ; ọmọ rẹ yè. ọkunrin na si gbà ọ̀rọ ti Jesu sọ fun u gbọ́, o si lọ. 51 Bi o si ti nsọkalẹ lọ, awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pade rẹ̀, nwọn si wi fun u pe, ọmọ rẹ yè. 52 Nigbana li o bère wakati ti o bẹ̀rẹ si isàn lọwọ wọn. Nwọn si wi fun u pe, Li ana, ni wakati keje, ni ibà na fi i silẹ. 53 Bẹ̃ni baba na mọ̀ pe, ni wakati kanna ni, ninu eyi ti Jesu wi fun u pe, Ọmọ rẹ yè: on tikararẹ̀ si gbagbọ́, ati gbogbo ile rẹ̀. 54 Eyi ni iṣẹ́ ami keji, ti Jesu ṣe nigbati o ti Judea jade wá si Galili.
John 4
Jesus Goes to Galilee
1 Therefore when the Lord knew that the Pharisees had heard that Jesus was making and baptizing more disciples than John2 (although Jesus Himself was not baptizing, but His disciples were),3 He left Judea and went away again into Galilee.4 And He had to pass through Samaria.5 So He *came to a city of Samaria called Sychar, near the parcel of ground that Jacob gave to his son Joseph;6 and Jacob's well was there. So Jesus, being wearied from His journey, was sitting thus by the well. It was about tthe sixth hour.
The Woman of Samaria
7 There *came a woman of Samaria to draw water. Jesus *said to her, "Give Me a drink."8 For His disciples had gone away into the city to buy food.9 Therefore the Samaritan woman *said to Him, "How is it that You, being a Jew, ask me for a drink since I am a Samaritan woman?" (For Jews have no dealings with Samaritans.)10 Jesus answered and said to her, "If you knew the gift of God, and who it is who says to you, 'Give Me a drink,' you would have asked Him, and He would have given you living water."11 She *said to Him, "Sir, You have nothing to draw with and the well is deep; where then do You get that living water?12 You are not greater than our father Jacob, are You, who gave us the well, and drank of it himself and his sons and his cattle?"13 Jesus answered and said to her, "Everyone who drinks of this water will thirst again;14 but whoever drinks of the water that I will give him shall never thirst; but the water that I will give him will become in him a well of water springing up to eternal life."
15 The woman *said to Him, "Sir, give me this water, so I will not be thirsty nor come all the way here to draw."16 He *said to her, "Go, call your husband and come here."17 The woman answered and said, "I have no husband." Jesus *said to her, "You have correctly said, 'I have no husband';18 for you have had five husbands, and the one whom you now have is not your husband; this you have said truly."19 The woman *said to Him, "Sir, I perceive that You are a prophet.20 Our fathers worshiped in this mountain, and you people say that in Jerusalem is the place where men ought to worship."21 Jesus *said to her, "Woman, believe Me, an hour is coming when neither in this mountain nor in Jerusalem will you worship the Father.22 You worship what you do not know; we worship what we know, for salvation is from the Jews.23 But an hour is coming, and now is, when the true worshipers will worship the Father in spirit and truth; for such people the Father seeks to be His worshipers.24 God is spirit, and those who worship Him must worship in spirit and truth."25 The woman *said to Him, "I know that Messiah is coming (He who is called Christ); when that One comes, He will declare all things to us."26 Jesus *said to her, "I who speak to you am He."
27 At this point His disciples came, and they were amazed that He had been speaking with a woman, yet no one said, "What do You seek?" or, "Why do You speak with her?"28 So the woman left her waterpot, and went into the city and *said to the men,29 "Come, see a man who told me all the things that I have done; this is not the Christ, is it?"30 They went out of the city, and were coming to Him.
31 Meanwhile the disciples were urging Him, saying, "Rabbi, eat."32 But He said to them, "I have food to eat that you do not know about."33 So the disciples were saying to one another, "No one brought Him anything to eat, did he?"34 Jesus *said to them, "My food is to do the will of Him who sent Me and to accomplish His work.35 Do you not say, 'There are yet four months, and then comes the harvest'? Behold, I say to you, lift up your eyes and look on the fields, that they are white for harvest.36 Already he who reaps is receiving wages and is gathering fruit for life eternal; so that he who sows and he who reaps may rejoice together.37 For in this case the saying is true, 'One sows and another reaps.'38 I sent you to reap that for which you have not labored; others have labored and you have entered into their labor."
The Samaritans
39 From that city many of the Samaritans believed in Him because of the word of the woman who testified, "He told me all the things that I have done."40 So when the Samaritans came to Jesus, they were asking Him to stay with them; and He stayed there two days.41 Many more believed because of His word;42 and they were saying to the woman, "It is no longer because of what you said that we believe, for we have heard for ourselves and know that this One is indeed the Savior of the world."
43 After the two days He went forth from there into Galilee.44 For Jesus Himself testified that a prophet has no honor in his own country.45 So when He came to Galilee, the Galileans received Him, having seen all the things that He did in Jerusalem at the feast; for they themselves also went to the feast.
Healing a Nobleman's Son
46 Therefore He came again to Cana of Galilee where He had made the water wine. And there was a royal official whose son was sick at Capernaum.47 When he heard that Jesus had come out of Judea into Galilee, he went to Him and was imploring Him to come down and heal his son; for he was at the point of death.48 So Jesus said to him, "Unless you people see signs and wonders, you simply will not believe."49 The royal official *said to Him, "Sir, come down before my child dies."50 Jesus *said to him, "Go; your son lives." The man believed the word that Jesus spoke to him and started off.51 As he was now going down, his slaves met him, saying that his son was living.52 So he inquired of them the hour when he began to get better. Then they said to him, "Yesterday at the tseventh hour the fever left him."53 So the father knew that it was at that hour in which Jesus said to him, "Your son lives"; and he himself believed and his whole household.54 This is again a second sign that Jesus performed when He had come out of Judea into Galilee.