previous next

Joh 8

Ìtàn Obinrin tí Ó Ṣe Àgbèrè

1 JESU si lọ si ori òke Olifi. 2 O si tún pada wá si tẹmpili ni kutukutu owurọ̀, gbogbo enia si wá sọdọ rẹ̀; o si joko, o nkọ́ wọn. 3 Awọn akọwe ati awọn Farisi si mu obinrin kan wá sọdọ rẹ̀, ti a mu ninu panṣaga; nigbati nwọn si mu u duro larin, 4 Nwọn wi fun u pe, Olukọni, a mu obinrin yi ninu panṣaga, ninu ṣiṣe e pãpã. 5 Njẹ ninu ofin, Mose paṣẹ fun wa lati sọ iru awọn bẹ̃ li okuta pa: ṣugbọn iwọ ha ti wi? 6 Eyini nwọn wi, nwọn ndán a wò, ki nwọn ba le ri ohun lati fi i sùn. Ṣugbọn Jesu bẹrẹ silẹ, o si nfi ika rẹ̀ kọwe ni ilẹ. 7 Ṣugbọn nigbati nwọn mbi i lẽre sibẹsibẹ, o gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba ṣe ailẹṣẹ ninu nyin, jẹ ki o kọ́ sọ okuta lù u. 8 O si tún bẹ̀rẹ̀ silẹ, o nkọwe ni ilẹ. 9 Nigbati nwọn gbọ eyi, nwọn si jade lọ lọkọ̃kan, bẹrẹ lati ọdọ awọn àgba titi de awọn ti o kẹhin; a si fi Jesu nikan silẹ, ati obinrin na lãrin, nibiti o ti wà. 10 Jesu si gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun u pe, Obinrin yi, awọn dà? kò si ẹnikan ti o da ọ lẹbi?

11 O wipe, Kò si ẹnikan, Oluwa. Jesu si wi fun u pe, Bẹ̃li emi na kò da ọ lẹbi: mã lọ, lati igbayi lọ má dẹṣẹ̀ mọ́.

Jesu ni Ìmọ́lẹ̀ Ayé


12 Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye. 13 Nitorina awọn Farisi wi fun u pe, Iwọ njẹri ara rẹ; ẹrí rẹ kì iṣe otitọ. 14 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Bi mo tilẹ njẹri fun ara mi, otitọ li ẹrí mi: nitoriti mo mọ̀ ibiti mo ti wá, mo si mọ̀ ibiti mo nlọ; ṣugbọn ẹnyin kò le mọ̀ ibiti mo ti wá, ati ibiti mo nlọ. 15 Ẹnyin nṣe idajọ nipa ti ara; emi kò ṣe idajọ ẹnikẹni. 16 Ṣugbọn bi emi ba si ṣe idajo, otitọ ni idajọ mi: nitori emi nikan kọ́, ṣugbọn emi ati Baba ti o rán mi. 17 Ẹ si kọ ọ pẹlu ninu ofin nyin pe, otitọ li ẹrí enia meji. 18 Emi li ẹniti njẹri ara mi, ati Baba ti o rán mi si njẹri fun mi. 19 Nitorina nwọn wi fun u pe, Nibo ni Baba rẹ wà? Jesu dahùn pe, Ẹnyin kò mọ̀ mi, bẹli ẹ kò mọ̀ Baba mi: ibaṣepe ẹnyin mọ̀ mi, ẹnyin iba si ti mọ̀ Baba mi pẹlu.

20 Ọ̀rọ wọnyi ni Jesu sọ nibi iṣura, bi o ti nkọ́ni ni tẹmpili: ẹnikẹni ko si mu u; nitori wakati rẹ̀ ko ti ide.

Ta Ni Jesu?


21 Nitorina o tun wi fun wọn pe, Emi nlọ, ẹnyin yio si wá mi, ẹ ó si kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: ibiti emi gbe nlọ, ẹnyin kì ó le wá. 22 Nitorina awọn Ju wipe, On o ha pa ara rẹ̀ bi? nitoriti o wipe, Ibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì ó le wá. 23 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti isalẹ wá; emi ti oke wá: ẹnyin jẹ ti aiye yi; emi kì iṣe ti aiye yi. 24 Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: nitori bikoṣepé ẹ ba gbagbọ́ pe, emi ni, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin. 25 Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? Jesu si wi fun wọn pe, Ani eyinì ti mo ti wi fun nyin li àtetekọṣe. 26 Mo ni ohun pupọ̀ lati sọ, ati lati ṣe idajọ nipa nyin: ṣugbọn olõtọ li ẹniti o ran mi, ohun ti emi si ti gbọ lati ọdọ rẹ̀ wá, nwọnyi li emi nsọ fun araiye. 27 Kò yé wọn pe, ti Baba li o nsọ fun wọn. 28 Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Nigbati ẹ ba gbé Ọmọ-enia soke, nigbana li ẹ o mọ̀ pe, emi ni, ati pe emi kò dá ohunkohun ṣe fun ara mi; ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi nsọ nkan wọnyi. 29 Ẹniti o rán mi si mbẹ pẹlu mi: kò jọwọ emi nikan si; nitoriti emi nṣe ohun ti o wù u nigbagbogbo.

30 Bi o ti nsọ nkan wọnyi, ọ̀pọ enia gbà a gbọ́.

Òtítọ́ yóo sọ Yín di Òmìnira


31 Nitorina Jesu wi fun awọn Ju ti o gbà a gbọ́ pe, Bi ẹnyin ba duro ninu ọ̀rọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ. 32 Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira. 33 Nwọn da a lohùn wipe, Irú-ọmọ Abrahamu li awa iṣe, awa kò si ṣe ẹrú fun ẹnikẹni ri lai: iwọ ha ṣe wipe, Ẹ o di omnira? 34 Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ. 35 Ẹrú kì si igbé ile titilai: Ọmọ ni igbe ile titilai. 36 Nitorina bi Ọmọ ba sọ nyin di omnira, ẹ ó di omnira nitõtọ. 37 Mo mọ̀ pe irú-ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe; ṣugbọn ẹ nwá ọ̀na ati pa mi, nitori ọ̀rọ mi kò ri àye ninu nyin. 38 Ohun ti emi ti ri lọdọ Baba ni mo nsọ: ẹnyin pẹlu si nṣe eyi ti ẹnyin ti gbọ lati ọdọ baba nyin. 39 Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Abrahamu ni baba wa. Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe, ẹnyin iba ṣe iṣẹ Abrahamu. 40 Ṣugbọn nisisiyi ẹnyin nwá ọ̀na ati pa mi, ẹniti o sọ otitọ fun nyin, eyi ti mo ti gbọ́ lọdọ Ọlọrun: Abrahamu kò ṣe eyi. 41 Ẹnyin nṣe iṣẹ baba nyin. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, A ko bí wa nipa panṣaga: a ni Baba kan, eyini li Ọlọrun. 42 Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe Ọlọrun ni Baba nyin, ẹnyin iba fẹran mi: nitoriti emi ti ọdọ Ọlọrun jade, mo si wá: bẹ̃li emi kò si wá fun ara mi, ṣugbọn on li o rán mi. 43 Ẽtiṣe ti ède mi kò fi yé nyin? nitori ẹ ko le gbọ́ ọ̀rọ mi ni. 44 Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹ ṣe. Apania li on iṣe lati atetekọṣe, ko si duro ni otitọ; nitoriti kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigbati o ba nṣeke, ninu ohun tirẹ̀ li o nsọ, nitori eke ni, ati baba eke. 45 Ṣugbọn nitori emi sọ otitọ fun nyin, ẹ kò si gbà mi gbọ́. 46 Tani ninu nyin ti o ti idá mi li ẹbi ẹ̀ṣẹ? Bi mo ba nsọ otitọ ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà mi gbọ́?

47 Ẹniti iṣe ti Ọlọrun, a ma gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun: nitori eyi li ẹnyin kò ṣe gbọ, nitori ẹnyin kì iṣe ti Ọlọrun.

Jesu ti wà ṣiwaju Abrahamu


48 Awọn Ju dahùn nwọn si wi fun u pe, Awa kò wi nitõtọ pe, ara Samaria ni iwọ iṣe, ati pe iwọ li ẹmi èṣu? 49 Jesu dahùn wipe, Emi kò li ẹmi èṣu; ṣugbọn emi mbọlá fun Baba mi, ẹnyin kò si bọla fun mi. 50 Emi kò wá ogo ara mi: ẹnikan mbẹ ti o nwà a ti o si nṣe idajọ. 51 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnikan ba pa ọ̀rọ mi mọ́, ki yio ri ikú lailai. 52 Awọn Ju wi fun u pe, Nigbayi ni awa mọ̀ pe iwọ li ẹmi èṣu. Abrahamu kú, ati awọn woli; iwọ si wipe, Bi ẹnikan ba pa ọ̀rọ mi mọ́, kì yio tọ́ ikú wò lailai. 53 Iwọ ha pọ̀ju Abrahamu baba wa lọ, ẹniti o kú? awọn woli si kú: tani iwọ nfi ara rẹ pè? 54 Jesu dahùn wipe, Bi mo ba nyìn ara mi li ogo, ogo mi kò jẹ nkan: Baba mi ni ẹniti nyìn mi li ogo, ẹniti ẹnyin wipe, Ọlọrun nyin ni iṣe: 55 Ẹ kò si mọ̀ ọ; ṣugbọn emi mọ̀ ọ: bi mo ba si wipe, emi kò mọ̀ ọ, emi ó di eke gẹgẹ bi ẹnyin: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, mo si pa ọ̀rọ rẹ̀ mọ́. 56 Abrahamu baba nyin yọ̀ lati ri ọjọ mi: o si ri i, o si yọ̀. 57 Nitorina awọn Ju wi fun u pe, Ọdún rẹ kò ti ito adọta, iwọ si ti ri Abrahamu? 58 Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ki Abrahamu to wà, emi ti wà. 59 Nitorina nwọn gbé okuta lati sọ lù u: ṣugbọn Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́, o si jade kuro ni tẹmpili.

John 8

The Adulterous Woman

1 But Jesus went to the Mount of Olives.2 Early in the morning He came again into the temple, and all the people were coming to Him; and He sat down and began to teach them.3 The scribes and the Pharisees *brought a woman caught in adultery, and having set her in the center of the court, 4 they *said to Him, "Teacher, this woman has been caught in adultery, in the very act.5 Now in the Law Moses commanded us to stone such women; what then do You say?"6 They were saying this, testing Him, so that they might have grounds for accusing Him. But Jesus stooped down and with His finger wrote on the ground.7 But when they persisted in asking Him, He straightened up, and said to them, "He who is without sin among you, let him be the first to throw a stone at her."8 Again He stooped down and wrote on the ground.9 When they heard it, they began to go out one by one, beginning with the older ones, and He was left alone, and the woman, where she was, in the center of the court. 10 Straightening up, Jesus said to her, "Woman, where are they? Did no one condemn you?"11 She said, "No one, Lord." And Jesus said, "I do not condemn you, either. Go. From now on sin no more."]

Jesus Is the Light of the World

12 Then Jesus again spoke to them, saying, "I am the Light of the world; he who follows Me will not walk in the darkness, but will have the Light of life."13 So the Pharisees said to Him, "You are testifying about Yourself; Your testimony is not true."14 Jesus answered and said to them, "Even if I testify about Myself, My testimony is true, for I know where I came from and where I am going; but you do not know where I come from or where I am going.15 You judge according to the flesh; I am not judging anyone.16 But even if I do judge, My judgment is true; for I am not alone in it, but I and the Father who sent Me.17 Even in your law it has been written that the testimony of two men is true.18 I am He who testifies about Myself, and the Father who sent Me testifies about Me."19 So they were saying to Him, "Where is Your Father?" Jesus answered, "You know neither Me nor My Father; if you knew Me, you would know My Father also."20 These words He spoke in the treasury, as He taught in the temple; and no one seized Him, because His hour had not yet come.

21 Then He said again to them, "I go away, and you will seek Me, and will die in your sin; where I am going, you cannot come."22 So the Jews were saying, "Surely He will not kill Himself, will He, since He says, 'Where I am going, you cannot come'?"23 And He was saying to them, "You are from below, I am from above; you are of this world, I am not of this world.24 Therefore I said to you that you will die in your sins; for unless you believe that I am He, you will die in your sins."25 So they were saying to Him, "Who are You?" Jesus said to them, "What have I been saying to you from the beginning?26 I have many things to speak and to judge concerning you, but He who sent Me is true; and the things which I heard from Him, these I speak to the world."27 They did not realize that He had been speaking to them about the Father.28 So Jesus said, "When you lift up the Son of Man, then you will know that I am He, and I do nothing on My own initiative, but I speak these things as the Father taught Me.29 And He who sent Me is with Me; He has not left Me alone, for I always do the things that are pleasing to Him."30 As He spoke these things, many came to believe in Him.

The Truth Will Make You Free

31 So Jesus was saying to those Jews who had believed Him, "If you continue in My word, then you are truly disciples of Mine;32 and you will know the truth, and the truth will make you free."33 They answered Him, "We are Abraham's descendants and have never yet been enslaved to anyone; how is it that You say, 'You will become free'?"

34 Jesus answered them, "Truly, truly, I say to you, everyone who commits sin is the slave of sin.35 The slave does not remain in the house forever; the son does remain forever.36 So if the Son makes you free, you will be free indeed.37 I know that you are Abraham's descendants; yet you seek to kill Me, because My word has no place in you.38 I speak the things which I have seen with My Father; therefore you also do the things which you heard from your father."

39 They answered and said to Him, "Abraham is our father." Jesus *said to them, "If you are Abraham's children, do the deeds of Abraham.40 But as it is, you are seeking to kill Me, a man who has told you the truth, which I heard from God; this Abraham did not do.41 You are doing the deeds of your father." They said to Him, "We were not born of fornication; we have one Father: God."42 Jesus said to them, "If God were your Father, you would love Me, for I proceeded forth and have come from God, for I have not even come on My own initiative, but He sent Me.43 Why do you not understand what I am saying? It is because you cannot hear My word.44 You are of your father the devil, and you want to do the desires of your father. He was a murderer from the beginning, and does not stand in the truth because there is no truth in him. Whenever he speaks a lie, he speaks from his own nature, for he is a liar and the father of lies.45 But because I speak the truth, you do not believe Me.46 Which one of you convicts Me of sin? If I speak truth, why do you not believe Me?47 He who is of God hears the words of God; for this reason you do not hear them, because you are not of God."

48 The Jews answered and said to Him, "Do we not say rightly that You are a Samaritan and have a demon?"49 Jesus answered, "I do not have a demon; but I honor My Father, and you dishonor Me.50 But I do not seek My glory; there is One who seeks and judges.51 Truly, truly, I say to you, if anyone keeps My word he will never see death."52 The Jews said to Him, "Now we know that You have a demon. Abraham died, and the prophets also; and You say, 'If anyone keeps My word, he will never taste of death.'53 Surely You are not greater than our father Abraham, who died? The prophets died too; whom do You make Yourself out to be? "54 Jesus answered, "If I glorify Myself, My glory is nothing; it is My Father who glorifies Me, of whom you say, 'He is our God';55 and you have not come to know Him, but I know Him; and if I say that I do not know Him, I will be a liar like you, but I do know Him and keep His word.56 Your father Abraham rejoiced to see My day, and he saw it and was glad."57 So the Jews said to Him, "You are not yet fifty years old, and have You seen Abraham?"58 Jesus said to them, "Truly, truly, I say to you, before Abraham was born, I am."59 Therefore they picked up stones to throw at Him, but Jesus hid Himself and went out of the temple.