Joh 6
Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) Eniyan
(Mat 14:13-21; Mak 6:30-44; Luk 9:10-17)
1 LẸHIN nkan wọnyi, Jesu kọja si apakeji okun Galili, ti iṣe okun Tiberia. 2 Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, nitoriti nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀, ti o nṣe lara awọn alaisàn. 3 Jesu si gùn ori òke lọ, nibẹ̀ li o si gbé joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 4 Ajọ irekọja, ọdun awọn Ju, si sunmọ etile. 5 Njẹ bi Jesu ti gbé oju rẹ̀ soke, ti o si ri ọ̀pọ enia wá sọdọ rẹ̀, o wi fun Filippi pe, Nibo li a o ti rà akara, ki awọn wọnyi le jẹ? 6 O si sọ eyi lati dán a wò; nitoriti on tikararẹ̀ mọ̀ ohun ti on ó ṣe. 7 Filippi da a lohùn pe, Akara igba owo idẹ ko to fun wọn, ti olukuluku wọn iba fi mu diẹ-diẹ. 8 Ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Anderu, arakunrin Simoni Peteru wi fun u pe, 9 Ọmọdekunrin kan mbẹ nihinyi, ti o ni iṣu akara barle marun, ati ẹja kékèké meji: ṣugbọn kini wọnyi jẹ lãrin ọ̀pọ enia wọnyi bi eyi? 10 Jesu si wipe, Ẹ mu ki awọn enia na joko. Koriko pipọ si wà nibẹ̀. Bẹ̃li awọn ọkunrin na joko, ìwọn ẹgbẹdọgbọn enia ni iye. 11 Jesu si mu iṣu akara wọnni; nigbati o si ti dupẹ, o pin wọn fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si pín wọn fun awọn ti o joko; bẹ̃ gẹgẹ si li ẹja ni ìwọn bi nwọn ti nfẹ. 12 Nigbati nwọn si yó, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ kó ajẹkù ti o kù jọ, ki ohunkohun máṣe ṣegbé. 13 Bẹ̃ni nwọn kó wọn jọ nwọn si fi ajẹkù ìṣu akara barle marun na kún agbọn mejila eyi ti o ṣikù, fun awọn ti o jẹun. 14 Nitorina nigbati awọn ọkunrin na ri iṣẹ àmi ti Jesu ṣe, nwọn wipe, Lõtọ eyi ni woli na ti mbọ̀ wá aiye.
15 Nigbati Jesu si woye pe, nwọn nfẹ wá ifi agbara mu on lọ ifi jọba, o tún pada lọ sori òke on nikan.Jesu Rìn lórí Omi
(Mat 14:22-33; Mak 6:45-52)
16 Nigbati alẹ si lẹ, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ sinu okun. 17 Nwọn si bọ sinu ọkọ̀, nwọn si rekọja okun lọ si Kapernaumu. Okunkun si ti kùn, Jesu kò si ti ide ọdọ wọn. 18 Okun si nru nitori ẹfufu lile ti nfẹ. 19 Nigbati nwọn wà ọkọ̀ to bi ìwọn furlongi mẹdọgbọn tabi ọgbọ̀n, nwọn ri Jesu nrìn lori okun, o si sunmọ ọkọ̀; ẹ̀ru si bà wọn. 20 Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi ni; ẹ má bẹ̀ru.
21 Nitorina nwọn fi ayọ̀ gbà a sinu ọkọ̀: lojukanna ọkọ̀ na si de ilẹ ibiti nwọn gbé nlọ.Àwọn Eniyan Wá Jesu Rí
22 Ni ijọ keji, nigbati awọn enia ti o duro li apakeji okun ri pe, kò si ọkọ̀ miran nibẹ̀, bikoṣe ọkanna ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀, ati pe Jesu kò ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀ inu ọkọ̀ na, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nikan li o lọ; 23 (Ṣugbọn awọn ọkọ̀ miran ti Tiberia wá, leti ibi ti nwọn gbe jẹ akara, lẹhin igbati Oluwa ti dupẹ:)
24 Nitorina nigbati awọn enia ri pe, Jesu kò si nibẹ̀, tabi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn pẹlu wọ̀ ọkọ̀ lọ si Kapernaumu, nwọn nwá Jesu.Jesu ni Oúnjẹ Ìyè
25 Nigbati nwọn si ri i li apakeji okun nwọn wi fun u pe, Rabbi, nigbawo ni iwọ wá sihinyi? 26 Jesu da wọn lohùn o si wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin nwá mi, ki iṣe nitoriti ẹnyin ri iṣẹ àmi, ṣugbọn nitori ẹnyin jẹ iṣu akara wọnni, ẹnyin si yó. 27 Ẹ máṣe ṣiṣẹ fun onjẹ ti iṣegbé, ṣugbọn fun onjẹ ti iwà ti di ìye ainipẹkun, eyiti Ọmọ-enia yio fifun nyin: nitoripe on ni, ani Ọlọrun Baba ti fi edidi dí. 28 Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Kili awa o ha ṣe, ki a le ṣe iṣẹ Ọlọrun? 29 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Eyi ni iṣẹ Ọlọrun pe, ki ẹnyin ki o gbà ẹniti o rán gbọ́. 30 Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iṣẹ ami kini iwọ nṣe, ki awa le ri, ki a si gbà ọ gbọ́? iṣẹ kini iwọ ṣe? 31 Awọn baba wa jẹ manna li aginjù; gẹgẹ bi a ti kọ o pe, O fi onjẹ fun wọn jẹ lati ọrun wá. 32 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, kì iṣe Mose li o fi onjẹ nì fun nyin lati ọrun wá; ṣugbọn Baba mi li o fi onjẹ otitọ nì fun nyin lati ọrun wá. 33 Nitoripe onjẹ Ọlọrun li ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ti o si fi ìye fun araiye. 34 Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Oluwa, mã fun wa li onjẹ yi titi lai. 35 Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai. 36 Sugbọn mo wi fun nyin pe, Ẹnyin ti ri mi, ẹ kò si gbagbọ́. 37 Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri. 38 Nitori emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi. 39 Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ. 40 Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. 41 Nigbana ni awọn Ju nkùn si i, nitoriti o wipe, Emi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá. 42 Nwọn si wipe, Jesu ha kọ́ eyi, ọmọ Josefu, baba ati iya ẹniti awa mọ̀? etiṣe wipe, Emi ti ọrun sọkalẹ wá? 43 Nitorina Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe kùn lãrin ara nyin. 44 Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ mi, bikoṣepe Baba ti o rán mi fà a: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. 45 A sá ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, A o si kọ́ gbogbo wọn lati ọdọ Ọlọrun wá. Nitorina ẹnikẹni ti o ba ti gbọ́, ti a si ti ọdọ Baba kọ́, on li o ntọ̀ mi wá. 46 Koṣepe ẹnikan ti ri Baba bikoṣe ẹniti o ti ọdọ Ọlọrun wá, on li o ti ri Baba. 47 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, o ni ìye ainipẹkun. 48 Emi li onjẹ ìye. 49 Awọn baba nyin jẹ manna li aginjù, nwọn si kú. 50 Eyi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá, ki enia le mã jẹ ninu rẹ̀ ki o má si kú. 51 Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye. 52 Nitorina li awọn Ju ṣe mba ara wọn jiyàn, wipe, ọkunrin yi yio ti ṣe le fi ara rẹ̀ fun wa lati jẹ? 53 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe ẹnyin ba jẹ ara Ọmo-enia, ki ẹnyin si mu ẹ̀jẹ rẹ̀, ẹnyin kò ni ìye ninu nyin. 54 Ẹnikẹni ti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ni ìye ti kò nipẹkun; Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. 55 Nitori ara mi li ohun jijẹ nitõtọ, ati ẹ̀jẹ mi li ohun mimu nitõtọ. 56 Ẹniti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ngbé inu mi, emi si ngbé inu rẹ̀. 57 Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi. 58 Eyi si li onjẹ na ti o sọkalẹ lati ọrun wá: ki iṣe bi awọn baba nyin ti jẹ manna, ti nwọn si kú: ẹniti o ba jẹ onjẹ yi yio yè lailai.
59 Nkan wọnyi li o sọ ninu sinagogu, bi o ti nkọni ni Kapernaumu.Ọ̀rọ̀ Ìyè Ainipẹkun
60 Nitorina nigbati ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọ̀rọ ti o le li eyi; tani le gbọ́ ọ? 61 Nigbati Jesu si mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nkùn si ọ̀rọ na, o wi fun wọn pe, Eyi jẹ ikọsẹ̀ fun nyin bi? 62 Njẹ, bi ẹnyin ba si ri ti Ọmọ-enia ngòke lọ sibi ti o gbé ti wà ri nkọ́? 63 Ẹmí ni isọni di ãye; ara kò ni ère kan; ọ̀rọ wọnni ti mo sọ fun nyin, ẹmi ni, ìye si ni. 64 Ṣugbọn awọn kan wà ninu nyin ti kò gbagbọ́. Nitori Jesu mọ̀ lati ìbẹrẹ wá ẹniti nwọn iṣe ti ko gbagbọ́, ati ẹniti yio fi on hàn. 65 O si wipe, Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, kò si ẹniti o le tọ̀ mi wá, bikoṣepe a fifun u lati ọdọ Baba mi wá. 66 Nitori eyi ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pada sẹhin, nwọn kò si ba a rìn mọ́. 67 Nitorina Jesu wi fun awọn mejila pe, Ẹnyin pẹlu nfẹ lọ bi? 68 Nigbana ni Simoni Peteru da a lohùn wipe, Oluwa, Ọdọ tali awa o lọ? iwọ li o ni ọ̀rọ ìye ainipẹkun. 69 Awa si ti gbagbọ́, a si mọ̀ pe, iwọ ni Kristi na, Ọmọ Ọlọrun alãye. 70 Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin mejila kọ́ ni mo yàn, ọkan ninu nyin kò ha si yà Èṣu? 71 O nsọ ti Judasi Iskariotu ọmọ Simoni: nitoripe on li ẹniti yio fi i hàn, ọkan ninu awọn mejila.
John 6
Five Thousand Fed
1 After these things Jesus went away to the other side of the Sea of Galilee (or Tiberias).2 A large crowd followed Him, because they saw the signs which He was performing on those who were sick.3 Then Jesus went up on the mountain, and there He sat down with His disciples.4 Now the Passover, the feast of the Jews, was near.5 Therefore Jesus, lifting up His eyes and seeing that a large crowd was coming to Him, *said to Philip, "Where are we to buy bread, so that these may eat?"6 This He was saying to test him, for He Himself knew what He was intending to do.7 Philip answered Him, "Two hundred tdenarii worth of bread is not sufficient for them, for everyone to receive a little."8 One of His disciples, Andrew, Simon Peter's brother, *said to Him,9 "There is a lad here who has five barley loaves and two fish, but what are these for so many people?"10 Jesus said, "Have the people sit down." Now there was much grass in the place. So the men sat down, in number about five thousand.11 Jesus then took the loaves, and having given thanks, He distributed to those who were seated; likewise also of the fish as much as they wanted.12 When they were filled, He *said to His disciples, "Gather up the leftover fragments so that nothing will be lost."13 So they gathered them up, and filled twelve baskets with fragments from the five barley loaves which were left over by those who had eaten.14 Therefore when the people saw the sign which He had performed, they said, "This is truly the Prophet who is to come into the world."
Jesus Walks on the Water
15 So Jesus, perceiving that they were intending to come and take Him by force to make Him king, withdrew again to the mountain by Himself alone.
16 Now when evening came, His disciples went down to the sea,17 and after getting into a boat, they started to cross the sea to Capernaum. It had already become dark, and Jesus had not yet come to them.18 The sea began to be stirred up because a strong wind was blowing.19 Then, when they had rowed about three or four miles, they *saw Jesus walking on the sea and drawing near to the boat; and they were frightened.20 But He *said to them, "It is I; do not be afraid."21 So they were willing to receive Him into the boat, and immediately the boat was at the land to which they were going.
22 The next day the crowd that stood on the other side of the sea saw that there was no other small boat there, except one, and that Jesus had not entered with His disciples into the boat, but that His disciples had gone away alone.23 There came other small boats from Tiberias near to the place where they ate the bread after the Lord had given thanks.24 So when the crowd saw that Jesus was not there, nor His disciples, they themselves got into the small boats, and came to Capernaum seeking Jesus.25 When they found Him on the other side of the sea, they said to Him, "Rabbi, when did You get here?"
Words to the People
26 Jesus answered them and said, "Truly, truly, I say to you, you seek Me, not because you saw signs, but because you ate of the loaves and were filled.27 Do not work for the food which perishes, but for the food which endures to eternal life, which the Son of Man will give to you, for on Him the Father, God, has set His seal."28 Therefore they said to Him, "What shall we do, so that we may work the works of God?"29 Jesus answered and said to them, "This is the work of God, that you believe in Him whom He has sent."30 So they said to Him, "What then do You do for a sign, so that we may see, and believe You? What work do You perform?31 Our fathers ate the manna in the wilderness; as it is written, 'HE GAVE THEM BREAD OUT OF HEAVEN TO EAT.'"32 Jesus then said to them, "Truly, truly, I say to you, it is not Moses who has given you the bread out of heaven, but it is My Father who gives you the true bread out of heaven.33 For the bread of God is tthat which comes down out of heaven, and gives life to the world."34 Then they said to Him, "Lord, always give us this bread."
35 Jesus said to them, "I am the bread of life; he who comes to Me will not hunger, and he who believes in Me will never thirst.36 But I said to you that you have seen Me, and yet do not believe.37 All that the Father gives Me will come to Me, and the one who comes to Me I will certainly not cast out.38 For I have come down from heaven, not to do My own will, but the will of Him who sent Me.39 This is the will of Him who sent Me, that of all that He has given Me I lose nothing, but raise it up on the last day.40 For this is the will of My Father, that everyone who beholds the Son and believes in Him will have eternal life, and I Myself will raise him up on the last day."
Words to the Jews
41 Therefore the Jews were grumbling about Him, because He said, "I am the bread that came down out of heaven."42 They were saying, "Is not this Jesus, the son of Joseph, whose father and mother we know? How does He now say, 'I have come down out of heaven'?"43 Jesus answered and said to them, "Do not grumble among yourselves.44 No one can come to Me unless the Father who sent Me draws him; and I will raise him up on the last day.45 It is written in the prophets, 'AND THEY SHALL ALL BE TAUGHT OF GOD.' Everyone who has heard and learned from the Father, comes to Me.46 Not that anyone has seen the Father, except the One who is from God; He has seen the Father.47 Truly, truly, I say to you, he who believes has eternal life.48 I am the bread of life.49 Your fathers ate the manna in the wilderness, and they died.50 This is the bread which comes down out of heaven, so that one may eat of it and not die.51 I am the living bread that came down out of heaven; if anyone eats of this bread, he will live forever; and the bread also which I will give for the life of the world is My flesh."
52 Then the Jews began to argue with one another, saying, "How can this man give us His flesh to eat?"53 So Jesus said to them, "Truly, truly, I say to you, unless you eat the flesh of the Son of Man and drink His blood, you have no life in yourselves.54 He who eats My flesh and drinks My blood has eternal life, and I will raise him up on the last day.55 For My flesh is true food, and My blood is true drink.56 He who eats My flesh and drinks My blood abides in Me, and I in him.57 As the living Father sent Me, and I live because of the Father, so he who eats Me, he also will live because of Me.58 This is the bread which came down out of heaven; not as the fathers ate and died; he who eats this bread will live forever."
Words to the Disciples
59 These things He said in the synagogue as He taught in Capernaum.
60 Therefore many of His disciples, when they heard this said, "This is a difficult statement; who can listen to it?"61 But Jesus, conscious that His disciples grumbled at this, said to them, "Does this cause you to stumble?62 What then if you see the Son of Man ascending to where He was before?63 It is the Spirit who gives life; the flesh profits nothing; the words that I have spoken to you are spirit and are life.64 But there are some of you who do not believe." For Jesus knew from the beginning who they were who did not believe, and who it was that would betray Him.65 And He was saying, "For this reason I have said to you, that no one can come to Me unless it has been granted him from the Father."
Peter's Confession of Faith
66 As a result of this many of His disciples withdrew and were not walking with Him anymore.67 So Jesus said to the twelve, "You do not want to go away also, do you?"68 Simon Peter answered Him, "Lord, to whom shall we go? You have words of eternal life.69 We have believed and have come to know that You are the Holy One of God."70 Jesus answered them, "Did I Myself not choose you, the twelve, and yet one of you is a devil?"71 Now He meant Judas the son of Simon Iscariot, for he, one of the twelve, was going to betray Him.